ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 109
  • Jésù Máa Fòpin sí Ìwà Ìkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Máa Fòpin sí Ìwà Ìkà
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Máa Fòpin sí Ipò Òṣì
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Jésù Máa Fòpin sí Ogun
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ta Lo Lè Fọkàn Tán?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìwà Ọ̀daràn Ń Peléke Sí I Kárí Ayé—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 109
Ọ̀daràn kan ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ bọ̀ lẹ́yìn obìnrin kan tó dá wà. Obìnrin náà ń pe ẹnì kan lórí fóònù pé kó ran òun lọ́wọ́.

alfa27/stock.adobe.com

Jésù Máa Fòpin sí Ìwà Ìkà

Jésù mọ ìrora tí ìwà ìkà àti àìṣèdájọ́ òdodo máa ń fà. Bí àpẹẹrẹ nígbà tó wà láyé, wọ́n parọ́ mọ́ ọn, wọ́n nà án láìṣẹ̀, wọ́n dá ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án pé ọ̀daràn ni, wọ́n pa á ní ìpa ìkà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, ó ṣe ohun tó fi hàn pé kò mọ tara ẹ̀ nìkan torí ó fínnúfíndọ̀ fi “ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mátíù 20:28; Jòhánù 15:13) Ní báyìí, Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa mú kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ kárí ayé, áá sì fòpin sí ìwà ìkà.—Àìsáyà 42:3.

Báwo ni ayé ṣe máa rí tí Jésù bá fòpin sí ìwà ìkà? Bíbélì sọ pé:

  • “Àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́; wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọn ò ní sí níbẹ̀. Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jésù ti ṣe fún wa àtohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká gbìyànjú láti mọ púpọ̀ sí i nípa “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” Ìhìn rere yìí náà sì ni Jésù wàásù nígbà tó wà láyé. (Lúùkù 4:43) Ka àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́