ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 September ojú ìwé 13
  • Ran Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Gbà Pé Ọlọ́run Wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Gbà Pé Ọlọ́run Wà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Máa Lo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́nà Tó Já Fáfá
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ṣé Ẹlẹ́dàá Wà Lóòótọ́?
    Jí!—2021
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 September ojú ìwé 13
Arábìnrin kan ń wàásù fún obìnrin kan tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ran Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Gbà Pé Ọlọ́run Wà

Tó o bá pàdé ẹni tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan lóde ìwàásù, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o má ṣe wàásù fún un torí o ronú pé kò ní fẹ́ gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan tẹ́lẹ̀ títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n nílò ni ẹni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà lóòótọ́.—Ro 1:20; 10:14.

Ẹ WO FÍDÍÒ MÁA RÁNTÍ PÉ ÀWỌN ALÁÌGBÀGBỌ́ LÈ DI ONÍGBÀGBỌ́!—ÀWỌN TÍ KÒ ṢE Ẹ̀SÌN KANKAN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tommaso ṣe jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká jẹ́ kó sú wa láti máa wàásù fáwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan?

Bó o ṣe lè ṣe é

Tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà, má ṣe dá a lẹ́bi, dípò bẹ́ẹ̀, fìfẹ́ hàn sí i, kó o sì fọgbọ́n béèrè ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀. (2Ti 2:24) Ẹ lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tó máa nífẹ̀ẹ́ sí. Tó o bá rí i pé ó wù ú láti jíròrò àwọn ẹ̀rí tó ti mú kí ọ̀pọ̀ gbà pé Ọlọ́run wà, á dáa kó o lo àwọn ìwé àti fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá. A ti fi ìwé Was Life Created? àti ìwé The Origin of Life—Five Questions Worth Asking sínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kó lè rọrùn láti rí.

O lè má mọ ohun tó o máa sọ tó o bá pàdé ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ní kí akéde kan tó nírìírí ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bákan náà, má gbàgbé pé Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti sọ ohun tó máa wọ ẹnì kan lọ́kàn, kódà tí ẹni náà ò bá tiẹ̀ kọ́kọ́ gbà pé Ọlọ́run wà.—Iṣe 13:48.

Ìwé “Was Life Created?”
Ìwé “The Origin of Life—Five Questions Worth Asking.”
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́