ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w20 March ojú ìwé 18-23
  • Ìgbà Wo Ló Tọ́ Pé Kéèyàn Sọ̀rọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ló Tọ́ Pé Kéèyàn Sọ̀rọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌGBÀ WO LÓ YẸ KÁ SỌ̀RỌ̀?
  • ÌGBÀ WO LÓ YẸ KÁ DÁKẸ́?
  • BÁWO LỌ̀RỌ̀ ẸNU WA ṢE MÁA Ń RÍ LÁRA JÈHÓFÀ?
  • Ó Hùwà Ọlọgbọ́n
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Hùwà Ọgbọ́n
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ábígẹ́lì Àti Dáfídì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Obìnrin Kan Tí Ó Lọ́gbọ́n Kòòré Ìjábá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
w20 March ojú ìwé 18-23

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 12

Ìgbà Wo Ló Tọ́ Pé Kéèyàn Sọ̀rọ̀?

“Ohun gbogbo ni àkókò wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” ​—ONÍW. 3:1, 7.

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Kí lọ̀rọ̀ tó wà nínú Oníwàásù 3:​1, 7 jẹ́ kó ṣe kedere?

ÀWỌN kan lára wa máa ń sọ̀rọ̀ gan-an. Àwọn míì ní tiwọn kò lè sọ̀rọ̀ ẹnu wọn tán, ìyẹn ni pé wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Bó ṣe wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà, ó ṣe kedere pé bí ìgbà tó yẹ kéèyàn sọ̀rọ̀ ṣe wà bẹ́ẹ̀ ni ìgbà tó yẹ kéèyàn dákẹ́ wà. (Ka Oníwàásù 3:​1, 7.) Síbẹ̀, ó lè wù wá pé káwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ máa sọ̀rọ̀. Ó sì lè wù wá pé káwọn míì tó ń sọ̀rọ̀ gan-an mọ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ níwọ̀nba.

2. Ta ló láṣẹ láti sọ bó ṣe yẹ kéèyàn sọ̀rọ̀ àti ìgbà tó yẹ kó sọ̀rọ̀?

2 Jèhófà ló fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ. (Ẹ́kís. 4:​10, 11; Ìfi. 4:11) Nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ká lóye bá a ṣe lè lo ẹ̀bùn náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nínú Bíbélì táá jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ àti ìgbà tó yẹ ká dákẹ́. A tún máa mọ bí ọ̀rọ̀ tá a sọ sáwọn míì ṣe máa ń rí lára Jèhófà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká jíròrò nípa ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀.

ÌGBÀ WO LÓ YẸ KÁ SỌ̀RỌ̀?

3. Bó ṣe wà nínú Róòmù 10:​14, ìgbà wo ló yẹ ká sọ̀rọ̀?

3 Ìgbà gbogbo ló yẹ ká ṣe tán láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. (Mát. 24:14; ka Róòmù 10:14.) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fara wé Jésù. Ọ̀kan lára ìdí tí Jésù fi wá sáyé ni pé kó lè kọ́ni ní òtítọ́ nípa Baba rẹ̀. (Jòh. 18:37) Àmọ́ ó tún ṣe pàtàkì ká mọ bó ṣe yẹ ká bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Torí náà, tá a bá ń sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ máa fi “ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” ṣe bẹ́ẹ̀, ká fi hàn pé a gba tiwọn rò, ká má sì kàn wọ́n lábùkù torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Pét. 3:15) Tá a bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò, wọ́n á gbọ́rọ̀ wa, wọ́n á sì rí ẹ̀kọ́ kọ́.

ÌGBÀ TÓ YẸ KÁ SỌ̀RỌ̀

  • Tá a bá ń sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ máa fi “ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀” ṣe bẹ́ẹ̀, ká má sì kàn wọ́n lábùkù torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ (ìpínrọ̀ 3)

  • Tá a bá kíyè sí i pé ẹnì kan fẹ́ ṣi ẹsẹ̀ gbé (ìpínrọ̀ 8)

  • Àwọn alàgbà máa ń mú sùúrù fún ẹni tí wọ́n ń gbà nímọ̀ràn, wọ́n sì máa ń bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mú kó rí ẹ̀kọ́ kọ́ (ìpínrọ̀ 4 àti 9)

Arábìnrin méjì lọ sí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta aṣọ. Ọ̀kan ń sọ fún èkejì pé síkẹ́ẹ̀tì tó mú lọ́wọ́ ti kéré jù, kò sì bójú mu.

(Wo ìpínrọ̀ 8)b

Alàgbà kan ṣí Bíbélì sọ́wọ́, ó sì ń fún ọ̀dọ́kùnrin kan nímọ̀ràn lórí ìmọ́tótó. Ilé ọ̀dọ́kùnrin náà rí wúruwùru.

(Wo ìpínrọ̀ 4 àti 9)c

4. Bí Òwe 9:9 ṣe sọ, báwo lọ̀rọ̀ wa ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́?

4 Àwọn alàgbà kì í lọ́ tìkọ̀ láti gba arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí nímọ̀ràn tó bá pọn dandan. Síbẹ̀, wọ́n máa ń wá àkókò tó wọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ kí ojú má bàa ti onítọ̀hún. Wọ́n tiẹ̀ lè mú sùúrù dìgbà tí wọ́n á lè bá ẹni náà sọ̀rọ̀ láìjẹ́ kí etí míì gbọ́. Àwọn alàgbà máa ń sapá láti buyì kún ẹni tí wọ́n ń gbà nímọ̀ràn. Wọ́n máa ń rí i dájú pé ìlànà Bíbélì làwọn fi tọ́ onítọ̀hún sọ́nà kó lè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. (Ka Òwe 9:9.) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ nígbà tó yẹ? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì tó yàtọ̀ síra nínú Bíbélì. Àkọ́kọ́ ni àpẹẹrẹ bàbá kan tí kò bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí, èkejì sì ni ti obìnrin kan tó bá ẹnì kan tó máa tó di ọba sọ̀rọ̀.

5. Ìgbà wo ló yẹ kí Élì àlùfáà àgbà sọ̀rọ̀ àmọ́ tí kò ṣe bẹ́ẹ̀?

5 Élì àlùfáà àgbà ní àwọn ọmọkùnrin méjì kan tó fẹ́ràn gan-an. Àmọ́ àwọn ọmọ náà kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà rárá. Àlùfáà làwọn méjèèjì, wọ́n sì ní ojúṣe pàtàkì tí wọ́n ń bójú tó nínú àgọ́ ìjọsìn. Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń ṣi ipò wọn lò, wọ́n sì ń hùwà ta ló máa mú mi tó bá kan ẹbọ táwọn èèyàn ń rú sí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń bá àwọn obìnrin ṣèṣekúṣe láìbìkítà nípa ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. (1 Sám. 2:​12-17, 22) Bí Òfin Mósè ṣe sọ, ṣe ló yẹ kí wọ́n pa àwọn méjèèjì, àmọ́ dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni bàbá wọn kàn fẹnu lásán bá wọn wí, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n máa bá iṣẹ́ àlùfáà lọ nínú àgọ́ ìjọsìn. (Diu. 21:​18-21) Báwo lohun tí Élì ṣe yẹn ṣe rí lára Jèhófà? Ó sọ fún Élì pé: “Kí ló dé tí ò ń bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ jù mí lọ?” Jèhófà wá pinnu pé òun máa pa àwọn ọmọkùnrin yẹn torí ìwà burúkú wọn.​—1 Sám. 2:​29, 34.

6. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Élì ṣe?

6 Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà tá a rí kọ́ nínú ohun tí Élì ṣe. Tá a bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ wa tàbí ìbátan wa kan dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà, kì í ṣe àsìkò yẹn ló yẹ ká dákẹ́, ṣe ló yẹ ká rán an létí ohun tí Jèhófà sọ. Bákan náà, ká rí i dájú pé ó sọ̀rọ̀ náà fáwọn tí Jèhófà yàn sípò kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. (Jém. 5:14) Ẹ má ṣe jẹ́ ká dà bí Élì, ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ ọ̀rẹ́ wa tàbí ìbátan wa ju Jèhófà lọ. Lóòótọ́ ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè kojú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ pé kó lọ gba ìrànwọ́, àmọ́ ó tọ́, ó sì yẹ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ti Élì, ìyẹn Ábígẹ́lì.

Ábígẹ́lì kúnlẹ̀ bó ṣe ń bá Dáfídì sọ̀rọ̀.

Ábígẹ́lì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, ó mọ ìgbà tó yẹ kóun sọ̀rọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 7 àti 8)d

7. Kí nìdí tí Ábígẹ́lì fi bá Dáfídì sọ̀rọ̀?

7 Ọlọ́rọ̀ ni Nábálì ọkọ Ábígẹ́lì. Lẹ́yìn tí Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ sá kúrò nílùú nítorí Ọba Sọ́ọ̀lù, ìgbà kan wà tí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn Nábálì, wọ́n sì dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn olè. Ṣé Nábálì mọyì ohun tí wọ́n ṣe fún un? Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Dáfídì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún òun àtàwọn èèyàn òun ní oúnjẹ díẹ̀ àti omi, ṣe ni Nábálì tutọ́ sókè tó sì fojú gbà á, kódà ó tún rọ̀jò èébú lé wọn lórí. (1 Sám. 25:​5-8, 10-12, 14) Ohun tó ṣe yẹn múnú bí Dáfídì, ó sì pinnu pé òun máa pa gbogbo ọkùnrin tó wà nílé Nábálì. (1 Sám. 25:​13, 22) Ṣé a máa rẹ́ni pẹ̀tù sọ́rọ̀ tó wà ńlẹ̀ yìí, tí wọn ò fi ní tàjẹ̀ sílẹ̀? Ábígẹ́lì rí i pé ó tó àsìkò kóun sọ̀rọ̀, torí náà ó ṣọkàn akin, ó sì lọ pàdé Dáfídì àtàwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọmọ ogun rẹ̀ tí ebi ń pa gan-an, tí wọ́n sì ń bínú. Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ó bá Dáfídì sọ̀rọ̀.

8. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ábígẹ́lì?

8 Nígbà tí Ábígẹ́lì pàdé Dáfídì, ó fìgboyà bá a sọ̀rọ̀, ó ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mú kí Dáfídì pèrò dà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Ábígẹ́lì ló fa ohun tó ṣẹlẹ̀, ó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Dáfídì. Pẹ̀lú ìdánilójú tí Ábígẹ́lì ní pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́ láti pẹ̀tù sí Dáfídì lọ́kàn, ó yin Dáfídì fáwọn nǹkan dáadáa tó ti ń ṣe bọ̀, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó ṣe ohun tó tọ́. (1 Sám. 25:​24, 26, 28, 33, 34) Bíi ti Ábígẹ́lì, ó lè gba pé káwa náà lo ìgboyà láti tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó má bàa ṣi ẹsẹ̀ gbé. (Sm. 141:5) Ká má ṣe kan onítọ̀hún lábùkù, síbẹ̀ ká rí i dájú pé a ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Tá a bá fìfẹ́ tọ́ ẹnì kan sọ́nà, ṣe là ń fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ la jẹ́.​—Òwe 27:17.

9-10. Kí ló yẹ kí ẹ̀yin alàgbà fi sọ́kàn tẹ́ ẹ bá ń fún àwọn míì nímọ̀ràn?

9 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kẹ́yin alàgbà lo ìgboyà kẹ́ ẹ lè tọ́ àwọn ará sọ́nà tí wọ́n bá ṣi ẹsẹ̀ gbé. (Gál. 6:1) Ẹ máa fi sọ́kàn pé aláìpé ni yín àti pé ẹ̀yin náà lè nílò kí ẹlòmíì gbà yín nímọ̀ràn. Àmọ́ ìyẹn ò wá ní kẹ́ ẹ lọ́ tìkọ̀ láti bá àwọn tó bá ṣàṣìṣe wí. (2 Tím. 4:2; Títù 1:9) Tẹ́ ẹ bá ń bá ẹnì kan wí, ẹ rí i dájú pé ẹ mú sùúrù fún un, kẹ́ ẹ sì bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń tuni lára kó lè rí ẹ̀kọ́ kọ́. Ẹ fìfẹ́ hàn sí i, tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, á yá a lára láti ṣàtúnṣe. (Òwe 13:24) Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ rọ̀ mọ́ ìlànà òdodo Jèhófà, kẹ́ ẹ sì dáàbò bo ìjọ torí pé ìyẹn ló máa bọlá fún Jèhófà.​—Ìṣe 20:28.

10 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, a ti jíròrò àwọn ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀. Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ohun tó dáa jù ni pé ká má ṣe sọ̀rọ̀. Kí ló lè mú kó ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀?

ÌGBÀ WO LÓ YẸ KÁ DÁKẸ́?

11. Àpèjúwe wo ni Jémíìsì lò, kí sì nìdí tó fi bá a mu?

11 Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣi ọ̀rọ̀ sọ torí pé aláìpé ni wá. Jémíìsì tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì lo àpèjúwe kan tó bá ọ̀rọ̀ yìí mu, ó ní: “Tí ẹnì kan kì í bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, á jẹ́ pé ẹni pípé ni, ó sì lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu.” (Jém. 3:​2, 3) Wọ́n sábà máa ń fi ìjánu sí ẹnu ẹṣin, ẹni tó ń gùn ún á sì máa fa ìjánu náà kó lè tọ́ ẹṣin náà sọ́nà. Ohun kan náà ló máa ṣe tó bá fẹ́ dá ẹṣin náà dúró. Tí ìjánu náà bá já pẹ́nrẹ́n tàbí tó bọ́ mọ́ ẹni tó gun ẹṣin náà lọ́wọ́, ṣe ni ẹṣin náà á máa sá eré àsápajúdé, ó sì lè ṣe ara ẹ̀ tàbí ẹni tó gùn ún léṣe. Lọ́nà kan náà, tá ò bá kó ahọ́n wa níjàánu, ó lè kó wa síyọnu, ó sì lè ṣe jàǹbá fáwọn míì. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn ìgbà tó yẹ ká “kó ara wa ní ìjánu” ká sì panu mọ́.

ÌGBÀ TÓ YẸ KÁ DÁKẸ́

  • Tó bá ṣe wá bíi pé ká sọ fáwọn míì nípa bá a ṣe ń ṣèpàdé àti bá a ṣe ń wàásù nílẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa (ìpínrọ̀ 12)

  • Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọ tó jẹ́ àṣírí tàbí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì nípa àwọn ará (ìpínrọ̀ 13 àti 14)

Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ará ń da ìbéèrè bo tọkọtaya kan tó wá sípàdé.

(Wo ìpínrọ̀ 12)e

Alàgbà kan ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù, ó ń ti ìlẹ̀kùn kí ìyàwó rẹ̀ tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú yàrá kejì má bàa gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

(Wo ìpínrọ̀ 13 àti 14)f

12. Ìgbà wo ló yẹ ká “kó ara wa ní ìjánu,” ká sì rí i pé a ò sọ ohunkóhun?

12 Kí lo máa ṣe tó o bá mọ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ní àwọn ìsọfúnni tí kò yẹ kó sọ fáwọn míì? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o pàdé ẹnì kan tó ń gbé nílẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, ṣé wàá fẹ́ kó sọ fún ẹ nípa ọgbọ́n tí wọ́n fi ń ṣèpàdé tí wọ́n sì fi ń wàásù? Kò sí àní-àní pé ohun tó dáa lo ní lọ́kàn. Ó ṣe tán a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, a sì máa ń fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń fẹ́ sọ ohun pàtó tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ tá a bá ń gbàdúrà fún wọn. Àmọ́, irú àsìkò yìí ló ti yẹ ká “kó ara wa ní ìjánu” ká má sì bi wọ́n nírú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Tá a bá ṣe ohun táá mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ àṣírí bẹ́ẹ̀ fún wa, a ò fìfẹ́ hàn sí onítọ̀hún, a ò sì fìfẹ́ hàn sáwọn ará tó fọkàn tán ẹni náà pé kò ní sọ ọ́ fáwọn míì. Ó dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa tó máa fẹ́ kí nǹkan túbọ̀ nira fáwọn ará tó ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Bákan náà, kò sí ìkankan nínú àwọn ará tó wà nírú ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó máa fẹ́ sọ ọgbọ́n tí wọ́n fi ń ṣèpàdé tí wọ́n sì fi ń wàásù fún ẹlòmíì.

13. Bó ṣe wà nínú Òwe 11:​13, kí lẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ ṣe, kí sì nìdí?

13 Bó ṣe wà nínú Òwe 11:​13, ó ṣe pàtàkì kẹ́yin alàgbà máa pa àṣírí mọ́. (Kà á.) Èyí lè nira díẹ̀, pàápàá fún alàgbà tó níyàwó. Ìdí ni pé lára ohun tó máa ń mú kí ìdè ìgbéyàwó lágbára ni bí tọkọtaya ṣe máa ń bára wọn sọ̀rọ̀, tí wọn kì í sì í fi nǹkan kan pa mọ́ fúnra wọn, títí kan bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn àtohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Bó ti wù kó rí, ẹ̀yin alàgbà mọ̀ pé ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ “ọ̀rọ̀ àṣírí” àwọn ará fún ìyàwó yín. Tí alàgbà kan bá sọ̀rọ̀ àṣírí síta, àwọn ará ò ní fọkàn tán an mọ́, á sì ba orúkọ rere tó ní jẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tá a yàn sípò nínú ìjọ kì í ṣe “ẹlẹ́nu méjì,” wọn kì í sì í tanni jẹ. (1 Tím. 3:8; àlàyé ìsàlẹ̀) Lédè míì, a ò gbọ́dọ̀ bá alàgbà èyíkéyìí nídìí òfófó tàbí kó máa sọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kiri. Alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ kò ní sọ ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́ láti gbọ́ fún un torí pé ńṣe nìyẹn máa fa ìnira fún obìnrin náà.

14. Báwo ni ìyàwó alàgbà kan ṣe lè mú kí ọkọ rẹ̀ túbọ̀ jẹ́ ẹni iyì lójú àwọn ará?

14 Báwo ni ìyàwó alàgbà kan ṣe lè mú kí ọkọ rẹ̀ túbọ̀ jẹ́ ẹni iyì lójú àwọn ará? Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí kì í bá fúngun mọ́ ọkọ rẹ̀ tàbí dọ́gbọ́n mú kó sọ̀rọ̀ àṣírí fún òun. Tí ìyàwó kan bá mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, tó sì fìmọ̀ràn yìí sílò, ṣe ló máa jẹ́ alátìlẹ́yìn gidi fún ọkọ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe ló ń fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fáwọn tó fọkàn tán ọkọ rẹ̀ tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ àṣírí fún un. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, irú ìyàwó bẹ́ẹ̀ ń múnú Jèhófà dùn torí pé bó ṣe mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ yìí ń mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan túbọ̀ gbilẹ̀ nínú ìjọ.​—Róòmù 14:19.

BÁWO LỌ̀RỌ̀ ẸNU WA ṢE MÁA Ń RÍ LÁRA JÈHÓFÀ?

15. Báwo lọ̀rọ̀ táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù sọ sí i ṣe rí lára Jèhófà, kí sì nìdí?

15 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nínú ìwé Jóòbù tó bá di irú ọ̀rọ̀ tó yẹ ká máa sọ àtìgbà tó yẹ ká sọ ọ́. Lẹ́yìn táwọn ìṣòro tó ń pinni lẹ́mìí rọ́ lu Jóòbù, àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wá láti tù ú nínú kí wọ́n sì gbà á nímọ̀ràn. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n kọ́kọ́ dákẹ́ lọ gbári. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu mẹ́ta lára wọn, ìyẹn Élífásì, Bílídádì àti Sófárì fi hàn pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa ran Jóòbù lọ́wọ́ ni wọ́n ń rò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó gbà wọ́n lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa fi hàn pé èèyàn burúkú ni Jóòbù. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí wọ́n sọ tó jóòótọ́, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú ohun tí wọ́n sọ nípa Jóòbù àti Jèhófà ló jẹ́ kìkìdá irọ́, kò sì fìfẹ́ hàn. Wọ́n dá Jóòbù lẹ́bi, wọ́n sì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. (Jóòbù 32:​1-3) Báwo lọ̀rọ̀ wọn ṣe rí lára Jèhófà? Jèhófà bínú gidigidi sáwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òmùgọ̀ ni wọ́n, ó sì ní kí wọ́n bẹ Jóòbù kó lè gbàdúrà fún wọn.​—Jóòbù 42:​7-9.

16. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ burúkú Élífásì, Bílídádì àti Sófárì?

16 Àwọn ẹ̀kọ́ mélòó kan wà tá a lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ burúkú àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn. Àkọ́kọ́, kò yẹ ká máa dá àwọn ará wa lẹ́jọ́. (Mát. 7:​1-5) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa fara balẹ̀ gbọ́ wọn, ká má sì já lu ọ̀rọ̀ wọn. Ìgbà yẹn la máa lóye ohun tó ń ṣe wọ́n. (1 Pét. 3:8) Ìkejì, tá a bá máa sọ̀rọ̀, ká rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára ló jáde lẹ́nu wa, ó sì jẹ́ òótọ́ látòkèdélẹ̀. (Éfé. 4:25) Ẹ̀kọ́ kẹta ni pé ká máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ń kíyè sí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ sáwọn míì.

17. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Élíhù?

17 Ẹni kẹrin tó wá sọ́dọ̀ Jóòbù ni Élíhù tó jẹ́ ìbátan Ábúráhámù. Ó fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Jóòbù àtèyí táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta sọ. Ó ṣe kedere pé ó tẹ́tí sí wọn dáadáa torí pé ó fún Jóòbù ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó jẹ́ kó tún èrò ẹ̀ ṣe, kò sì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. (Jóòbù 33:​1, 6, 17) Ohun tó jẹ Élíhù lógún jù ni bó ṣe máa gbé Jèhófà ga, kì í ṣe bó ṣe máa gbé ara ẹ̀ tàbí ẹlòmíì ga. (Jóòbù 32:​21, 22; 37:​23, 24) Àpẹẹrẹ Élíhù jẹ́ ká rí i pé ìgbà tó yẹ kéèyàn dákẹ́ wà, ìgbà tó sì yẹ kéèyàn sọ̀rọ̀ wà. (Jém. 1:19) A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé tá a bá máa fúnni nímọ̀ràn, ohun tó yẹ kó gbà wá lọ́kàn ni bá a ṣe máa bọlá fún Jèhófà, kì í ṣe bá a ṣe máa bọlá fún ara wa.

18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún wa?

18 A lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Jèhófà fún wa tá a bá ń fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì sílò nípa ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ àti bó ṣe yẹ ká sọ ọ́. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Bí àwọn èso ápù oníwúrà tó wà nínú abọ́ fàdákà ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Tá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn míì, tá a sì ń ronú jinlẹ̀ ká tó sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa máa dà bí ápù oníwúrà, tó dùn ún wò, tó sì tún níye lórí. Nígbà náà, yálà ọ̀rọ̀ wa pọ̀ tàbí ó mọ níwọ̀n, ó ní láti jẹ́ èyí tó ń gbéni ró tó sì ń múnú Jèhófà dùn. (Òwe 23:15; Éfé. 4:29) Ó ṣe kedere pé ọ̀nà tó dáa jù téèyàn lè gbà fi hàn pé òun mọyì ẹ̀bùn yìí ni pé kó fi gbé àwọn míì ró, kó sì múnú Jèhófà dùn.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Ìgbà wo ló yẹ ká sọ̀rọ̀?

  • Ìgbà wo ló yẹ ká dákẹ́?

  • Kí lo rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

ORIN 82 Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”

a Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àwọn ìlànà táá jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ àti ìgbà tó yẹ ká dákẹ́. Tá a bá fi àwọn ìlànà yìí sọ́kàn, tá a sì ń fi wọ́n sílò, ọ̀rọ̀ wa máa múnú Jèhófà dùn.

b ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan rí i pé ó yẹ kóun gba arábìnrin míì nímọ̀ràn tó máa ṣe é láǹfààní.

c ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń gba ọ̀dọ́kùnrin kan níyànjú lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó.

d ÀWÒRÁN: Ábígẹ́lì lọ bá Dáfídì lásìkò tó yẹ, ó pàrọwà fún un, ìyẹn sì mú kí Dáfídì pèrò dà.

e ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan kọ̀ láti sọ bí nǹkan ṣe ń lọ ní ilẹ̀ kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa fún àwọn míì.

f ÀWÒRÁN: Alàgbà kan ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kọ́rọ̀ àṣírí nípa ìjọ ta sí ìyàwó rẹ̀ tàbí àwọn míì létí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́