ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Gbádùn Ayé Mi Gan-an Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
ỌDÚN 1958 ni wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà. Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni mí nígbà yẹn, iṣẹ́ tí wọ́n sì kọ́kọ́ fún mi ni pé kí n máa gbálẹ̀ ibi tí wọ́n ti ń tẹ̀wé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n ní kí n máa lo ẹ̀rọ tó máa ń gé etí àwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀. Mò ń gbádùn ìgbésí ayé mi gan-an, inú mi sì dùn pé mo wà ní Bẹ́tẹ́lì.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ṣèfilọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì pé wọ́n nílò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó máa lọ ṣiṣẹ́ níbi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì South Africa. Mo forúkọ sílẹ̀, inú mi sì dùn pé mo wà lára àwọn tí wọ́n mú. Yàtọ̀ sí èmi, wọ́n tún mú àwọn mẹ́ta míì tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ìyẹn Dennis Leech, Bill McLellan àti Ken Nordin. Wọ́n sì sọ fún wa pé a máa pẹ́ gan-an níbẹ̀.
Torí náà mo pe màmá mi lórí fóònù, mo sì sọ fún wọn pé: “Mo ní ìròyìn ayọ̀ kan fún yín o. Mò ń lọ sí South Africa!” Ẹni jẹ́jẹ́ ni màmá mi, àmọ́ wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Wọn ò sọ̀rọ̀ púpọ̀, àmọ́ mo mọ̀ pé wọ́n fọwọ́ sí ohun tí mo fẹ́ ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn òbí mi ò dùn pé mi ò ní sí nítòsí wọn mọ́, síbẹ̀ wọn ò lòdì sí ìpinnu tí mo ṣe yẹn.
MO LỌ SÍ SOUTH AFRICA!
Èmi àti Dennis Leech, Ken Nordin àti Bill McLellan rèé nínú ọkọ̀ ojú irin tó gbé wa láti Cape Town lọ sí Johannesburg lọ́dún 1959
Àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rèé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì South Africa lọ́dún 2019, a tún pa dà ríra lẹ́yìn ọgọ́ta (60) ọdún tá a dé sí South Africa
Àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn fún oṣù mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, a wọ ọkọ̀ òkun lọ sí ìlú Cape Town ní South Africa. Nígbà tá a débẹ̀, a wọkọ̀ ojú irin láti Cape Town lọ sí Johannesburg lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Karoo tó wà ní agbègbè kan tó jẹ́ aṣálẹ̀ la ti kọ́kọ́ dúró lọ́wọ́ ìdájí. Ibẹ̀ móoru gan-an, eruku sì pọ̀ níbẹ̀. Àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń yọjú lójú wíńdò, a sì ń ronú pé irú ìlú wo ni eléyìí? Kí la kóra wa sí báyìí? Àyà mi já torí ọmọ ogún ọdún (20) péré ni mí nígbà yẹn. Àmọ́ láwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, a ṣèbẹ̀wò sí agbègbè yìí, a sì mọyì àwọn ohun tá a rí níbẹ̀ àti báwọn èèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn.
Iṣẹ́ tí mo ṣe fún bí ọdún mélòó kan ni pé mo máa ń lo ẹ̀rọ kan tí wọ́n ń pè ní Linotype tí wọ́n máa ń lò kí wọ́n tó tẹ àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Kì í ṣe South Africa nìkan ni ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn ń tẹ ìwé fún, wọ́n tún ń tẹ ìwé fáwọn orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Áfíríkà. Inú wa dùn gan-an pé à ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé yìí dáadáa torí ohun tó gbé wa wá láti odindi Kánádà wá sí South Africa nìyẹn.
Nígbà tó yá, mo ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ ìtẹ̀wé, àwọn tó ń kó ìwé ránṣẹ́ àti iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè. Mò ń gbádùn iṣẹ́ mi gan-an bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ mi máa ń dí.
MO GBÉYÀWÓ, A SÌ GBA IṢẸ́ TUNTUN
Èmi àti Laura rèé lọ́dún 1968 nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe
Ní 1968, mo fẹ́ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Laura Bowen tó ń gbé nítòsí Bẹ́tẹ́lì. Aṣáájú-ọ̀nà ni, ó sì tún ń bá Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè ṣiṣẹ́. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó kì í dúró sí Bẹ́tẹ́lì. Torí náà, wọ́n sọ wá di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ẹ̀rù bà mí nígbà tá a gbaṣẹ́ yìí. Ìdí ni pé ní gbogbo ọdún mẹ́wàá tí mo lò ní Bẹ́tẹ́lì, mi ò sanwó ilé, mi ò sì sanwó oúnjẹ. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ń fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní 25 rand, ìyẹn dọ́là márùnlélọ́gbọ̀n (35) lóṣooṣù. Ká tó lè rí owó yìí gbà pé, wákàtí wa gbọ́dọ̀ pé, iye ìwé tá a fi sóde àti ìpadàbẹ̀wò wa sì gbọ́dọ̀ pé iye tí wọ́n ń retí. Inú owó yẹn kan náà la ti máa sanwó ilé, owó oúnjẹ, owó ọkọ̀, owó tá a máa fi tọ́jú ara wa tá a bá ṣàìsàn àtàwọn ìnáwó míì.
Àwùjọ kékeré kan tó wà nítòsí ìlú Durban ni wọ́n rán wa lọ. Torí pé ìlú náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Íńdíà, àwọn ọmọ ilẹ̀ Íńdíà pọ̀ ńbẹ̀ gan-an, ọ̀pọ̀ wọn ló sì jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn lébìrà tó ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ṣúgà láwọn ọdún 1800. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ míì ni ọ̀pọ̀ wọn ń ṣe báyìí, àṣà wọn àti oúnjẹ wọn ò yí pa dà. Torí pé wọ́n gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa, ìyẹn mú kí nǹkan rọrùn fún wa gan-an.
Àádọ́jọ (150) wákàtí ni wọ́n ń retí kí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe máa ṣe lóṣooṣù. Torí náà, èmi àtìyàwó mi pinnu láti ṣe wákàtí mẹ́fà lọ́jọ́ àkọ́kọ́. Ooru mú gan-an lọ́jọ́ yẹn, a ò ní ìpadàbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ la ò sì ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, ilé dé ilé la ṣe fún wákàtí mẹ́fà lọ́jọ́ yẹn. Lẹ́yìn tá a ti ṣiṣẹ́ lọ, mo wojú aago mi. Àṣé gbogbo ohun tá a ti ṣe látàárọ̀ ò tíì pé wákàtí kan. Mo wá ronú pé ìgbà wo la máa ṣèyí dà?
Kò pẹ́ tá a fi ṣètò ara wa dáadáa. Lójoojúmọ́, a máa ń gbé ohun tá a lè jẹ dání, àá sì bu ọbẹ̀ tàbí kọfí sínú kúlà. Tá a bá fẹ́ sinmi, a máa ń páàkì mọ́tò wa sábẹ́ igi kan tó ní ibòji. Ká tó mọ̀, àwọn ọmọdé á ti pagbo yí wa ká, wọ́n á sì máa wò wá torí pé àwọ̀ wa yàtọ̀ sí tiwọn! Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a mọwọ́ iṣẹ́ náà dáadáa, a kì í sì í mọ̀gbà tí wákàtí mẹ́fà máa pé.
Àwọn èèyàn ìlú yẹn fẹ́ràn àlejò gan-an, inú wa sì dùn pé a lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fúnni, wọ́n lawọ́, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn Hindu gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, Jésù, Bíbélì, ayé tuntun àti ìrètí àjíǹde. Lẹ́yìn ọdún kan péré, a ti ní ogún (20) èèyàn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò sí ọjọ́ kan ká má rí ọ̀kan lára àwọn ìdílé tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó máa ní ká wá jẹ oúnjẹ ọ̀sán lọ́dọ̀ àwọn. Ká sòótọ́, a gbádùn àsìkò yẹn gan-an.
Kò pẹ́ tá a fi gba iṣẹ́ míì, wọ́n sọ wá di alábòójútó àyíká, wọ́n sì ní ká máa ṣèbẹ̀wò sáwọn ìjọ tó wà ní etí Òkun Íńdíà. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tá a bá lọ bẹ ìjọ wò, ìdílé kan máa ń gbà wá sílé. A sì máa ń bá àwọn akéde ìjọ ṣiṣẹ́ ká lè fún wọn níṣìírí. Ńṣe làwa àtàwọn ìdílé tó ń gbà wá lálejò dà bí ọmọ ìyá, a sì gbádùn ká máa bá àwọn ọmọ wọn ṣeré. Kódà, àwọn ẹran ọ̀sìn wọn mojú wa. Ká tó mọ̀, ọdún méjì ti kọjá. Ṣàdédé la gba ìpè kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Wọ́n sọ pé: “À ń ronú àtipè yín pa dà sí Bẹ́tẹ́lì.” Mo wá dá wọn lóhùn pé, “A sì ń gbádùn iṣẹ́ wa gan-an níbí o.” Àmọ́, a gbà pé a máa ṣiṣẹ́ níbikíbi tí ètò Ọlọ́run bá ti fẹ́ lò wá.
A PA DÀ SÍ BẸ́TẸ́LÌ
Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ni mo ti ṣiṣẹ́ nígbà tí mo pa dà sí Bẹ́tẹ́lì. Níbẹ̀, mo bá àwọn arákùnrin tó nírìírí gan-an ṣiṣẹ́. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ lẹ́yìn tí alábòójútó àyíká bá bẹ̀ wọ́n wò. Nínú àwọn lẹ́tà yẹn, ètò Ọlọ́run máa ń gbóríyìn fáwọn ará, wọ́n sì máa ń fún wọn láwọn ìtọ́ni tí wọ́n nílò. Iṣẹ́ ńlá làwọn akọ̀wé wa máa ń ṣe láti tú àwọn lẹ́tà tí ìjọ kọ lédè Xhosa, Zulu àtàwọn èdè míì sí Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn náà, wọ́n á tú èsì tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ sí wọn láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sáwọn èdè yẹn. Mo mọyì iṣẹ́ takuntakun táwọn arákùnrin tó ń túmọ̀ àwọn lẹ́tà yẹn ń ṣe torí ìyẹn jẹ́ kí n mọ ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ dúdú ń kojú.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà wà lórílẹ̀-èdè South Africa. Ìjọba ṣòfin pé àwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn aláwọ̀ dúdú ò gbọ́dọ̀ máa ṣe nǹkan pa pọ̀. Kódà, ibi táwọn aláwọ̀ funfun ń gbé yàtọ̀ síbi táwọn aláwọ̀ dúdú ń gbé. Torí náà, èdè wọn ni àwọn ará wa tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú máa ń sọ, òun náà ni wọ́n fi ń wàásù, òun sì ni wọ́n fi ń ṣèpàdé.
Mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ará wa tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú torí pé ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni mo wà látìgbà tí mo ti dé South Africa. Ní báyìí, mo láǹfààní láti mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ará wa tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú àti àṣà wọn. Mo rí i pé kì í ṣohun kékeré làwọn ará wa ń kojú tó bá dọ̀rọ̀ àwọn àṣà ìbílẹ̀ àtàwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu. Wọ́n nígboyà gan-an! Ìdí ni pé kò rọrùn fún wọn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu àtàwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ìdílé wọn àtàwọn ará ìlú máa ń fúngun mọ́ wọn tí wọ́n sì máa ń ṣenúnibíni sí wọn torí pé wọn ò lọ́wọ́ sáwọn àṣà yẹn mọ́. Tálákà lèyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbé ní ìgbèríko. Ọ̀pọ̀ wọn ni ò lọ iléèwé, síbẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ìgbà kan wà tí mo wà lára àwọn tó bójú tó ọ̀rọ̀ ẹjọ́ nípa báwọn ará wa á ṣe lómìnira láti máa jọ́sìn Jèhófà bó ṣe yẹ, táwọn èèyàn ò sì ní máa fúngun mọ́ wọn láti ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn. Ó wúni lórí gan-an láti rí báwọn ọ̀dọ́ wa ṣe jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n sì lo ìgboyà nígbà tí wọ́n lé wọn kúrò níléèwé torí pé wọn ò dara pọ̀ nínú kíkọ orin ìsìn àti àdúrà.
Àwọn ará wa tún kojú ìṣòro míì lórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ń pè ní Swaziland nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Nígbà tí Ọba Sobhuza Kejì kú, ìjọba ṣòfin pé kí gbogbo ọkùnrin tó wà nílùú fá orí wọn, káwọn obìnrin sì gé irun wọn nítorí ẹni tó kú náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni wọ́n ṣenúnibíni sí torí wọn ò lọ́wọ́ sí àṣà tí kò bá Bíbélì mu yẹn, tó sì tún jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà. Bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà múnú wa dùn gan-an. Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn ará wa yẹn jẹ́ fún wa tó bá di pé ká jẹ́ olóòótọ́, ká jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì máa mú sùúrù, ìyẹn sì mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára.
MO PA DÀ SÍ Ẹ̀KA ÌTẸ̀WÉ
Lọ́dún 1981, ètò Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun tó ń lo kọ̀ǹpútà. Torí náà, wọ́n ní kí n pa dà sí Ẹ̀ka Ìtẹ̀wé, mo sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Ìtẹ̀síwájú túbọ̀ ń bá ọ̀nà tí wọ́n gbà ń tẹ̀wé lọ́pọ̀ ibi láyé, ìyẹn sì mú kí nǹkan yí pa dà gan-an. Ilé iṣẹ́ kan gbé ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan tó ń lo kọ̀ǹpútà fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé kí wọ́n lò ó wò láìgba owó. Èyí mú ká fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun márùn-ún tó ń lo kọ̀ǹpútà rọ́pò ẹ̀rọ Linotype mẹ́sàn-án tá à ń lò tẹ́lẹ̀. Nígbà tó yá, a tún ní ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá. Ìyẹn mú kí iṣẹ́ yá gan-an, a sì ń tẹ ọ̀pọ̀ ìwé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Àwọn ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tuntun náà tún mú ká lè lo ètò ìṣiṣẹ́ MEPS, ìyẹn Multilanguage Electronic Publishing System láti mú kí àwọn ìwé wa dùn ún wò, kí wọ́n sì túbọ̀ dùn ún kà. Ẹ ò rí i pé ìtẹ̀síwájú ńlá gbáà nìyẹn! A ò lo Linotype tó ṣòro lò yẹn mọ́. Ẹ má sì gbàgbé pé tìtorí ẹ̀rọ yẹn làwa mẹ́rin láti Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà ṣe wá sí South Africa. (Àìsá. 60:17) Lásìkò yìí, gbogbo wa ti gbéyàwó. Àwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà la fẹ́. Èmi àti Bill ṣì wà ní Bẹ́tẹ́lì, Ken àti Dennis ti bímọ, wọ́n sì ń gbé nítòsí Bẹ́tẹ́lì.
Iṣẹ́ túbọ̀ ń fẹjú ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àwọn èdè tá à ń túmọ̀ ìwé wa sí túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ìyẹn sì mú kí iye ìwé tá à ń tẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ń kó ìwé ránṣẹ́ sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì. Èyí mú kó pọn dandan pé ká kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun. Wọ́n kọ́ ọ sí ìlú kan nítòsí Johannesburg, wọ́n sì yà á sí mímọ́ lọ́dún 1987. Inú mi dùn pé gbogbo ìtẹ̀síwájú yìí ṣojú mi àti pé mo wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka South Africa fún ọ̀pọ̀ ọdún.
IṢẸ́ MI TÚN YÍ PA DÀ!
Ohun kan ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2001 tó yà mí lẹ́nu gan-an. Ètò Ọlọ́run ní kí n wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Amẹ́ríkà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wa ò dùn láti fi iṣẹ́ wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sílẹ̀ ní South Africa, a láyọ̀ pé a máa di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Amẹ́ríkà.
Àmọ́ à ń ṣàníyàn pé a máa fi màmá ìyàwó mi tó ti dàgbà sílẹ̀. Ìwọ̀nba la máa lè ṣe fún wọn láti New York, àmọ́ inú wa dùn pé àwọn àbúrò ìyàwó mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ pé àwọn á máa tọ́jú màmá. Wọ́n sọ pé: “Àwa ò lè ṣiṣẹ́ alákòókò kíkún, àmọ́ tá a bá ń tọ́jú màmá, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ lè máa báṣẹ́ yín lọ.” A mọrírì ohun tí wọ́n ṣe yẹn.
Ohun kan náà ni ẹ̀gbọ́n mi àtìyàwó wọn tó ń gbé ní Kánádà ṣe fún màmá wa lẹ́yìn tí bàbá wa kú. Nígbà yẹn, màmá mi ti lo ohun tó lé lógún ọdún lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi. A mọrírì bí wọ́n ṣe tọ́jú wọn títí wọ́n fi kú kété tá a dé New York. Nǹkan ayọ̀ ni téèyàn bá ní àwọn mọ̀lẹ́bí tó nífẹ̀ẹ́ ẹni, tó sì ṣe tán láti ṣe àwọn àyípadà kan kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe tí ò rọrùn!
Ẹ̀ka ìtẹ̀wé ni mo ti ṣiṣẹ́ fún ọdún mélòó kan ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ẹ̀rọ ìgbàlódé tó ń múṣẹ́ yá ni wọ́n sì ń lò. Àmọ́ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, Ẹ̀ka Tó Ń Rajà ni mo ti ń ṣiṣẹ́. Ogún (20) ọdún rèé tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ńlá yìí. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) làwa tá à ń gbé nínú Bẹ́tẹ́lì nígbà táwọn bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ń tilé wá ṣiṣẹ́. Mo láyọ̀ gan-an pé mo jẹ́ ara ìdílé yìí!
Mi ò lè ronú ẹ̀ láé ní ọgọ́ta (60) ọdún sẹ́yìn pé ibí ni màá wà lónìí. Mi ò jẹ́ kóyán ìyàwó mi kéré torí pé alátìlẹ́yìn gidi ló jẹ́ ní gbogbo àwọn ọdún yẹn. Tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, a gbádùn ìgbésí ayé wa gan-an! A gbádùn gbogbo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ti ní àti onírúurú àwọn ará tá a ti bá ṣiṣẹ́, títí kan àwọn tá a bá pàdé láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tá a bẹ̀ wò láwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé. Ní báyìí tí mo ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún, wọ́n ti dín àwọn iṣẹ́ mi kù torí a ti ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó kúnjú ìwọ̀n tí wọ́n lè bójú tó àwọn iṣẹ́ náà.
Onísáàmù kan sọ pé: “Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Sm. 33:12) Ó dájú pé òótọ́ ni onísáàmù yẹn sọ! Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà o pé èmi náà wà lára àwọn èèyàn ẹ̀ tó ń fayọ̀ sìn ín.