Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ní 1 Peteru 2:9, ìtumọ̀ “King James Version” pé àwọn Kristian ẹni àmì òróró ni “ìran tí a yàn.” Èyí ha ní láti nípa lórí ojú ìwòye wa nípa bí Jesu ṣe lo “ìran” nínú àkọsílẹ̀ Matteu 24:34 bí?
Ọ̀rọ̀ náà “ìran” fara hàn nínú ìtumọ̀ àyọkà méjèèjì nínú àwọn ìtumọ̀ kan pàtó. Ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ King James Version, aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn, olú àlùfáà, orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀; kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọlá ńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn.” Jesu sì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.”—1 Peteru 2:9; Matteu 24:34.
Nínú àyọkà tí ó ṣáájú, aposteli Peteru lo ọ̀rọ̀ Griki náà geʹnos, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ge·ne·aʹ ni a rí nínú gbólóhùn ọ̀rọ̀ Jesu. Àwọn ọ̀rọ̀ Griki méjì wọ̀nyí lè dà bí nǹkankan náà, wọ́n sì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìpìlẹ̀ kan náà; síbẹ̀, ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n, wọ́n sì ní ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures—With References sọ nínú àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé lórí 1 Peteru 2:9 pé: “‘Ẹ̀yà ìran.’ Gr., geʹnos; yàtọ̀ sí ge·ne·aʹ, ‘ìran,’ gẹ́gẹ́ bí a ti rí i ní Matteu 24:34.” A rí àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé tí ó bá a mú ní Matteu 24:34.
Bí àwọn àkíyèsí ẹsẹ ìwé wọ̀nyẹn ti fi hàn, ọ̀rọ̀ èdè Yorùbá náà “ẹ̀yà ìran” túmọ̀ geʹnos lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ìtumọ̀ èdè Yorùbá. Ní 1 Peteru 2:9, Peteru lo àsọtẹ́lẹ̀ tí a rí nínú Isaiah 61:6 fún àwọn Kristian ẹni àmì òróró tí wọ́n ní ìrètí ti òkè ọ̀run. Àwọn wọ̀nyí ni a mú láti inú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà, ṣùgbọ́n ipò àtilẹ̀wá àbínibí kò jẹ́ nǹkankan fún wọn, níwọ̀n bí wọ́n ti di apá kan orílẹ̀-èdè Israeli tẹ̀mí. (Romu 10:12; Galatia 3:28, 29; 6:16; Ìṣípayá 5:9, 10) Peteru fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó di àwùjọ àrà ọ̀tọ̀ kan, nípa tẹ̀mí—“ẹ̀yà-ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, awọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.”
Ṣùgbọ́n nínú ẹsẹ̀ ìwé Griki tí a ti rí ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ ní Matteu 24:34, a rí ọ̀rọ̀ náà ge·ne·aʹ. A mọ̀ ọ́n bí ẹní mowó pé, kì í ṣe “ẹ̀yà ìran” àwọn ènìyàn èyíkéyìí ni Jesu ń tọ́ka sí, bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí ń gbé ní sáà àkókò kan pàtó.
Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Charles T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, mu èyí ṣe kedere, ní kíkọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè sọ pé ọ̀rọ̀ náà ‘ìran’ àti ‘ẹ̀yà ìran’ wá láti inú ìpìlẹ̀ tàbí orísun kan náà, síbẹ̀ wọn kì í ṣe ohun kan náà; àti nínú ìlò Ìwé Mímọ́, àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì náà yàtọ̀ gédégédé. . . . Nínú àkọsílẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti àsọtẹ́lẹ̀ yìí, a tọ́ka sí i pé Oluwa wa lo odindi ọ̀rọ̀ Griki náà (genea) tí kò túmọ̀ sí ẹ̀yà ìran, ṣùgbọ́n ó ti ní ìjẹ́pàtàkì kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì wa náà generation [Yorùbá, ìran]. Àwọn ọ̀nà mìíràn tí a gbà lo ọ̀rọ̀ Griki náà (genea) jẹ́rìí sí i pé, a kò lò ó pẹ̀lú ìjẹ́pàtàkì kan náà tí ẹ̀yà ìran ní, ṣùgbọ́n ní títọ́ka sí àwọn ènìyàn tí wọ́n jọ gbé ayé papọ̀.”—The Day of Vengeance, ojú ìwé 602 sí 603.
Láìpẹ́ yìí, ìwé náà, A Handbook on the Gospel of Matthew (1988), tí a ṣe fún àwọn atúmọ̀ Bibeli, wí pé: “[The New International Version] túmọ̀ ìran yìí ní ṣáńgílítí, ṣùgbọ́n àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé tẹ̀ lé e pé, ‘Tàbí ẹ̀yà ìran.’ Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan lórí Májẹ̀mú Titun gbàgbọ́ pé, ‘kì í ṣe ìran àkọ́kọ́ lẹ́yìn Jesu nìkan ni Matteu ní lọ́kàn, bí kò ṣe gbogbo ìran àwọn Júù tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.’ Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí ẹ̀rí ìmọ̀ èdè tí a fi lè ṣàlàyé èyíkéyìí àwọn ìparí èrò yìí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, a sì gbọ́dọ̀ pa wọ́n tì, gẹ́gẹ́ bí ìgbìdánwò láti yẹra fún ìtumọ̀ ṣíṣe kedere. Nínú ìlò rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀, àwọn alájọgbáyé Jesu nìkan ni ó tọ́ka sí.”
Gẹ́gẹ́ bí a ti jíròrò rẹ̀ lójú ìwé 10 sí 15, Jesu dẹ́bi fún ìran àwọn Júù ti àkókò rẹ̀, àwọn alájọgbáyé rẹ̀ tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Luku 9:41; 11:32; 17:25) Ó sábà máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́nlé bíi “burúkú ati panṣágà,” “aláìnígbàgbọ́ ati onímàgòmágó,” àti “panṣágà ati ẹlẹ́ṣẹ̀” láti ṣàpèjúwe ìran náà. (Matteu 12:39; 17:17; Marku 8:38) Nígbà tí Jesu lo ọ̀rọ̀ náà “ìran” fún ìgbà ìkẹyìn, ó wà lórí Òkè Olifi pẹ̀lú àwọn aposteli mẹ́rin. (Marku 13:3) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn, tí a kò tí ì fi ẹ̀mí yàn tàbí tí wọn kò tí i di apá kan ìjọ Kristian, dájúdájú, kò para pọ̀ jẹ́ “ìran” kan tàbí ẹ̀yà ìran àwọn ènìyàn kan. Ṣùgbọ́n, wọ́n dojúlùmọ̀ pẹ̀lú bí Jesu ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìran” ní títọ́ka sí àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nítorí náà, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, wọn yóò lóye ohun tí ó ní lọ́kàn nígbà tí ó mẹ́nu kan “ìran yìí“ fún ìgbà ìkẹyìn.a Aposteli Peteru, tí ó wà níbẹ̀, rọ àwọn Júù lẹ́yìn náà pé: “Ẹ gba ara yín là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yii.”—Ìṣe 2:40.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ti tẹ ẹ̀rí jáde pé, ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jesu sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìjíròrò kan náà yìí (bí ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àti ìyàn) ti ní ìmúṣẹ láàárín ìgbà tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà àti ìparun Jerusalemu ní 70 C.E. Ọ̀pọ̀ ni ó ní ìmúṣẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, kò sí ẹ̀rí pé lẹ́yìn tí àwọn ará Romu kọlu Jerusalemu (66 sí 70 C.E.), “àmì Ọmọkùnrin ènìyàn” fara hàn, tí ó sì mú kí “gbogbo awọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé” lu ara wọn. (Matteu 24:30) Nípa bẹ́ẹ̀, ìmúṣẹ náà láàárín 33 C.E. àti 70 C.E., ti wulẹ̀ lè jẹ́ ti àkọ́kọ́, tí kì í sì í ṣe ìmúṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ tàbí lọ́nà gbígbòòrò tí Jesu pẹ̀lú ń tọ́ka sí.
Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ìwé Josephus, The Jewish War, tí ó túmọ̀, G. A. Williamson kọ̀wé pé: “Matteu sọ fún wa pé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bi [Jesu] ní ìbéèrè alápá méjì—nípa ìparun Tẹ́ḿpìlì àti nípa bíbọ̀ Òun fúnra rẹ̀ ìkẹyìn—Ó sì fún wọn ní ìdáhùn alápá méjì, apá àkọ́kọ́ ní kedere jù lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kádàrá pé yóò rí bẹ́ẹ̀, tí Josephus ṣàpèjúwe lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.”
Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́, “ìran yìí,” ní kedere túmọ̀ sí ohun kan náà bí ó ti rí ní àwọn àkókò mìíràn—ìran àwọn alájọgbáyé ti àwọn Júù aláìgbàgbọ́. “Ìran” náà kì yóò kọjá lọ láìnírìírí ohun tí Jesu sọ tẹ́lẹ̀. Bí Williamson ṣe sọ, èyí jẹ́ òtítọ́ ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ṣáájú ìparun Jerusalemu, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan tí ó fojú rí i, Josephus, ti ṣàlàyé.
Nínú ìmúṣẹ kejì tàbí èyí tí ó tóbi jù, “ìran yìí” lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu yóò tún jẹ́ àwọn ènìyàn alájọgbáyé. Bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ti ó bẹ̀rẹ̀ ní ojú iwé 16 ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀, a kò ní láti parí èrò sí pé, Jesu ń tọ́ka sí àwọn ọdún kan pàtó tí ó para pọ̀ jẹ́ “ìran” kan.
Ní òdìkejì, a lè sọ ohun pàtàkì méjì nípa àkókò èyíkéyìí tí “ìran” túmọ̀ sí. (1) A kò lè fojú wo ìran àwọn ènìyàn kan gẹ́gẹ́ bí sáà kan tí ó ní iye ọdún kan pàtó, bí ọ̀ràn ti rí ní ti ohun tí àkókò dúró fún, tí ó túmọ̀ sí iye ọdún kan pàtó (ẹ̀wádún tàbí ọ̀rúndún). (2) Àwọn ènìyàn ìran kan ń gbé fún sáà kúkúrú ní ìfiwéra, kì í ṣe èyí tí ó gùn jàn-àn-ràn jan-an-ran.
Nítorí náà, nígbà tí àwọn aposteli gbọ́ tí Jesu ń tọ́ka sí “ìran yìí,” kí ni wọn yóò ní lọ́kàn? Pẹ̀lú àǹfààní mímọ ohun tí yóò jẹ́ àbájáde, bí àwa tilẹ̀ mọ̀ pé ìparun Jerusalemu nínú “ìpọ́njú ńlá” dé ní ọdún 37 lẹ́yìn náà, àwọn aposteli tí wọ́n gbọ́ ohun tí Jesu sọ lè má mọ ìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, mímẹ́nu kàn tí ó mẹ́nu kan “ìran,” ti lè gbé èrò àwọn ènìyàn tí ń gbé ní sáà àkókò kúkúrú kan ní ìfiwéra sí wọn lọ́kàn, kì í ṣe èrò ti sáà gígùn jàn-àn-ràn jan-an-ran kan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn tiwa rí. Nígbà náà, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ tẹ̀ lé e ti bá a mu wẹ́kú tó: “Níti ọjọ́ ati wákàtí yẹn kò sí ẹni kan tí ó mọ̀, kì í ṣe awọn áńgẹ́lì awọn ọ̀run tabi Ọmọkùnrin, bíkòṣe Baba nìkan. . . . Nítìtorí èyí ẹ̀yin pẹlu ẹ wà ní ìmúratán, nitori pé ní wákàtí tí ẹ̀yin kò ronú pé yoo jẹ́, ni Ọmọkùnrin ènìyàn ń bọ̀.”—Matteu 24:36, 44.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú gbólóhùn náà “ìran yìí,” irú ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ aṣàfihàn náà, houʹtos bá ọ̀rọ̀ Yorùbá náà “yìí” mu wẹ́kú. Ó lè tọ́ka sí ohun kan tí ó wà ní àrọ́wọ́tó tàbí níwájú olùbánisọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n ó tún lè ní àwọn ìtumọ̀ mìíràn. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Exegetical Dictionary of the New Testament (1991) sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà [houʹtos] dúró fún kókó abájọ ojú ẹsẹ̀. Nípa báyìí ‘ayé tí ó wà nísinsìnyí’ ni [aion houʹtos] . . . ‘ìran tí ó wà láàyè nísinsìnyí’ sì ni [geneaʹ haute] (fún àpẹẹrẹ, Matt 12:41 àlàyé ẹsẹ̀ ìwé, 45; 24:34).” Ọ̀mọ̀wé George B. Winer kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ orúkọ tí ó sún mọ́ ọn jù lọ ní ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà [houʹtos] ń tọ́ka sí nígbà mìíràn, bí kò ṣe èyí tí ó jìnnà jù lọ, tí ó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí orí ọ̀rọ̀, òun ni ó sún mọ́ ọn jù lọ ní ti èrò orí, èyí tí ó wà lọ́kàn òǹkọ̀wé náà jù lọ.”—A Grammar of the Idiom of the New Testament, ìtẹ̀jáde keje, 1897.