ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 April ojú ìwé 8-13
  • Túbọ̀ Fọkàn Tán Jèhófà àti Ètò Ẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Túbọ̀ Fọkàn Tán Jèhófà àti Ètò Ẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÈTÒ ỌLỌ́RUN MÁA Ń TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ JÉSÙ
  • MÁA ṢE OHUN TÓ FI HÀN PÉ O MỌYÌ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
  • MÁ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN SỌ Ẹ́ DẸNI TÍ Ò FỌKÀN TÁN ÈTÒ ỌLỌ́RUN MỌ́
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìyàtọ̀ Láàárín Òtítọ́ àti Irọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Wàá Túbọ̀ Láyọ̀ Tó O Bá Ń Fún Àwọn Èèyàn Ní Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 April ojú ìwé 8-13

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 15

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

Túbọ̀ Fọkàn Tán Jèhófà àti Ètò Ẹ̀

“Ẹ máa rántí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín, tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín.”—HÉB. 13:7.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ètò Ọlọ́run, ká sì fọkàn tán an.

1. Báwo ni Jèhófà ṣe darí àwọn èèyàn ẹ̀ nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀?

TÍ JÈHÓFÀ bá gbé iṣẹ́ kan fáwa èèyàn ẹ̀, ó máa ń fẹ́ ká ṣe é létòlétò. (1 Kọ́r. 14:33) Bí àpẹẹrẹ, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn níbi gbogbo láyé. (Mát. 24:14) Jésù ni Jèhófà gbé iṣẹ́ náà fún, Jésù sì rí i dájú pé à ń ṣe iṣẹ́ náà létòlétò. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀, wọ́n sì yan àwọn alàgbà táá máa bójú tó àwọn ará ìjọ. (Ìṣe 14:23) Àwùjọ àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin máa ń ṣe àwọn ìpinnu lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan, àwọn alàgbà ìjọ á wá sọ ìpinnu náà fún gbogbo àwọn ará. (Ìṣe 15:2; 16:4) Torí pé àwọn ará ń ṣe ohun tí wọ́n sọ fún wọn, “àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.”—Ìṣe 16:5.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀, tó sì ń tọ́ wọn sọ́nà látọdún 1919?

2 Títí dòní, Jèhófà ṣì ń darí àwa èèyàn ẹ̀ ká lè máa ṣe nǹkan létòlétò, Jésù ló sì ń lò láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àtọdún 1919 ni Jésù ti ń lo àwùjọ àwọn ọkùnrin mélòó kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró láti ṣètò bí àá ṣe máa wàásù. Wọ́n tún máa ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.a (Lúùkù 12:42) Kò sí àní-àní pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí.—Àìsá. 60:22; 65:13, 14.

3-4. (a) Sọ àǹfààní tá à ń rí torí pé a wà létòlétò. (b) Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Tí kò bá sí ètò tá à ń tẹ̀ lé, a ò ní lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù gbé fún wa láṣeyọrí. (Mát. 28:19, 20) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé wọn ò ṣètò àwọn ibi tá a ti máa wàásù, tó jẹ́ pé kálukú kàn ń wàásù níbi tó wù ú, àwọn ìpínlẹ̀ kan máa wà tí àá máa ṣe léraléra, àwọn míì á sì wà tá ò ní ṣe rárá. Ṣé o ronú kan àwọn ọ̀nà míì tá à ń gbà jàǹfààní torí pé a wà létòlétò?

4 Jésù ṣètò àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nígbà tó wà láyé, ohun kan náà ló ṣì ń ṣe lónìí fáwa ìránṣẹ́ Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ àti bí ètò Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn lónìí. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ètò Ọlọ́run.

ÈTÒ ỌLỌ́RUN MÁA Ń TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ JÉSÙ

5. Sọ ọ̀nà kan tí ètò Ọlọ́run ń gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Jòhánù 8:28)

5 Ohun tí Jésù kọ́ lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ló ń ṣe, tó sì ń sọ. Bíi ti Jésù, ohun tí Bíbélì sọ ni ètò Ọlọ́run fi máa ń pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, tí wọ́n sì fi máa ń tọ́ wa sọ́nà. (Ka Jòhánù 8:28; 2 Tím. 3:16, 17) Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń rán wa létí pé ká máa ka Bíbélì déédéé, ká sì máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣohun tí wọ́n sọ yìí?

6. Sọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

6 Tá a bá ń fi àwọn ìwé wa ṣèwádìí nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí. Bí àpẹẹrẹ, ó máa jẹ́ ká lè fi ohun tí Bíbélì sọ wé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fún wa. Torí náà, tá a bá rí i pé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ bá ohun tí Bíbélì sọ mu, àá túbọ̀ fọkàn tán wọn.—Róòmù 12:2.

7. Kí ni Jésù wàásù nípa ẹ̀, báwo sì ni àwa tá a wà nínú ètò Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

7 Jésù wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43, 44) Jésù tún pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n wàásù nípa Ìjọba náà. (Lúùkù 9:1, 2; 10:8, 9) Lónìí, gbogbo àwa èèyàn Jèhófà tó wà nínú ètò rẹ̀ là ń wàásù nípa Ìjọba náà, láìka ibi tá à ń gbé sí tàbí ojúṣe tá a ní nínú ètò Ọlọ́run.

8. Àǹfààní ńlá wo la ní?

8 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn! Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló nírú àǹfààní yìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wà láyé, kò jẹ́ káwọn ẹ̀mí èsù sọ̀rọ̀ nípa òun. (Lúùkù 4:41) Lónìí, kẹ́nì kan tó lè máa wàásù pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sí. Torí náà, a máa fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti wàásù, tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo àti níbikíbi tá a bá ti rí wọn. Bíi ti Jésù, ohun táwa náà fẹ́ ni pé ká gbin ẹ̀kọ́ òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run sọ́kàn àwọn èèyàn, ká sì máa bomi rin ín.—Mát. 13:3, 23; 1 Kọ́r. 3:6.

9. Báwo ni ètò Ọlọ́run ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run?

9 Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, ó sọ pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.” (Jòh. 17:26) Bíi ti Jésù, ètò Ọlọ́run náà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ orúkọ Ọlọ́run. Torí náà, wọ́n rí i dájú pé àwọn dá orúkọ Ọlọ́run pa dà síbi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó ju igba ó lé àádọ́rin (270) lọ. Tó o bá wo Àfikún A4 àti A5 nínú ìtumọ̀ Bíbélì yìí, wàá rí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bá a ṣe dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sínú Bíbélì. Àfikún C, tó wà nínú Bíbélì tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì tún jẹ́ ká rí ẹ̀rí lóríṣiríṣi pé ó yẹ kí orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní ìgbà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́tàdínlógójì (237) nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

10. Kí lo kọ́ nínú ohun tí obìnrin kan tó ń gbé ní Myanmar sọ?

10 Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ orúkọ Ọlọ́run. Nígbà tí obìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin (67) tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Myanmar mọ̀ pé Ọlọ́run lórúkọ, omijé bọ́ lójú ẹ̀, ó sì sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ rèé láyé mi tí màá gbọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. . . . Ẹ ti kọ́ mi lóhun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kí n mọ̀.” Ìrírí obìnrin yìí jẹ́ ká rí i pé táwọn èèyàn bá mọ orúkọ Ọlọ́run, ó lè yí ìgbésí ayé wọn pa dà.

MÁA ṢE OHUN TÓ FI HÀN PÉ O MỌYÌ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

11. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fi hàn pé ẹ mọyì ètò Ọlọ́run? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fi hàn pé ẹ mọyì ètò Ọlọ́run? Tí ètò Ọlọ́run bá ní kẹ́ ẹ ṣe ohun kan, ó yẹ kẹ́ ẹ fara balẹ̀ ka ohun tí wọ́n sọ, kẹ́ ẹ sì rí i dájú pé ẹ ṣe nǹkan náà. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run máa ń sọ bẹ́ ẹ ṣe máa darí ìpàdé, bẹ́ ẹ ṣe máa gbàdúrà nínú ìjọ àti bẹ́ ẹ ṣe máa bójú tó àwọn ará tí Kristi fi síkàáwọ́ yín. Torí náà, tẹ́yin alàgbà bá ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, ọkàn àwọn ará máa balẹ̀, wọ́n á sì rí i pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn.

Fọ́tò: 1. Àwọn alàgbà mẹ́ta pàdé ní Ilé Ìpàdé, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn. 2. Lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwọn alàgbà yẹn ń sọ fún àwọn arábìnrin méjì nípa ibi tí wọ́n máa gbé àtẹ ìwé sí, tí jàǹbá ò ti ní ṣe wọ́n.

Àwọn alàgbà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fún wa (Wo ìpínrọ̀ 11)b


12. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe ohun táwọn tó ń ṣàbójútó wa bá sọ fún wa? (Hébérù 13:7, 17) (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wo ibi táwọn tó ń ṣàbójútó wa dáa sí?

12 Táwọn alàgbà bá ní ká ṣe nǹkan kan, ó yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa ṣe é. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kí iṣẹ́ àbójútó rọ̀ wọ́n lọ́rùn, inú wọn á sì máa dùn. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ṣègbọràn sáwọn tó ń ṣàbójútó wa, ká sì máa tẹrí ba fún wọn. (Ka Hébérù 13:7, 17.) Ká sòótọ́, kì í rọrùn nígbà míì. Kí nìdí? Ìdí ni pé aláìpé ni wọ́n. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ibi tí wọ́n kù sí là ń wò, tá ò wo ibi tí wọ́n dáa sí, ṣe làwọn ọ̀tá wa máa ráyè wọlé sí wa lára. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó lè má jẹ́ ká fọkàn tán ètò Ọlọ́run mọ́, ohun táwọn ọ̀tá wa sì fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Báwo la ṣe lè mọ irọ́ táwọn ọ̀tá ń pa mọ́ wa, tá ò sì ní gba àwọn irọ́ náà gbọ́?

MÁ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN SỌ Ẹ́ DẸNI TÍ Ò FỌKÀN TÁN ÈTÒ ỌLỌ́RUN MỌ́

13. Ohun tí ò dáa wo làwọn ọ̀tá Ọlọ́run máa ń sọ nípa ètò rẹ̀?

13 Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run máa ń sọ ohun tí ò dáa nípa ètò Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa là ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì ni pé káwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà máa jẹ́ kára wa mọ́ tónítóní, ká jẹ́ kí ìwà wa dáa, ká sì máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́. Jèhófà ní kí wọ́n yọ ẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá, tí kò sì ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:11-13; 6:9, 10) A sì máa ń rí i pé a ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ torí pé à ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ, àwọn tó ń ta kò wá máa ń sọ pé a máa ń fọwọ́ tó le jù mú nǹkan, a máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, a ò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.

14. Ta ló wà nídìí irọ́ táwọn èèyàn ń pa mọ́ ètò Ọlọ́run?

14 Mọ ẹni tó ń ta kò wá. Sátánì Èṣù ló wà nídìí irọ́ táwọn èèyàn ń pa mọ́ ètò Ọlọ́run. Òun gan-an ni “baba irọ́.” (Jòh. 8:44; Jẹ́n. 3:1-5) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Sátánì ń lo àwọn ọ̀tá wa láti pa oríṣiríṣi irọ́ mọ́ ètò Ọlọ́run. Irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀.

15. Kí làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe fún Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀?

15 Nígbà tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé wà láyé, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, àmọ́ Sátánì lo àwọn ọ̀tá láti pa oríṣiríṣi irọ́ mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn sọ fáwọn èèyàn pé “alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù” ló fún Jésù lágbára tó fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. (Máàkù 3:22) Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ Jésù, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn tún fẹ̀sùn kàn án pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì, wọ́n sì rọ àwọn èèyàn náà láti sọ fáwọn aláṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù. (Mát. 27:20) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń wàásù ìhìn rere, àwọn alátakò ‘ru àwọn èèyàn sókè’ kí wọ́n lè ṣenúnibíni sí wọn. (Ìṣe 14:2, 19) Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ December 1, 1998 ń ṣàlàyé Ìṣe 14:2, ó sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé àwọn Júù alátakò yẹn ò tẹ́tí sí ìhìn rere táwọn Kristẹni ń wàásù, ṣe ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n lórúkọ jẹ́ káwọn èèyàn má bàa tẹ́tí sí wọn, kí wọ́n sì kórìíra wọn.”

16. Kí ló yẹ ká máa rántí tá a bá gbọ́ ìròyìn èké nípa ètò Ọlọ́run?

16 Sátánì ṣì ń parọ́ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà títí dòní. Kódà, ó ṣì ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà.” (Ìfi. 12:9) Tó o bá gbọ́ ìròyìn tí kì í ṣòótọ́ nípa ètò Ọlọ́run tàbí àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa, máa rántí pé àwọn ọ̀tá Ọlọ́run pa irú irọ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sáwa èèyàn Jèhófà, ohun táwọn alátakò sì ń ṣe sí wa lónìí nìyẹn. (Mát. 5:11, 12) Tá a bá ń rántí pé Sátánì ló ń lo àwọn alátakò yẹn láti parọ́ mọ́ wa, a ò ní gba irọ́ wọn gbọ́, àá sì kọ̀ ọ́ lójú ẹsẹ̀. Torí náà, kí la lè ṣe tá ò fi ní gba ìròyìn èké gbọ́?

17. Kí la lè ṣe tá ò fi ní gba ìròyìn tó lè pa wá lára gbọ́? (2 Tímótì 1:13) (Tún wo àpótí náà “Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Tó O Bá Gbọ́ Ìròyìn Èké.”)

17 Má gba ìròyìn èké gbọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá gbọ́ ìròyìn èké. Ó sọ fún Tímótì pé kó “pàṣẹ fún àwọn kan pé kí wọ́n má . . . tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké” àti “ìtàn èké tí kò buyì kúnni.” (1 Tím. 1:3, 4; 4:7) Ọmọ kékeré kan lè mú nǹkan kan nílẹ̀ kó sì kì í bọ ẹnu láìmọ̀ pé kò dáa, àmọ́ àgbàlagbà ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó mọ̀ pé ó léwu. Lọ́nà kan náà, torí a mọ̀ pé Sátánì ló wà nídìí irọ́ táwọn èèyàn ń pa mọ́ wa, a kì í gba irọ́ náà gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, “àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní” nìkan la máa ń tẹ́tí sí.—Ka 2 Tímótì 1:13.

Fọ́tò: Báwọn èèyàn ṣe máa ń tan ìròyìn èké kiri. 1. Ọkùnrin kan ń ṣe àtẹ́tísí orí ìkànnì. 2. Obìnrin kan ń ṣòfófó. 3. Lẹ́tà orí ìkànnì táwọn tá ò mọ̀ rí fi ránṣẹ́ sí wa. 4. Arábìnrin kan rí ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i nínú àpótí tí wọ́n fi ń gba lẹ́tà, ó sì ya á.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Tó O Bá Gbọ́ Ìròyìn Èké

Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn lè gbà tan ìròyìn tí kì í ṣòótọ́ kiri. Bí àpẹẹrẹ, ó lè wu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ sí wa, àmọ́ kí wọ́n má fara balẹ̀ wò ó dáadáa bóyá òótọ́ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwọn kan tá ò mọ̀ rí sì lè kọ lẹ́tà orí ìkànnì láti fi irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù wa. A tún lè gbọ́ ìròyìn èké lẹ́nu àwọn apẹ̀yìndà nígbà tá a bá ń wàásù, tó sì jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń díbọ́n bíi pé àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

1. Ìròyìn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa fi ránṣẹ́ sí wa:

Béèrè lọ́wọ́ arákùnrin tàbí arábìnrin náà pé ṣé ó ti wádìí bóyá ìròyìn náà jóòótọ́. Tí kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, má gba ìròyìn náà gbọ́, má kà á, má sì fi ránṣẹ́ sáwọn ẹlòmíì.—Òwe 14:15.

2. Lẹ́tà orí ìkànnì tó jẹ́ ìròyìn àsọdùn nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn tá ò mọ̀ rí fi ránṣẹ́ sí wa:

Nígbà míì, ó lè dà bíi pé àwọn ará wa ló fi àwọn lẹ́tà orí ìkànnì bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí wa. Torí náà, béèrè lọ́wọ́ arákùnrin tàbí arábìnrin náà bóyá òun ló fi ránṣẹ́ sí ẹ àti pé ṣé ó ti wádìí bóyá ìròyìn náà jóòótọ́. Tó bá sọ pé òun kọ́ lòun fi ránṣẹ́ tàbí tí kò ṣèwádìí nípa ẹ̀, yọ ọ́ kúrò lórí fóònù ẹ kíá.—Òwe 27:12.

3. Àwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n ń díbọ́n bíi pé àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì:

Tó o bá rí i pé ohun tí ò dáa nípa ètò Ọlọ́run lẹni náà máa ń sọ ṣáá tàbí tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ èké àwọn apẹ̀yìndà, rọra fọgbọ́n fòpin sírú ìjíròrò bẹ́ẹ̀.—2 Jòh. 10.

18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ètò Ọlọ́run?

18 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà mẹ́ta tí ètò Ọlọ́run ń gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, máa kíyè sí àwọn ọ̀nà míì tí ètò Ọlọ́run ń gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Máa ran àwọn ará lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, má sì fi ètò rẹ̀ sílẹ̀ torí òun ló ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ mọyì ètò Ọlọ́run. (Sm. 37:28) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn ní gbogbo ìgbà pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti wà lára àwọn ará tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ nínú ètò rẹ̀.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Àwọn nǹkan wo làwa èèyàn Jèhófà ń ṣe tó fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

  • Báwo la ṣe lè máa fi hàn pé a mọyì ètò Ọlọ́run?

  • Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbọ́ ìròyìn tí kì í ṣòótọ́?

ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

a Wo àpótí náà “Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919” nínú ìwé Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò! lójú ìwé 102-103.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn táwọn alàgbà jíròrò ohun tí ètò Ọlọ́run sọ nípa báwọn ará ṣe máa wàásù níbi àtẹ ìwé, alábòójútó àwùjọ kan wá ń sọ ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fáwọn ará pé kí wọ́n dúró síbi tí wọ́n á ti kẹ̀yìn sí ògiri kí jàǹbá má bàa ṣe wọ́n.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́