Friday, September 5
Jèhófà ń gbé gbogbo àwọn tó ti fẹ́ ṣubú ró, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tó dorí kodò dìde.—Sm. 145:14.
Ó bani nínú jẹ́ pé kò sí bá a ṣe ṣiṣẹ́ kára tó tàbí bá a ṣe kó ara wa níjàánu tó, àwọn nǹkan kan ṣì lè mú kọ́wọ́ wa má tètè tẹ àfojúsùn wa. Bí àpẹẹrẹ, “ìgbà àti èèṣì” lè má jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń lé. (Oníw. 9:11) Yàtọ̀ síyẹn, ìṣòro lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ká má sì lókun mọ́. (Òwe 24:10) Torí pé aláìpé ni wá, a lè máa ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń lé. (Róòmù 7:23) Gbogbo nǹkan sì lè tojú sú wa. (Mát. 26:43) Torí náà, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro yìí? Máa rántí pé tóhun kan ò bá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tètè tẹ nǹkan tó ò ń lé, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kó o pa nǹkan náà tì. Bíbélì sọ pé ìṣòro lè dé bá wa léraléra. Àmọ́, ó tún sọ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro náà. Ó dájú pé tó o bá ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, ìyẹn á jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé o fẹ́ ṣohun tóun fẹ́. Wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ohun tó ò ń lé! w23.05 30 ¶14-15
Saturday, September 6
Ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.—1 Pét. 5:3.
Tí ọ̀dọ́ kan bá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, á jẹ́ kó mọ bó ṣe lè bá onírúurú èèyàn ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ kó mọ bá a ṣe ń ṣówó ná. (Fílí. 4:11-13) Tó o bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lo máa kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Tó o bá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, á jẹ́ kó o láǹfààní láti ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè di ọ̀kan lára àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run tàbí kó o máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ó yẹ káwọn arákùnrin máa ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà, á sì jẹ́ kí wọ́n lè sin àwọn ará nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé táwọn arákùnrin bá ń ṣiṣẹ́ kára láti di alábòójútó, ‘iṣẹ́ rere ni wọ́n fẹ́ ṣe.’ (1 Tím. 3:1) Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Onírúurú ọ̀nà làwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń gbà ran àwọn alàgbà lọ́wọ́. Torí pé àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nírẹ̀lẹ̀, wọ́n ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́, wọ́n sì ń fìtara wàásù pẹ̀lú wọn. w23.12 28 ¶14-16
Sunday, September 7
Nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀.—2 Kíró. 34:3.
Ọ̀dọ́ ni Ọba Jòsáyà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà. Ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kó sì máa ṣohun tó fẹ́. Àmọ́ nǹkan ò rọrùn fún ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí. Nígbà yẹn, ìjọsìn èké lọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe. Torí náà, ó di dandan pé kí Jòsáyà fìgboyà gbèjà ìjọsìn tòótọ́, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Kódà, kí Jòsáyà tó pé ọmọ ogún (20) ọdún ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìjọsìn èké kúrò lórílẹ̀-èdè náà. (2 Kíró. 34:1, 2) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, o lè fara wé Jòsáyà tó o bá ń wá Jèhófà, tó o sì ń fàwọn ànímọ́ ẹ̀ ṣèwà hù. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á wù ẹ́ láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Kí nìyẹn máa mú kó o ṣe lójoojúmọ́? Arákùnrin Luke tó ṣèrìbọmi nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14) sọ pé: “Àtìgbà tí mo ti ya ara mi sí mímọ́ ni mo ti pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà ló máa gbawájú láyé mi, màá sì máa múnú ẹ̀ dùn.” (Máàkù 12:30) Tíwọ náà bá pinnu pé ohun tó o máa ṣe nìyẹn, wàá láyọ̀! w23.09 11 ¶12-13