ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 28
ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìyàtọ̀ Láàárín Òtítọ́ àti Irọ́?
“Ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ fi òtítọ́ di inú yín lámùrè.”—ÉFÉ. 6:14.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa mọ ìyàtọ̀ láàárín òtítọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa àti irọ́ burúkú tí Sátánì àtàwọn tó ń ta kò wá ń pa káàkiri.
1. Báwo ni òtítọ́ tó o kọ́ ṣe rí lára ẹ?
ÀWA èèyàn Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Òtítọ́ yìí la sì gbà gbọ́. (Róòmù 10:17) Ó ti dá wa lójú báyìí pé Jèhófà dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ kó lè jẹ́ “òpó àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tím. 3:15) Inú wa sì dùn láti ṣe ohun tí “àwọn tó ń mú ipò iwájú” láàárín wa bá sọ fún wa bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, tí wọ́n sì ń tọ́ wa sọ́nà bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.—Héb. 13:17.
2. Bí Jémíìsì 5:19 ṣe sọ, kí ló lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
2 Síbẹ̀, lẹ́yìn tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tá a sì ti mọ̀ pé ètò Ọlọ́run ni Jèhófà ń lò láti tọ́ wa sọ́nà, a ṣì lè ṣìnà. (Ka Jémíìsì 5:19.) Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé ká má gba òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì gbọ́ mọ́, ká má sì tẹ̀ lé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fún wa.—Éfé. 4:14.
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká di òtítọ́ mú ṣinṣin? (Éfésù 6:13, 14)
3 Ka Éfésù 6:13, 14. Láìpẹ́, Èṣù máa fi irọ́ ṣi gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́nà láti ta ko Jèhófà. (Ìfi. 16:13, 14) A sì mọ̀ pé Sátánì máa lo gbogbo agbára ẹ̀ láti ṣi àwa èèyàn Jèhófà lọ́nà. (Ìfi. 12:9) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ ara wa láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín òtítọ́ àti irọ́, ká sì pinnu pé òtítọ́ la máa dì mú. (Róòmù 6:17; 1 Pét. 1:22) Ìdí sì ni pé òtítọ́ tá a bá mọ̀ ló máa jẹ́ ká là á já nígbà ìpọ́njú ńlá!
4. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ méjì tó máa jẹ́ ká dá òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì mọ̀, táá sì jẹ́ ká máa ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ fún wa. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó yẹ ká ṣe ká lè di òtítọ́ mú ṣinṣin.
ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÁÁ JẸ́ KÁ DÁ ÒTÍTỌ́ MỌ̀
5. Tá a bá bẹ̀rù Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká dá òtítọ́ mọ̀?
5 Ìbẹ̀rù Jèhófà. Tá a bá bẹ̀rù Jèhófà bó ṣe yẹ, a máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an débi pé a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bà á nínú jẹ́. Á máa wù wá láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ àti ìyàtọ̀ tó wà láàárín òtítọ́ àti irọ́ ká lè máa ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn. (Òwe 2:3-6; Héb. 5:14) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn ju ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lọ torí pé ohun táwọn èèyàn fẹ́ kì í sábà múnú Jèhófà dùn.
6. Kí ni ìbẹ̀rù èèyàn mú káwọn ìjòyè Ísírẹ́lì mẹ́wàá ṣe?
6 Tá a bá bẹ̀rù àwọn èèyàn ju bá a ṣe bẹ̀rù Ọlọ́run lọ, ó lè mú ká kúrò nínú òtítọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ìjòyè méjìlá (12) lọ ṣe amí ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí pé òun fẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mẹ́wàá lára àwọn amí yẹn bẹ̀rù àwọn ọmọ Kénáánì gan-an, ìyẹn sì fi hàn pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Wọ́n sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù pé: “A ò lè lọ bá àwọn èèyàn náà jà, torí wọ́n lágbára jù wá lọ.” (Nọ́ń. 13:27-31) Tá a bá ní ká fojú èèyàn wò ó, àwọn ọmọ Kénáánì lágbára ju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ lóòótọ́. Àmọ́ irọ́ ni wọ́n pa bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn torí ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé àwọn ọ̀tá yẹn lágbára ju Jèhófà lọ. Ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ló yẹ káwọn amí mẹ́wàá yẹn gbájú mọ́. Ó sì tún yẹ kí wọ́n ronú nípa bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n sílẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Ìyẹn ò bá ti jẹ́ kí wọ́n rí i pé agbára àwọn ọmọ Kénáánì ò tó nǹkan tá a bá fi wé agbára ńlá tí Jèhófà ní. Jóṣúà àti Kélẹ́bù ò ṣe bí àwọn amí tí ò nígbàgbọ́ yẹn torí pé wọ́n fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Wọ́n sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Bí inú Jèhófà bá dùn sí wa, ó dájú pé ó máa mú wa dé ilẹ̀ yìí.”—Nọ́ń. 14:6-9.
7. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ máa bẹ̀rù Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Ká lè túbọ̀ bẹ̀rù Jèhófà, bá a ṣe máa ṣèpinnu táá múnú ẹ̀ dùn ló yẹ kó jẹ wá lógún. (Sm. 16:8) Tó o bá ń ka ìtàn kan nínú Bíbélì, bi ara ẹ pé, ‘Tó bá jẹ́ pé èmi nirú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, kí ni màá ṣe?’ Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wò ó pé o wà níbi táwọn ìjòyè Ísírẹ́lì mẹ́wàá yẹn ti ń sọ ohun tí ò dáa nípa ibi tí wọ́n lọ. Ṣé ìbẹ̀rù Jèhófà àti bó ṣe ń wù ẹ́ láti múnú ẹ̀ dùn ló máa borí àbí ṣe ni wàá jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn mú kó o máa gbọ̀n jìnnìjìnnì? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ò gba ohun tí Jóṣúà àti Kélẹ́bù sọ gbọ́. Ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Nọ́ń. 14:10, 22, 23.
Ká sọ pé o wà níbẹ̀, ta lo máa gbà gbọ́? (Wo ìpínrọ̀ 7)
8. Ìwà wo ló yẹ ká sapá láti ní, kí sì nìdí?
8 Ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn tó nírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà máa ń jẹ́ kó mọ òtítọ́. (Mát. 11:25) Torí pé a nírẹ̀lẹ̀ la ṣe gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 8:30, 31) Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ kíyè sára ká má bàa jọ ara wa lójú. Tá a bá jọ ara wa lójú, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé ohun kan náà ni èrò wa pẹ̀lú ohun tí ìlànà Bíbélì sọ àtohun tí ètò Ọlọ́run ní ká ṣe, tó sì lè má rí bẹ́ẹ̀.
9. Kí lá mú ká máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nìṣó?
9 Ká lè máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nìṣó, ó yẹ ká máa rántí pé a ò tó nǹkan kan tá a bá fi ara wa wé Jèhófà. (Sm. 8:3, 4) A tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká túbọ̀ nírẹ̀lẹ̀, ká sì ṣe tán láti gba ẹ̀kọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ ká mọ̀ pé èrò òun ṣe pàtàkì ju èrò wa lọ, ó sì ń fi èyí kọ́ wa nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ àti ètò ẹ̀. Tó o bá ń ka Bíbélì, ronú nípa bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn tó nírẹ̀lẹ̀ àti bó ṣe kórìíra àwọn tó jọ ara wọn lójú, tí wọ́n sì gbéra ga. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o kíyè sára kó o má bàa gbéra ga tí wọ́n bá fún ẹ láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìsìn kan nínú ètò Ọlọ́run táá jẹ́ káwọn ará mọ̀ ẹ́.
KÍ LÓ MÁA JẸ́ KÁ DI ÒTÍTỌ́ MÚ ṢINṢIN?
10. Àwọn wo ni Jèhófà lò láti máa tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà, kí wọ́n sì máa darí wọn?
10 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ètò Ọlọ́run ni Jèhófà ń lò. Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, Mósè ni Jèhófà lò láti darí àwọn èèyàn ẹ̀, ó sì lo Jóṣúà náà nígbà tó yá. (Jóṣ. 1:16, 17) Gbogbo ìgbà ni nǹkan máa ń lọ dáadáa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá ṣègbọràn sáwọn tí Jèhófà ní kó máa darí wọn. Nígbà tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) ló máa ń sọ ohun táwọn Kristẹni máa ṣe. (Ìṣe 8:14, 15) Lẹ́yìn náà, wọ́n yan àwọn alàgbà kan láti Jerúsálẹ́mù láti dara pọ̀ mọ́ àwọn àpọ́sítélì, kí wọ́n lè jọ máa ṣèpinnu. Báwọn Kristẹni ṣe ń tẹ̀ lé ohun táwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí ń sọ fún wọn, “àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.” (Ìṣe 16:4, 5) Bákan náà lónìí, Jèhófà máa ń bù kún wa tá a bá ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run ní ká ṣe. Àmọ́ báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà tá a bá ń ta ko àwọn tó yàn láti bójú tó wa? Ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà táwọn aṣojú Ọlọ́run ń darí wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí.
11. Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò gbà pé Mósè ni Jèhófà ń lò láti darí wọn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìnrìn àjò lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn ọkùnrin tó gbajúmọ̀ láàárín wọn wá bá Mósè, wọ́n sì sọ fún un pé Jèhófà kọ́ ló yàn án láti máa darí àwọn. Wọ́n ní: ‘Gbogbo àpéjọ yìí ló jẹ́ mímọ́, kì í ṣe Mósè nìkan, gbogbo wọn pátá, Jèhófà sì wà láàárín wọn.’ (Nọ́ń. 16:1-3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé “gbogbo àpéjọ” náà jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà, Mósè ló yàn láti máa darí àwọn èèyàn ẹ̀. (Nọ́ń. 16:28) Torí náà, báwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe ń ṣàríwísí Mósè, Jèhófà ni wọ́n ń ṣàríwísí ẹ̀. Wọn ò gbájú mọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́, bí wọ́n ṣe máa ní agbára àti òkìkí tó pọ̀ sí i ni wọ́n ń wá. Ọlọ́run pa gbogbo olórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run, ó sì tún pa gbogbo àwọn tó fara mọ́ wọn. (Nọ́ń. 16:30-35, 41, 49) Lónìí, ó dájú pé inú Jèhófà ò ní dùn sí ẹni tí ò bá tẹ̀ lé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ.
Ká sọ pé o wà níbẹ̀, ta lo máa fara mọ́? (Wo ìpínrọ̀ 11)
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán ètò Ọlọ́run?
12 Ó yẹ ká fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Tí àwọn tó ń ṣàbójútó wa nínú ètò Ọlọ́run bá rí i pé ó yẹ káwọn ṣàtúnṣe òye Bíbélì tá a ní tàbí kí wọ́n ṣàtúnṣe ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn Jèhófà, wọ́n máa ń tètè ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 4:18) Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ló ṣe pàtàkì jù. Wọ́n máa ń rí i dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n fi ń ṣe ìpinnu tí wọ́n bá fẹ́ ṣe, ìlànà yìí sì ni gbogbo àwa èèyàn Jèhófà máa ń tẹ̀ lé.
13. Kí ni “ìlànà àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní,” irú ọwọ́ wo ló sì yẹ ká fi mú un?
13 “Máa tẹ̀ lé ìlànà àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní.” (2 Tím. 1:13) “Ìlànà àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní” ni àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni tó wà nínú Bíbélì. (Jòh. 17:17) Àwọn ẹ̀kọ́ yìí ni ìpìlẹ̀ gbogbo ohun tá a gbà gbọ́. Ètò Ọlọ́run sì ti kọ́ wa pé ká rọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ yìí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bù kún wa.
14. Báwo làwọn Kristẹni kan ò ṣe rọ̀ mọ́ “ìlànà àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní”?
14 Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá rọ̀ mọ́ “ìlànà àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní”? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn kan ń sọ ọ́ kiri láàárín àwọn Kristẹni pé ọjọ́ Jèhófà ti dé. Kí ló fà á tí wọ́n fi ń sọ àhesọ yẹn? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n gba lẹ́tà kan tí wọ́n rò pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ ọ́. Láì wádìí ọ̀rọ̀ náà, àwọn Kristẹni kan ní Tẹsalóníkà gba àhesọ náà gbọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ kiri. Ká sọ pé wọ́n rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ́ wọn nígbà tó wà lọ́dọ̀ wọn ni, wọn ò ní gba irọ́ náà gbọ́. (2 Tẹs. 2:1-5) Torí náà, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará nímọ̀ràn pé kì í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá gbọ́ ló yẹ kí wọ́n gbà gbọ́. Kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ má bàa wáyé lọ́jọ́ iwájú, Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ kan nígbà tó ń parí lẹ́tà rẹ̀ kejì tó kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà, ó ní: “Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ, ó jẹ́ àmì nínú gbogbo lẹ́tà mi; bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyí.”—2 Tẹs. 3:17.
15. Kí ni ò ní jẹ́ ká gba irọ́ tó jọ òótọ́ gbọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Kí la lè kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà? Tá a bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan tó ta ko ohun tá a ti kọ́ nínú Bíbélì tàbí tá a gbọ́ ìròyìn tó ń dẹ́rù bani, ó yẹ ká wádìí ẹ̀ wò ká tó gbà á gbọ́. Nígbà ìjọba Soviet Union, àwọn ọ̀tá ètò Ọlọ́run kọ lẹ́tà kan tó jọ pé oríléeṣẹ́ ló ti wá, wọ́n sì pín in kiri. Lẹ́tà yẹn sọ pé kí àwọn arákùnrin kan dá ètò kan sílẹ̀ tí kì í ṣe ara ètò Ọlọ́run. Ẹni tó bá ka lẹ́tà náà máa rò pé ètò Ọlọ́run ló kọ ọ́. Àmọ́, àwọn arákùnrin olóòótọ́ ò jẹ́ kí lẹ́tà náà tan àwọn jẹ. Wọ́n mọ̀ pé ohun tó wà nínú lẹ́tà yẹn ta ko ohun tí ètò Ọlọ́run kọ́ wọn. Bákan náà lásìkò wa yìí, àwọn ọ̀tá òtítọ́ máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì àti ìkànnì àjọlò láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ kí wọ́n lè dá ìyapa sáàárín wa. Dípò “kí ọkàn [wa] tètè mì,” ó yẹ ká ronú dáadáa nípa ohun tá a gbọ́ tàbí ohun tá a kà bóyá ó ta ko òtítọ́ tá a ti kọ́, ìyẹn sì máa dáàbò bò wá.—2 Tẹs. 2:2; 1 Jòh. 4:1.
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n fi irọ́ tó jọ òótọ́ tàn ẹ́ jẹ (Wo ìpínrọ̀ 15)a
16. Kí ni Róòmù 16:17, 18 sọ pé ká ṣe táwọn kan bá ń sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nínú ìjọ?
16 Wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo àwa tá à ń jọ́sìn ẹ̀ wà níṣọ̀kan. A máa wà níṣọ̀kan tá a bá rọ̀ mọ́ òtítọ́. Àwọn tó ń sọ ohun tó ta ko òtítọ́ máa ń fa ìyapa nínú ìjọ, torí náà, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé ká “yẹra fún wọn.” Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í gba àwọn nǹkan tí kì í ṣe òótọ́ gbọ́, ó sì lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀.—Ka Róòmù 16:17, 18.
17. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá mọ òtítọ́, tá a sì dì í mú ṣinṣin?
17 Tá a bá mọ òtítọ́, tá a sì dì í mú ṣinṣin, a máa sún mọ́ Jèhófà, ìgbàgbọ́ wa á sì lágbára. (Éfé. 4:15, 16) Yàtọ̀ síyẹn, Sátánì ò ní lè fi irọ́ àti ẹ̀kọ́ èké tàn wá jẹ, Jèhófà á sì dáàbò bò wá nígbà ìpọ́njú ńlá. Torí náà, ẹ jẹ́ ká di òtítọ́ mú ṣinṣin, “Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú [wa].”—Fílí. 4:8, 9.
ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin
a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí jẹ́ ká rí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Soviet Union táwọn ọ̀tá ètò Ọlọ́run kọ lẹ́tà kan tó jọ pé oríléeṣẹ́ ló ti wá. Bákan náà lásìkò wa yìí, àwọn ọ̀tá wa máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi sọ ohun tí ò jóòótọ́ nípa ètò Ọlọ́run.