Thursday, September 4
Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀, àní, ọ̀nà tí à ń pè ní Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.—Àìsá. 35:8.
Àwọn Júù tó pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ “èèyàn mímọ́” lójú Ọlọ́run. (Diu. 7:6) Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wọn ò ní ṣe àyípadà kankan, kí wọ́n lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ìlú Bábílónì ni wọ́n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù yẹn sí, ọ̀nà táwọn ará Bábílónì sì ń gbà ronú àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan ti mọ́ wọn lára. Nígbà táwọn kan lára àwọn Júù kọ́kọ́ pa dà sí Ísírẹ́lì, ó ya Gómìnà Nehemáyà lẹ́nu gan-an pé àwọn ọmọ táwọn Júù yẹn bí sí Ísírẹ́lì ò lè sọ èdè Júù. (Diu. 6:6, 7; Neh. 13:23, 24) Báwo làwọn ọmọ yẹn ṣe máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n á sì máa sìn ín tí wọn ò bá gbọ́ èdè Hébérù, ìyẹn èdè tí wọ́n fi kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Ẹ́sírà 10:3, 44) Torí náà, ó hàn gbangba pé àwọn Júù yẹn gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan, ìyẹn sì máa rọrùn torí ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni wọ́n wà níbi tí ìjọsìn mímọ́ ti ń pa dà bọ̀ sípò.—Neh. 8:8, 9. w23.05 15 ¶6-7
Friday, September 5
Jèhófà ń gbé gbogbo àwọn tó ti fẹ́ ṣubú ró, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tó dorí kodò dìde.—Sm. 145:14.
Ó bani nínú jẹ́ pé kò sí bá a ṣe ṣiṣẹ́ kára tó tàbí bá a ṣe kó ara wa níjàánu tó, àwọn nǹkan kan ṣì lè mú kọ́wọ́ wa má tètè tẹ àfojúsùn wa. Bí àpẹẹrẹ, “ìgbà àti èèṣì” lè má jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń lé. (Oníw. 9:11) Yàtọ̀ síyẹn, ìṣòro lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ká má sì lókun mọ́. (Òwe 24:10) Torí pé aláìpé ni wá, a lè máa ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń lé. (Róòmù 7:23) Gbogbo nǹkan sì lè tojú sú wa. (Mát. 26:43) Torí náà, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro yìí? Máa rántí pé tóhun kan ò bá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tètè tẹ nǹkan tó ò ń lé, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kó o pa nǹkan náà tì. Bíbélì sọ pé ìṣòro lè dé bá wa léraléra. Àmọ́, ó tún sọ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro náà. Ó dájú pé tó o bá ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, ìyẹn á jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé o fẹ́ ṣohun tóun fẹ́. Wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ohun tó ò ń lé! w23.05 30 ¶14-15
Saturday, September 6
Ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.—1 Pét. 5:3.
Tí ọ̀dọ́ kan bá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, á jẹ́ kó mọ bó ṣe lè bá onírúurú èèyàn ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ kó mọ bá a ṣe ń ṣówó ná. (Fílí. 4:11-13) Tó o bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lo máa kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Tó o bá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, á jẹ́ kó o láǹfààní láti ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè di ọ̀kan lára àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run tàbí kó o máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ó yẹ káwọn arákùnrin máa ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà, á sì jẹ́ kí wọ́n lè sin àwọn ará nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé táwọn arákùnrin bá ń ṣiṣẹ́ kára láti di alábòójútó, ‘iṣẹ́ rere ni wọ́n fẹ́ ṣe.’ (1 Tím. 3:1) Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Onírúurú ọ̀nà làwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń gbà ran àwọn alàgbà lọ́wọ́. Torí pé àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nírẹ̀lẹ̀, wọ́n ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́, wọ́n sì ń fìtara wàásù pẹ̀lú wọn. w23.12 28 ¶14-16