ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 March ojú ìwé 20-25
  • Máa Ṣe Ohun Tó Fi Hàn Pé O Nígbàgbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣe Ohun Tó Fi Hàn Pé O Nígbàgbọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • TÁ A BÁ Ń WÁṢẸ́
  • TÁ A BÁ FẸ́ YAN ẸNI TÁ A MÁA FẸ́
  • TÍ ÈTÒ ỌLỌ́RUN BÁ SỌ OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Bó O Ṣe Lè Borí Èrò Tí Ò Tọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Máa Ṣe Ìpinnu Táá Múnú Jèhófà Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 March ojú ìwé 20-25

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 12

ORIN 119 Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́

Máa Ṣe Ohun Tó Fi Hàn Pé O Nígbàgbọ́

“À ń rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí à ń rí.”—2 KỌ́R. 5:7.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa kọ́ bá a ṣe lè gbára lé Jèhófà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.

1. Kí nìdí tí inú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi dùn nígbà tó rántí ohun tó fayé ẹ̀ ṣe?

ÌGBÀ kan wà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé wọ́n máa tó pa òun, àmọ́ inú ẹ̀ dùn nígbà tó rántí ohun tó fayé ẹ̀ ṣe. Nígbà tó ń ronú nípa ẹ̀, ó sọ pé: “Mo ti sá eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Tím. 4:6-8) Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, ó sì dá a lójú pé inú Jèhófà dùn sóun. Àwa náà fẹ́ ṣe ìpinnu tó dáa, a sì fẹ́ kínú Jèhófà dùn sí wa. Báwo la ṣe máa ṣe é?

2. Kí ni ẹni tó ń rìn nípa ìgbàgbọ́ máa ń ṣe?

2 Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara ẹ̀ àtàwọn Kristẹni olóòótọ́ míì pé: “À ń rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí à ń rí.” (2 Kọ́r. 5:7) Kí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ? Nígbà míì nínú Bíbélì, tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan “ń rìn,” ohun tí wọ́n ń sọ ni bí ẹni náà ṣe ń gbé ìgbé ayé ẹ̀. Tí ẹnì kan bá ń rìn nípa ohun tó ń rí, ẹni náà á máa fi ohun tó rí, ohun tó gbọ́ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ ṣèpinnu. Àmọ́ ẹni tó ń rìn nípa ìgbàgbọ́ máa ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ tó bá fẹ́ ṣèpinnu. Ó dá a lójú pé tóun bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ayé òun máa dáa nísinsìnyí, Jèhófà sì máa bù kún òun lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 119:66; Héb. 11:6.

3. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́? (2 Kọ́ríńtì 4:18)

3 Òótọ́ ni pé nígbà míì, gbogbo wa la máa ń ṣèpinnu torí ohun tá a rí. Àmọ́ ó ṣeé ṣe ká níṣòro tó bá jẹ́ pé àwọn ohun tá a rí tàbí ohun tá a gbọ́ nìkan la fi ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nígbà míì, ohun tá a rí tàbí ohun tá a gbọ́ lè má jẹ́ òótọ́. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ lohun tá a rí, àmọ́ tó jẹ́ ìyẹn nìkan la fẹ́ fi ṣèpinnu, a ṣì máa ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. (Oníw. 11:9; Mát. 24:37-39) Àmọ́ tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́, àá máa ṣèpinnu “tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.” (Éfé. 5:10) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run, ọkàn wa máa balẹ̀, àá sì láyọ̀. (Sm. 16:8, 9; Àìsá. 48:17, 18) Tá a bá sì ń rìn nípa ìgbàgbọ́, a máa wà láàyè títí láé.—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:18.

4. Báwo lẹnì kan ṣe lè mọ̀ bóyá òun ń rìn nípa ìgbàgbọ́ tàbí nípa ohun tóun ń rí?

4 Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá à ń rìn nípa ìgbàgbọ́ tàbí nípa ohun tá à ń rí? Àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká mọ̀: Àwọn nǹkan wo ni mo máa ń rò tí mo bá fẹ́ ṣèpinnu? Ṣé àwọn nǹkan tí mo bá rí nìkan ni mo fi ń ṣèpinnu? Àbí mo máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà, mo sì máa ń gbẹ́kẹ̀ lé e? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa rìn nípa ìgbàgbọ́ láwọn apá pàtàkì mẹ́ta yìí: tá a bá ń wáṣẹ́, tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́ àti ìgbà tí ètò Ọlọ́run bá sọ ohun tó yẹ ká ṣe. Ní apá kọ̀ọ̀kan, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ká lè ṣèpinnu tó dáa.

TÁ A BÁ Ń WÁṢẸ́

5. Kí ló yẹ ká rò tá a bá fẹ́ wá iṣẹ́ tá a máa ṣe?

5 Gbogbo wa ló máa ń wù pé ká lè pèsè ohun táwa àti ìdílé wa nílò. (Oníw. 7:12; 1 Tím. 5:8) Àwọn iṣẹ́ kan máa ń mówó gọbọi wọlé. Irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè mú kó rọrùn láti gbọ́ bùkátà, kéèyàn sì tún tọ́jú owó pa mọ́. Owó tó kéré lèèyàn máa rí nídìí àwọn iṣẹ́ míì, àwọn nǹkan kòṣeémáàní nìkan nirú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè pèsè fún ìdílé. Lóòótọ́, tá a bá fẹ́ gbaṣẹ́ kan, a máa ro iye owó tí wọ́n á máa san fún wa. Àmọ́ tẹ́nì kan bá ń rìn nípa ohun tó ń rí, iye owó yẹn nìkan lá máa rò.

6. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń rìn nípa ìgbàgbọ́ tá a bá fẹ́ wá iṣẹ́ tá a máa ṣe? (Hébérù 13:5)

6 Tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́, a máa ronú nípa ìpalára tí iṣẹ́ tá a fẹ́ gbà lè ṣe fún àjọṣe àwa àti Jèhófà. Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé iṣẹ́ náà máa gba pé kí n máa ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra?’ (Òwe 6:16-19) ‘Ṣé ó máa dí ìjọsìn mi lọ́wọ́, ṣé ó máa gba pé kí n fi ìdílé mi sílẹ̀, kí n sì pẹ́ níbi tí mo lọ?’ (Fílí. 1:10) Tí ìdáhùn wa bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, á dáa ká má gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tí ò bá tiẹ̀ rọrùn láti ríṣẹ́. Tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́, àá máa ṣe àwọn ìpinnu tó fi hàn pé a gbà pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tá a nílò.—Mát. 6:33; ka Hébérù 13:5.

7-8. Báwo ni Arákùnrin Javier ṣe rìn nípa ìgbàgbọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Ẹ jẹ́ ká wo bí Arákùnrin Javier a tó ń gbé South America ṣe ń rìn nípa ìgbàgbọ́. Ó sọ pé: “Àyè kan ṣí sílẹ̀ níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ táá jẹ́ kí n máa gba ìlọ́po méjì owó tí mò ń gbà báyìí, wọ́n á sì máa fún mi láwọn owó àjẹmọ́nú míì àtàwọn nǹkan amáyédẹrùn, mo sì kọ̀wé kí wọ́n lè fún mi níṣẹ́ náà.” Àmọ́ ó wu Javier gan-an pé kó di aṣáájú-ọ̀nà. Ó tún sọ pé: “Wọ́n ní kí ọ̀kan lára ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ náà fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Kó tó fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ torí òun ló mọ ohun tó dáa jù fún mi. Ó wù mí kí n tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ mi, àmọ́ mi ò ní gba iṣẹ́ yìí tí ò bá ní jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ ohun tí mo fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run.”

8 Javier sọ pé: “Nígbà tó ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, ọ̀gá náà sọ fún mi pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni màá máa ṣe àfikún iṣẹ́. Mo wá sọ fún un pé mi ò ní lè ṣe àfikún iṣẹ́ torí ìjọsìn mi.” Bí Javier ò ṣe gbaṣẹ́ yẹn nìyẹn. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Kí ọdún yẹn tó parí, ó ríṣẹ́ tí ò ní máa gba gbogbo àkókò ẹ̀. Ó sọ pé: “Jèhófà gbọ́ àdúrà mi, ó sì pèsè iṣẹ́ táá jẹ́ kí n máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Inú mi dùn pé mo ríṣẹ́ táá jẹ́ kí n máa lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, kí n sì máa ran àwọn ará lọ́wọ́.”

Arákùnrin kan wọ aṣọ iṣẹ́, ó sì mú akoto dání. Ọ̀gá ẹ̀ mú un lọ sí ọ́fí ìsì tuntun tó fẹ́ kó ti máa ṣiṣẹ́, ó sì ń sọ fún un pé òun fẹ́ gbé e ga lẹ́nu iṣẹ́.

Tí wọ́n bá fẹ́ gbé ẹ ga níbi iṣẹ́, ṣé ìpinnu tó o máa ṣe máa fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 7-8)


9. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Trésor?

9 Ká sọ pé iṣẹ́ tó ò ń ṣe báyìí ò jẹ́ kó o máa rìn nípa ìgbàgbọ́ ńkọ́, kí lo máa ṣe? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Trésor tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kóńgò. Ó sọ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ríṣẹ́ kan tí mò ń ṣe, mo sì lè má rírú ẹ̀ mọ́ láé. Ìlọ́po mẹ́ta owó tí mò ń gbà tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ń san fún mi báyìí, àwọn èèyàn sì ń bọ̀wọ̀ fún mi gan-an.” Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni Trésor kì í wá sípàdé torí àfikún iṣẹ́ tó ń ṣe. Wọ́n tún máa ń fúngun mọ́ ọn pé kó parọ́ káwọn aláṣẹ má bàa mọ àwọn nǹkan kan tí wọ́n ń ṣe níbi iṣẹ́ náà. Trésor fẹ́ fiṣẹ́ yẹn sílẹ̀, àmọ́ àyà ẹ̀ ń já pé òun lè má ríṣẹ́ míì. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Hábákúkù 3:17-19 jẹ́ kí n rí i pé tí mi ò bá tiẹ̀ níṣẹ́ lọ́wọ́, Jèhófà máa bójú tó mi. Torí náà, mo fiṣẹ́ sílẹ̀.” Ó wá sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbani síṣẹ́ máa ń rò pé kò sóhun téèyàn ò lè yááfì torí iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé. Kódà, onítọ̀hún lè má ráyè gbọ́ ti ìdílé ẹ̀ àti ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. Inú mi dùn pé mi ò ba àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ìfẹ́ tá a ní síra wa nínú ìdílé mi ò sì dín kù. Ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà jẹ́ kí n ríṣẹ́ tó jẹ́ kí n lè máa gbọ́ bùkátà, kí n sì máa lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run. Tá a bá ń fi Jèhófà ṣáájú ohun gbogbo, àwọn ìgbà míì wà tá a lè má fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, àmọ́ Jèhófà máa bójú tó wa.” Ó dájú pé tá a bá ń fàwọn ìlànà Jèhófà sílò, tá a sì gbà pé àwọn ìlérí ẹ̀ máa ṣẹ, àá máa rìn nípa ìgbàgbọ́, ó sì máa bù kún wa.

TÁ A BÁ FẸ́ YAN ẸNI TÁ A MÁA FẸ́

10. Kí ló lè mú ká máa rìn nípa ohun tá à ń rí tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́?

10 Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìgbéyàwó, ìdí nìyẹn tó fi máa ń wù wá pé ká ṣègbéyàwó. Tí arábìnrin kan bá ń wá ẹni tó máa fẹ́, ó máa kíyè sí ìwà arákùnrin náà, ìrísí ẹ̀ àti irú ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí. Ó yẹ kó bi ara ẹ̀ pé, ṣé ó níṣẹ́ tó máa fi gbọ́ bùkátà mi? Ṣé òun ló ń gbọ́ bùkátà àwọn èèyàn ẹ̀? Yàtọ̀ síyẹn, ṣé ó máa ń múnú mi dùn?b Àwọn nǹkan yìí ṣe pàtàkì lóòótọ́. Àmọ́ tó bá jẹ́ àwọn nǹkan yìí nìkan ló gbé yẹ̀ wò, á jẹ́ pé ó ń rìn nípa ohun tó ń rí nìyẹn.

11. Báwo la ṣe lè máa rìn nípa ìgbàgbọ́ tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́? (1 Kọ́ríńtì 7:39)

11 Inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn arábìnrin àtàwọn arákùnrin tó ń fi ìmọ̀ràn Jèhófà sílò tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò gbàgbé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí wọ́n dúró títí dìgbà tí wọ́n bá “kọjá ìgbà ìtànná èwe” kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà. (1 Kọ́r. 7:36) Ẹni tó bá láwọn ìwà tí Jèhófà sọ pé ó máa jẹ́ kéèyàn di ọkọ rere tàbí aya rere ni wọ́n máa ń ronú láti fẹ́. (Òwe 31:10-13, 26-28; Éfé. 5:33; 1 Tím. 5:8) Tẹ́nì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sọ pé àwọn fẹ́ fẹ́ wọn, wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa” bó ṣe wà ní 1 Kọ́ríńtì 7:39. (Kà á.) Wọ́n máa ń rìn nípa ìgbàgbọ́ torí wọ́n gbà pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn, ó sì máa bójú tó wọn.—Sm. 55:22.

12. Kí lo kọ́ nínú ohun tí Rosa ṣe?

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Rosa ní Kòlóńbíà. Iṣẹ́ tó ń ṣe máa ń jẹ́ kó wà pẹ̀lú ọkùnrin kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, Rosa náà sì ń nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó sọ pé: “Lójú mi, ọkùnrin tó dáa ni. Ó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ládùúgbò ẹ̀, kì í sì í hùwà játijàti. Ó máa ń ṣìkẹ́ mi. Irú ọkọ tí mo fẹ́ gan-an nìyẹn, ó kàn jẹ́ pé kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.” Ó tún sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti sọ pé mi ò ní fẹ́ ẹ torí èmi náà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Lásìkò yẹn, ó ń ṣe mí bíi pé mo dá wà, ó sì wù mí kí n lọ́kọ, àmọ́ mi ò rẹ́nì kankan tí mo lè fẹ́ nínú òtítọ́.” Síbẹ̀, kì í ṣe nǹkan tí Rosa ń rí nìkan ló gbé yẹ̀ wò. Ó ronú nípa bí ìpinnu tóun fẹ́ ṣe yìí ṣe lè ba àjọṣe òun àti Jèhófà jẹ́. Torí náà, ó pinnu pé iṣẹ́ nìkan ló máa pa àwọn pọ̀, ó sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, ètò Ọlọ́run pè é sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe báyìí. Rosa sọ pé: “Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an, mo sì ń láyọ̀.” Kì í rọrùn rárá láti máa rìn nípa ìgbàgbọ́ pàápàá tá a bá fẹ́ ṣèpinnu pàtàkì. Àmọ́ tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, a máa jàǹfààní.

TÍ ÈTÒ ỌLỌ́RUN BÁ SỌ OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE

13. Tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe ohun kan, àwọn nǹkan wo ló máa fi hàn pé à ń rìn nípa ohun tá à ń rí?

13 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ètò Ọlọ́run máa ń sọ ohun tó yẹ ká ṣe fún wa. Ó lè jẹ́ àwọn alàgbà, àwọn alábòójútó àyíká, ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa sọ ọ́ fún wa. Àmọ́ nígbà míì tá ò bá mọ ìdí tí wọ́n fi ní ká ṣe ohun kan ńkọ́? Ó lè jẹ́ pé ìnira tó máa fà fún wa nìkan la máa rí. Kódà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rí àìpé àwọn arákùnrin tó ń sọ ohun tá a máa ṣe.

14. Tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe ohun kan, àwọn nǹkan wo ló máa fi hàn pé à ń rìn nípa ìgbàgbọ́? (Hébérù 13:17)

14 Tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́, a máa gbà pé Jèhófà ló ń darí ètò ẹ̀ àti pé ó mọ ohun tá a fẹ́. Torí náà, a máa ń tètè ṣègbọràn, a sì gbà pé nǹkan náà máa yọrí sí rere. (Ka Hébérù 13:17.) A mọ̀ pé tá a bá ṣègbọràn, á jẹ́ kí ìjọ wà níṣọ̀kan. (Éfé. 4:2, 3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa, a mọ̀ pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá ṣègbọràn sí wọn. (1 Sám. 15:22) Tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, ó máa ṣàtúnṣe ohun tí ò tọ́.—Míkà 7:7.

15-16. Kí ló ran arákùnrin kan lọ́wọ́ láti máa rìn nípa ìgbàgbọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò kọ́kọ́ fẹ́ ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ẹ jẹ́ ká wo ìrírí kan tó jẹ́ ká rí àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́. Lórílẹ̀-èdè Peru, èdè Sípáníìṣì ni èdè àjọgbà, àmọ́ ọ̀pọ̀ tún máa ń sọ àwọn èdè ìbílẹ̀. Ọ̀kan lára èdè náà ni Quechua. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń sọ èdè Quechua fi ń wá àwọn tó ń sọ èdè náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Àmọ́, kí wọ́n má bàa rú òfin ìjọba, ètò Ọlọ́run ṣe àtúnṣe bí wọ́n á ṣe máa wàásù. (Róòmù 13:1) Torí náà, àwọn kan rò pé ìyẹn ò ní jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti rí àwọn tó ń sọ èdè náà. Àmọ́ nígbà táwọn ará ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, wọ́n rí i pé Jèhófà bù kún àwọn, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Quechua.

16 Alàgbà kan tó ń jẹ́ Kevin wà ní ìjọ tó ń sọ èdè Quechua, ó sì wà lára àwọn tó ń rò pé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ ò ní ṣiṣẹ́ lágbègbè wọn. Ó ní: “Mo sọ pé, ‘Báwo la ṣe máa rí àwọn tó ń sọ èdè Quechua báyìí?’” Kí ni Kevin wá ṣe? Ó sọ pé: “Mo rántí ohun tó wà ní Òwe 3:5, mo sì ronú nípa Mósè. Òun ló máa kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì. Jèhófà sì sọ fún un pé kó kó wọn lọ gba Òkun Pupa, ìyẹn sì jọ pé wọn ò ní lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. Síbẹ̀, ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ, Jèhófà sì bù kún wọn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ torí pé ó ṣègbọràn.” (Ẹ́kís. 14:1, 2, 9-11, 21, 22) Kevin gbà láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n ṣe. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ó sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo rí bí Jèhófà ṣe jẹ́ ká ṣàṣeyọrí. Kó tó dìgbà yẹn, a máa ń rìn gan-an tá a bá ń wàásù, ẹnì kan tàbí ẹni méjì tó ń sọ èdè Quechua la sì máa ń rí. Ní báyìí, àwọn ìpínlẹ̀ táwọn tó ń sọ èdè Quechua pọ̀ sí la ti ń wàásù. Torí náà, à ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀, à ń pa dà bẹ̀ wọ́n wò, a sì ń kọ́ ọ̀pọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bákan náà, iye àwọn tó ń wá sípàdé ti pọ̀ sí i.” Ẹ ò rí i pé tá a bá ń rìn nípa ìgbàgbọ́, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa.

Ọkùnrin kan tó ń sọ èdè Quechua ń bá tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sọ̀rọ̀ lóde ìwàásù. Ó ń fi ibi tí ẹlòmí ì tó ń sọ èdè náà ń gbé hàn wọ́n.

Àwọn ará rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń wàásù fún máa ń sọ ibi táwọn ti lè rí àwọn tó ń sọ èdè Quechua lágbègbè wọn (Wo ìpínrọ̀ 15-16)


17. Kí lo kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

17 A ti sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa rìn nípa ìgbàgbọ́ láwọn apá pàtàkì mẹ́ta. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ máa rìn nípa ìgbàgbọ́ nínú àwọn nǹkan yòókù tá a bá ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú tá a fẹ́ ṣe, tá a bá fẹ́ pinnu iye ìwé tá a máa kà tàbí iye ọmọ tá a máa bí. Ìpinnu yòówù tá a bá fẹ́ ṣe, kì í ṣe ohun tá à ń rí nìkan ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò, ó tún yẹ ká ronú nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà, ìmọ̀ràn tó ń fún wa àti ìlérí tó ṣe pé òun máa bójú tó wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá “máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé.”—Míkà 4:5.

BÁWO LA ṢE LÈ MÁA RÌN NÍPA ÌGBÀGBỌ́ . . .

  • tá a bá fẹ́ wá iṣẹ́ tá a máa ṣe?

  • tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́?

  • tí ètò Ọlọ́run bá sọ ohun tó yẹ ká ṣe?

ORIN 156 Mo Ní Ìgbàgbọ́

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Kí ọ̀rọ̀ yìí lè túbọ̀ yé wa, arábìnrin tó ń wá ọkọ la sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú ìpínrọ̀ yìí, àmọ́ ọ̀rọ̀ yìí kan arákùnrin tó ń wá ìyàwó náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́