Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ìjọsìn Ọlọ́run Máa Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀?
OBÌNRIN kan tó pe ara rẹ̀ ní ẹlẹ́sìn Kristi sọ pé: “Mo gba Ọlọ́run gbọ́ mo sì fẹ́ràn rẹ̀. Àmọ́ . . . ó ti sú mi láti máa lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì.” Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Ibi tọ́rọ̀ náà wà ni pé àwọn kan ti hùmọ̀ ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà sin Ọlọ́run nítorí pé ó ti sú wọn, wọn ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn mọ́, wọn ò sì mọ èyí tí wọn ì bá ṣe mọ́.
Ìwé ìròyìn kan tó sọ̀rọ̀ nípa báwọn èèyàn ṣe ń hùmọ̀ ọ̀nà tó wù wọ́n láti máa jọ́sìn tiẹ̀ pe irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ ní “ẹ̀sìn ṣe-bó-o-ti-fẹ́.” Àmọ́ ní tàwọn tó jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n fẹ́ kí ìjọsìn Ọlọ́run máa dùn mọ́ àwọn, irú ẹ̀sìn àdábọwọ́ bẹ́ẹ̀ ò lè rọ̀ wọ́n lọ́rùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé bó bá jẹ́ pé ohùn tí kò tẹ́ wọn lọ́rùn tí wọ́n rí ní ṣọ́ọ̀ṣì ló lé wọn kúrò, wọ́n tún lè lọ rí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ níbi tí wọ́n bá sá lọ.
Ìyẹn lè wá mú kéèyàn béèrè pé, Ṣé ohun tó máa ń sú èèyàn àtohun tí kì í fúnni láyọ̀ ni ìjọsìn Ọlọ́run? Rárá o! Àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé kò rí bẹ́ẹ̀ rèé nínú ọ̀rọ̀ onísáàmù kan nínú Bíbélì. Ó sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a fi ìdùnnú ké jáde sí Jèhófà! . . . Ẹ wọlé wá, ẹ jẹ́ kí a jọ́sìn, kí a sì tẹrí ba; ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Jèhófà Olùṣẹ̀dá wa.”—Sáàmù 95:1, 6.
Ìmọrírì tún sún òmíràn lára àwọn tó kọ Sáàmù inú Bíbélì débi tó fi kọrin pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ìwé Mímọ́ tún pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì ti jẹ́ àṣà àwọn tó ń sìn ín, yálà nísinsìnyí tàbí látijọ́, láti máa láyọ̀.—Sáàmù 83:18; 1 Tímótì 1:11.
Àwọn Nǹkan Tó Lè Múni Láyọ̀
Ohun tó lè mú ká ní ojúlówó ayọ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà ni pé ká máa rántí ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà fi hàn pé lóòótọ́ lòun nífẹ̀ẹ́ wa. Kí sì lohun náà? “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [ìran èèyàn] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo [Jésù Kristi] fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí “onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì kan sọ nìkan la gbọ́dọ̀ mọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní “òye” ohun tá a bá kà, tó túmọ̀ sí pé a ó máa fara balẹ̀ ka Bíbélì a ó sì máa fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. (Mátíù 15:10) Kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ìwé Òwe sọ pe: “Ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” Ìyẹn á múni láyọ̀ gan-an ni!—Òwe 2:1-5.
Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn ará Makedóníà tí wọ́n ń gbé nílùú Bèróà nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, “wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, . . . wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀” ló rí. Wọn kì bá ní irú ìháragàgà bẹ́ẹ̀ bó bá jẹ́ pé ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ máa ń sú wọn tí kì í sì í fún wọn láyọ̀.—Ìṣe 17:11.
Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, níwọ̀n bí a ó ti bọ́ wọn yó.” (Mátíù 5:6) Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn arebipa tí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í róúnjẹ jẹ déédéé, inú ọ̀pọ̀ èèyàn ń dùn lónìí pé àwọn ń rí gbogbo ohun táwọn nílò kí àjọṣe àwọn pẹ̀lú Jèhófà má bàa yingin. Nítorí náà, “púpọ̀ nínú wọ́n [ti di] onígbàgbọ́” bíi tàwọn ará Bèróà.—Ìṣe 17:12.
Ọ̀nà Táwọn Kristẹni Ń Gbà Jọ́sìn Ọlọ́run Lójoojúmọ́
Èdè táwọn olùjọsìn Jèhófà máa ń lò ní ọ̀rúndún kìíní ni “Ọ̀nà Náà,” èyí tí ìwé Ìṣe 9:2 lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tuntun táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Ohun tí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ kí ìjọsìn Ọlọ́run máa mú wọ́n láyọ̀ lóde tòní náà gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì máa darí èrò wọn àti ìwà tí wọ́n bá ń hù lójoojúmọ́.
Ìdí ẹ̀ nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn èèyàn tó wà nílùú Éfésù pé: “Kí ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé.” Kò wá mọ síbẹ̀ yẹn ṣá o, nítorí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfésù 4:22-24.a
Bá a ti ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn yẹn, tá à ń yí ìgbésí ayé wa padà ká lè máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, á ṣeé ṣe fún wa láti rí ọ̀nà tá a lè gbà máa ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ ńláǹlà. Ọ̀nà wo nìyẹn ná? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe àtúnṣe ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn “kí [wọ́n] lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kólósè 1:10) Ó dájú pé wíwulẹ̀ mọ̀ pé ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa tẹ́ Jèhófà lọ́rùn lásán ti tó láti mú ká máa láyọ̀! Pabanbarì ẹ̀ tún wá ni pé Ọlọ́run ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wu òun “ní kíkún.” Lọ́nà wo nìyẹn ná? Nípasẹ̀ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
Kò sẹ́ni tí kì í dẹ́ṣẹ̀ nínú wa; gbogbo wa ló pọn dandan fún pé ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Tímótì 1:15 pé: “Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.” Nígbà tí Jésù fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nítorí wa, ó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà. Nítorí náà, ẹní bá ń fi òtítọ́ sin Ọlọ́run á rí ìtura, nítorí pé ṣe ló máa dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹrù ẹ̀bi kúrò ní ọkàn àyà rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ á lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, á sì máa yọ̀ nítorí pé ó máa dá a lójú pé bóun bá ń bá a nìṣó láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun á máa rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun gbà.
Àwọn Ohun Tó Tún Lè Mú Kéèyàn Máa Láyọ̀
Ẹní bá pinnu pé Ọlọ́run lòun á máa sìn kò dá wà lóun nìkan. Dáfídì, ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù kọ̀wé pé: “Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé: ‘Jẹ́ kí a lọ sí ilé Jèhófà.’” (Sáàmù 122:1) Kò sírọ́ ńbẹ̀, bá a bá ń pàdé pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ńṣe ni ayọ̀ wa á túbọ̀ máa pọ̀ sí i.
Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan lọ sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó kọ̀wé pé: “Wọ́n gbà wá tọwọ́ tẹsẹ̀, wọn ò fi ohunkóhun jẹ wá níyà, a sì rí i kedere pé gbogbo àwọn tó wà nípàdé náà wà ní ‘ìṣọ̀kan.’ Ìmúra ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó wà níbẹ̀ ṣe wẹ́kú, ó sì dájú pé ìyẹn á máa mórí àwọn míì àti tàwọn òbí wọn wú. Mo fẹ́ láti dúpẹ́ fún pípè tẹ́ ẹ pè mí láti wá ní irú ìrírí alárinrin bí èyí.”
Ìwọ pẹ̀lú lè rí i pé ìjọsìn Jèhófà máa ń múni láyọ̀, ó sì lè máa múnú rẹ dùn bó ṣe mú inú Dáfídì dùn ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ó rọ̀ wá pé: “Ẹ fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà. Ẹ fi igbe ìdùnnú wọlé wá síwájú rẹ̀.” (Sáàmù 100:2) Kò sí ni, béèyàn bá fi ọkàn tó tọ́ sin Ọlọ́run òtítọ́, ìjọsìn rẹ̀ á mú kó láyọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá fẹ́ ní òye tó ṣe kedere nípa ohun tó wé mọ́ gbígbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, jọ̀wọ́ ka Éfésù orí 4 àti Kólósè orí 3.
ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ẹ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?
◼ Orí kí ni ìjọsìn tòótọ́ dúró lé?—1 Tímótì 2:3-6.
◼ Báwo ni ẹbọ ìràpadà Kristi ṣe ń mú ká láyọ̀?—1 Tímótì 1:15.
◼ Báwo làwọn ìpàdé ìjọ ṣe lè mú kí ìjọsìn Ọlọ́run mú ẹ láyọ̀?—Sáàmù 100:1-5.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Kékeré kọ́ layọ̀ tó wà nínú dídara pọ̀ mọ́ àwọn míì láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì