ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/06 ojú ìwé 23-25
  • Báwo Lo Ṣe Máa Pẹ́ Tó Láyé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lo Ṣe Máa Pẹ́ Tó Láyé?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó Ṣe Yẹ Kí Ìgbésí Ayé Rí Látìbẹ̀rẹ̀
  • Ìràpadà Kúrò Lọ́wọ́ Hẹ́gẹhẹ̀gẹ Ọjọ́ Ogbó
  • Ìyè Ayérayé
  • Báwo Lo Ṣe Máa Pẹ́ Tó Láyé?
  • Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tó Lọ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • O Lè Wà Láàyè Títí Láé Lórí Ilẹ̀ Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìràpadà Kristi Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Là Sílẹ̀ Fún Ìgbàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 7/06 ojú ìwé 23-25

Báwo Lo Ṣe Máa Pẹ́ Tó Láyé?

“Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.”—JÓÒBÙ 33:25.

BÍ AJÁ kan bá kú lẹ́yìn tó ti lo ọdún mẹ́wàá tàbí ogún ọdún láyé, ó ṣeé ṣe kó ti ṣe ọ̀pọ̀ ohun tó yẹ kí ajá ṣe. Ó lè ti bímọ, kó ti máa sá tọ ológbò, kó ti fọ́ eegun, kó sì ti dáàbò bo olówó ẹ̀. Àmọ́ béèyàn bá kú lẹ́yìn àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún, díẹ̀ lonítọ̀hún á tíì lè ṣe nínú ohun tí ì bá lè ṣe. Tó bá jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn eré ìdárayá ni, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀kan tàbí méjì nínú ẹ̀ ló mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa. Tó bá jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn orin, bóyá ló lè ju èlò orin ẹyọ kan ṣoṣo tàbí méjì péré tó mọ̀ ọ́n lò dáadáa. Tó bá jẹ́ pé ó fẹ́ràn láti máa kọ́ èdè àwọn ẹlòmíì ni, bóyá láá fi gbọ́ ju èdè méjì tàbí mẹ́ta dáadáa. Ká ní ẹ̀mí ẹ̀ lè gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ ni, bóyá ì bá ti pàdé àwọn èèyàn tó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, bóyá ì bá ti mọ àwọn nǹkan tuntun ṣe tàbí kó sún mọ́ Ọlọ́run ju bó ṣe sún mọ́ ọn lọ.

O wá lè máa rò ó pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run dá èèyàn báyìí tó sì fi sí i lọ́kàn láti máa gbádùn àwọn nǹkan síbẹ̀ tí kò fún un ní ẹ̀mí tó gùn táá fi jẹ́ kó lè gbádùn ọ̀pọ̀ nǹkan tí ì bá wù ú láti gbádùn?’ Ó dà bíi pé kíkúrú tí ẹ̀mí èèyàn kúrú yìí kò bá ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣe àwọn ìṣẹ̀dá ẹ̀ mu, torí pé ó fara hàn gbangba nínú ìṣẹ̀dá pé ó ní ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi dá èèyàn. O tún lè máa rò ó pé ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi dá àwọn èèyàn pẹ̀lú àwọn ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bí ìdájọ́ òdodo àti ìyọ́nú síbẹ̀ tó tún fi sí wọn lọ́kàn láti máa ṣe ohun tí kò dáa?’

Tó o bá rí mọ́tò dáadáa kan tí ibì kan tẹ̀ wọnú lára rẹ̀, ṣé ojú ẹsẹ̀ náà ni wàá ti gbà pé bẹ́ni tó ṣe mọ́tò yẹn ṣe ṣe é nìyẹn? O ò ní gbà bẹ́ẹ̀! Ó dájú pé wàá sọ pé, ‘Bẹ́ni tó ṣe mọ́tò yìí ṣe fẹ́ kó rí kọ́ ló rí yìí. Ó ní láti jẹ́ pé ó ṣe é dáadáa àmọ́ bàsèjẹ́ kan ló bà á jẹ́ nígbà tó yá.’ Bákan náà gẹ́lẹ́, tá a bá ronú lórí ẹ̀bùn àgbàyanu tí ìwàláàyè èèyàn jẹ́, àwa náà á rí i pé bí Ẹlẹ́dàá ṣe fẹ́ kó rí nígbà tó dá a kọ́ ló rí báyìí. Ẹ̀mí wa tí kì í gùn yìí àti bí ìwà ibi ṣe máa ń wá sí wa lọ́kàn dà bí ojú ibi tó tẹ̀ wọnú lára ọ̀kọ̀ kan tó dúró dáadáa. Ó dájú pé ẹnì kan ló ṣàkóbá fún wa tí ẹ̀bùn ìwàláàyè tá a ní fi dòbu mọ́ wa lọ́wọ́. Ta ló dán irú ẹ̀ wò? Àwọn ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì fi hàn kedere pé ọ̀rọ̀ ọ̀hún ò ṣẹ̀yìn ẹnì kan báyìí.

Tó bá jẹ́ pé nígbà tí ìwàláàyè èèyàn bẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ dáadáa débi téèyàn lè fi wà láàyè títí láé, ta ló lè wá ṣàkóbá fún ìwàláàyè ọ̀hún lẹ́yìn náà o? Ẹnì kan ṣoṣo tó lè ṣe irú ẹ̀ náà ò lè ju ẹni tó jẹ́ bàbá gbogbo èèyàn, ìyẹn ẹni tí gbogbo ayé ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ ẹ̀. Tẹ́lòmíì tó yàtọ̀ sí bàbà gbogbo èèyàn bá máa ṣàkóbá fún ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn, àwọn kan nínú ìran èèyàn ni ì bá kó bá, ìyẹn àwọn tó bá ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ ẹ̀. Nítorí náà èrò tó ṣe kedere yìí bá ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ mu nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn [kan Ádámù, ènìyàn àkọ́kọ́] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 5:12) Torí náà, Ìwé Mímọ́ sọ pé Ádámù leku ẹdá tó dá wàhálà yìí sí wa lọ́rùn. Báwo ni ìgbésí ayé èèyàn ì bá ṣe rí tẹ́lẹ̀ ná?

Bó Ṣe Yẹ Kí Ìgbésí Ayé Rí Látìbẹ̀rẹ̀

Nígbà tí Bíbélì sọ pé ikú “wọ ayé,” ohun tí Bíbélì ń sọ ni pé látìbẹ̀rẹ̀ wá Ọlọ́run ò dá èèyàn láti máa kú. Ohun tó fà á téèyàn fi ń darúgbó tó sì fi ń kú ni ìwà ọ̀tẹ̀ tí èèyàn àkọ́kọ́ hù lòdì sí Ọlọ́run. Ní tàwọn ẹranko, Ọlọ́run ò dá wọn láti máa wà láàyè títí láé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:21; 4:4; 9:3, 4.

Ọlọ́run dá àwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn ẹranko. Ìwàláàyè tiwa ga ju tàwọn ẹranko lọ, gẹ́gẹ́ bí ìwàláàyè àwọn áńgẹ́lì ṣe ga ju tàwa èèyàn náà lọ. (Hébérù 2:7) Èyí tá a tún fi wá yàtọ̀ sáwọn ẹranko ni pé á da wa ní “àwòrán Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, a tún yàtọ̀ sáwọn ẹranko nítorí Bíbélì pe Ádámù ní “ọmọkùnrin Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Látàrí gbogbo èyí, a ní ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti gbà pé Ọlọ́run ò dá èèyàn láti máa darúgbó kí wọ́n sì máa kú. Ọlọ́run kì í kú, kò sì dá àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa kú.—Hábákúkù 1:12; Róòmù 8:20, 21.

Tá a bá tún wo ìtàn àwọn èèyàn tó kọ́kọ́ gbé láyé, a óò túbọ̀ rí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá èèyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nígbà yẹn, àwọn èèyàn máa ń lo ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún láyé kí wọ́n tó darúgbó. Ádámù lò tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé ọgbọ̀n [930] ọdún láyé. Nígbà tó fi máa dorí àwọn ìran mélòó kan lẹ́yìn náà, Ṣémù ọmọ Nóà ò lò ju ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lọ nígbà tí Ápákíṣádì, ọmọ ọmọ Nóà, lo òjìlénírínwó ó dín méjì [438] ọdún.a (Jẹ́nẹ́sísì 5:5; 11:10-13) Nígbà tó dorí Ábúráhámù, ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án [175] ló lò láyé. (Jẹ́nẹ́sísì 25:7) Ṣe ló dà bíi pé ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ ń ní lórí èèyàn ń lágbára sí i, èyí sì wá ń dín iye ọdún téèyàn lè lò láyé kù débi tó wá ń kéré sí i bí ìran èèyàn ṣe ń jìnnà sí àkókò ìpilẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí Ẹlẹ́dàá dá ènìyàn ní pípé. Ṣùgbọ́n níbẹ̀rẹ̀, ṣe ni Ẹlẹ́dàá dá èèyàn láti máa gbé títí láé. Kò burú nígbà náà tẹ́nì kan bá ń béèrè pé, ‘Ṣé Ọlọ́run ṣì fẹ́ káwọn èèyàn máa gbádùn ìgbésí ayé tí kò lópin lórí ilẹ̀ ayé ṣá?’

Ìràpadà Kúrò Lọ́wọ́ Hẹ́gẹhẹ̀gẹ Ọjọ́ Ogbó

Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti kéde pé ẹnikẹ́ni tí kò bá gbọ́ràn sóun lẹ́nu, á jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó dá nítorí pé kíkú ló máa kú, ó dà bíi pé kò sí ìrètí kankan fáwọn ọmọ Ádámù nínú ipò tí wọ́n wà yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí jẹ́ ká nírètí pé ẹnì kan máa san ohun tó máa rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ọjọ́ ogbó. A kà pé: “Gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ sísọ̀kalẹ̀ sínú kòtò! Mo ti rí ìràpadà! Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.” (Jóòbù 33:24, 25; Aísáyà 53:4, 12) Ìrètí àgbàyanu ni Bíbélì fún wa níbí yìí, ìyẹn ni pé ẹnì kan máa san ìràpadà láti lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó!

Ta ló lè san ìràpadà yìí? Ìràpadà náà kì í ṣohun tówó lè rà. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn aláìpé, ó sọ pé: “Kò sí ẹnì kankan nínú wọn tí ó lè tún arákùnrin kan pàápàá rà padà ní ọ̀nà èyíkéyìí, tàbí kí ó fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀ . . . tí yóò ṣì fi wà láàyè títí láé.” (Sáàmù 49:7-9) Àmọ́, Jésù Kristi ní nǹkan kan tó ju owó lọ. Nígbà tó wà láyé, ó ní ìwàláàyé ẹ̀dá èèyàn pípé torí pé, gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run, ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ò nípa lórí rẹ̀. Jésù sọ pé òun wá láti fi ẹ̀mí òun ṣe “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Ní àkókò míì ó sọ pé: “Èmi ti wá kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ yanturu.”—Mátíù 20:28; Jòhánù 10:10.

Ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun ló jẹ́ lájorí ohun tí Jésù ń wàásù. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ọ̀kan lára àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn Pétérù sọ fún un pé: “Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:68) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, ìyè àìnípẹ̀kun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀?

Ìyè Ayérayé

Àwọn àpọ́sítélì Jésù ń retí ìgbà tí wọ́n máa gbádùn ìyè ayérayé lókè ọ̀run nígbà tí wọ́n bá ń bá Jésù jọba. (Lúùkù 22:29; Jòhánù 14:3) Síbẹ̀, Jésù sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé. (Mátíù 5:5; 6:10; Lúùkù 23:43) Nítorí náà, àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù àti ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni nípa ìyè àìnípẹ̀kun bá àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún kí Jésù tó wá sáyé mu. Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà ṣèlérí pé: “Ní ti tòótọ́, òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísáyà 25:8) Kò ní sí pé èèyàn ń darúgbó lẹ́yìn tó bá ti lo ìwọ̀nba ọdún mélòó kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ tí ìlera rẹ̀ á sì bẹ̀rẹ̀ sí í jagọ̀ tí ara rẹ̀ á sì wá di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.

Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ wá, nígbà táwọn èèyàn olóòótọ́ bá di pípé, wọ́n á bọ́ lọ́wọ́ hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó. Bíbélì sọ pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ìyẹn á mà ga o! Báwọn èèyàn ṣe ń dàgbà sí i ni ọgbọ́n wọn àti ìrírí wọn á máa pọ̀ sí i. Síbẹ̀, bí wọ́n bá ṣe ń gbé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún láyé, okun ìgbà ọ̀dọ́ wọn á máa wà bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ ìgbà yẹn á ṣojú ẹ?

Báwo Lo Ṣe Máa Pẹ́ Tó Láyé?

Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, àwọn èèyàn tó wà láyé á ti dín kù ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run bá fi máa parí. (Mátíù 24:21, 22) Jésù sọ pé: “Fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.

Láti lè wà lára àwọn tó máa gbádùn ìyè ayérayé, o ní láti wá ojú rere Ọlọ́run. Ibi tó o ti máa bẹ̀rẹ̀ ni pé wàá kọ́kọ́ mọ Ọlọ́run. Jésù ṣàlàyé pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú.” (Jòhánù 17:3) A mọ̀ pé ó gba ìsapá kéèyàn tó lè mọ Ọlọ́run dáadáa; síbẹ̀, irú ìsapá bẹ́ẹ̀ kò ní ṣàì sèsoore. Bó ṣe gba ìsapá kéèyàn tó lè rí owó táá fi máa jẹ oúnjẹ òòjọ́ náà nìyẹn. Nígbà tí Jésù sì ń fi ìmọ̀ Ọlọ́run wé oúnjẹ, ó ní: “Ẹ ṣiṣẹ́, kì í ṣe fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, bí kò ṣe fún oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:27) Ṣé ipá èyíkéyìí téèyàn bá sà láti ní ìyè tí kò lópin lè pọ̀ jù bí?—Mátíù 16:26.

Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Torí náà bó o ṣe máa pẹ́ tó láyé sinmi lórí ohun tó o bá ṣe sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí ọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn kan sọ pé kì í ṣe ọdún gidi làwọn ọdún tí Bíbélì ń mẹ́nu kàn yẹn, oṣù ni wọn. Àmọ́, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà sọ pé Ápákíṣádì bí Ṣélà nígbà tó pé ọmọ ọdún márùndínlógójì. Tá a bá sọ pé oṣù márùndínlógójì ni Bíbélì ń sọ níbẹ̀ yẹn, á jẹ́ pé Ápákíṣádì ti di bàbá ọmọ kó tó pé ọmọ ọdún mẹ́ta, ó dájú pé ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn orí tó ṣáájú nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì lo oòrùn àti òṣùpá láti fi ìyàtọ̀ kedere hàn láàárín bí ọdún ṣe máa ń yí po àti bí oṣù ṣe máa ń yí po.—Jẹ́nẹ́sísì 1:14-16; 7:11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]

Lẹ́yìn ọgọ́rin ọdún láyé, èèyàn ò tí ì lè ṣe kọjá díẹ̀ nínú ohun tí ì bá lè ṣe

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

Bí ẹlẹ́dàá ṣe dá àwa èèyàn ga lọ́lá ju bó ṣe dá àwọn ẹranko

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ṣé ẹni tó ṣe mọ́tò yìí ló ṣe é kó rọra tẹ̀ sínú bó ṣe wà yí ni?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn yóò padà sí ‘okun ìgbà ọ̀dọ́ wọn’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́