ORIN 47
Máa Gbàdúrà sí Jèhófà Lójoojúmọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Gbàdúrà sí Jáà, ó ń gbọ́ àdúrà.
Àǹfààní ló jẹ́ pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ.
O lè fọkàn tán an, ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni.
Gbàdúrà lójoojúmọ́.
2. Gbàdúrà sí Jáà, dúpẹ́ ẹ̀mí rẹ.
Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, tọrọ ‘dáríjì;
Kí ìwọ náà sì máa dárí jini.
Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ pérùpẹ̀ ni wá.
Gbàdúrà lójoojúmọ́.
3. Gbàdúrà sí Jáà tíṣòro bá dé.
Bàbá wa ló jẹ́, kò jìnnà sí wa.
Wá ìrànlọ́wọ́ àti ààbò rẹ̀.
Má bẹ̀rù rárá, o lè gbẹ́kẹ̀ lé e.
Gbàdúrà lójoojúmọ́.
(Tún wo Sm. 65:5; Mát. 6:9-13; 26:41; Lúùkù 18:1.)