ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 21-23
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àkókò Ìṣefàájì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àkókò Ìṣefàájì?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣe Àwọn Nǹkan Pa Pọ̀
  • Òde Àríyá Tí Ń Gbéni Ró
  • Ìmóríyá Ìdílé
  • Nígbà Tí O Bá Dá Wà
  • “Ìgbádùn” Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
  • Èé Ṣe Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Mìíràn Ń Gbádùn Gbogbo Ìmóríyá Náà?
    Jí!—1996
  • Eré Ìnàjú Tó Dára Tó Sì Ń tuni Lára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ara Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 21-23

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àkókò Ìṣefàájì?

“Mo rò pé a máa ń ní àwọn ohun amóríyá púpọ̀ láti ṣe. Nínú ìjọ wa, a ń sapá gidigidi láti kóra jọ pọ̀. A ń ní ìmóríyá gbígbámúṣé. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èwe nínú ayé kò lè sọ bẹ́ẹ̀.”—Jennifer.

ERÉ ìtura—gbogbo ènìyàn nílò rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé eré ìtura tilẹ̀ lè kó “ipa pàtàkì kan nínú ìlera èrò orí àti ti ara ìyára ẹnì kan.” Kódà, Bíbélì tìkára rẹ̀ sọ pé “ìgbà láti rẹ́rìn-ín” wà, ìyẹn ni, ìgbà láti gbádùn ara ẹni!—Oníwàásù 3:1, 4.a

Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà “recreation” tí a túmọ̀ sí “eré ìtura” wá láti inú ọ̀rọ̀ èdè Latin kan tí ó túmọ̀ sí “láti ṣẹ̀dá lákọ̀tun, láti mú bọ̀ sípò, láti tù lára.” (Webster’s New Collegiate Dictionary) Ó bani nínú jẹ́ pé, púpọ̀ lára àwọn ohun tí àwọn ọ̀dọ́ ń ṣe fún “ìmóríyá”—bí àpèjẹ oníwà ẹhànnà tàbí ìlòkulò oògùn àti ọtí líle tàbí ìbálòpọ̀ tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu—kì í tuni lára ní ti gidi rárá, ṣùgbọ́n wọ́n ń pani run. Nítorí náà, ó jẹ́ ìpèníjà gidigidi láti ṣàwárí àwọn ìgbòkègbodò eré ìtura gbígbámúṣé, tí ó gbádùn mọ́ni. Ṣùgbọ́n bí Jennifer, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀, ṣe fi hàn, ó ṣeé ṣe!

Ṣíṣe Àwọn Nǹkan Pa Pọ̀

Láìpẹ́ yìí, Jí! fọ̀rọ̀ wá àwọn ọ̀dọ̀ mélòó kan lẹ́nu wò nípa kókó ọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n sọ pé àwọ́n ń gbádùn ìkórajọpọ̀ pẹ̀lú àwọn èwe mìíràn. Ìwọ́ ha ní ìmọ̀lára kan náà—ṣùgbọ́n tí o sábà ń rí i pé a kì í ké sí ọ bí? O kò ṣe gbé ìgbésẹ̀ àtinúdá náà nígbà náà? Fún àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin ará Gúúsù Áfíríkà kan tí ń jẹ́ Leigh sọ pé: “Bí mo bá ń dàníyàn láti wo sinimá kan, n óò tẹ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi láago, a óò sì fi tó àwọn ọ̀rẹ́ wa mìíràn létí.” Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń lọ wòran sinimá náà lójúmọmọ. Lẹ́yìn náà, àwọn òbí wọn yóò kó wọn sọ́kọ̀, wọn yóò sì jùmọ̀ jẹun pọ̀ ní ilé àrójẹ kan ládùúgbò.

Àwọn eré ìdárayá pẹ̀lú ń fúnni láǹfààní láti ṣe eré ìmárale tí ń ṣara láǹfààní, kí a sì ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé. (Tímótì Kìíní 4:8) Ọ̀dọ́ tí ń jẹ́ Roelien sọ pé: “Mo kọ́kọ́ ń jíròrò ibi tí mo fẹ́ẹ́ lọ pẹ̀lú ìdílé mi, lẹ́yìn náà, a máa ń ké sí àwùjọ kékeré kan láti dara pọ̀ mọ́ wa.” Ní tòótọ́, àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ti ṣàwárí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ eré ìdárayá gbígbámúṣé tí wọ́n lè ṣe pẹ̀lú àwọn mìíràn: tí díẹ̀ lára wọn jẹ́ yíyọ̀ lórí yìnyín, gígun kẹ̀kẹ́, sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́, gbígbá tẹníìsì, bọ́ọ̀lù àjùfigigbá, bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá, àti bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá.

Láìṣe àní-àní, o kò ní láti náwó rẹpẹtẹ tàbí kí o kówó lé ohun èèlò títayọ lọ́lá kan kí o tóó lè ṣe fàájì. Ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba Kristẹni kan sọ pé: “Èmi, àwọn òbí mi, àti àwọn ọ̀rẹ́ mi ti lo ọ̀pọ̀ wákàtí ìṣefàájì ní rírin ìrìn ìnàjú ní àwọn òkè ńláńlá àti agbègbè aginjù àdúgbò. Wíwulẹ̀ lọ gbafẹ́fẹ́ atura pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ dáadáa máa ń gbádùn mọ́ni gan-an ni!”

Òde Àríyá Tí Ń Gbéni Ró

Bí ó ti wù kí ó rí, lójú ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, ìmóríyá túmọ̀ sí lílọ òde àríyá. Aveda ọ̀dọ́ sọ pé: “A máa ń gbádùn pípe àwọn ọ̀rẹ́ láti wáá jẹun, kí wọ́n sì gbọ́ orin nílé wa.” Àwọn òde àríyá ní àyè tiwọn láàárín àwọn Kristẹni. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ lọ sí àwọn àkànṣe àpèjẹ, ibi ayẹyẹ ìgbeyàwó, àti àwọn òde àríyá mìíràn. (Lúùkù 5:27-29; Jòhánù 2:1-10) Bákan náà ni àwọn Kristẹni ìjímìjí gbádùn àwọn àkókò tí wọ́n fi kóra jọ fún oúnjẹ jíjẹ àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbéni ró.—Fi wé Júúdà 12.

Bí àwọn òbí rẹ bá gbà ọ́ láyè láti gbàlejò ìkórajọpọ̀ kan, kí ni o lè ṣe láti yẹra fún àwọn ìṣòro, kí o sì rí i dájú pé olúkúlùkù àwọn tó wá ṣe fàájì? Ètò àfẹ̀sọ̀ṣe ni ohun pàtàkì jù lọ. (Òwe 21:5) Láti ṣàpèjúwe: Ó bọ́gbọ́n mu láti pe kìkì iye tí a lè bójú tó dáradára lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Àwọn ìkórajọpọ̀ alábọ́ọ́dé kò sábà máa ń di “àríyá aláriwo” tàbí “àpèjẹ oníwà ẹhànnà.”—Gálátíà 5:21; Byington.

A kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní láti yẹra fún bíbá àwọn tí “ń rìn ségesège” ṣàríyá. (Tẹsalóníkà Kejì 3:11-15) Ọ̀nà tí ó sì dájú jù lọ láti ba ìkórajọpọ̀ kan jẹ́ lónìí ni láti pe àwọn ọ̀dọ́ tí a mọ̀ pé wọ́n jẹ́ aláriwo àti alaìṣeéṣàkóso. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó yẹ kí o ṣọ́ra nípa irú ẹni tí o ké sí, má ṣe fi mọ sí ọ̀dọ̀ kìkì agbo àwọn ọ̀rẹ́ kan náà. “Gbòòrò síwájú,” kí o sì mọ àwọn ẹlòmíràn, títí kan àwọn àgbàlagbà, nínú ìjọ.—Kọ́ríńtì Kejì 6:13.

Ìwọ yóò ha pèsè ìpápánu bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe dandan kí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ tàbí jẹ́ olówó ńlá, kí àwọn àlejò rẹ tóó ṣe fàájì. (Lúùkù 10:38-42) Sanchia, ọmọbìnrin kan láti Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Nígbà míràn, a má ń pé jọ láṣàálẹ́ láti jẹ búrẹ́dì tí a fi ohun aládùn sínú rẹ̀ lásán.” Àwọn àlejò sábà máa ń fínnúfíndọ̀ gbé ohun jíjẹ díẹ̀ dání wá.

Àwọn ohun díẹ̀ wo ni o lè ṣe níbi ìkórajọpọ̀ kan—yàtọ̀ sí wíwo tẹlifíṣọ̀n, gbígbọ́ orin, tàbí jíjíròrò lásán? Sanchia sọ pé: “A sábà máa ń wéwèé ìrọ̀lẹ́ náà ṣáájú. A ti ṣe àwọn eré àṣedárayá tàbí kí ẹnì kan máa tẹ dùùrù, kí gbogbo wa lè máa kọrin pọ̀.” Ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan tí ń jẹ́ Masene wí pé: “Nígbà míràn, a máa ń ta káàdì, ayò draughts [checkers], àti ayò chess.”

Jennifer, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ tẹ́lẹ̀, sọ fún Jí! pé: “A ní alàgbà kan nínú ìjọ wa tí ó máa ń ké sí wa sílé rẹ̀ láti ṣe àwọn eré tí ó níí ṣe pẹ̀lú Bíbélì. O ní láti ní ìmọ̀ Bíbélì dáradára kí o tóó lè ṣe àwọn eré náà dáradára.” Aṣojú Jí! náà béèrè lọ́wọ́ àwọn èwe mìíràn pé: “Ẹ kò ha rò pé ṣíṣe àwọn eré tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Bíbélì kò bóde mu bí?” Ìdáhùn wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ariwo pé, “Rárá o!”

Ọmọbìnrin ọ̀dọ́langba kan sọ pé: “Ó ń múni ronú.” Òmíràn sọ pé: “Ohun amóríyá ni.” Nígbà tí a bá ń ṣe àwọn eré tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Bíbélì fún ìmóríyá, tí a sì kápá ẹ̀mí ìbánidíje, wọ́n lè gbádùn mọ́ni, kí wọ́n sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́!—Wo “Mimu Ki Ipejọpọ Larinrin sibẹ Ki O Ṣanfani,” nínú ìtẹ̀jáde Ji!, March 8, 1973.

Ìmóríyá Ìdílé

Ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, kò ṣàjèjì fún àwọn ìdílé láti gbádùn oríṣi àwọn eré ìtura mélòó kan pa pọ̀. (Lúùkù 15:25) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀dọ́ tí ó kọ ìwé The Kids’ Book About Parents ṣàkíyèsí pé “ọwọ́ àwọn òbí àti àwọn ọmọ dí lóde òní tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnì kankan kò fi ráyè wéwèé àwọn ìgbòkègbodò . . . A rò pé ó ṣe pàtàkì fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ láti rí i dájú pé wọ́n ń lo àkókò pa pọ̀ lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní ṣíṣe àwọn ìgbòkègbodò tí wọ́n wà fún ìmóríyá ní pàtàkì.”

Èwe ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan tí ń jẹ́ Paki sọ pé: “Friday ni ọjọ́ ìdílé wa. A sábà máa ń tayò pa pọ̀.” Ẹ má sì ṣe jẹ́ kí a gbàgbé àwọn ọmọ ìyá rẹ. Bronwyn ọ̀dọ́ sọ pé: “Mo máa ń gbádùn àwòrán yíyà àti ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ọnà míràn pẹ̀lú àbúrò mi obìnrin.” O ha lè lo àtinúdá, kí o sì dámọ̀ràn àwọn ìgbòkègbodò amóríyá díẹ̀ láti ṣe pẹ̀lú ìdílé rẹ bí?

Nígbà Tí O Bá Dá Wà

Bí o bá dá wà ńkọ́? Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ sú ọ, kí o sì nímọ̀lára ìdánìkanwà. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ṣíṣàǹfààní, tí ó gbádùn mọ́ni ni a lè gbà lo irú àwọn sáà àkókò bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìgbòkègbodò àfipawọ́. Láti àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì wá, tọkùnrin tobìnrin ti rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ orin kíkọ ń mú ayọ̀ ẹni kún sí i. (Jẹ́nẹ́sísì 4:21; Sámúẹ́lì Kìíní 16:16, 18) Rachel sọ pé: “Mo máa ń tẹ dùùrù. Ohun kan tí o lè ṣe nígbà tí nǹkan bá sú ọ ni.” Bí o kò bá ní ìfẹ́ tó bẹ́ẹ̀ sí orin, o lè gbádùn kíkọ́ aṣọ rírán, ṣíṣe iṣẹ́ nínú ọgbà ọ̀gbìn, ṣíṣàkójọ sítám̀pù, tàbí kíkọ́ èdè àjèjì kan. Gẹ́gẹ́ bí èrè àìròtẹ́lẹ̀, o tilẹ̀ lè kọ́ àwọn iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe kan tí yóò wúlò lẹ́yìnwá ọ̀la.

Bíbélì sọ fún wa pé àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́, bí Aísíìkì, wá àkókò ìdáwà fún ṣíṣe àṣàrò. (Jẹ́nẹ́sísì 24:63) Ọ̀dọ́kùnrin ará Austria kan ti ń jẹ́ Hans sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo wulẹ̀ máa ń lọ síbi pípa rọ́rọ́ kan nínú ọgbà, tí n óò sì jókòó láti wo wíwọ̀ oòrùn. Èyí máa ń mú inú mi dùn gan-an, ó sì ń mú mi sún mọ́ Ọlọ́run mi, Jèhófà, sí i.”

“Ìgbádùn” Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Kristi yóò rí “ìgbádùn” nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà Ọlọ́run. (Aísáyà 11:3) Bí ó sì tilẹ̀ ti jẹ́ pé iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Ọlọ́run kì í ṣe eré ìtura ní ti gidi, ó lè tuni lára, kí ó sì tẹ́ni lọ́rùn.—Mátíù 11:28-30.

Hans, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ṣáájú, tún rántí ìrírí gbígbádùn mọ́ni kan. Ó wí pé: “Èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń fẹ́ẹ́ rántí àwọn òpin ọ̀sẹ̀ tí a lò láti ṣiṣẹ́ ní kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan [fún ìjọsìn]. A kọ́ láti ṣe iṣẹ́ pa pọ̀, a sì túbọ̀ mọ ẹnì kíní kejì dáradára sí i. Ní ṣíṣàṣàrò lórí ohun tí ó ti kọjá, a ní ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn pé a ti ṣe ohun títóyeyẹ tí ó sì tún jẹ́ amóríyá.”

Ọ̀rọ̀ ẹ̀rí àwọn èwe Kristẹni wọ̀nyí mú kókó wíwọni lọ́kàn kan ṣe kedere: O kò ní láti pàdánù àǹfààní ìṣefàájì. Tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Máa finú wòye! Máa lo àtinúdá gbígbámúṣé! Ìwọ yóò rí i pé o lè gbádùn ara rẹ ní àwọn ọ̀nà tí yóò gbé ọ ró, tí kì yóò sì bì ọ́ lulẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Mìíràn Ń Gbádùn Gbogbo Ìmóríyá Náà?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti July 22, 1996.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

“Wíwulẹ̀ lọ gbafẹ́fẹ́ atura pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ dáadáa máa ń gbádùn mọ́ni gan-an ni!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kò di ìgbà tí o náwó rẹpẹtẹ kí o tóó ṣe fàájì pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́