ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 orí 6 ojú ìwé 58-66
  • Kí Nìdí Tára Mi Fi Ń Yí Pa Dà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tára Mi Fi Ń Yí Pa Dà?
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó Ṣe Ń Ṣàwọn Obìnrin
  • Bó Ṣe Ń Ṣàwọn Ọkùnrin
  • Bó O Ṣe Lè Máa Fara Da Bí Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Rẹ
  • Ìyípadà Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìbàlágà?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • ‘Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Mi Yìí?’
    Jí!—2004
  • Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́
    Jí!—2016
  • Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 orí 6 ojú ìwé 58-66

ORÍ 6

Kí Nìdí Tára Mi Fi Ń Yí Pa Dà?

“Mo tètè ga ju ọjọ́ orí mi lọ. Mi ò gbádùn ẹ̀ rárá. Òótọ́ ni pé ohun tó yẹ kó mórí èèyàn wú nìyẹn, àmọ́ iṣan ẹsẹ̀ á tó máa fa èmi náà. Ohun tí mi ò sì fẹ́ gan-an nìyẹn!”—Paul.

“O mọ̀ pé ara ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí yí pa dà, o ò sì fẹ́ káwọn èèyàn fojú sí ẹ lára. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ẹnì kan tó kàn fẹ́ pọ́n ẹ lé sọ fún ẹ pé ìbàdí ẹ ti gún régé, pé o ti dàgbà tó láti bímọ. Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ yẹn lọ́wọ́ ló ń ṣe ẹ́ bíi kí ilẹ̀ lanu kó sì gbé ẹ mì!”—Chanelle.

ṢÉWỌ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ ti jọ kó lọ sádùúgbò míì rí? Báwo ló ṣe rí lára ẹ? Kò rọrùn àbí? Ó dájú pé kò rọrùn torí gbogbo nǹkan tó o ti mọ̀, bí ilé tẹ́ ẹ̀ ń gbé, iléèwé tó ò ń lọ àtàwọn ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ ti jọ mọwọ́ ara yín, lo máa fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Bẹ́ ẹ bá tún débi tẹ́ ẹ̀ ń kó lọ, ó tún lè má rọrùn láti mojú àdúgbò tuntun.

Nígbà tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, tíwọ náà rí i pé o ti ń dọkùnrin tàbí dobìnrin, ọ̀kan lára àwọn ìyípadà tó ga jù tó máa ń ṣẹlẹ̀ séèyàn lò ń nírìírí rẹ̀ yẹn. Lọ́nà kan, ńṣe ló dà bí ìgbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé “àdúgbò” tuntun kan. Ó gbádùn mọ́ ẹ, àbí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! Àmọ́ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára èèyàn kì í sábà jẹ́ kí nǹkan rọrùn nígbà téèyàn bá ń bàlágà torí lọ́pọ̀ ìgbà ìrònú èèyàn kì í dúró sójú kan, ó sì máa ń jẹ́ kó ṣòro láti mọ èwo ni ṣíṣe. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an láwọn àkókò tó gbádùn mọ́ni àmọ́ tí nǹkan ń tojú súni yìí?

Bó Ṣe Ń Ṣàwọn Obìnrin

Ìyípadà tó máa ń wáyé nígbà ìbàlágà ò ṣeé fi bò. Púpọ̀ lára àwọn ìyípadà tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ làwọn èèyàn máa rí. Bí àpẹẹrẹ, àkókò yẹn làwọn èròjà kan nínú ara ẹ máa mú kí irun bẹ̀rẹ̀ sí í hù sí ẹ lójú ara. Yàtọ̀ síyẹn, wàá rí i pé àsìkò yìí ni ọyàn ẹ á bẹ̀rẹ̀ sí yọ, ìbàdí, ìdí àti itan rẹ á sì bẹ̀rẹ̀ sí tóbi sí i. Díẹ̀díẹ̀ lára ẹ máa bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní tọmọdé tá á sì bẹ̀rẹ̀ sí í gún régé bíi tọlọ́mọge. Èyí ò tó nǹkan tá á mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí ronú, torí bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀rí ni gbogbo ìyípadà yìí jẹ́, pé ara ẹ ti ń múra sílẹ̀ de ìgbà tí ìwọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí bímọ tí wàá sì di ìyá àbúrò!

Kò ní pẹ́ rárá lẹ́yìn ìgbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí bàlágà tí wàá bẹ̀rẹ̀ sí í rí nǹkan oṣù ẹ. Bó ò bá mọ ohunkóhun nípa ìyípadà pàtàkì yìí tẹ́lẹ̀, ó ṣeé ṣe kó dẹ́rù bà ẹ́. Samantha rántí ìgbà tó kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù ẹ̀, ó ní: “Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù mi, mi ò retí ẹ̀ rárá. Ó rí mi lára. Gbogbo ìgbà ni mo lọ ń wẹ̀, bí mo sì ṣe wà nínú balùwẹ̀ ni mò ń ronú pé, ‘Ṣé èmi náà ni mo wá di ọ̀bùn báyìí?’ Tí mo bá rántí pé bí màá ṣe máa rí i lóṣooṣù rèé lẹ̀rù máa ń bà mí!”

Àmọ́, má gbàgbé pé nǹkan oṣù yìí ló fi hàn pé ara ẹ dá pé láti bímọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún ṣì máa gorí ọdún kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí bímọ, ìwọ náà ti dobìnrin wàyí. Síbẹ̀, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ nígbà tó o bá ń ṣe nǹkan oṣù lè máa yí pa dà. Kelli sọ pé: “Ohun tó burú jù tí mo ní láti fara dà ni bí ìmọ̀lára mi ṣe máa ń tètè yí pa dà. Inú mi lè dùn gan-an lọ́sàn-án tí màá máa rẹ́rìn-ín kèékèé, àmọ́ tó bá fi máa dalẹ́ ó lè jẹ́ pé ńṣe ni màá máa wa ẹkún mu. Inú sì máa ń bí mi gan-an tí mo bá rántí pé kò sóhun tí mo lè ṣe sí i.”

Bó bá jẹ́ pé bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ìwọ náà nìyẹn, fara balẹ̀. Ó máa tó mọ́ ẹ lára. Ọmọ ogún [20] ọdún kan tó ń jẹ́ Annette sọ pé: “Mo rántí ìgbà tí mo gba kámú, tí mo gbà pé nǹkan oṣù tí mò ń ṣe ló sọ mí dobìnrin tí mo sì wá gbà pé ẹ̀bùn tí Jèhófà fún mi kí n lè bímọ ni. Ó pẹ́ díẹ̀ kémi náà tó gbà pé bó ṣe yẹ kí nǹkan rí nìyẹn, ìyẹn sì máa ń le gan-an fáwọn ọmọbìnrin míì. Àmọ́ bó pẹ́ bó yá, ìwọ náà á kọ́ láti gbà bẹ́ẹ̀.”

Ṣáwọn ìyípadà tá a ṣàlàyé lókè yìí ti ń dé bá ara tìẹ náà? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kọ àwọn ìbéèrè tó o bá ní nípa àwọn ìyípadà tó o ti rí sórí ìlà yìí.

․․․․․

Bó Ṣe Ń Ṣàwọn Ọkùnrin

Bó o bá jẹ́ ọkùnrin, ara ẹ á máa yàtọ̀ tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà. Bí àpẹẹrẹ, ara ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí sun òróró jáde, ìyẹn sì lè jẹ́ kí rorẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí yọ sí ẹ lójú.a Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Matt sọ pé: “Bí rorẹ́ ṣe ń yọ sí mi lójú máa ń bí mi nínú ṣáá ni, mi ò gba tiẹ̀ rárá. Bí ìgbà téèyàn ń jagun lèèyàn ṣe máa kó tì í kó tó wábi gbà. O ò lè sọ pé ìgbà báyìí ló máa lọ, bóyá ó máa dápàá sí ẹ lójú tàbí bóyá àwọn èèyàn a máa fojú ọmọdé wò ẹ́.”

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìyípadà tó máa wáyé ló máa burú, torí bó bá yá, wàá rí i pé wàá bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, wàá lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, igẹ̀ rẹ á sì bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀. Lásìkò yìí kan náà ni irun á bẹ̀rẹ̀ sí hù ní ẹsẹ̀, àyà, ojú àti abíyá rẹ. Mọ̀ dájú pé bí irun ara ẹ ṣe pọ̀ tó kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú bó o ṣe jẹ́ ọkùnrin tó; àjogúnbá lásán ni.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kì í ṣe bákan náà làwọn ẹ̀yà ara rẹ á ṣe máa dàgbà, àwọn págunpàgun díẹ̀ díẹ̀ ò ní ṣàì wà. Dwayne rántí bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní: “Òdì kejì ohun tí mo fẹ́ ló ń ṣẹlẹ̀ sí mi. Ńṣe ló ń dà bí ìgbà tí mò ń sọ fún ẹsẹ̀ mi pé kó rìn, àmọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá dá mi lóhùn lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan gbáko!”

Nígbà tó o bá ti tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ohùn ẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Fúngbà díẹ̀, o lè ṣàkíyèsí pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó o bá ń sọ̀rọ̀ ohùn ẹ kàn lè ṣàdéédéé dún sókè tàbí kó fẹ́ há, ìyẹn sì lè bù ẹ́ kù lójú àwọn tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀. Bó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, máà jẹ́ kó dá ẹ lágara. Bó pẹ́ bó yá, ohùn ẹ máa já gaara. Ní báyìí ná, táwọn èèyàn bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ìwọ náà máa bá wọn rẹ́rìn-ín, ìyẹn ò sì ní í jẹ́ kó máa dùn ẹ́.

Bí ẹ̀yà ara rẹ tó wà fún ìbímọ bá ṣe ń dàgbà ni nǹkan ọmọkùnrin ẹ á máa tóbi sí i tí irun á sì máa hù yí i ká. Nínú ẹ̀yà ara tó wà fún ìbímọ yìí ni àtọ̀ ti ń wá. Ọ̀kẹ́ àìmọye èròjà tín-ín-tìn-ìn-tín ló wà nínú àtọ̀ tó máa ń jáde nígbà ìbálòpọ̀. Ọ̀kan lára àwọn èròjà tín-ín-tìn-ìn-tín wọ̀nyí lágbára láti sọ ẹyin tó máa ń wà nínú obìnrin dọmọ.

Ara ẹ á máa mú àtọ̀ jáde, á sì máa lo díẹ̀ lára àtọ̀ náà, àmọ́ látìgbàdégbà àwọn kan á máa jáde látinú nǹkan ọmọkùnrin ẹ nígbà tó o bá sùn. Kò sóhun tó burú nínú ẹ̀. Bíbélì gan-an sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Léfítíkù 15:16, 17) Bí àtọ̀ bá ń jáde lára ẹ, ńṣe ló ń fi hàn pé o dá pé, ó sì ń jẹ́ kó o mọ̀ pé ìwọ náà ti dọkùnrin.

Ṣéwọ náà ti ń rí àwọn ìyípadà tá a ṣàlàyé lókè yìí? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kọ àwọn ìbéèrè tó o bá ní nípa àwọn ìyípadà tó o ti rí sórí ìlà yìí.✎

․․․․․

Bó O Ṣe Lè Máa Fara Da Bí Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Rẹ

Bí ètò ìbímọ tí Ọlọ́run dá mọ́ wa ṣe ń dàgbà ni ọkàn ọkùnrin á máa fà sí obìnrin ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọkàn obìnrin náà á sì máa fà sí ọkùnrin ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Matt sọ pé: “Ìgbà tí mo bàlágà ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé àwọn ọmọge tó rẹwà ló yí mi ká. Ìyẹn máa ń mú kí nǹkan tojú sú mi torí mo mọ̀ pé kò sí bí wọ́n ṣe lè pọ̀ tó, ó dìgbà tí mo bá dàgbà díẹ̀ sí i kí n tó lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀.” Orí 29 nínú ìwé yìí máa ṣàlàyé kíkún lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára lásìkò yìí. Ohun tó ṣe pàtàkì báyìí ni pé kó o mọ bó o ṣe lè kóra ẹ níjàánu tó bá dọ̀ràn ìbálòpọ̀. (Kólósè 3:5) Bó ti wù kó dà bíi pé èyí ṣòro tó, o lè pinnu láti kóra ẹ níjàánu!

Àwọn nǹkan míì tún wà tó o ní láti fara dà nígbà ìbàlágà. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò wúlò fún nǹkan kan. Ó sì lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ò ń dá nìkan wà, kó o sì máa sorí kọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí nǹkan bá rí báyìí, ó máa dáa kó o bá àwọn òbí rẹ tàbí àgbàlagbà kan tó ṣeé finú tán sọ̀rọ̀. Kọ orúkọ àgbàlagbà kan tí wàá fẹ́ sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún sórí ìlà yìí:

․․․․․

Ìyípadà Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ

Ìyípadà tó ṣe pàtàkì jù kì í ṣe bó o ṣe ga tó, kì í ṣe bára ẹ ṣe rí, kì í sì í ṣe bójú ẹ ṣe rí, àmọ́ ó ní í ṣe pẹ̀lú bó o ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ àti pàtàkì ibẹ̀, irú ẹni tó o jẹ́ nípa tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Ẹ̀kọ́ tó wà nínú ẹsẹ yìí ṣe kedere. Ohun tó ń sọ irú ẹni tá a jẹ́ ju ká kàn fojú jọ àgbàlagbà. O gbọ́dọ̀ kọ́ bí wàá ṣe máa hùwà, bí wàá ṣe máa sọ̀rọ̀ àti bí wàá ṣe máa ronú bí àgbàlagbà. Má ṣe jẹ́ káwọn ìyípadà tó ń bá ara ẹ gbà ẹ́ lọ́kàn débi tó ò fi ní ráyè gbọ́ ti irú ẹni tó o jẹ́ nínú lọ́hùn-ún!

Má sì gbàgbé pé Ọlọ́run máa ń wo “ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bíbélì sọ pé Sọ́ọ̀lù Ọba ga ó sì rẹwà lọ́kùnrin, àmọ́ pàbó lọ̀rọ̀ ẹ̀ já sí gẹ́gẹ́ bí ọba, kódà kò hùwà àgbà. (1 Sámúẹ́lì 9:2) Sákéù ní tiẹ̀ ò fi nǹkan kan jọ Sọ́ọ̀lù torí “ó kéré ní ìrísí,” síbẹ̀ irú ẹni tó jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ràn án lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà, ó sì wá di ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Lúùkù 19:2-10) Ó ṣe kedere nígbà náà pé ohun tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló ṣe pàtàkì jù kì í ṣe ìrísí wa.

Ohun kan dájú: Ewu wà nínú mímú kí ìyípadà tó ń bá ara yára tàbí kó falẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Torí náà, kàkà kó o máa fapá jánú nítorí ìyípadà tó ń bá ara ẹ, yá a gbà á tẹ̀rín tọ̀yàyà, kó o sì jẹ́ kínú ẹ máa dùn. Bíbàlágà kì í ṣàrùn, ìwọ sì kọ́ ló máa kọ́kọ́ ṣe. Sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá bọ́ ńbẹ̀. Nígbà tí gbogbo àìbáradé ìgbà ìbàlágà bá ti kọjá, ìwọ náà á wá rí i pé àgbà ti dé!

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Bó ò bá fẹ́ràn bó o ṣe rí nígbà tó o bá ń wojú ara ẹ nínú dígí ńkọ́? Kí lo lè ṣe tíyẹn ò fi ní di nǹkan bàbàrà lójú ẹ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọkùnrin nìkan kọ́ ni rorẹ́ máa ń yọ sí lójú, ó máa ń ṣàwọn ọmọbìnrin náà. Àmọ́ ìmọ́tótó ara lè jẹ́ kó mọ níwọ̀nba.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”—Sáàmù 139:14.

ÌMỌ̀RÀN

Bó o ti ń bàlágà, má máa wọṣọ tó ń ṣí ara sílẹ̀ tàbí tó fún pinpin. Aṣọ tó ń fi hàn pó o ‘mẹ̀tọ́mọ̀wà àti pé èrò inú rẹ yè kooro’ ni kó o máa wọ̀.—1 Tímótì 2:9.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ìgbà ìbàlágà máa ń yàtọ̀ síra. Tàwọn kan lè bẹ̀rẹ̀ lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, ó sì lè jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni tàwọn míì á ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Kò séyìí tí ò dáa nínú méjèèjì.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí mo ti ń bàlágà, ìwà tí màá fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí jù lọ ni ․․․․․

Ohun tí mo máa ṣe rèé kí n lè mójú tó bí mo ṣe ń dàgbà nípa tẹ̀mí ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí táwọn ìyípadà tó máa ń bá ara àtàwọn ìyàtọ̀ tó máa ń bá bí nǹkan ṣe máa ń rí lára nígbà téèyàn bá ń bàlágà fi máa ń le koko?

● Èwo lára àwọn ìyípadà yìí ló nira jù fún ẹ láti fara dà?

● Kí nìdí tí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run fi lè dín kù nígbà ìbàlágà, àmọ́ kí lo lè ṣe láti má ṣe jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 61]

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń tojú súni nígbà ìbàlágà, o ò lè sọ pé ìyípadà báyìí ló kàn. Àmọ́ bó o ṣe ń dàgbà, wàá kọ́ láti gbà pé ohun tó yẹ kó ṣẹlẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kódà wàá nífẹ̀ẹ́ sáwọn ìyípadà wọ̀nyẹn.’’—Annette

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 63, 64]

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Dádì Tàbí Mọ́mì Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀?

“Bí mo bá ní ìbéèrè èyíkéyìí nípa ìbálòpọ̀, mi ò tiẹ̀ lè bi Dádì tàbí Mọ́mì láéláé.”—Beth.

“Kí ni màá ní mo jẹ yó tí màá fi dá irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn sílẹ̀?”—Dennis.

Bó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Beth àti Dennis ló rí lára ìwọ náà, ewu ń bẹ. O fẹ́ mọ̀ nípa ìbálòpọ̀, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà o kì í fẹ́ bi àwọn tó ní ìdáhùn sáwọn ìbéèrè ẹ, ìyẹn àwọn òbí ẹ! Ọ̀pọ̀ nǹkan ni kì í jẹ́ kó yá ẹ lára láti bi wọ́n:

Kí ni wọ́n á máa rò nípa mi?

“Mi ò ní fẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí mi, torí nǹkan tí mo bi wọ́n.”—Jessica.

“Wọn ò fẹ́ mọ̀ péèyàn ti ń dàgbà, ọjọ́ tó o bá sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí ẹ.”—Beth.

Báwo ló ṣe máa rí lára wọn?

“Ẹ̀rù máa ń bà mí pé àwọn òbí mi lè yára parí èrò sí pé mo ti ń ṣèṣekúṣe, kí wọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọyé tí ò ní tán bọ̀rọ̀ lé mi lórí.”—Gloria.

“Àwọn òbí mi ò mọ béèyàn ṣe ń pa ọ̀rọ̀ mọ́ra, ẹ̀rù sì lè máa bà mí tí mo bá rí i lójú wọn pé wọ́n ń rò pé mo ti dójú ti àwọn. Kódà mi ò tíì ní parí ọ̀rọ̀ mi, tí Dádì á ti máa múra àsọyé tí wọ́n fẹ́ sọ fún mi sílẹ̀.”—Pam.

Ṣé wọn ò ní ṣì mí lóye báyìí?

“Wọ́n lè gbaná jẹ, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi mí láwọn ìbéèrè bíi, ‘Àbí wọ́n ti tì ẹ́ ṣe é?’ tàbí ‘Ṣáwọn ọ̀rẹ́ ẹ fẹ́ fipá mú ẹ ṣe é ni?’ Àmọ́, ìwọ kàn fẹ́ mọ̀ nípa ẹ̀ ní tìẹ ni.”—Lisa.

“Kò sígbà tí mo sọ̀rọ̀ nípa bọ̀bọ́ kan tí mi ò kí ń rí i lójú Dádì pé ọ̀rọ̀ mi ń kọ wọ́n lóminú. Tí wọ́n bá sì máa dá sí i báyìí, ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ni wọ́n máa gbẹ́nu lé. Ó máa ń ṣe mí bíi kí n sọ pé, ‘Dádì, mo kàn sọ pé bọ̀bọ́ yẹn dáa ni, mi ò sọ nǹkan kan nípa ìgbéyàwó tàbí ìbálòpọ̀!’”—Stacey.

Ó lè tù ẹ́ nínú láti mọ̀ pé bó ṣe ń tì ẹ́ lójú láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ló ṣe ń ti àwọn náà lára láti bá ẹ sọ ọ́! Bóyá ìyẹn á tiẹ̀ jẹ́ kó o rí ìdí tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣèwádìí lẹ́nu ọgọ́rùn-ún [100] òbí láti mọ̀ bóyá wọ́n máa ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, márùndínláàádọ́rin [65] ló sọ pé àwọn máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ mọ́kànlélógójì [41] péré lára wọn làwọn ọmọ wọn gbà pé irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ wáyé rí.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ó lè máà yá àwọn òbí ẹ lára láti bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn òbí tiwọn pàápàá ò bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ rí! Ohunkóhun tí ì báà fà á tí wọ́n fi ń tijú láti sọ ọ́, ìwọ ṣáà má fagídí mú wọn. Bóyá tó o bá nígboyà láti dá a sílẹ̀ lọ́jọ́ kan, á lè ṣe ẹ̀yin méjèèjì láǹfààní. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀

Ohun táwọn òbí ẹ mọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ò kéré rárá, ìmọ̀ràn tí wọ́n sì lè fún ẹ nípa rẹ̀ ò lóǹkà, ìwọ ṣáà ti mọ bó o ṣe lè dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. O lè gbìyànjú ẹ báyìí ná:

1 Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú jíjẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé kò rọrùn fún ẹ láti wá bá wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yìí. “Ẹ̀rù ń bà mí láti dá irú ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀ torí ẹ lè máa rò pé . . . ”

2 Lẹ́yìn náà, sọ ohun tó ń kọ ẹ́ lóminú fún Dádì tàbí Mọ́mì. “Mo ní ìbéèrè kan, ó sì máa wù mí kó jẹ́ ẹ̀yin lẹ máa dáhùn ẹ̀ ju kí n lọ bi ẹlòmíì lọ.”

3 La ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀. “Ìbéèrè mi ni pé . . . ”

4 Rí i dájú pé ibi tẹ́ ẹ parí ọ̀rọ̀ náà sí á tún mú kírú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ lè wáyé nígbà míì. “Ṣé mo tún lè wá bá a yín tí irú ọ̀rọ̀ báyìí bá tún ń gbé mi nínú?”

Bó o bá tiẹ̀ mọ̀ pé ìdáhùn wọn máa tẹ́ ẹ lọ́rùn, jẹ́ kó tẹnu wọn wá, ìyẹn á ṣí ọ̀nà sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, á sì jẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀ kó sì yá ẹ lára láti lọ bá wọn nígbà míì. Gbìyànjú ẹ̀ báyìí! O sì lè wá gbà pẹ̀lú Trina tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] báyìí. Ó ní: “Mo rántí pé nígbà témi àti Mọ́mì kọ́kọ́ máa sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé a ò bá ti má sọ̀rọ̀ yìí rárá. Àmọ́ ní báyìí, inú mi dùn pé Mọ́mì ò fi dúdú pe funfun fún mi, ńṣe ni wọ́n ṣàlàyé ẹ̀ bó ṣe jẹ́ gan-an. Ọ̀rọ̀ yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 59]

Bí ìgbà téèyàn ń kó kúrò nílé ni kíkúrò lọ́mọdé máa ń rí, àmọ́ bó pẹ́ bó yá, ó máa bá ẹ lára mu

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́