ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“GBOGBO ILÉ ÁHÁBÙ LÓ MÁA ṢÈGBÉ”—2Ọb 9:8
ÌJỌBA ILẸ̀ JÚDÀ
Jèhóṣáfátì di ọba
nǹkan bíi 911 Ṣ.S.K.: Jèhórámù (ọmọ Jèhóṣáfátì; ọkọ Ataláyà, ọmọbìnrin Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba
nǹkan bíi 906 Ṣ.S.K.: Ahasáyà (ọmọ ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba
nǹkan bíi 905 Ṣ.S.K.: Ataláyà pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ó sì sọ ara ẹ̀ di ọba. Àmọ́, Jèhóádà Àlùfáà Àgbà gbé Jèhóáṣì ọmọ ọmọ rẹ̀ pa mọ́—2Ọb 11:1-3
898 Ṣ.S.K.: Jèhóáṣì di ọba. Jèhóádà Àlùfáà Àgbà pa Ataláyà.—2Ọb 11:4-16
ÌJỌBA ILẸ̀ ÍSÍRẸ́LÌ
nǹkan bíi 920 Ṣ.S.K.: Ahasáyà (ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba
nǹkan bíi 917 Ṣ.S.K.: Jèhórámù (ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba
nǹkan bíi 905 Ṣ.S.K.: Jéhù pa Ọba Jèhórámù ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtàwọn arákùnrin ẹ̀, ó tún pa ìyá Jèhórámù (ìyẹn Jésíbẹ́lì) àti Ọba Ahasáyà ti ilẹ̀ Júdà àtàwọn arákùnrin ẹ̀.—2Ọb 9:14–10:17
nǹkan bíi 904 Ṣ.S.K.: Jéhù di ọba