Orin 8
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà, Baba wa ní ọ̀run,
Alẹ́ mímọ́ lèyí fún wa!
Ògo, agbára, ìfẹ́, ẹ̀tọ́, ọgbọ́n rẹ
Hàn lọ́jọ́ kẹrìnlá Nísàn.
Wọ́n jẹ àgùntàn Ìrékọjá,
Ísírẹ́lì dòmìnira.
Jésù ta ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ sílẹ̀ láti mú
Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lẹ́yìn náà.
2. A pé jọ síwájú rẹ Baba,
Bí àgùntàn pápá tìrẹ.
Láti yìn ọ́ fún ìfẹ́ tó mú Kristi wá,
Láti bọlá fórúkọ rẹ.
Kí Ìrántí Ikú Kristi yìí
Má ṣe kúrò lọ́kàn wa láé.
Ká lè máa rìn lọ́nà tí Jésù fi hàn wá,
Ká lè rí ìyè àìnípẹ̀kun.
(Tún wo Lúùkù 22:14-20; 1 Kọ́r. 11:23-26.)