Sunday, July 20
Èrò mi yàtọ̀ sí èrò yín.—Àìsá. 55:8.
Tá ò bá rí àwọn nǹkan tá à ń béèrè nínú àdúrà wa gbà, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan. Àkọ́kọ́ ni pé ‘Ṣé ohun tó tọ́ ni mò ń béèrè?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ronú pé a mọ ohun tó dáa jù fún wa. Àmọ́ àwọn ohun tá à ń béèrè yẹn lè má ṣe wá láǹfààní. Tá a bá ń gbàdúrà nípa ìṣòro kan, ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà míì wà láti gbà yanjú ìṣòro náà tó dáa ju ohun tá a rò lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn nǹkan míì tá a béèrè lè má bá ìfẹ́ Jèhófà mu. (1 Jòh. 5:14) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àwọn òbí tí wọ́n ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ọmọ àwọn dúró sínú òtítọ́. Àdúrà tó dáa nìyẹn. Síbẹ̀, Jèhófà ò ní fipá mú ẹnikẹ́ni nínú wa láti jọ́sìn òun. Ó fẹ́ kí gbogbo wa títí kan àwọn ọmọ wa pinnu pé òun làá máa sìn. (Diu. 10:12, 13; 30:19, 20) Torí náà, ohun tó yẹ kí wọ́n bẹ Jèhófà ni pé kó jẹ́ káwọn kọ́ ọmọ àwọn lọ́nà tá á fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá á sì jọ́sìn ẹ̀.—Òwe 22:6; Éfé. 6:4. w23.11 21 ¶5; 23 ¶12
Monday, July 21
Ẹ máa . . . tu ara yín nínú.—1 Tẹs. 4:18.
Tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò tí wọ́n tú sí ‘tù nínú’ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní túmọ̀ sí “kí ẹnì kan dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹni tó níṣòro tó le gan-an, kó sì fún un níṣìírí.” Tá a bá tu arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú, ńṣe là ń ràn án lọ́wọ́ kó lè máa rìn ní ọ̀nà ìyè nìṣó. Torí náà, gbogbo ìgbà tá a bá dúró ti àwọn ará là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (2 Kọ́r. 7:6, 7, 13) Ẹni tó lójú àánú àti ẹni tó máa ń tu àwọn èèyàn nínú ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹni tó lójú àánú máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì máa ń fẹ́ yanjú ìṣòro wọn. Torí náà, tá a bá lójú àánú, àá máa tu àwọn èèyàn nínú. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé olójú àánú ni Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi máa ń tu àwọn èèyàn nínú. Ó pe Jèhófà ní “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́r. 1:3. w23.11 9-10 ¶8-10
Tuesday, July 22
Ẹ jẹ́ ká máa yọ̀ nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú.—Róòmù 5:3.
Gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Kristi la máa rí ìpọ́njú. Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó sọ fáwọn tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń sọ fún yín pé a máa ní ìpọ́njú, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn.” (1 Tẹs. 3:4) Ó sì sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “A fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa ìpọ́njú tó bá wa . . . a ò tiẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀mí wa ò ní bọ́.” (2 Kọ́r. 1:8; 11:23-27) Àwa Kristẹni lónìí náà mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìpọ́njú lè dé bá wa. (2 Tím. 3:12) Àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ lè máa gbógun tì ẹ́ torí pé o nígbàgbọ́ nínú Jésù, o sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. Ṣé àwọn ará ibi iṣẹ́ ẹ ti ń fúngun mọ́ ẹ torí pé o jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo? (Héb. 13:18) Àbí àwọn aláṣẹ ìjọba ń ta kò ẹ́ torí pé ò ń wàásù? Láìka ìpọ́njú yòówù kó dé bá wa sí, Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa yọ̀. w23.12 10-11 ¶9-10