ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 36-38
  • Ìròyìn Nípa Àwọn Ará Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìròyìn Nípa Àwọn Ará Wa
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọlọ́pàá Bá Wa Já Lára Búlọ́ọ̀kù Náà
  • Ó Ta Kẹ̀kẹ́ Rẹ̀
  • Wọ́n Ràn Wá Lọ́wọ́
  • Àwọn Ọmọ Náà Ta Súìtì
  • Àwọn Ilé Tá À Ń Kọ́ Ń Bọlá fún Jèhófà
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba—Ọ̀kan Pàtàkì Lára Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ojúṣe Rẹ Nínú Kíkọ́lé fún Ọjọ́ Ọ̀la
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Ń Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 36-38
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 36]

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ìròyìn Nípa Àwọn Ará Wa

Àwọn Ọlọ́pàá Bá Wa Já Lára Búlọ́ọ̀kù Náà

Ní ìlú Kutaisi, tó tóbi ṣìkejì lórílẹ̀-èdè Georgia, ọdún mẹ́tàlá gbáko ni àwọn ará wa fi ń ṣe ìpàdé nínú ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe ọtí tẹ́lẹ̀, ilé náà kò sì dára mọ́. Ṣe ni wọ́n máa ń ta ọ̀rá sókè kí òjò má bàa pa àwọn tó wà lórí ìjókòó. Àmọ́ ní báyìí, Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan tó ṣe gbayawu tó sì ṣeé lò fún àpéjọ ni wọ́n ń lò. Lọ́jọ́ kan nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ lọ́wọ́, àwọn ọlọ́pàá kan yà wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Àádọ́ta [50] àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ń já búlọ́ọ̀kù látinú ọkọ̀ akẹ́rù. Ayọ̀ tí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní àti bí wọ́n ṣe jára mọ́ṣẹ́ wú àwọn ọlọ́pàá náà lórí, wọ́n yìn wọ́n gan-an, kódà wọ́n bá wọn já lára búlọ́ọ̀kù náà. Wọ́n ní kí àwọn ará pe àwọn tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ dí wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn máa wá sí àpéjọ àkọ́kọ́ tá a máa ṣe nínú gbọ̀ngàn tuntun náà.

Ó Ta Kẹ̀kẹ́ Rẹ̀

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni Malachi tó jẹ́ alàgbà lórílẹ̀-èdè Bùrúńdì ń ṣe, ó sì tún máa ń fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ bá àwọn èèyàn kó ẹrù. Ó pinnu pé ojoojúmọ́ lòun á máa lọ síbi tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ó nílò owó díẹ̀ kó lè fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ ní gbogbo oṣù méjì tí wọ́n fi máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Torí náà, ó ta kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó fún ìyàwó rẹ̀ lára owó tó rí níbẹ̀, ó sì fi ìyókù sínú àpótí ọrẹ láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Torí bó ṣe yọ̀ǹda ara rẹ̀ yìí, ó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jíire lọ́dọ̀ àwọn tó wá bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lẹ́yìn tí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà parí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ kí Malachi wá bá àwọn kọ́lé torí wọ́n rí i pé ó ti di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Kò pẹ́ tí Malachi fi ra kẹ̀kẹ́ míì!

Wọ́n Ràn Wá Lọ́wọ́

Àwọn ìṣòro tó ṣàrà ọ̀tọ̀ la ní nígbà tí à ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn ibi tó jìnnà gan-an lórílẹ̀-èdè Màláwì. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àgbègbè kan tí àwọn ọ̀nà ibẹ̀ ti bà jẹ́ kọjá sísọ. Àwọn ọkọ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń bá jíà ṣiṣẹ́ ni àwọn ará tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì fi kó àwọn ohun èlò ìkọ́lé wá síbi tá a ti fẹ́ kọ́ gbọ̀ngàn náà. Àwọn ará tó wà níbẹ̀ sọ pé àwọn ará ìlú náà nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ náà gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè náà ló yọ̀ǹda ara wọn tí wọ́n sì máa ń bá wa ṣiṣẹ́ títí di alẹ́, wọ́n bá wa já iyanrìn, òkúta, sìmẹ́ǹtì àti páànù tá a fi kanlé. Kódà nígbà míì, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló pọ̀ jù lára àwọn tó wá ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀! Inú wọn dùn gan-an sí iṣẹ́ takuntakun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láti kọ́ ibi ìjọsìn tó bójú mu láwọn ìgbèríko bíi tiwọn yìí, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́.

Àwọn Ọmọ Náà Ta Súìtì

Tọkọtaya kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire ń kọ́ àwọn òbí ọlọ́mọ mẹ́wàá kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè Bete, tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ àgbègbè náà. Ní oṣù May 2013, wọ́n gbọ́ pé àpéjọ àkọ́kọ́ ní èdè Bete máa wáyé ní ìlú Daloa, gbogbo ìdílé náà ló sì fẹ́ lọ. Àmọ́ owó ọkọ̀ àlọ àti àbọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa jẹ́ 800 CFA (ìyẹn nǹkan bí àpò méjì ààbọ̀ náírà [₦250]). Apá olórí ìdílé yìí kò sì lè ká owó tó máa gbé gbogbo wọn lọ bọ̀. Torí náà, ó gbìyànjú ohun kan tó máa jẹ́ kí gbogbo wọn lè lọ. Ó fún èyí tó dàgbà jù lára àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní 300 CFA (ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún náírà [₦100]) pé kó máa fi ṣe súìtì kó sì máa tà á. Ọmọ yìí ta súìtì náà, ó sì jẹ èrè tí ó tó láti sanwó ọkọ̀ tiẹ̀. Olórí ìdílé yìí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ yòókù ní 300 CFA kí àwọn náà lè fi ṣòwò súìtì kí wọ́n sì lè san owó ọkọ̀ wọn. Nígbà tọ́jọ́ pé, ìdílé yìí àtàwọn míì jọ lọ sí àpéjọ náà. Inú wọn dùn gan-an pé wọ́n gbádùn àpéjọ náà ní èdè àbínibí wọn!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́