ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 May ojú ìwé 3
  • Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wò Ẹ́ Ni Kó O Fi Máa Wo Ara Ẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wò Ẹ́ Ni Kó O Fi Máa Wo Ara Ẹ
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 May ojú ìwé 3

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wò Ẹ́ Ni Kó O Fi Máa Wo Ara Ẹ

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, Jèhófà mọ àwọn ìwà dáadáa tá a ní, ó sì mọ̀ pé a tún lè ṣe dáadáa sí i lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì sọ pé: “Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm 149:4) Àmọ́ nígbà míì, ó máa ń ṣòro láti mọ ibi táwa fúnra wa dáa sí. Bákan náà, ohun táwọn kan ṣe sí wa lè mú ká máa wo ara wa bí ẹni tí ò wúlò. Nígbà míì sì rèé, tá a bá ń ronú lórí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, a lè máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wa. Tí irú àwọn èrò yìí bá ń wá sí wa lọ́kàn, kí la lè ṣe?

Fi sọ́kàn pé Jèhófà ń rí ohun gbogbo títí kan àwọn ohun tí ojú ẹ̀dá èèyàn ò tó. (1Sa 16:7) Èyí túmọ̀ sí pé ó mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa lọ. A mà dúpẹ́ o, pé Bíbélì ti jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wò wá. Tá a bá ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn ìtàn inú Bíbélì tó dá lórí bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, ìyẹn a jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ TÓBI JU ỌKÀN WA LỌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni àpèjúwe ọmọkùnrin tó ń sáré àti bàbá ẹ̀ kọ́ wa nípa ojú tí Jèhófà fi ń wò wá?

  • Tí ẹnì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára, tó sì ti ṣe ohun tó yẹ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kí ló máa fi ẹni náà lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ti dárí ji òun?​—1Jo 3:19, 20

  • Báwo ni ìtàn Dáfídì àti Jèhóṣáfátì tí arákùnrin yẹn kà, tó sì ronú lé lórí ṣe ràn án lọ́wọ́?

Àwọn ìtàn inú Bíbélì tó jẹ́ kó dá wa lójú pé . . .

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa láìka irú ojú táwọn èèyàn fi ń wò wá sí

  • Énọ́kù (Jẹ 5:24; Heb 11:5; Jud 14, 15)

  • Hánà (1Sa 1:1–2:11, 18-21, 26)

Jèhófà máa dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn

  • Mánásè (2Kr 33:1-7, 12, 13)

  • Pọ́ọ̀lù (1Ti 1:12-16)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́