ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ojú ìwé 27-ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lérè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lérè
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mímúra Ọkàn Rẹ Sílẹ̀ Láti Kẹ́kọ̀ọ́
  • Bí A Ṣe Ń Kẹ́kọ̀ọ́
  • Ohun Tí A Máa Lò fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
  • “Gbé Agbo Ilé Rẹ Ró”
  • Èrè Rẹ̀
  • Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Yin Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Apá kan Ìjọ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Máa Ṣe Bí Ọba
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ojú ìwé 27-ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lérè

ǸJẸ́ o ti rí ibi tí àwọn èèyàn ti ń ṣa èso rí? Ọ̀pọ̀ jù lọ ló máa ń wo bí àwọ̀ rẹ̀ ṣe rí àti bó ṣe tóbi tó láti fi mọ bí ó ṣe pọ́n sí. Àwọn mìíràn máa ń fi imú gbóòórùn èso yẹn wò. Àwọn mìíràn yóò fi ọwọ́ kàn án, wọ́n a tiẹ̀ tẹ̀ ẹ́ wò. Àwọn mìíràn a tún wo bó ṣe tẹ̀wọ̀n sí, wọ́n á sọ ọ́ wò láti fi bó ṣe wúwo tó mọ èyí tó lómi nínú jù. Kí lèrò ọkàn àwọn èèyàn wọ̀nyí ná? Ńṣe ni wọ́n ń ṣàyẹ̀wò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan, wọ́n ń wo bí àwọn èso wọ̀nyẹn ṣe yàtọ̀ síra, láìgbàgbé bí èyí tí wọ́n mú tẹ́lẹ̀ ṣe rí, wọn a sì fi ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí báyìí wé èyí tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Nítorí pé wọ́n fara balẹ̀ ṣa èso wọn, èso tó dùn ló máa bá wọn délé.

Dájúdájú, èrè kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ju ìyẹn lọ dáadáa. Bó bá ti di pé irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ gba ipò pàtàkì nínú ayé wa, ìgbàgbọ́ wa yóò lágbára sí i, ìfẹ́ wa á túbọ̀ jinlẹ̀, àṣeyọrí iṣẹ́ ìsìn wa yóò pọ̀ sí i, àwọn ìpinnu tí a bá sì ṣe yóò fi ẹ̀rí hàn pé a túbọ̀ ní òye àti ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Òwe 3:15 sọ nípa irú èrè yẹn, ó ní: “A kò . . . lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba.” Ṣé o ń jẹ irú èrè bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà tó o gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ lè jẹ́ kókó pàtàkì tí yóò pinnu ìyẹn.—Kól. 1:9, 10.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30

Lo àkókò láti ṣàṣàrò

Kí ni ìkẹ́kọ̀ọ́? Ó ju ìwé kíkà oréfèé lọ. Ó wé mọ́ lílo ọpọlọ rẹ láti fara balẹ̀ gbé kókó kan yẹ̀ wò, tàbí láti rò ó jinlẹ̀. Ó kan fífọ́ ohun tó ò ń kà sí wẹ́wẹ́, fífi í wéra pẹ̀lú ohun tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, àti ṣíṣàkíyèsí àwọn ìdí tí wọ́n fi ṣe irú àlàyé tí wọ́n ṣe níbẹ̀. Nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, máa ronú jinlẹ̀ lórí gbogbo ohun tí wọ́n ṣàlàyé níbẹ̀ tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tún ronú lórí bí ìwọ fúnra rẹ ṣe lè túbọ̀ fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ sílò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Bí o ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó tún yẹ kó o ronú nípa àwọn ìgbà tó o lè láǹfààní láti fi ohun tó o kọ́ yẹn ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ó dájú pé àṣàrò ṣíṣe jẹ́ apá kan ẹ̀kọ́ kíkọ́.

Mímúra Ọkàn Rẹ Sílẹ̀ Láti Kẹ́kọ̀ọ́

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30

Láti jàǹfààní kíkún rẹ́rẹ́ látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ, múra ọkàn rẹ sílẹ̀

Bí o bá ń múra láti kẹ́kọ̀ọ́, o máa ń mú Bíbélì rẹ, àwọn ìtẹ̀jáde èyíkéyìí tó o bá ní lọ́kàn láti lò àti ohun ìkọ̀wé rẹ, bóyá o tún máa ń mú ìwé tó o máa kọ nǹkan sí pẹ̀lú. Ọkàn rẹ wá ńkọ́, ǹjẹ́ ò ń múra rẹ̀ sílẹ̀? Bíbélì sọ fún wa pé Ẹ́sírà “múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́ àti láti máa kọ́ni ní ìlànà àti ìdájọ́ òdodo ní Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 7:10) Kí ni irú ìmúra ọkàn ẹni sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ wé mọ́?

Àdúrà máa ń jẹ́ ká lè fi ọkàn tí ó tọ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun tí à ń fẹ́ ni pé kí ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún wa lè ríbi jókòó sí nínú ọkàn wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, bẹ Jèhófà pé kí ó fẹ̀mí rẹ̀ ràn ọ́ lọ́wọ́. (Lúùkù 11:13) Sọ fún un pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lè mọ ìtumọ̀ ohun tó o fẹ́ kọ́, kí o mọ bí wọ́n ṣe wé mọ́ ète rẹ̀, kí o mọ bí yóò ṣe jẹ́ kí o lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun rere àti búburú, kí o mọ bí o ṣe lè fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé rẹ, kí o sì mọ bí ẹ̀kọ́ náà yóò ṣe nípa lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú rẹ̀. (Òwe 9:10) Bí o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ, “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run” pé kó fún ọ lọ́gbọ́n. (Ják. 1:5) Fi ohun tó ò ń kọ́ yẹ ara rẹ wò láìṣẹ̀tàn, bí o ṣe ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà pé kí o lè borí àwọn èròkérò tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Máa “fi ìdúpẹ́ dá Jèhófà lóhùn” nígbà gbogbo nítorí àwọn ohun tó ń ṣí payá. (Sm. 147:7) Fífi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà báyìí máa ń mú kéèyàn sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́, nítorí ó máa ń jẹ́ kí a lè kọbi ara sí ohun tó ń tipa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wa sọ.—Sm. 145:18.

Níní irú àyà ìgbàṣe báyìí ni àwọn èèyàn Jèhófà fi yàtọ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù. Láàárín àwọn tí kò ní ìfọkànsin Ọlọ́run, ohun tó wọ́pọ̀ ni pé, wọ́n máa ń ṣiyè méjì nípa ohun tó wà lákọọ́lẹ̀, tàbí kí wọ́n máa ṣàríwísí rẹ̀. Àmọ́ àwa kò ní irú ìwà yẹn ní tiwa. Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé. (Òwe 3:5-7) Bí nǹkan kan ò bá yé wa, a ò kàn ní fi ìkùgbù gbà pé àṣìṣe ló ní láti jẹ́. Bí a ṣe ń wá ìdáhùn kiri, tí a sì ń ṣèwádìí jinlẹ̀ lórí rẹ̀, a óò dúró de Jèhófà. (Míkà 7:7) Ohun tí Ẹ́sírà ṣe làwa náà ń fẹ́ ṣe, ńṣe la fẹ́ fi ohun tí à ń kọ́ sílò ká sì tún fi kọ́ ẹlòmíràn pẹ̀lú. Bí a bá ti fi èyí sọ́kàn, ó dájú pé a ó jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.

Bí A Ṣe Ń Kẹ́kọ̀ọ́

Dípò tí wàá kàn ṣáà fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ látorí ìpínrọ̀ kìíní tí wàá sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí dé ìparí rẹ̀, kọ́kọ́ fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ tàbí orí ìwé tó o fẹ́ kà látòkèdélẹ̀ ná. Lẹ́yìn náà wá ronú lórí ìtumọ̀ àkòrí ohun tó o fẹ́ kà yìí. Òun ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ohun tó o fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà wá fara balẹ̀ kíyè sí bí àwọn àkọlé kéékèèké inú rẹ̀ ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí. Ṣàyẹ̀wò àwọn àwòrán, àwọn atọ́ka, tàbí àwọn àpótí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó bá wà nínú ibi tó o fẹ́ kà. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Lójú àyẹ̀wò tí mo kọ́kọ́ ṣe yìí, kí ni mo ń retí láti kọ́ ná? Ọ̀nà wo ni yóò gbà wúlò fún mi?’ Èyí á jẹ́ atọ́nà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30

Mọ àwọn ohun èlò ìṣèwádìí tó wà ní èdè rẹ dunjú

Wá gbé àlàyé ẹ̀kọ́ yẹn yẹ̀ wò wàyí. A máa ń tẹ àwọn ìbéèrè sí àwọn àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìwé kan. Bí o ṣe ń ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, ó dáa pé kí o sàmì sí àwọn ìdáhùn tó wà níbẹ̀. Bí kò bá tiẹ̀ sí ìbéèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀, o ṣì lè sàmì sí àwọn kókó pàtàkì tó o fẹ́ láti rántí. Bí o bá ka nǹkan kan tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀, lo àkókò díẹ̀ lórí rẹ̀ láti rí i dájú pé ó yé ọ dáadáa. Máa kíyè sí àwọn àpèjúwe tàbí àwọn àlàyé tí yóò wúlò fún ọ lóde ẹ̀rí tàbí èyí tí o lè lò nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá yàn fún ọ láti sọ lọ́jọ́ iwájú. Ronú nípa àwọn ẹni pàtó kan tí o lè sọ ohun tó ò ń kọ́ fún tí yóò sì gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. Sàmì sí àwọn kókó tó o fẹ́ lò, kí o sì ṣàtúnyẹ̀wò wọn nígbà tó o bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ.

Bí o ṣe ń gbé ẹ̀kọ́ yẹn yẹ̀ wò, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́ka sí. Ronú nípa bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe wé mọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ìpínrọ̀ yẹn ń kọ́ni.

O lè pàdé àwọn kókó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ yé ọ, tàbí èyí tó o máa fẹ́ túbọ̀ ṣèwádìí dáadáa nípa rẹ̀. Dípò fífi ìyẹn dí ara rẹ lọ́wọ́, kọ ọ́ sílẹ̀ kí o lè fún un láfiyèsí tó bá yá. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á ṣàlàyé kókó yẹn níwájú bí o ṣe ń ka ìwé náà lọ. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, o lè ṣe àfikún ìwádìí nípa rẹ̀. Àwọn nǹkan wo lo lè kọ sílẹ̀ láti gbé yẹ̀ wò lọ́nà bẹ́ẹ̀? Bóyá wọ́n fa ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan yọ tí kò fí bẹ́ẹ̀ yé ọ tó, tàbí o lè má fi bẹ́ẹ̀ rí bó ṣe kan kókó tí wọ́n ń jíròrò. Bóyá o sì rò pé òye ohun kan nínú ìwé yẹn yé ọ, àmọ́ kò yé ọ tó èyí tó o fi lè ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹlòmíràn. Dípò tí wàá kàn fi gbójú fò wọ́n, ó lè bọ́gbọ́n mu pé kí o ṣe ìwádìí nípa wọn lẹ́yìn tó o bá parí ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ lọ́wọ́.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30

Rí i dájú pé o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ibẹ̀

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà alálàyé kíkún rẹ́rẹ́ sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni, ó dá ọ̀rọ̀ tó ń sọ bọ̀ dúró díẹ̀ láàárín kan, ó ní: “Lájorí kókó rẹ̀ nìyí.” (Héb. 8:1) Ǹjẹ́ o máa ń dúró bẹ́ẹ̀ látìgbàdégbà láti rántí ohun tí ò ń bá bọ̀? Wo ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àwọn orí ìṣáájú nínú lẹ́tà rẹ̀ onímìísí yìí, ó ti kọ́kọ́ fi hàn pé Kristi tí Ọlọ́run fi jẹ Àlùfáà Àgbà títóbi ti wọ ọ̀run lọ́hùn-ún lọ. (Héb. 4:14–5:10; 6:20) Síbẹ̀, bí Pọ́ọ̀lù ṣe dá lájorí kókó yẹn yà sọ́tọ̀, tó sì wá tẹnu mọ́ ọn ní ìbẹ̀rẹ̀ Héb orí kẹjọ ẹsẹ 1, ńṣe ló fi ìyẹn múra ọkàn àwọn òǹkàwé rẹ̀ sílẹ̀, kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ lórí bí ó ṣe kan ìgbésí ayé tiwọn. Ó wá fi hàn pé Kristi ti lọ fara hàn níwájú Ọlọ́run tìkára rẹ̀ fún wọn, ó sì wá ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn kí àwọn náà lè wọnú “ibi mímọ́” yẹn ní ọ̀run. (Héb. 9:24; 10:19-22) Dídájú tí ìrètí wọn dájú yìí yóò mú kí wọ́n lè fi ìmọ̀ràn tó sọ síwájú sí i nínú lẹ́tà rẹ̀ sílò, ìmọ̀ràn nípa ìgbàgbọ́, ìfaradà, àti ìwà híhù Kristẹni. Bákan náà, bí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, fífi ọkàn sí àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ yóò jẹ́ kí a lè róye bí ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn ṣe ń tẹ̀ síwájú, yóò sì jẹ́ kí àwọn ìdí yíyèkooro tó fi yẹ kí á ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ yẹn sọ wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin.

Ṣé ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ yóò sún ọ láti fi ohun tó o kọ́ sílò? Ìbéèrè yìí ṣe kókó. Bí o bá ti kọ́ nǹkan kan, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ipa wo ló yẹ kí èyí ní lórí ìwà mi àti àwọn ohun tí mò ń lépa nínú ìgbésí ayé? Báwo ni mo ṣe lè lo ìsọfúnni yìí nígbà tí mo bá fẹ́ yanjú ìṣòro, nígbà tí mo bá ń ṣe ìpinnu, tàbí nígbà tí mo bá ń lépa nǹkan kan? Báwo ni mo ṣe lè lò ó nínú ìdílé mi, lóde ẹ̀rí, àti nínú ìjọ?’ Ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, kí o sì ronú nípa àwọn ipò gidi tó o ti lè lo ìmọ̀ rẹ.

Bí o bá ka orí kan tàbí àpilẹ̀kọ kan tán, lo àsìkò díẹ̀ láti fi ṣàtúnyẹ̀wò ráńpẹ́. Wò ó bóyá o lè rántí àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ àti àwọn àlàyé tí wọ́n ṣe nípa wọn. Ìgbésẹ̀ yìí yóò jẹ́ kí o lè rántí ìsọfúnni yẹn láti lè lò ó lọ́jọ́ iwájú.

Ohun Tí A Máa Lò fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

Bí a ṣe jẹ́ èèyàn Jèhófà, a ní ohun púpọ̀ láti kọ́. Àmọ́ ibo ni ká ti bẹ̀rẹ̀ ná? Lójoojúmọ́, ó dára pé kí á ka ẹsẹ ojoojúmọ́ àti àlàyé rẹ̀ látinú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, ẹ̀kọ́ tí a bá kọ́ láti fi múra ìpàdé wọ̀nyí sílẹ̀ yóò jẹ́ ká lè jàǹfààní púpọ̀ gan-an. Láfikún sí èyí, àwọn kan ń lo àkókò wọn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, wọ́n fi ń ka àwọn kan lára àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni tó ti wà kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn mìíràn ń yan apá kan nínú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ wọn, wọ́n á ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyẹn.

Bí ipò tó yí ọ ká kò bá jẹ́ kó o lè fara balẹ̀ ka gbogbo ìsọfúnni tí a máa gbé yẹ̀ wò láwọn ìpàdé ìjọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ńkọ́? Yẹra fún àṣìṣe pé kí o sáré ka ìwé yẹn fìrìfìrì láti kàn rí i pé o ṣáà kà á, tàbí àṣìṣe tó tiẹ̀ burú jù ìyẹn lọ, ìyẹn ni kí o tìtorí pé o kò ní lè ka gbogbo rẹ̀ tán kó o máà kúkú ka ìkankan rárá lára rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wo ìwọ̀nba tó o bá lè kà, kí o sì kà á dáadáa. Máa kà á bẹ́ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tó bá yá, gbìyànjú láti máa kárí àwọn apá ìpàdé tí o kì í kárí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

“Gbé Agbo Ilé Rẹ Ró”

Jèhófà mọ̀ pé àwọn olórí ìdílé ní láti ṣiṣẹ́ kára láti lè gbọ́ bùkátà àwọn ará ilé wọn. Òwe 24:27 sọ pé: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún ara rẹ ní pápá.” Síbẹ̀, o kò lè gbójú fo ohun tí ìdílé rẹ nílò nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ni ẹsẹ yẹn fi tẹ̀ síwájú pé: “Lẹ́yìn ìgbà náà, kí o gbé agbo ilé rẹ ró pẹ̀lú.” Báwo ni àwọn olórí ìdílé ṣe lè ṣe èyí? Òwe 24:3 sọ pé: “Nípa ìfòyemọ̀ [ni agbo ilé] yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”

Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ṣàǹfààní fún ìdílé rẹ? Ìfòyemọ̀ ni pé kéèyàn lè fi làákàyè mọ ohun tí kò hàn sójú táyé. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ká sọ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó gbéṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti orí fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìdílé rẹ fúnra rẹ. Báwo ni àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nípa tẹ̀mí? Fetí sílẹ̀ dáadáa bí ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀. Ṣé ẹ̀mí ìráhùn tàbí ìkórìíra wà níbẹ̀? Ṣé ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ló jẹ wọ́n lógún? Bí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá wà lóde ẹ̀rí, ṣé ó máa ń yá wọn lára láti sọ lójú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn? Ǹjẹ́ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà ti ìdílé ń gbádùn mọ́ wọn? Ǹjẹ́ wọ́n ń fi ọ̀nà Jèhófà ṣe ọ̀nà ìgbésí ayé wọn ní ti tòótọ́? Bí o bá fẹ̀sọ̀ ṣàkíyèsí wọn, wàá lè mọ ohun tí ìwọ olórí ìdílé ní láti ṣe láti lè gbin ànímọ́ tẹ̀mí sọ́kàn olúkúlùkù ẹni tó wà nínú ìdílé rẹ.

Wo inú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! láti rí àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun pàtó kan tó ń fẹ́ àbójútó. Kó o wá sọ ohun tí ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ fún ìdílé rẹ ṣáájú, kí àwọn náà lè ronú lórí ìsọfúnni yẹn. Jẹ́ kí àsìkò ìkẹ́kọ̀ọ́ yín tura. Ṣàlàyé bí ohun tí ẹ ń gbé yẹ̀ wò lọ́wọ́ ṣe wúlò, kí o sọ bí ó ṣe kan ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìdílé yín ní pàtó láìsí pé o ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé tàbí pé o ń dójú ti ẹnikẹ́ni. Jẹ́ kí gbogbo ìdílé pátá lóhùn sí i. Ran olúkúlùkù lọ́wọ́ láti rí bí Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe “pé” ní ti ọ̀nà tó gbà ń pèsè ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò gan-an ní ìgbésí ayé rẹ̀.—Sm. 19:7.

Èrè Rẹ̀

Àwọn èèyàn tó lákìíyèsí, ṣùgbọ́n tí wọn kò lóye ohun tẹ̀mí, lè ṣèwádìí nípa ojú ọ̀run, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé, àti nípa àwọn fúnra wọn pàápàá, síbẹ̀ kí wọ́n má mọ ìtumọ̀ ohun tí wọ́n ń rí ní ti gidi. Láìdàbíi tiwọn, àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé ń tipasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run rí òye iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ látinú àwọn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n ń rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àti bí Ọlọ́run ṣe ń ṣí ète tí yóò fi bù kún àwọn onígbọràn nínú aráyé, payá.—Máàkù 13:4-29; Róòmù 1:20; Ìṣí. 12:12.

Bí ìyẹn sì ṣe jẹ́ ohun ìyanu tó yìí, kò yẹ kí ó mú wa gbéra ga rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Diu. 17:18-20) Ó tún ń gbà wá lọ́wọ́ “agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀,” nítorí pé bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkàn wa, wíwù tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń wuni kò ní lè borí ìpinnu tí a ti ṣe láti dènà ẹ̀ṣẹ̀. (Héb. 2:1; 3:13; Kól. 3:5-10) Nípa bẹ́ẹ̀, a óò lè “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí [a] ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.” (Kól. 1:10) Nítorí kí a lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an la kúkú ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló sì jẹ́ èrè tó ga jù lọ.

LÁTI LÈ JÀǸFÀÀNÍ TÓ GA JÙ LỌ

  • Múra ọkàn rẹ sílẹ̀

  • Kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ibi tó o fẹ́ kà

  • Fa àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ yọ

  • Ronú nípa bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ibẹ̀ ṣe fi ìdí tí wọ́n fi ṣe irú àlàyé tí wọ́n ṣe hàn

  • Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lájorí kókó rẹ̀

  • Ṣàṣàrò nípa bí ó ṣe yẹ kí ohun tó ò ń kọ́ nípa lórí ìgbésí ayé ìwọ fúnra rẹ

  • Wá ọ̀nà láti lo ohun tó ò ń kọ́ láti fi ran ẹlòmíràn lọ́wọ́

BÍ A ṢE KỌ́KỌ́ Ń ṢÀYẸ̀WÒ ÌWÉ KÍ A TÓ KÀ Á

  • Ronú lórí ohun tí àkòrí rẹ̀ túmọ̀ sí

  • Ronú nípa bí àkọlé kéékèèké kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ àkòrí rẹ̀

  • Ṣàyẹ̀wò gbogbo àwọn àwòrán, àwọn atọ́ka, tàbí àpótí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ibẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́