ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 33
ORIN 4 “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹ
“Mo [ti] fà ọ́ mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”—JER. 31:3.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àtohun tó yẹ ká ṣe kó lè dá wa lójú pé lóòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ wa.
1. Kí ló jẹ́ kó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
ṢÉ O rántí ìgbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? Kí nìdí tó o fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, o mọ ẹni tó jẹ́, o sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. O ṣèlérí pé ohun tó fẹ́ ni wàá máa fayé ẹ ṣe, wàá sì fi gbogbo ọkàn ẹ, gbogbo ara ẹ, gbogbo èrò ẹ àti gbogbo okun ẹ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Máàkù 12:30) Látìgbà yẹn, o wá túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àmọ́, kí lo máa sọ tẹ́nì kan bá bi ẹ́ pé, “Ṣé òótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?” Ó dájú pé ohun tó o máa sọ ni pé, “Òun ni mo nífẹ̀ẹ́ jù lọ!”
Ṣé o rántí bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́, tó o sì ṣèrìbọmi? (Wo ìpínrọ̀ 1)
2-3. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Jeremáyà 31:3)
2 Kí lo máa sọ tẹ́nì kan bá bi ẹ́ pé, “Ṣé o rò pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ?” Ó lè má yá ẹ lára láti sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ irú èèyàn bíi tìẹ láé. Arábìnrin kan tí nǹkan ò rọrùn fún nígbà tó wà lọ́mọdé sọ pé: “Mo mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì dá mi lójú. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.” Tó o bá ń nírú èrò yìí, kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ lóòótọ́?
3 Jèhófà fẹ́ kó o mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ. (Ka Jeremáyà 31:3.) Ká sòótọ́, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi, ó fún ẹ ní ohun kan tó ṣeyebíye, ìyẹn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí ẹ. Ìfẹ́ tó ní sí ẹ yìí jinlẹ̀ gan-an débi pé kò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. Ìfẹ́ yìí kan náà ló jẹ́ káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà “ṣeyebíye” lójú ẹ̀, ìwọ náà sì wà lára wọn. (Mál. 3:17, àlàyé ìsàlẹ̀) Bó ṣe dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, Jèhófà fẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ó dá mi lójú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tó wà nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ló máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:38, 39) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àtohun tó yẹ ká ṣe ká lè mọ̀ pé lóòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ wa.
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ GBÀ PÉ JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ WA
4. Kí ni Sátánì máa ń fẹ́ ká rò, báwo la sì ṣe lè borí ẹ̀?
4 Tá a bá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, àá borí “àrékérekè” Sátánì. (Éfé. 6:11) Gbogbo ohun tó bá gbà ni Sátánì máa ṣe ká má bàa sin Jèhófà mọ́. Ọ̀kan lára ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì máa ń lò láti mú wa ni pé ó máa ń fẹ́ ká rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. Má gbàgbé pé Sátánì ń wá bó ṣe máa wọlé sí wa lára. Ó sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá rẹ̀wẹ̀sì nítorí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn tàbí tí ìṣòro kan bá ń bá wa fínra àti nígbà tá a bá ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la. (Òwe 24:10) A lè fi Sátánì wé kìnnìún tó fẹ́ pa ẹranko kan tí ò lágbára mọ́. Torí náà, tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, ó máa ń fẹ́ ká ṣe nǹkan tó lè mú ka má sin Jèhófà mọ́. Àmọ́ tá a bá jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, àá lè “kọjú ìjà” sí Sátánì, àá sì mọ àwọn ọgbọ́n èwẹ́ tó ń lò.—1 Pét. 5:8, 9; Jém. 4:7.
5. Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì mọyì ẹ?
5 Tá a bá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, àá túbọ̀ sún mọ́ ọn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jèhófà dá wa lọ́nà tó jẹ́ pé a lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àwọn náà sì lè nífẹ̀ẹ́ wa. Táwọn èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ wa, ó máa ń jẹ́ káwa náà nífẹ̀ẹ́ wọn. Torí náà, tá a bá rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì mọyì wa, àwa náà á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (1 Jòh. 4:19) Bá a bá ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lòun náà á túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ wa. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jém. 4:8) Torí náà, kí ló yẹ ká ṣe kó lè dá wa lójú pé òótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
ÀWỌN NǸKAN WO LÓ MÁA JẸ́ KÁ GBÀ PÉ JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ WA?
6. Tó o bá ń rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, kí ló yẹ kó o ṣe?
6 Sọ ohun tó o fẹ́ tó o bá ń gbàdúrà, má sì jẹ́ kó sú ẹ. (Lúùkù 18:1; Róòmù 12:12) Máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ, kódà o lè gbàdúrà láìmọye ìgbà lójúmọ́. Òótọ́ ni pé o lè ní ẹ̀dùn ọkàn débi pé á ṣòro fún ẹ láti gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹ. Àmọ́ máa rántí pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. (1 Jòh. 3:19, 20) Ó mọ̀ ẹ́ ju bó o ṣe mọ ara ẹ lọ, ó sì rí àwọn ànímọ́ tó dáa tó o ní tíwọ fúnra ẹ lè má mọ̀. (1 Sám. 16:7; 2 Kíró. 6:30) Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ láti “tú ọkàn [ẹ] jáde” tàbí sọ ohun tó o fẹ́ fún Jèhófà, kó o sì ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. (Sm. 62:8) Lẹ́yìn tó o bá ti sọ ohun tó o fẹ́ fún Jèhófà, á dáa kó o ṣe àwọn nǹkan tá a fẹ́ sọ yìí.
7-8. Kí làwọn Sáàmù kan sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
7 Fọkàn tán Jèhófà. Jèhófà fi ẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì kí wọ́n lè sọ ẹni tó jẹ́ fún wa. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Dáfídì sọ nípa Jèhófà tó fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sọ pé: “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ̀mí wọn là.” (Sm. 34:18, àlàyé ìsàlẹ̀) Tó o bá rẹ̀wẹ̀sì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí pé nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, òun máa wà pẹ̀lú ẹ torí ó mọ̀ pé o nílò ìrànlọ́wọ́. Ohun míì tí Dáfídì sọ nínú sáàmù kan tó kọ ni pé: “Gba omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.” (Sm. 56:8) Jèhófà mọ ohun tó ń bà ẹ́ nínú jẹ́, tó sì ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ. Ó nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, ó sì mọ nǹkan tó ò ń bá yí. Ńṣe ló dà bíi pé ó gba omijé ẹ sínú ìgò awọ kan, tó sì tọ́jú ẹ̀ pa mọ́ bí ìgbà tí arìnrìn-àjò kan tọ́jú omi pa mọ́ sínú ìgò awọ. Dáfídì tún sọ ní Sáàmù 139:3 pé: “Gbogbo àwọn ọ̀nà mi ò ṣàjèjì sí [Jèhófà].” Torí náà, Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe, àmọ́ ibi tó o dáa sí ló ń wò. (Héb. 6:10) Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọyì bó o ṣe ń sapá láti ṣe ohun tó fẹ́.a
8 Àwọn ọ̀rọ̀ tá a kà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn ń fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an. Ńṣe ni Jèhófà ń sọ fún ẹ pé: “Mo fẹ́ kó o mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, mi ò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀.” Àmọ́ bá a ṣe sọ níṣàájú, Sátánì fẹ́ kó o máa rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, á dáa kó o bi ara ẹ pé, ‘Ta ló yẹ kí n fọkàn tán, ṣé “baba irọ́” ni àbí “Ọlọ́run òtítọ́”?’—Jòh. 8:44; Sm. 31:5.
9. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀? (Ẹ́kísódù 20:5, 6)
9 Máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹ tó. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ka Ẹ́kísódù 20:5, 6.) Jèhófà ṣèlérí pé òun á máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òun. Ohun tí Jèhófà sọ yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun náà máa nífẹ̀ẹ́ wa torí pé adúróṣinṣin ni. (Neh. 1:5) Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ mọ́, bi ara ẹ pé, ‘Ṣémi náà ṣì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?’ Tí ìdáhùn ẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ṣohun tó fẹ́, ó dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìwọ náà. (Dán. 9:4; 1 Kọ́r. 8:3) Tó bá dá ẹ lójú pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ṣó yẹ kó o máa rò pé kò nífẹ̀ẹ́ ẹ? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé.
10-11. Kí ni Jèhófà fẹ́ kó o mọ̀ nípa ìràpadà? (Gálátíà 2:20)
10 Máa ronú nípa ìràpadà. Ìràpadà lohun tó tóbi jù lọ tí Jèhófà fún aráyé, ìyẹn bó ṣe gbà kí Jésù Kristi kú nítorí wa. (Jòh. 3:16) Àmọ́, ṣé Jésù kú nítorí ìwọ náà? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ẹ rántí pé kó tó di Kristẹni, ó ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan, ó sì ní láti máa bá àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní yí lẹ́yìn tó di Kristẹni. (Róòmù 7:24, 25; 1 Tím. 1:12-14) Síbẹ̀, ó gbà pé torí òun ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí Jésù kú. (Ka Gálátíà 2:20.) Rántí pé Jèhófà ló fi ẹ̀mí ẹ̀ darí Pọ́ọ̀lù pé kó kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú Bíbélì. Jèhófà sì fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó kọ. (Róòmù 15:4) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ jẹ́ ká rí i pé Jèhófà fẹ́ kíwọ náà gbà pé nítorí ẹ ni Jésù ṣe kú. Tó o bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an.
11 A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá pé Jèhófà rán Jésù wá sáyé kó lè kú nítorí wa. Àmọ́ nǹkan míì wà tí Jésù wá ṣe láyé, ó wá kọ́ wa ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Jòh. 18:37) Lára òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ wa ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.
JÉSÙ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ WA
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká gba ohun tí Jésù sọ nípa Jèhófà gbọ́?
12 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ ká mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. (Lúùkù 10:22) Ó yẹ ká gba ohun tó sọ nípa Jèhófà gbọ́ torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jésù àti Jèhófà ti jọ wà lọ́run kó tó wá sáyé. (Kól. 1:15) Jésù mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an, ó sì mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ àti gbogbo àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
13. Kí ni Jésù fẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
13 Jésù fẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa bó ṣe nífẹ̀ẹ́ òun. Nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, ó ju ìgbà ọgọ́jọ (160) lọ tí Jésù pe Jèhófà ní “Baba.” Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tó ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Baba yín” tàbí “Baba yín ọ̀run.” (Mát. 5:16; 6:26) Àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mátíù 5:16 nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbà àtijọ́ pe Jèhófà ní ‘Olódùmarè,’ ‘Ẹni Gíga Jù Lọ,’ ‘Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá’ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ká lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù pè é ní ‘Bàbá’ ká lè mọ bí àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àtàwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó.” Torí náà, ó hàn gbangba pé Jésù fẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an bí bàbá kan ṣe nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò níbi tí Jésù ti pe Jèhófà ní “Baba.”
14. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣeyebíye lójú Jèhófà Baba wa ọ̀run? (Mátíù 10:29-31) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jésù sọ ní Mátíù 10:29-31. (Kà á.) Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ kéré gan-an, wọn ò sì lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tàbí jọ́sìn ẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà ń kíyè sí ẹyẹ ológoṣẹ́ kọ̀ọ̀kan débi pé ó mọ ìgbà tí wọ́n bá já bọ́. Tí Jèhófà bá lè kíyè sí ẹyẹ ológoṣẹ́ tí ò tó nǹkan, ó dájú pé ó máa kíyè sí àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó sì máa bójú tó wa bá a ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀! Mátíù 10:30 sọ pé: “Kódà, gbogbo irun orí yín la ti kà.” Nígbà tí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàlàyé ẹsẹ yìí, ó sọ pé: “Tí Jèhófà bá lè ka irun orí wa tó sì mọ iye wọn, ó dájú pé ó máa mọ gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.” Torí náà, ohun tí Jésù fẹ́ ká mọ̀ ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣeyebíye lójú Jèhófà Baba wa ọ̀run.
Jèhófà mọyì àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ débi pé tí ọ̀kan lára wọn bá já bọ́, ó máa ń mọ̀. Tí Jèhófà bá lè kíyè sí ẹyẹ ológoṣẹ́ tí ò tó nǹkan, ó dájú pé ó máa kíyè sí àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀! (Wo ìpínrọ̀ 14)
15. Kí lohun tí Jésù sọ ní Jòhánù 6:44 jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
15 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ kejì níbi tí Jésù ti pe Jèhófà ní “Baba.” (Ka Jòhánù 6:44.) Bàbá ẹ ọ̀run fúnra ẹ̀ ló fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀, ìyẹn ni pé òun ló jẹ́ kó o rí òtítọ́. Kí nìdí tó fi fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà rí ọkàn ẹ, ó sì mọ̀ pé o láwọn ìwà tó dáa. (Ìṣe 13:48) Àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jòhánù 6:44 nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ nínú ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé ni Jésù ń sọ. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Mo [ti] fà ọ́ mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ [tàbí mò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ].” (Jer. 31:3; àlàyé ìsàlẹ̀; fi wé Hósíà 11:4.) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an torí pé ibi tó o dáa sí tíwọ fúnra ẹ lè má mọ̀ ni Baba wa ọ̀run ń wò.
16. (a) Kí ni Jésù ń sọ nígbà tó pe Jèhófà ní Baba wa, kí sì nìdí tó fi yẹ ká gba ohun tó sọ gbọ́? (b) Kí lo lè ṣe kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ni Baba tó ju baba lọ? (Wo àpótí náà “Baba Tó Ju Baba Lọ.”)
16 Nígbà tí Jésù pe Jèhófà ní Baba wa, ohun tó ń sọ ni pé: “Jèhófà kì í ṣe Baba mi nìkan, Baba tìẹ náà ni. Mo fẹ́ kó o mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, ó sì ń bójú tó ẹ.” Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé kò yẹ kí n gba ọ̀rọ̀ tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run sọ gbọ́ torí pé gbogbo ìgbà ló máa ń sọ òtítọ́, ó sì mọ Baba wa ọ̀run dáadáa?’—1 Pét. 2:22.
JẸ́ KÓ TÚBỌ̀ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ Ẹ
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
17 Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Bá a ṣe sọ níṣàájú, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni Sátánì ọ̀tá wa, ó sì máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe ká má bàa sin Jèhófà mọ́. Sátánì máa ń fẹ́ ká rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa kó lè rí wa mú. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó tàn wá jẹ!—Jóòbù 27:5.
18. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ?
18 Kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, máa gbàdúrà pé kó jẹ́ kó o rí i pé òótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ ẹ. Máa ro nǹkan tí Bíbélì sọ nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Má gbàgbé pé tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa nífẹ̀ẹ́ ìwọ náà. Bákan náà, máa ronú nípa ẹ̀bùn tó tóbi jù tí Jèhófà fún ẹ, ìyẹn bó ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà ẹ́ pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, gba ohun tí Jésù sọ gbọ́ pé Jèhófà ni Bàbá ẹ ọ̀run. Tí ẹnikẹ́ni bá wá bi ẹ́ pé: “Ṣé o rò pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ?” Gbogbo ẹnu ni wàá fi sọ fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó nífẹ̀ẹ́ mi! Èmi náà sì ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lójoojúmọ́ láti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀!”
ORIN 154 Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀