Orin 83
Ó Yẹ Ká Ní Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Lọ́kàn, lérò, níṣe la nífẹ̀ẹ́ Jáà;
Torí àìpé, ká máa kóra níjàánu.
Ìṣòro lèrò ti ara ńfà.
Tẹ̀mí ńfa àlàáfíà òun ìyè.
2. Sátánì ńdẹ wá wò lójoojúmọ́,
Òfin ẹ̀ṣẹ̀ inú wa ńmú wa ṣìnà.
Agbára òótọ́ ju tẹ̀ṣẹ̀ lọ.
Pẹ̀lú ìrànwọ́ Jáà a ńborí.
3. Ọ̀rọ̀ òun ìṣe wa kan oókọ Jáà,
Torí náà, ká ríi pé a ńhùwà mímọ́.
Nínú gbogbo nǹkan, ká máa ríi pé:
A ńkó ara wa níjàánu gan-an.
(Tún wo 1 Kọ́r. 9:25; Gál. 5:23; 2 Pét. 1:6.)