1 | Àdúrà “Ẹ Máa Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lọ Sọ́dọ̀ Rẹ̀”
BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ [Ọlọ́run], torí ó ń bójú tó yín.”—1 PÉTÉRÙ 5:7.
Ohun Tó Túmọ̀ Sí
Jèhófà Ọlọ́run ní ká bá òun sọ ohunkóhun tó dà bí ẹrù ìnira fún ọkàn àti ọpọlọ wa. (Sáàmù 55:22) Kò sí ìṣòro tó tóbi jù tàbí tó kéré jù láti gbàdúrà nípa ẹ̀. Tá a bá wà nínú ìṣòro, ó máa ń wu Jèhófà gan-an láti ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run.—Fílípì 4:6, 7.
Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
Tẹ́nì kan bá ní àárẹ̀ ọpọlọ, gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹni náà kì í sábà yé àwọn míì. (Òwe 14:10) Àmọ́ tó bá sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe é fún Ọlọ́run láìfi ohunkóhun pa mọ́, Ọlọ́run máa ṣàánú ẹ̀ torí pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ yé e. Jèhófà rí wa tán, ó mọ àwọn ohun tó ń fa ìnira fún wa, ó sì fẹ́ ká gbàdúrà sí òun nípa ohunkóhun tó ń kó ìdààmú bá wa.—2 Kíróníkà 6:29, 30.
Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, á túbọ̀ dá wa lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́. Àwa náà lè wá ṣe bíi ti onísáàmù tó sọ fún Jèhófà pé: “O ti rí ìpọ́njú mi; o mọ ìdààmú ńlá tó bá mi.” (Sáàmù 31:7) Tá a bá ń rántí pé Jèhófà mọ gbogbo bó ṣe ń ṣe wá, ìyẹn ò ní jẹ́ ká sọ̀rètí nù nígbà ìṣòro. Kì í ṣe pé Jèhófà rí àwọn ìṣòro wa nìkan, àmọ́ ó tún mọ bí ohun tí ìṣòro náà ń fà ṣe rí lára wa ju ẹnikẹ́ni míì lọ, ó sì ń lo Bíbélì láti fún wa ní ìṣírí àti ìtùnú.