Wednesday, July 23
Wàhálà ńlá lẹ kó mi sí yìí.—Jẹ́n. 34:30.
Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni Jékọ́bù fara dà. Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù tó ń jẹ́ Síméónì àti Léfì dójú ti ilé bàbá wọn, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, Réṣẹ́lì tí Jékọ́bù fẹ́ràn gan-an kú nígbà tó fẹ́ bímọ kejì. Nítorí ìyàn tó mú ní ilẹ̀ náà, ó di dandan kí Jékọ́bù àti ìdílé ẹ̀ ṣí lọ sí Íjíbítì nígbà tó darúgbó. (Jẹ́n. 35:16-19; 37:28; 45:9-11, 28) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro dé bá Jékọ́bù, kò fi Jèhófà sílẹ̀, ó nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí tó ṣe, Jèhófà náà sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà bù kún Jékọ́bù, ó sì jẹ́ kó lóhun ìní tó pọ̀. Ó dájú pé inú Jékọ́bù máa dùn, ó sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an nígbà tó pa dà rí Jósẹ́fù tó rò pé ó ti kú! Torí pé àjọṣe tó dáa wà láàárín Jékọ́bù àti Jèhófà, ìyẹn jẹ́ kó lè borí àwọn ìṣòro tó ní. (Jẹ́n. 30:43; 32:9, 10; 46:28-30) Táwa náà bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, àá borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa. w23.04 15 ¶6-7
Thursday, July 24
Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní.—Sm. 23:1.
Sáàmù 23 jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa. Dáfídì tó kọ Sáàmù yìí ṣàlàyé bí ìfẹ́ tó wà láàárín òun àti Jèhófà tó ń ṣọ́ ọ bí Olùṣọ́ àgùntàn ṣe lágbára tó. Ọkàn Dáfídì balẹ̀ bó ṣe jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà, ìyẹn sì jẹ́ kó gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Torí náà, ó dá Dáfídì lójú pé ojoojúmọ́ ni Jèhófà á máa nífẹ̀ẹ́ òun. Kí ló mú kó dá a lójú? Dáfídì gbà pé Jèhófà bójú tó òun dáadáa torí gbogbo ìgbà ni Jèhófà pèsè ohun tó nílò. Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì gbádùn bóun àti Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́, ó sì tún rí ojúure ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi dá a lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa bójú tó òun. Dáfídì gbà pé ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ní sóun máa jẹ́ kóun borí ìṣòro yòówù kóun ní, ó sì máa jẹ́ kóun láyọ̀, kóun sì ní ìtẹ́lọ́rùn.—Sm. 16:11. w24.01 28-29 ¶12-13
Friday, July 25
Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.—Mát. 28:20.
Àtìgbà Ogun Àgbáyé Kejì làwa èèyàn Jèhófà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti ń gbádùn àlàáfíà déwọ̀n àyè kan, a sì lómìnira láti wàásù. Kódà, kárí ayé làwa èèyàn Jèhófà ti ń wàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti wá mọ Jèhófà. Lónìí, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà ń jẹ́ kí Kristi tọ́ àwọn sọ́nà. Tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu nípa ohun táwọn ará máa ṣe, wọ́n máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí Jèhófà àti Kristi fẹ́ làwọn máa sọ fáwọn ará. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣèpinnu náà tán, wọ́n máa ń ní káwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà fi jíṣẹ́ fáwọn ará nínú ìjọ. Ó ṣe tán, àwọn alàgbà tó jẹ́ ẹni àmì òróró títí kan gbogbo àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ló wà ní “ọwọ́ ọ̀tún” Kristi. (Ìfi. 2:1) Ká sòótọ́, aláìpé làwọn alàgbà yìí, wọ́n sì máa ń ṣàṣìṣe. Àwọn ìgbà kan wà tí Mósè àti Jóṣúà ṣàṣìṣe, àwọn àpọ́sítélì náà sì ṣàṣìṣe. (Nọ́ń. 20:12; Jóṣ. 9:14, 15; Róòmù 3:23) Síbẹ̀, Kristi ṣì ń fìfẹ́ bójú tó ẹrú olóòótọ́ àtàwọn alàgbà, á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó. Torí náà, kò sídìí tí ò fi yẹ ká ṣe ohun tí wọ́n bá sọ fún wa torí Kristi ló ń darí wọn. w24.02 23-24 ¶13-14