ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 July ojú ìwé 14-19
  • Ṣé A Ṣì Lè Rí Nǹkan Kọ́ Nínú Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tá A Kọ́kọ́ Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé A Ṣì Lè Rí Nǹkan Kọ́ Nínú Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tá A Kọ́kọ́ Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • JÈHÓFÀ NI ẸLẸ́DÀÁ
  • ÌDÍ TÍ ỌLỌ́RUN FI FÀYÈ GBA ÌYÀ TÓ Ń JẸ ARÁYÉ
  • “ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN” LA WÀ YÌÍ
  • MỌYÌ ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ Ń KỌ́ WA
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìyàtọ̀ Láàárín Òtítọ́ àti Irọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Mú Kó O Máa Wàásù Nìṣó
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 July ojú ìwé 14-19

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 30

ORIN 97 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè

Ṣé A Ṣì Lè Rí Nǹkan Kọ́ Nínú Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tá A Kọ́kọ́ Mọ̀?

“[Ó] wù mí kí n máa rán yín létí àwọn nǹkan yìí nígbà gbogbo, bí ẹ tiẹ̀ mọ̀ wọ́n, tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́.”—2 PÉT. 1:12.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jàǹfààní àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tá a ti kọ́ wọn.

1. Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kọ́kọ́ mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì?

ÀWỌN ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀ ti yí ìgbésí ayé wa pa dà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ó wù wá láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Àìsá. 42:8) Nígbà tá a mọ̀ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn èèyàn wa tó ti kú ò jìyà. (Oníw. 9:10) Nígbà tá a kọ́ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ayé máa di Párádísè, a ò da ara wa láàmú mọ́ nípa bọ́jọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí. Ó sì túbọ̀ dá wa lójú pé kì í ṣe àádọ́rin (70) tàbí ọgọ́rin (80) ọdún péré la máa gbé láyé, títí láé ni.—Sm. 37:29; 90:10.

2. Báwo ni 2 Pétérù 1:12, 13 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lè jàǹfààní àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀?

2 Kò yẹ ká fojú kéré àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀. Àwọn Kristẹni tí wọ́n “fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́” ni àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí. (Ka 2 Pétérù 1:12, 13.) Nígbà yẹn, àwọn olùkọ́ èké àtàwọn èèyàn burúkú tí wọ́n fẹ́ kó àwọn ará ṣìnà ti wà nínú ìjọ. (2 Pét. 2:1-3) Pétérù rí i pé ó yẹ kóun fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin náà lókun kí wọ́n má bàa ṣì wọ́n lọ́nà. Torí náà, ó rán wọn létí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ yìí sì máa jẹ́ kí wọ́n jólóòótọ́ títí dópin.

3. Sọ àpèjúwe tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀.

3 Bí òtítọ́ ṣe ń jinlẹ̀ sí i nínú wa, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tuntun látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Tí alásè kan tó moúnjẹ sè dáadáa àti ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ bá fẹ́ se oúnjẹ, àwọn méjèèjì lè lo èròjà kan náà. Àmọ́ alásè yẹn máa mọ bó ṣe máa fi èròjà yẹn se oríṣiríṣi oúnjẹ tí ata tó, tí iyọ̀ sì dùn torí ó pẹ́ tó ti ń se oúnjẹ. Lọ́nà kan náà, ẹ̀kọ́ táwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́ máa rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì kan máa yàtọ̀ sí tàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa àtàwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run báyìí ṣeé ṣe kó ti yàtọ̀ sí tìgbà tá a ṣèrìbọmi. Tá a bá ń ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, a máa rí àwọn ọ̀nà tuntun tá a lè gbà lò wọ́n. Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lè kọ́ nínú mẹ́ta lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀.

JÈHÓFÀ NI ẸLẸ́DÀÁ

4. Àǹfààní wo la rí bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá?

4 “Ọlọ́run ló kọ́ ohun gbogbo.” (Héb. 3:4) Ó dá wa lójú pé Ẹlẹ́dàá tó gbọ́n tó sì lágbára jù lọ ló dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú ẹ̀. Òun ló dá wa, kò sì sóhun tí ò mọ̀ nípa wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ ká gbádùn ayé wa. Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ti ṣe wá láǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé wa túbọ̀ dáa.

5. Kí ló máa jẹ́ ká nírẹ̀lẹ̀? (Àìsáyà 45:9-12)

5 Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá lè jẹ́ ká nírẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jóòbù ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò lẹ́bi. Torí náà, Jèhófà rán an létí pé òun ni Ẹlẹ́dàá, kò sì sẹ́ni tó lágbára tó òun. (Jóòbù 38:1-4) Ohun tí Ọlọ́run sọ fún Jóòbù yìí jẹ́ kó rí i pé èrò Ọlọ́run ga ju ti èèyàn lọ fíìfíì. Abájọ tí Àìsáyà fi sọ nígbà tó yá pé: “Ṣé ó yẹ kí amọ̀ sọ fún Amọ̀kòkò pé: ‘Kí lò ń mọ?’”—Ka Àìsáyà 45:9-12.

6. Ìgbà wo ló ṣe pàtàkì jù pé ká ronú nípa bí Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ṣe lágbára tó? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Bí Kristẹni kan bá ṣe túbọ̀ ń ní ìrírí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbára lé òye tara ẹ̀ dípò kó jẹ́ kí Jèhófà àti Bíbélì máa tọ́ òun sọ́nà. (Jóòbù 37:23, 24) Àmọ́ tẹ́ni náà bá ronú jinlẹ̀ nípa ọgbọ́n Jèhófà tí ò láàlà àti bó ṣe lágbára tó ńkọ́? (Àìsá. 40:22; 55:8, 9) Ìyẹn máa jẹ́ kó nírẹ̀lẹ̀, kò sì ní ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.

Fọ́tò: 1. Alàgbà kan mú àbá wá nípàdé àwọn alàgbà, àmọ́ àwọn alàgbà tó kù ń kọminú sí àbá ẹ̀. 2. Nígbà tó yá, alàgbà náà ń wo ìràwọ̀ ojú ọ̀run lálẹ́, ó sì ń ṣàṣàrò.

Kí ni ò ní jẹ́ ká máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ? (Wo ìpínrọ̀ 6)d


7. Kí ni Rahela ṣe tó jẹ́ kó lè fara mọ́ àyípadà kan tó wáyé nínú ètò Ọlọ́run?

7 Nígbà tí Rahela tó ń gbé orílẹ̀-èdè Slovenia ronú jinlẹ̀ nípa Ẹlẹ́dàá, ó jẹ́ kó fara mọ́ àyípadà kan tó wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Nígbà míì, kì í rọrùn fún mi láti fara mọ́ ìpinnu táwọn tó ń ṣàbójútó wa máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí mo wo Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2023 #8, ètò Ọlọ́run sọ pé àwọn arákùnrin lè máa dá irùngbọ̀n sí. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo kọ́kọ́ rí arákùnrin tó nírùngbọ̀n tó ń sọ àsọyé. Torí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n lè fara mọ́ àyípadà yìí.” Rahela gbà pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé, ìyẹn jẹ́ kó dá a lójú pé ó máa tọ́ ètò ẹ̀ sọ́nà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Tí kò bá rọrùn fún ẹ láti fara mọ́ àyípadà kan tó wáyé tàbí òye tuntun tá a ní, o ò ṣe rẹ ara ẹ sílẹ̀, kó o sì ronú nípa bí ọgbọ́n àti agbára Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa ṣe pọ̀ tó?—Róòmù 11:33-36.

ÌDÍ TÍ ỌLỌ́RUN FI FÀYÈ GBA ÌYÀ TÓ Ń JẸ ARÁYÉ

8. Àǹfààní wo la ti rí bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?

8 Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé? Àwọn tí ò mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí máa ń bínú sí Ọlọ́run tàbí kí wọ́n gbà pé kò sí Ọlọ́run! (Òwe 19:3) Àmọ́ ọ̀rọ̀ tìẹ ò rí bẹ́ẹ̀, o mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé, kì í ṣe Jèhófà. Bákan náà, o mọ̀ pé Jèhófà ní sùúrù, ìyẹn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àìmọye èèyàn láti wá mọ̀ ọ́n, ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé. (2 Pét. 3:9, 15) Ohun tó o mọ̀ yìí tù ẹ́ nínú, ó sì ti jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

9. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tó máa gba pé ká ronú nípa ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba ìyà?

9 Bá a ṣe ń retí ìgbà tí Jèhófà máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé, a mọ̀ pé ó yẹ ká ní sùúrù. Àmọ́ tí àwa tàbí àwọn tó sún mọ́ wa bá níṣòro, tí wọ́n rẹ́ wa jẹ tàbí tí èèyàn wa kan kú, a lè máa rò pé kí ló dé tí Jèhófà ò tètè fòpin sí ìṣòro náà? (Háb. 1:2, 3) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, á dáa ká ronú nípa ìdí tí Jèhófà fi fàyè gbà á káwọn olóòótọ́ máa jìyà.a (Sm. 34:19) Bákan náà, ká ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn bó ṣe máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé.

10. Báwo ni Anne ṣe fara dà á nígbà tí ìyá ẹ̀ kú?

10 Bá a ṣe mọ ìdí tí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa. Arábìnrin Anne tó ń gbé erékùṣù Mayotte ní agbègbè Indian Ocean sọ pé: “Nígbà tí ìyá mi kú ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, inú mi bà jẹ́ gan-an. Àmọ́, ìgbà gbogbo ni mo máa ń rán ara mi létí pé Jèhófà kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Ó ṣe tán láti mú gbogbo ìyà tó ń jẹ wá kúrò, kó sì jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde. Bí mo ṣe ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, ìyẹn sì ń múnú mi dùn.”

11. Kí ló ń jẹ́ ká lè máa wàásù nìṣó?

11 Bá a ṣe mọ ìdí tí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé jẹ́ ká lè máa wàásù nìṣó. Lẹ́yìn tí Pétérù ṣàlàyé pé sùúrù tí Jèhófà ní fáwọn tó ronú pìwà dà ló máa jẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà, ó sọ pé: “Ẹ ronú nípa irú ẹni tó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pét. 3:11) Iṣẹ́ ìwàásù wà lára “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” tá à ń ṣe. Bí Jèhófà Bàbá wa ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn làwa náà nífẹ̀ẹ́ wọn. A fẹ́ káwọn náà gbénú ayé tuntun Ọlọ́run níbi tí òdodo máa wà. Jèhófà ní sùúrù fáwọn èèyàn kí wọ́n lè wá jọ́sìn ẹ̀. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé ò ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́, o sì ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí òpin tó dé!—1 Kọ́r. 3:9.

“ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN” LA WÀ YÌÍ

12. Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe mọ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé?

12 Bíbélì sọ ìwà táwọn èèyàn á máa hù tó bá di “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tím. 3:1-5) Tá a bá kíyè sí ìwà táwọn èèyàn ń hù lágbègbè wa, a máa rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ń ṣẹ. Bá a sì ṣe ń rí i táwọn èèyàn túbọ̀ ń hùwà burúkú, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń dá wa lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeé gbára lé.—2 Tím. 3:13-15.

13. Tá a bá ronú nípa àpèjúwe tí Jésù ṣe ní Lúùkù 12:15-21, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

13 Bá a ṣe mọ̀ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà jẹ́ ká gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Àpèjúwe tí Jésù ṣe ní Lúùkù 12:15-21 jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. (Kà á.) Kí nìdí tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà fi jẹ́ “aláìlóye”? Kì í ṣe torí pé ọkùnrin náà lọ́rọ̀, àmọ́ torí pé kò gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Ó to ‘ìṣúra jọ fún ara ẹ̀ àmọ́ kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.’ Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkùnrin yẹn tètè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà? Ìdí ni pé Ọlọ́run sọ fún un pé: “Òru òní ni wọ́n máa béèrè ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́ rẹ.” Torí náà, bá a ṣe ń rí i pé òpin ò ní pẹ́ dé, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe fi hàn pé ìjọsìn Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù láyé mi? Táwọn ọmọ mi bá fẹ́ yan ohun tí wọ́n máa fayé wọn ṣe, ṣé mo máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìjọsìn Jèhófà ló yẹ kí wọ́n fi ṣáájú? Ṣé kì í ṣe pé mò ń lo okun mi, àkókò mi àti owó mi láti kó àwọn nǹkan ìní jọ dípò kí n máa to ìṣúra jọ sí ọ̀run?’

14. Bá a ṣe rí i nínú ìrírí Arábìnrin Miki, kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ẹ̀rí tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí?

14 Tá a bá ń ronú nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Miki jẹ́ ká rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ girama, ó wù mí kí n kàwé sí i kí n lè túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn ẹranko. Ó tún wù mí kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kí n sì lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù. Àwọn ọ̀rẹ́ mi tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn gbà mí nímọ̀ràn pé kí n ronú dáadáa nípa ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sọ fún mi pé tí mo bá lọ kàwé sí i, ṣé màá ṣì lè ṣe àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Wọ́n rán mi létí pé òpin ò ní pẹ́ dé. Wọ́n tún jẹ́ kí n mọ̀ pé nínú ayé tuntun, títí láé ni màá fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa oríṣiríṣi ẹranko. Torí náà, mo pinnu pé màá lọ sílé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́, tí kò sì ní gba ọ̀pọ̀ àkókò. Lẹ́yìn tí mo parí ẹ̀kọ́ mi, mo ríṣẹ́ tó jẹ́ kí n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó sì yá, mo kó lọ sí orílẹ̀-èdè Ecuador níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù.” Ní báyìí, Arábìnrin Miki àti ọkọ ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká ní Ecuador.

15. Kí làwọn èèyàn tí ò gbọ́ ìwàásù báyìí ṣì lè ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa táwọn èèyàn ò bá gbọ́ ìwàásù ìhìn rere. Ìdí ni pé àwọn èèyàn ṣì lè yí pa dà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jémíìsì àbúrò Jésù. Ó mọ Jésù láti kékeré títí tó fi dàgbà tó sì di Mèsáyà, ó sì tún mọ̀ pé kò sí olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ bíi Jésù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọdún kọjá kí Jémíìsì tó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Ẹ̀yìn tí Jésù jíǹde ni Jémíìsì di ọmọ ẹ̀yìn, ó sì nítara.b (Jòh. 7:5; Gál. 2:9) Bákan náà lónìí, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kò tíì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àtàwọn tí kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, torí náà a ò gbọ́dọ̀ fiṣẹ́ ìwàásù jáfara. Ohun tá a bá sọ fún wọn báyìí lè mú kí wọ́n wá sin Jèhófà tó bá yá, kódà ó lè jẹ́ lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀.c

Nígbà tí arábìnrin kan ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó pe ẹ̀gbọ́n ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí fóònù kó lè wàásù fún un. Ẹ̀gbọ́n ẹ̀ àti ọmọ ẹ̀ wà níbi tí wọ́n ti ń rajà.

Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kò tíì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (Wo ìpínrọ̀ 15)e


MỌYÌ ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ Ń KỌ́ WA

16. Báwo lo ṣe ń jàǹfààní ìwé àtàwọn fídíò wa? (Tún wo àpótí náà “Máa Fi Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Kọ́ Àwọn Èèyàn.”)

16 Àwọn ìwé àtàwọn fídíò kan wà tí ètò Ọlọ́run dìídì ṣe fáwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àsọyé tá a máa ń gbọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò kan lórí jw.org títí kan àwọn ìwé ìròyìn tá à ń fáwọn èèyàn la ṣe fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń jàǹfààní wọn. Àwọn ìwé àtàwọn fídíò yìí ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ń jẹ́ ká túbọ̀ gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa.—Sm. 19:7.

Máa Fi Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Kọ́ Àwọn Èèyàn

Tó o bá ka àpilẹ̀kọ kan, tó o wo fídíò kan tàbí tó o gbọ́ àsọyé kan, tó o sì rí i pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló wà fún, wo bó o ṣe lè fi àwọn nǹkan náà kọ́ àwọn èèyàn. O lè bi ara ẹ pé:

  • ‘Àwọn nǹkan wo ló wà níbẹ̀ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ làwọn gbọ́?’

  • ‘Ṣé àpèjúwe kan wà tí mo lè lò tí mo bá fẹ́ fi ohun tó wà níbẹ̀ kọ́ ẹnì kan?’

  • ‘Ta ló máa fẹ́ mọ ẹ̀kọ́ náà, ìgbà wo ni mo sì lè fi kọ́ ọ?’

17. Àwọn nǹkan wo ló lè mú ká ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀?

17 Inú àwa èèyàn Jèhófà máa ń dùn tí ètò Ọlọ́run bá ṣàtúnṣe ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a mọ̀ tẹ́lẹ̀. Àmọ́, a mọyì àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀ yẹn gan-an torí pé àwọn ló jẹ́ ká kọ́kọ́ mọ Jèhófà. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tó bá ń ṣe wá bíi pé ká gbára lé òye tara wa dípò ká ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì máa rántí pé Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tó gbọ́n jù lọ tó sì lágbára jù lọ ló ń darí ètò ẹ̀. Tí àwa tàbí èèyàn wa kan bá ń fara da ìṣòro, ó yẹ ká ní sùúrù, ká sì ronú nípa ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé. Tá a bá ń ronú ohun tá a máa fi àkókò wa àti nǹkan ìní wa ṣe, ó yẹ ká rántí pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà, òpin ò sì ní pẹ́ dé. Àdúrà wa ni pé káwọn nǹkan tí Jèhófà ń kọ́ wa máa fún wa lókun, kó jẹ́ ká gbọ́n sí i, ká sì máa sìn ín nìṣó.

KÍ LA KỌ́ NÍNÚ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ TÁ A KỌ́KỌ́ MỌ̀ YÌÍ?

  • Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá

  • Ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé

  • “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí

ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tí Kò Fi Ní Pẹ́ Tí Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2007, ojú ìwé 21-25.

b Wo ẹ̀kọ́ 8 nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn.

c Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí La Mọ̀ Nípa Bí Jèhófà Ṣe Máa Ṣèdájọ́ Lọ́jọ́ Iwájú?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 2024, ojú ìwé 8-13.

d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Nígbà tí ìgbìmọ̀ alàgbà kan ń ṣèpàdé, wọn ò gba àbá alàgbà kan. Nígbà tó ń wo ìràwọ̀ lálẹ́, ó wá rí i pé èrò òun yàtọ̀ sóhun tí Jèhófà fẹ́.

e ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Nígbà tí arábìnrin kan ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó wá àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. Ìyẹn jẹ́ kó pe ẹ̀gbọ́n ẹ̀ lórí fóònù, ó sì wàásù fún un.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́