Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 96
Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 239
Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 111,719
Iye Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 19,013,343
Iye Tó Jẹ Nínú Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 12,604
Gongo Akéde: 7,782,346
Ìpíndọ́gba Iye Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 7,538,994
Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2011 Lọ: 143,322
Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 268,777
Ìpíndọ́gba Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 416,993
Ìpíndọ́gba Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Déedée Lóṣooṣù: 950,022
Àròpọ̀ Iye Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù: 1,748,697,447
Ìpíndọ́gba Iye Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣooṣù: 8,759,988
Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2012, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná iye tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìn-lé-lọ́gọ́sàn-án [184,000,000] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́nu iṣẹ́ wọn.
◼ Bákan náà, kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànlélógún, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìlá [21,612]. Wọ́n wà lára Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.