Orin 89
Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọ̀dọ́kùnrin ọ̀dọ́bìnrin,
fọkàn fún mi.
Kí ọ̀tá tó ń ṣáátá mi
lè wá ríi pé,
Ìgbà ọ̀dọ́ lo fi sìn mí
tọkàntọkàn;
O jẹ́ kí aráyé mọ̀ pé
tèmi ni ọ́.
(ÈGBÈ)
Ọmọ mi lọ́kùnrin lóbìnrin,
Jẹ́ ọlọ́gbọ́n mọ́kàn mi yọ̀.
Kí o sìn mí látọkàn rẹ wá,
Fìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo.
2. Máa yọ̀, fi gbogbo okun
inú rẹ sìn mí,
Bóo kọsẹ̀ tóo ṣubú,
èmi yóò gbé ọ ǹde.
Ẹní wù kó já ọ
kulẹ̀ tàbí ṣàìtọ́,
Mọ́kàn le, mọ̀ pé
ọmọlójú mi ni ọ́.
(ÈGBÈ)
Ọmọ mi lọ́kùnrin lóbìnrin,
Jẹ́ ọlọ́gbọ́n mọ́kàn mi yọ̀.
Kí o sìn mí látọkàn rẹ wá,
Fìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo.
(Tún wo Diu. 6:5; Oníw. 11:9; Aísá. 41:13.)