ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Wọ́n fòróró yan Jéhù ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì (1-13)

      • Jéhù pa Jèhórámù àti Ahasáyà (14-29)

      • Wọ́n pa Jésíbẹ́lì; àwọn ajá jẹ ẹran ara rẹ̀ (30-37)

2 Àwọn Ọba 9:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ohun tí a fi amọ̀ ṣe tó dà bí ìgò ńlá.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:25, 28

2 Àwọn Ọba 9:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:16, 17

2 Àwọn Ọba 9:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 22:7

2 Àwọn Ọba 9:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2011, ojú ìwé 3

2 Àwọn Ọba 9:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:16

2 Àwọn Ọba 9:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:4; 19:2; 21:15, 25; Lk 18:7

2 Àwọn Ọba 9:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:20, 21

2 Àwọn Ọba 9:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:28, 29
  • +1Ọb 16:11, 12

2 Àwọn Ọba 9:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:23
  • +2Ọb 9:3

2 Àwọn Ọba 9:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2022,

2 Àwọn Ọba 9:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 9:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2022,

2 Àwọn Ọba 9:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 21:7
  • +2Sa 15:10; 1Ọb 1:34, 39

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 3/2022,

2 Àwọn Ọba 9:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:16
  • +2Ọb 8:28
  • +1Ọb 19:15; 2Ọb 8:15; 10:32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2011, ojú ìwé 3

2 Àwọn Ọba 9:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:17, 18; 1Ọb 21:1
  • +2Kr 22:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2011, ojú ìwé 3

2 Àwọn Ọba 9:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2011, ojú ìwé 3-4

    6/15/1993, ojú ìwé 6-7

2 Àwọn Ọba 9:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọmọ.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2011, ojú ìwé 4

    8/1/2005, ojú ìwé 11

    1/1/1998, ojú ìwé 13-14

2 Àwọn Ọba 9:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:25, 29; 2Kr 22:7
  • +1Ọb 21:1, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/15/1993, ojú ìwé 6-7

2 Àwọn Ọba 9:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:31; 18:4; 19:2; 21:7
  • +Le 20:6; Di 18:10; 1Ọb 18:19

2 Àwọn Ọba 9:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọrun.”

2 Àwọn Ọba 9:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ọ̀wọ́ ẹṣin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń fà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:19
  • +1Ọb 21:29

2 Àwọn Ọba 9:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:8, 10; Sm 9:12; 72:14
  • +Jẹ 9:5; Le 24:17
  • +1Ọb 21:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 13-14

2 Àwọn Ọba 9:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:29; 2Kr 22:7
  • +Joṣ 17:11

2 Àwọn Ọba 9:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:7

2 Àwọn Ọba 9:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:24; 2Kr 22:2

2 Àwọn Ọba 9:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tọ́ lẹ́ẹ̀dì.”

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:1
  • +1Ọb 16:31; 21:25

2 Àwọn Ọba 9:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:15-19

2 Àwọn Ọba 9:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:26; Sm 94:16

2 Àwọn Ọba 9:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:31

2 Àwọn Ọba 9:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 9:10

2 Àwọn Ọba 9:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 55:10, 11
  • +1Ọb 21:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 120-121

Àwọn míì

2 Ọba 9:12Ọb 8:25, 28
2 Ọba 9:21Ọb 19:16, 17
2 Ọba 9:32Kr 22:7
2 Ọba 9:61Ọb 19:16
2 Ọba 9:71Ọb 18:4; 19:2; 21:15, 25; Lk 18:7
2 Ọba 9:81Ọb 21:20, 21
2 Ọba 9:91Ọb 15:28, 29
2 Ọba 9:91Ọb 16:11, 12
2 Ọba 9:101Ọb 21:23
2 Ọba 9:102Ọb 9:3
2 Ọba 9:122Ọb 9:6
2 Ọba 9:13Mt 21:7
2 Ọba 9:132Sa 15:10; 1Ọb 1:34, 39
2 Ọba 9:141Ọb 19:16
2 Ọba 9:142Ọb 8:28
2 Ọba 9:141Ọb 19:15; 2Ọb 8:15; 10:32
2 Ọba 9:15Joṣ 19:17, 18; 1Ọb 21:1
2 Ọba 9:152Kr 22:6
2 Ọba 9:212Ọb 8:25, 29; 2Kr 22:7
2 Ọba 9:211Ọb 21:1, 15
2 Ọba 9:221Ọb 16:31; 18:4; 19:2; 21:7
2 Ọba 9:22Le 20:6; Di 18:10; 1Ọb 18:19
2 Ọba 9:251Ọb 21:19
2 Ọba 9:251Ọb 21:29
2 Ọba 9:26Jẹ 4:8, 10; Sm 9:12; 72:14
2 Ọba 9:26Jẹ 9:5; Le 24:17
2 Ọba 9:261Ọb 21:24
2 Ọba 9:272Ọb 8:29; 2Kr 22:7
2 Ọba 9:27Joṣ 17:11
2 Ọba 9:282Sa 5:7
2 Ọba 9:292Ọb 8:24; 2Kr 22:2
2 Ọba 9:301Ọb 21:1
2 Ọba 9:301Ọb 16:31; 21:25
2 Ọba 9:311Ọb 16:15-19
2 Ọba 9:32Ẹk 32:26; Sm 94:16
2 Ọba 9:341Ọb 16:31
2 Ọba 9:352Ọb 9:10
2 Ọba 9:36Ais 55:10, 11
2 Ọba 9:361Ọb 21:23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 9:1-37

Àwọn Ọba Kejì

9 Lẹ́yìn náà, wòlíì Èlíṣà pe ọ̀kan lára àwọn ọmọ wòlíì, ó sì sọ fún un pé: “Ká aṣọ rẹ mọ́ra, kí o sì yára mú ṣágo* òróró yìí lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 2 Tí o bá ti dé ibẹ̀, kí o wá Jéhù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọmọ Nímúṣì; wọlé lọ bá a, kí o ní kó dìde kúrò láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí o sì mú un lọ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún. 3 Kí o mú ṣágo òróró náà, kí o sì dà á sí i lórí, kí o wá sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.”’+ Lẹ́yìn náà, ṣí ilẹ̀kùn, kí o sì tètè sá lọ.”

4 Torí náà, ìránṣẹ́ wòlíì náà bọ́ sọ́nà, ó sì forí lé Ramoti-gílíádì. 5 Nígbà tó dé ibẹ̀, àwọn olórí ọmọ ogun wà ní ìjókòó. Ló bá sọ pé: “Iṣẹ́ kan wà tí wọ́n ní kí n jẹ́ fún ọ, balógun.” Jéhù béèrè pé: “Èwo nínú wa?” Ó dáhùn pé: “Balógun, ìwọ ni.” 6 Nítorí náà, Jéhù dìde, ó wọnú ilé; ìránṣẹ́ náà da òróró sí i lórí, ó sì sọ fún un pé,“Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí àwọn èèyàn Jèhófà, lórí Ísírẹ́lì.+ 7 Kí o pa àwọn ará ilé Áhábù olúwa rẹ, màá sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti ti gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà tí Jésíbẹ́lì pa.+ 8 Gbogbo ilé Áhábù ló máa ṣègbé; màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run, títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+ 9 Màá ṣe ilé Áhábù bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà. 10 Ní ti Jésíbẹ́lì, àwọn ajá ló máa jẹ ẹ́ ní ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì,+ ẹnì kankan ò ní sin ín.’” Ló bá ṣí ilẹ̀kùn, ó sì sá lọ.+

11 Nígbà tí Jéhù pa dà sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé kò sí o? Kí nìdí tí ayírí yìí fi wá bá ọ?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ̀yin náà mọ irú èèyàn tí ọkùnrin náà jẹ́, ẹ sì mọ ohun tí irú wọn máa ń sọ.” 12 Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “Irọ́ ni! Jọ̀ọ́, sòótọ́ fún wa.” Nígbà náà, ó sọ pé: “Báyìí-báyìí ló sọ fún mi, ó sì fi kún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.”’”+ 13 Ní kíá, kálukú mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí àtẹ̀gùn kó lè gun orí rẹ̀,+ wọ́n fun ìwo, wọ́n sì sọ pé: “Jéhù ti di ọba!”+ 14 Lẹ́yìn náà, Jéhù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọmọ Nímúṣì dìtẹ̀ sí Jèhórámù.

Ní àkókò yẹn, Jèhórámù àti gbogbo Ísírẹ́lì wà ní Ramoti-gílíádì,+ wọn ò sì dẹra nù nítorí Hásáẹ́lì+ ọba Síríà. 15 Nígbà tó yá, ọba Jèhórámù pa dà sí Jésírẹ́lì+ kó lè tọ́jú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára nígbà tó bá Hásáẹ́lì ọba Síríà+ jà.

Ni Jéhù bá sọ pé: “Bí ẹ* bá gbà pẹ̀lú mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn ní Jésírẹ́lì.” 16 Lẹ́yìn náà, Jéhù gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì lọ sí Jésírẹ́lì, torí ibẹ̀ ni Jèhórámù dùbúlẹ̀ sí pẹ̀lú ọgbẹ́ lára, Ahasáyà ọba Júdà sì wá wo Jèhórámù níbẹ̀. 17 Bí olùṣọ́ ṣe dúró sórí ilé gogoro tó wà ní Jésírẹ́lì, ó rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jéhù tí wọ́n ń bọ̀. Ní kíá, ó sọ pé: “Mo rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bọ̀.” Jèhórámù bá sọ pé: “Mú agẹṣinjagun kan, kí o rán an lọ pàdé wọn, kó sì béèrè pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” 18 Torí náà, agẹṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọba ní kí n bi yín pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” Ṣùgbọ́n Jéhù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ‘àlàáfíà’ wo lò ń sọ? Bọ́ sẹ́yìn mi!”

Olùṣọ́ wá ròyìn pé: “Òjíṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì pa dà.” 19 Nítorí náà, ó rán agẹṣin kejì jáde, nígbà tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ó sọ pé: “Ọba ní kí n bi yín pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” Àmọ́ Jéhù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ‘àlàáfíà’ wo lò ń sọ? Bọ́ sẹ́yìn mi!”

20 Lẹ́yìn náà, olùṣọ́ ròyìn pé: “Ó dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì pa dà, bó ṣe ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bíi ti Jéhù ọmọ ọmọ* Nímúṣì, nítorí eré àsápajúdé ló máa ń sá.” 21 Jèhórámù sọ pé: “Di kẹ̀kẹ́ ẹṣin!” Nítorí náà, wọ́n di kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, Jèhórámù ọba Ísírẹ́lì àti Ahasáyà+ ọba Júdà sì jáde lọ, kálukú nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ láti pàdé Jéhù. Wọ́n bá a pàdé ní ilẹ̀ Nábótì+ ará Jésírẹ́lì.

22 Bí Jèhórámù ṣe rí Jéhù, ó sọ pé: “Ṣé àlàáfíà lo bá wá, Jéhù?” Àmọ́, ó sọ pé: “Àlàáfíà báwo, nígbà tó jẹ́ pé Jésíbẹ́lì+ ìyá rẹ kò jáwọ́ nínú ìṣekúṣe àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀?”+ 23 Lójú ẹsẹ̀, Jèhórámù yíjú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pa dà kó lè sá lọ, ó sì sọ fún Ahasáyà pé: “Wọ́n ti tàn wá, Ahasáyà!” 24 Jéhù mú ọfà,* ó sì ta á lu Jèhórámù ní àárín méjì ẹ̀yìn rẹ̀, ọfà náà jáde ní ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú sínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 25 Jéhù wá sọ fún Bídíkárì tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun pé: “Gbé e, kí o sì jù ú sínú ilẹ̀ Nábótì ará Jésírẹ́lì.+ Rántí pé èmi pẹ̀lú rẹ jọ ń gun ẹṣin* tẹ̀ lé Áhábù bàbá rẹ̀ nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ kéde ìdájọ́ lé e lórí pé:+ 26 ‘“Bí mo ṣe rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì+ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá,” ni Jèhófà wí, “màá san án pa dà+ fún ọ ní ilẹ̀ yìí kan náà,” ni Jèhófà wí.’ Torí náà, gbé e, kí o sì jù ú sórí ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ.”+

27 Nígbà tí Ahasáyà+ ọba Júdà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà ilé ọgbà. (Lẹ́yìn náà, Jéhù lépa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ pa òun náà!” Torí náà, wọ́n ṣe é léṣe nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ bó ṣe ń lọ sí Gúrì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Íbíléámù.+ Àmọ́ kò dúró títí ó fi sá dé Mẹ́gídò, ó sì kú síbẹ̀. 28 Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé e lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì sin ín sí sàréè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ 29 Ọdún kọkànlá Jèhórámù ọmọ Áhábù ni Ahasáyà  + di ọba lórí Júdà.)

30 Nígbà tí Jéhù dé Jésírẹ́lì,+ Jésíbẹ́lì+ gbọ́ pé ó ti dé. Torí náà, ó lé tìróò* sójú, ó ṣe irun rẹ̀ lóge, ó sì bojú wolẹ̀ látojú fèrèsé.* 31 Bí Jéhù ṣe ń gba ẹnubodè wọlé, Jésíbẹ́lì sọ pé: “Ǹjẹ́ ó dáa fún Símírì, ẹni tó pa olúwa rẹ̀?”+ 32 Bí Jéhù ṣe gbójú sókè wo fèrèsé náà, ó sọ pé: “Ta ló wà lẹ́yìn mi nínú yín? Ta ni?”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn méjì sí mẹ́ta tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ààfin yọjú wò ó látòkè. 33 Ó sọ pé: “Ẹ jù ú sísàlẹ̀!” Torí náà, wọ́n jù ú sísàlẹ̀, lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sára ògiri àti sára àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jéhù sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. 34 Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó sì mu. Ó wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ palẹ̀ obìnrin ẹni ègún yìí mọ́, kí ẹ sì sin ín. Ó ṣe tán, ọmọ ọba ni.”+ 35 Àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sin ín, agbárí rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ nìkan ló ṣẹ́ kù tí wọ́n rí.+ 36 Nígbà tí wọ́n pa dà tí wọ́n sì sọ fún un, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló ṣẹ,+ èyí tó gbẹnu Èlíjà ará Tíṣíbè ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé, ‘Orí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì ni àwọn ajá ti máa jẹ ẹran ara Jésíbẹ́lì.+ 37 Òkú Jésíbẹ́lì yóò sì di ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì, tí ẹnikẹ́ni ò fi ní lè sọ pé: “Jésíbẹ́lì nìyí.”’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́