Saturday, July 19
Àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì.—Héb. 11:32.
Nígbà táwọn ọmọ Éfúráímù bínú sí Gídíónì gidigidi, kò gbaná jẹ, kò sì fìbínú sọ̀rọ̀ sí wọn. (Oníd. 8:1-3) Ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ torí ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, ó sì fọgbọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àwọn alàgbà tó gbọ́n máa ń fara wé Gídíónì. Táwọn èèyàn bá ṣàríwísí wọn, wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, wọn kì í sì í gbaná jẹ. (Jém. 3:13) Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ló ń mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. Nígbà táwọn èèyàn ń yin Gídíónì torí pé ó ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì, Jèhófà ló fìyìn fún. (Oníd. 8:22, 23) Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fara wé Gídíónì? Ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ló ń ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. (1 Kọ́r. 4:6, 7) Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá gbóríyìn fún alàgbà kan torí àsọyé tó sọ, ó yẹ kó jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lòun ti mú ohun tóun sọ tàbí kó sọ pé àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Ọlọ́run ń fún wa ló ran òun lọ́wọ́. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà máa kíyè sára tẹ́ ẹ bá ń kọ́ni, kó má jẹ́ pé ẹ̀yin làwọn èèyàn á máa kan sárá sí, dípò kí wọ́n fògo fún Jèhófà. w23.06 4 ¶7-8
Sunday, July 20
Èrò mi yàtọ̀ sí èrò yín.—Àìsá. 55:8.
Tá ò bá rí àwọn nǹkan tá à ń béèrè nínú àdúrà wa gbà, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan. Àkọ́kọ́ ni pé ‘Ṣé ohun tó tọ́ ni mò ń béèrè?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ronú pé a mọ ohun tó dáa jù fún wa. Àmọ́ àwọn ohun tá à ń béèrè yẹn lè má ṣe wá láǹfààní. Tá a bá ń gbàdúrà nípa ìṣòro kan, ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà míì wà láti gbà yanjú ìṣòro náà tó dáa ju ohun tá a rò lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn nǹkan míì tá a béèrè lè má bá ìfẹ́ Jèhófà mu. (1 Jòh. 5:14) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àwọn òbí tí wọ́n ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ọmọ àwọn dúró sínú òtítọ́. Àdúrà tó dáa nìyẹn. Síbẹ̀, Jèhófà ò ní fipá mú ẹnikẹ́ni nínú wa láti jọ́sìn òun. Ó fẹ́ kí gbogbo wa títí kan àwọn ọmọ wa pinnu pé òun làá máa sìn. (Diu. 10:12, 13; 30:19, 20) Torí náà, ohun tó yẹ kí wọ́n bẹ Jèhófà ni pé kó jẹ́ káwọn kọ́ ọmọ àwọn lọ́nà tá á fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá á sì jọ́sìn ẹ̀.—Òwe 22:6; Éfé. 6:4. w23.11 21 ¶5; 23 ¶12
Monday, July 21
Ẹ máa . . . tu ara yín nínú.—1 Tẹs. 4:18.
Tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò tí wọ́n tú sí ‘tù nínú’ nínú ẹsẹ ojúmọ́ wa tòní túmọ̀ sí “kí ẹnì kan dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹni tó níṣòro tó le gan-an, kó sì fún un níṣìírí.” Tá a bá tu arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú, ńṣe là ń ràn án lọ́wọ́ kó lè máa rìn ní ọ̀nà ìyè nìṣó. Torí náà, gbogbo ìgbà tá a bá dúró ti àwọn ará là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (2 Kọ́r. 7:6, 7, 13) Ẹni tó lójú àánú àti ẹni tó máa ń tu àwọn èèyàn nínú ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹni tó lójú àánú máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì máa ń fẹ́ yanjú ìṣòro wọn. Torí náà, tá a bá lójú àánú, àá máa tu àwọn èèyàn nínú. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé olójú àánú ni Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi máa ń tu àwọn èèyàn nínú. Ó pe Jèhófà ní “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́r. 1:3. w23.11 9-10 ¶8-10