ORIN 49
Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
1. A jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣèfẹ́ Jáà.
Àwa yóò máa hùwà ọgbọ́n.
Tá a bá ńṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé
A fẹ́ máa mú inú rẹ̀ dùn.
2. Ẹrú olóòótọ́, olóye
Ń kéde ògo rẹ fáráyé.
Wọ́n ń bọ́ wa lásìkò tó yẹ,
Kí a lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ.
3. Fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ
Ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.
Ká ṣohun tó máa gbé ọ ga,
Ká sì máa mú inú rẹ dùn.
(Tún wo Mát. 24:45-47; Lúùkù 11:13; 22:42.)