ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Ìmọ́lẹ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
TORÍ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé Jèhófà ni Orísun ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tàbí pé Òun ló lè jẹ́ káwọn lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ‘ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́’ máa tọ́ àwọn sọ́nà, kó sì máa darí àwọn. (Sm. 43:3) Bí ayé yìí ṣe túbọ̀ ń jìn sínú òkùnkùn birimùbirimù, ṣe ni Jèhófà túbọ̀ ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ máa ṣamọ̀nà àwa èèyàn rẹ̀. Èyí wá mú kí ipa ọ̀nà wa “dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i.” (Òwe 4:18) Bí Jèhófà ṣe túbọ̀ ń fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ṣamọ̀nà wa ti mú kí ọ̀nà tá a gbà ṣètò àwọn nǹkan túbọ̀ dára sí i, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àti ìwà wa ń sunwọ̀n sí i. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí sáwọn ohun tá a gbà gbọ́?