ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 128-129
  • Jèhófà Gbé Mi Dìde

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Gbé Mi Dìde
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Ti Wá Dẹni Iyì
    Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Mo Ti Rí i Pé Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Nígbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • “Àwọn Tó Ń Fetí Sí Ọ” Máa Rí Ìgbàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 128-129

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

Jèhófà Gbé Mi Dìde

Jay Campbell

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1966

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1986

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó ní àrùn rọpárọsẹ̀, síbẹ̀ ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

LÁTI kékeré ni ẹsẹ̀ mi méjèèjì ti rọ. Inú agboolé kan tí àwọn ìdílé tálákà pọ̀ sí ni èmi àti ìyá mi ń gbé ní ìlú Freetown. Torí pé ẹ̀rù máa ń bà mí, ojú sì máa ń tì mí torí ohun tí àwọn tó bá rí mi á máa sọ, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni mo jáde nínú ọgbà ilé wa ní odindi ọdún méjìdínlógún [18].

Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méjìdínlógún, Arábìnrin Pauline Landis, ọ̀kan lára míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ilé wa, ó sì sọ pé òun fẹ́ máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí mo sọ fún Arábìnrin Pauline pé mi ò mọ̀wé kà, mi ò sì mọ̀ ọ́n kọ, ó sọ pé òun máa kọ́ mi. Mo sì gbà pé kó wá máa kọ́ mi.

Àwọn ohun tí mo kọ́ látinú Bíbélì mú inú mi dùn gan-an. Lọ́jọ́ kan, mo béèrè lọ́wọ́ Arábìnrin Pauline bóyá mo lè wá sí ìpàdé ìjọ tí wọ́n ń ṣe nítòsí ilé wa. Mo sọ fún un pé: “Màá fi igi kékeré tí mo fi ń tilẹ̀ rìn débẹ̀.”

Nígbà tí Arábìnrin Pauline wá pè mí ká lè jọ lọ, ẹ̀rù ń ba ìyá mi àti àwọn ará ilé wa pé mi ò ní lè lọ. Mo di àwọn igi kékeré tí mo fi ń rìn mú, mo sì sún mọ́ iwájú láti fi wọ́n tilẹ̀. Mo wá wọ́ ara mi síwájú àwọn igi náà. Bí mo ṣe ń jáde lọ nínú agboolé wa, àwọn ará ilé wa bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo mọ́ Arábìnrin Pauline, wọ́n ní: “Ṣe lò ń fipá mú ọmọ yìí, ó ti gbìyànjú láti rìn tẹ́lẹ̀, àmọ́ pàbó ló já sí.”

Pauline rọra béèrè lọ́wọ́ Jay pé: “Ṣé o fẹ́ lọ lóòótọ́?”

Mo fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí mo pinnu nìyẹn.”

Bí mo ṣe ń lọ sí ẹnu géètì ọgbà ilé wa kẹ́kẹ́ pa mọ́ wọn lẹ́nu. Àmọ́ ariwo ayọ̀ sọ nígbà tí mo jáde nínú ọgbà ilé wa.

Mo mà gbádùn ìpàdé yẹn gan-an o! Nígbà tó yá, mo pinnu pé màá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí n tó lè dé ibẹ̀, mo máa ní láti dé ìyànà àdúgbò wa, kí n wọ mótò dé ibì kan, kí àwọn ará sì gbé mi gun òkè kan tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni aṣọ mi ti máa ń tutù tó sì máa ń kó ẹrọ̀fọ̀ tí n bá fi máa dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, torí náà mo máa ń pààrọ̀ aṣọ mi níbẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, arábìnrin kan gbé kẹ̀kẹ́ arọ ránṣẹ́ sí mi láti orílẹ̀-èdè Switzerland, èyí jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti máa lọ káàkiri láì jẹ́ pé aṣọ mi dọ̀tí.

Àwọn ìrírí tí mo kà nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara ti jẹ́ kí n túbọ̀ sa gbogbo ipá mi láti máa sin Jèhófà. Lọ́dún 1988, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ kí ọwọ́ mi lè tẹ àfojúsùn mi, kí n lè ran ẹnì kan nínú ìdílé mi àti ẹnì kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù mi lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Jèhófà. Jèhófà dáhùn àdúrà mi ní tí pé ó jẹ́ kí n lè ran méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n mi lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, títí kan obìnrin kan tí mo bá pàdé nígbà tí mò ń wàásù ní òpópónà.

Ní báyìí, apá mi méjèèjì kò fi bẹ́ẹ̀ lókun bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, àwọn ẹlòmíì ló sì máa ń bá mi ti kẹ̀kẹ́ arọ mi. Ara ríro tún máa ń bá mi fínra. Àmọ́ mo ti wá rí i pé kíkọ́ àwọn ẹlòmíì nípa Jèhófà máa ń dín ìrora mi kù. Ayọ̀ tí mò ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù máa ń tù mí lára, ó sì ń tù mí nínú torí Jèhófà ti gbé mi dìde, ó sì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́