ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 11/8 ojú ìwé 21-25
  • Àtikékeré Ni Wọ́n Ti Kọ́ Mi Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtikékeré Ni Wọ́n Ti Kọ́ Mi Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìjọba Kọ́múníìsì Bẹ̀rẹ̀ sí Fín Wa Lápe
  • Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú
  • Wọ́n Fún Wa Lómìnira Díẹ̀ Sí I
  • A Tẹ̀ Síwájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
  • Àwọn Ìṣòro Mìíràn Tún Yọjú
  • Wọ́n Dá Mi Sílẹ̀ Mo sì Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan
  • Títọ́ Ọmọ àti Ṣíṣiṣẹ́ Sin Àwọn Ẹlòmíràn
  • Ìkésíni Tí Mi Ò Rò Tì
  • Bí Ìdílé Wa Ṣe Rí Lónìí
  • Mo Borí Ìṣòro Tíì Bá Dí Mi Lọ́wọ́ Láti Sin Ọlọ́run
    Jí!—2005
  • Jíjẹ́ Adúróṣinṣin—Lolórí Àníyàn Mi
    Jí!—2000
  • Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú Lọ sí Siberia!
    Jí!—1999
  • Ó Lé Lógójì Ọdún Táa Fi Wà Lábẹ́ Ìfòfindè Ìjọba Alájọgbé-bùkátà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 11/8 ojú ìwé 21-25

Àtikékeré Ni Wọ́n Ti Kọ́ Mi Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

GẸ́GẸ́ BÍ ANATOLY MELNIK ṢE SỌ Ọ́

Ọ̀pọ̀ ló máa ń pè mí ní bàbá àgbà. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti gbọ́ tí wọ́n pè mí báyìí, ńṣe ló máa ń wọ̀ mí ní akínyẹmí ara nítorí pé ó máa ń mú mi rántí bàbá ìyá tèmi gan-an, ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ gidigidi, ó gbìyànjú púpọ̀ fún mi o. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn rẹ̀ fún yín kí n sì sọ bóun àti màmá màmá mi ṣe nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé àwa tá a wà nínú ìdílé wọn àtàwọn mìíràn.

ABÚLÉ Hlina tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pè ní Moldova báyìí ni wọ́n bí mi sí.a Láàárín ọdún 1920 sí 1929, àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò tí wọ́n ń pè ní arìnrìn-àjò ìsìn nígbà náà wá láti orílẹ̀-èdè Romania sí àgbègbè olókè rírẹwà níbi tí à ń gbé. Àwọn òbí màmá mi tẹ́tí sí ìwàásù ìhìn rere táwọn fúnra wọn rí i pé inú Bíbélì ni wọ́n ti fà á yọ. Ní ọdún 1927, wọ́n di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn ni orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939, ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ti wà ní abúlé wa kékeré.

Nígbà tí wọ́n fi máa bí mi lọ́dún 1936, gbogbo ìbátan mi ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà àyàfi bàbá mi tó ṣì ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń jà lọ́wọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí ìtumọ̀ ìgbésí ayé, nígbà tó sì yá, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà Ọlọ́run, ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi nínú omi. Bàbá mi àgbà ṣe gudugudu méje láti rí i pé ìdílé wa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ó fẹ́ràn Bíbélì, àìmọye ẹsẹ Bíbélì ló sì mọ̀ sórí. Kò sí ìjíròrò náà tí kò lè sọ di ti Bíbélì.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń jókòó sórí ẹsẹ̀ bàbá àgbà tí màá máa gbọ́ bó ṣe ń sọ àwọn ìtàn Bíbélì. Ó gbin ìfẹ́ Ọlọ́run sí mi nínú. Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìyẹn o! Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, mo bá bàbá àgbà lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù fún ìgbà àkọ́kọ́. Láti inú Bíbélì, a fi ẹni tó ń jẹ́ Jèhófà han àwọn tá a jọ wà ní abúlé, a sì fi bí wọ́n ṣe lè sún mọ́ ọn hàn wọ́n.

Àwọn Ìjọba Kọ́múníìsì Bẹ̀rẹ̀ sí Fín Wa Lápe

Lọ́dún 1947, àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a wà ní Moldova nítorí pé àwọn Kọ́múníìsì ò nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa táwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì sì ń rúná abẹ́lẹ̀. Àwọn aṣojú fáwọn ọlọ́pàá inú tí wọ́n wá mọ̀ sí KGB àti àwọn ọlọ́pàá tó wà lábúlé máa ń wá sílé wa, wọ́n á sì bi wá léèrè nípa àwọn tó ń léwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù wa, ibi tí àwọn ìwé wa ti ń wá àti ibi tá a ti ń pàdé fún ìjọsìn. Wọ́n sọ pé àwọn máa dá iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró. Wọ́n ní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “ni ò jẹ́ kí ìjọba Kọ́múníìsì rọ́wọ́ mú lórílẹ̀-èdè náà.”

Lákòókò yìí, bàbá mi, ẹni tó kàwé dáadáa, ti wá fẹ́ràn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì gan-an. Àtòun àti bàbá àgbà mọ bí wọ́n ṣe ń dá àwọn tó bá fẹ́ lù wọ́n lẹ́nu gbọ́rọ̀ lóhùn kí wọ́n má bàa tú àṣírí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa. Onígboyà àti onífẹ̀ẹ́ ni wọ́n, wọ́n sì máa ń jà fún ire àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Bíi tiwọn ni màmá mi náà máa ń ṣe, ara ẹ̀ balẹ̀ kì í sì í gbọ̀n jìnnìjìnnì.

Lọ́dún 1948, wọ́n wá mú bàbá mi lọ. Títí di báyìí, wọn ò sọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ló ṣẹ̀ fún wa. Wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n ọdún méje nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí ò sí béèyàn ṣe lè jáde níbẹ̀, tó bá sì parí ọdún ẹ̀ níbẹ̀, á tún lọ lo ọdún méjì sí i nígbèkùn. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rán an lọ sí ẹkùn Magadan lápá ibi tó jìnnà jù lọ níhà ìlà oòrùn àríwá Rọ́ṣíà, níbi tó fi bí ẹgbẹ̀rún méje kìlómítà jìn sí ibùgbé wa. Ọdún mẹ́sàn-án gbáko la ò fi fojú kan ara wa. Ó ṣòro kéèyàn wà láìní bàbá o, ṣùgbọ́n bàbá àgbà ò jẹ́ kí n màlá tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Wọ́n Lé Wa Kúrò Nílùú

Lóru ọjọ́ kan, ìyẹn ní June 6, 1949 àwọn sójà méjì àti òṣìṣẹ́ ìjọba kan wá ká wa mọ́lé. Wọ́n ní wákàtí méjì péré làwọn fún wa ká fi jáde nílé ká sì kó sínú ọkọ̀ àwọn. Wọn ò ṣàlàyé jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n kàn ṣá sọ fún wa pé wọ́n ń kó wa kúrò nílùú ni àti pé a ò ní tẹ ibẹ̀ yẹn mọ́ láé. Bí wọ́n ṣe kó èmi, màámi, bàbá àgbà, màmá àgbà àtàwọn arákùnrin wa lọ sí Siberia nìyẹn o. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni mí nígbà náà. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, a bá ara wa nínú irà, nínú igbó kìjikìji níbi tó tutù rinrinrin. Ibẹ̀ ò tiẹ̀ fi nǹkan kan jọ àdúgbò tí mo gbé dàgbà, áà, àjò ò mà dà bí ilé o! Àá kàn ṣàdéédéé bú sẹ́kún nígbà míì. Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé.

Ahéré mẹ́wàá tí wọ́n fi pákó kọ́ ló wà nínú abúlé kékeré tí wọ́n kó wa lọ. Wọ́n kó àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn lọ sáwọn abúlé mìíràn tó wà káàkiri inú igbó kìjikìji yìí. Kí ẹ̀rù wa lè máa ba àwọn ará abúlé náà, kí wọ́n sì lè gbin ẹ̀tanú wa sí wọn lọ́kàn, àwọn aláṣẹ sọ pé ajẹ̀nìyàn làwa Ẹlẹ́rìí. Àmọ́ kò pẹ́ ṣá táwọn èèyàn náà fi mọ̀ pé irọ́ ni àti pé kò sídìí fún wọn láti máa bẹ̀rù wa.

Inú ahéré àtijọ́ kan báyìí ni wọ́n kó wa sí fún oṣù méjì tá a kọ́kọ́ lò níbẹ̀. Ṣùgbọ́n a rí i pé ó yẹ ká kọ́ ibi tó máa rọrùn jù bẹ́ẹ̀ lọ láti gbé kí òtútù tó mú kọjá àlà tó dé. Bàbá àgbà àti màmá àgbà kún èmi àti màámi lọ́wọ́ láti kọ́ ilé kótópó kan tí ìdajì rẹ̀ wà lókè, tí ìdajì yòókù sì wà nínú ilẹ̀. Ó ju ọdún mẹ́ta tá a fi gbénú ilé yẹn. Wọ́n ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ kúrò lábúlé yẹn láìgbàṣẹ, wọn ò sì fún wa láṣẹ ọ̀hún títí.

Nígbà tó yá, wọ́n gbà mí láyè láti lọ sílé ìwé. Níwọ̀n bí ohun tí ẹ̀sìn tèmi fi ń kọ́ni ti yàtọ̀ sí tàwọn yòókù níbẹ̀, àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi máa ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ mi. Ayọ̀ máa ń hàn lójú bàbá àgbà nígbà tí mo bá délé ròyìn fún un bí mo ṣe ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wa nílé ìwé.

Wọ́n Fún Wa Lómìnira Díẹ̀ Sí I

Lẹ́yìn ikú ààrẹ apàṣẹwàá náà, Stalin lọ́dún 1953, ara tù wá díẹ̀ sí i. Wọ́n gbà wá láyè láti jáde kúrò ní abúlé náà. Èyí mú kó rọrùn fún wa láti bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa péjọ pọ̀ ká sì lè lọ sí ìpàdé láwọn abúlé tí wọ́n kó àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn lọ. Kí àwọn èèyàn má bàa kíyè sí wa, a máa ń kóra jọ láwùjọ kéékèèké. Ká tó débẹ̀, a máa ń rìn tó ọgbọ̀n kìlómítà, nígbà míì nínú yìnyín tó máa ń mù wá dé orúnkún, tí òtútù á sì mú ju ti ilé ẹja lọ. Lọ́jọ́ kejì, a ó fẹsẹ̀ rin ọ̀nà jíjìn yìí padà sílé. Lójú ọ̀nà, àá máa fi kóró ṣúgà bíi mélòó kan jẹ apálá tá a ti rẹ sínú ọtí kó má bàa bàjẹ́. Síbẹ̀, bíi tí Dáfídì àtijọ́, ńṣe la máa ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀!—Sáàmù 122:1.

Lọ́dún 1955, mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé mo ti ya ara mí sí mímọ́ fún Jèhófà. Ní àkókò díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn ni mo pàdé Lidiya, ọmọbìnrin jẹ́jẹ́ kan báyìí tí irún orí rẹ̀ dúdú minimini ní ìpàdé ìjọ lábúlé kan tó wà nítòsí wa. Ẹlẹ́rìí bíi tiwa ni òun àti ìdílé rẹ̀, kíkó ni wọ́n sì kó àwọn náà kúrò ní Moldova. Olóhùn iyọ̀ lọmọbìnrin yìí, ó sì fẹ́ẹ̀ lè kọ gbogbo orin òjìlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín mẹ́ta [337] tó wà nínú ìwé orín tá à ń lò nígbà yẹn lórí. Ó fi ìyẹn wù mí torí pé èmi pẹ̀lú fẹ́ràn àwọn ohùn orin wa àtàwọn orin náà. Lọ́dún 1956, a pinnu pé a máa fẹ́ra wa.

Mo kọ́ lẹ́tà sí bàámi, nítorí pé a mọ̀ pé wọ́n ti rán an lọ́ sí ìgbèkùn nílùú Magadan, a sì sún ìgbéyàwó wa síwájú títí di ìgbà tí ó fi máa fọwọ́ si í. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n fi bàbá mi sílẹ̀, ìyẹn sì mú kó lè wá bá wa níbi tá a wà. Ó sọ fún wa pé agbara Ọlọ́run lòun àtàwọn Kristẹni yòókù ò fi kú sínú ipò tó le koko táwọn wà nínú ẹ̀wọ̀n yẹn. Irú àwọn ìtàn báwọ̀nyẹn fún ìgbàgbọ́ wa lókun.

Kò pẹ́ tí bàbá mi dé ni ìjàǹbá kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí màmá mi ń gbá epo tá a fi ń palé tá a sì fi ń kun nǹkan. Agbada tó fi ń gbá epo náà kàn dédé dojú dé ni, nǹkan gbígbóná tó wà nínú ẹ̀ sì dà lé màmá mi lórí. Ilé ìwòsàn ló kú sí. Ìbánújẹ́ ńláǹlà wọlé tọ̀ wá wá. Nígbà tó ṣe, ìbànújẹ́ bàbá mi dín kù, ó sì fẹ́ Tatyana, Ẹlẹ́rìí kan tó wà ní abúlé tí kò jìnnà sí wa.

A Tẹ̀ Síwájú Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

Lọ́dún 1958, èmi àti Lidiya kúrò ní Kizak lábúlé tá à ń gbé, a sì kó lọ sí abúlé Lebyaie tó tóbi jù ú lọ, tó sì fi nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà jìn sí i. A ti kà á pé láwọn ilẹ̀ mìíràn àwọn Kristẹni ń wàásù láti ilé dé ilé. Nítorí náà, a gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ níbi tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fòfin de ìwé ìròyin Ilé Ìṣọ́ àti Jí! síbẹ̀ à ń dọ́gbọ́n rí àwọn ẹ̀dà wọn kó wọlé láti àwọn ibòmíràn. Wọ́n sọ fún wa báyìí pé lédè Rọ́ṣíà nìkan la ó ti máa rí àwọn ìwé ìròyìn yìí gbà. Títí dìgbà yẹn, à ń rí wọn gbà lédè Moldavia pẹ̀lú. Nítorí náà, a kẹ́kọ̀ọ́ taratara láti lè gbọ́ èdè Rọ́ṣíà. Kódà títí dòní, mo ṣì rántí àwọn àkòrí àpilẹ̀kọ wọ̀nyẹn, ìyẹn nìkan kọ́ o, mi ò tíì gbàgbé àwọn àlàyé tó wà nínú wọn pẹ̀lú.

Ká lè máa rí owó gbọ́ bùkátà ara wa, Lidiya ń ṣisẹ́ nílé iṣẹ́ ọkà èmi sì ń bá wọn já igi sílẹ̀ lẹ́yìn ọkọ̀. Iṣẹ́ yẹn le gan-an kò sì sówó nídìí ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí máa ń ṣiṣẹ́ wa bí iṣẹ́, síbẹ̀ wọn ò fún wa lówó ìrànwọ́ tàbí àjẹmọnú kankan. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba là á mọ́lẹ̀ pé: “Kò sáyè fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi táwọn Kọ́múníìsì bá ti ń ṣèjọba.” Síbẹ̀, inú wa dùn pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣẹ sí wa lára pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.”—Jòhánù 17:16.

Àwọn Ìṣòro Mìíràn Tún Yọjú

A bí ọmọbìnrin wa Valentina lọ́dún 1959. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí inúnibíni tún bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Olórí ìjọba orílẹ̀-èdè náà Nikita Khrushchev bẹ̀rẹ̀ sí dìde ogun sí àwọn ìsìn láàárín ọdún 1959 sí ọdún 1964.” Àwọn ọlọ́pàá KGB sọ fún wa pé tí ìjọba Soviet Union ò bá rẹ́yìn gbogbo ìsìn, pàápàá jù lọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn ò ní dẹ̀yìn.

Valentina ò tíì ju ọmọ ọdún kan lọ, nígbà tí wọ́n pè mí pé kí n wá gbaṣẹ́ ológun. Nígbà tí mi ò lọ gbà á, wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì. Lákòókò kan ìyàwó mi wá wò mí, ọ̀gà kan nínú àwọn ọlọ́pàá KGB sọ fún un pé: “A ti rí ìsọfúnni gbà látọ̀dọ̀ ìjọba Kremlin pé láàárín ọdún méjì, a ò ní gbúròó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ ní Soviet Union.” Ló bá kìlọ̀ fún un pé: “O jẹ́ yáa sọ pé o ò ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá lọ fimú dánrin lẹ́wọ̀n.” Ọ̀gágun yẹn rò pé ìhàlẹ̀ yẹn á pa àwọn obìnrin lẹ́nu mọ́ ni, ó sọ pé: “Ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ̀rọ̀ tiwọn, kò tó ohun tá à ń lọ àdá bẹ́.”

Ká tó rí bí ọjọ́ mélòó kan wọ́n ti fẹ́ẹ̀ kó gbogbo àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí dà sẹ́wọ̀n àti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tán. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni obìnrin aláìṣojo ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní pẹrẹu. Wọ́n ń forí la ewu ńlá kọjá láti rí i pé wọ́n dọ́gbọ́n mú ìwé wọ inú àwọn ẹ̀wọ̀n àtàwọn àgọ́ iṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tá a wà. Lidiya náà dojú kọ irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà sì làwọn ọkùnrin á máa fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́ nítorí pé mi ò sí nílé. Àni wọ́n tún ń sọ fún un pé wọn ò ní fi mí sílẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ojú tì wọ́n, wọ́n fi mí sílẹ̀!

Wọ́n Dá Mi Sílẹ̀ Mo sì Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan

Wọ́n tún àkọsílẹ̀ ẹjọ́ mi gbé yẹ̀wò lọ́dún 1963, wọ́n sì fi mí sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìyẹn lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́ta lẹ́wọ̀n. Ṣùgbọ́n a ò rí ìwé àṣẹ láti gbé ìlú gbà níbikíbi, mi ò sì ríṣẹ́. Òfin Orílẹ̀-èdè yẹn kan sọ pé: “Ẹni tí ò bá láṣẹ àtigbé ìlú kò lè ríṣẹ́ ṣe.” A fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà, a bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, a pinnu láti kó lọ sí ìlú Petropavl ní àríwá orílẹ̀-èdè Kazakhstan. Àmọ́, wọ́n ti sọ̀rọ̀ wa fún àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ ibẹ̀, wọn ò jẹ́ ká dúró níbẹ̀ wọn ò sì jẹ́ ká ríṣẹ́ ṣe. Ó tó nǹkan bí àádọ́ta Ẹlẹ́rìí nílùú yìí tó fara gbá irú inúnibíni bẹ́ẹ̀.

Àwa àti tọkọtaya Ẹlẹ́rìí mìíràn kó lọ sí ìlú kékeré Shchuchinsk níhà gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tó ń gbé níbẹ̀, àwọn aláṣẹ ibẹ̀ ò sì mọ nǹkan kan nípa iṣẹ́ ìwàásù wa. Ọ̀sẹ̀ kan gbáko lèmi àti Ivan fi ń wáṣẹ́ kiri nígbà táwọn ìyàwó wa méjèèjì wà ní ibùdókọ̀ ojú irin níbi tá à ń sùn lálaalẹ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, a ríṣẹ́ sí iléeṣẹ́ gíláàsì. A rẹ́ǹtì yàrá kékeré kan tó gbà bẹ́ẹ̀dì méjì àtàwọn nǹkan wẹ́rẹwẹ̀rẹ mìíràn, ibẹ̀ làwa ìdílé méjèèjì ń gbé, a sì fara mọ́ ọn.

Èmi àti Ivan fi taratara ṣiṣẹ́ wa, inú àwọn tó gbà wá ṣíṣẹ́ sì dùn sí wa. Nígbà tí wọ́n tún pè mí lẹ́ẹ̀kan sí i pé kí n wá wọṣẹ́ ológun, ẹni tó ń bójú tó ilé iṣẹ́ yẹn ti mọ̀ pé ẹ̀rí ọkàn mi tí mo ti fi Bíbélì kọ́ kò ní jẹ́ kí n lè kọ́ṣẹ́ ológun. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tó lọ bá ọ̀gágun tó sì sọ fún un pé òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ gan-an lèmi àti Ivan, tí ò bá sì sí wa níléeṣẹ́ yẹn, wọ́n á kógbá sílé. Bí wọ́n ṣe ní ká máa ṣiṣẹ́ wa lọ nìyẹn o.

Títọ́ Ọmọ àti Ṣíṣiṣẹ́ Sin Àwọn Ẹlòmíràn

A bí ọmọbìnrin wa kejì, Lilya lọ́dún 1966. Lọ́dún kan lẹ́yìn ìyẹn a ṣí lọ sí ìlú Belyye Vody tó wà níhà gúúsù orílẹ̀-èdè Kazakhstan níbi ààlà Uzbekistan. Àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó kan wà níbẹ̀ yẹn. Kò pẹ́ sígbà náà tá a fi dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀, wọ́n sì yàn mí ṣe alábòójútó olùṣalága. A bí ọmọkùnrin kan tá a sọ ní Oleg lọ́dún 1969, lọ́dún méjì lẹ́yìn náà la bí Natasha tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn wa. Èmi àti ìyàwó mi ò fìgbà kan gbàgbé rí pé ogún látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọmọ jẹ́. (Sáàmù 127:3) A jíròrò ohun tó yẹ ká ṣe tá a fi máa lè tọ́ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

Títí di àárín ọdún 1970 sí 1979 ni ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣì fi wà láwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ọ̀pọ̀ ìjọ ló ṣì nílò àbójútó àti ìdarí tó múná dóko. Nítorí náà, lákòókò yẹn ọrùn ìyàwó mi ni iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ já lé jù, nígbà míì a máa ṣiṣẹ́ ìyá mọ́ ti bàbá, tí èmi sì ń ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. Mo máa ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní Kazakhstan àtàwọn orílẹ̀-èdè Tajikistan, Turkmenistan, àti Uzbekistan, tí gbogbo wọn jẹ́ orílẹ̀-èdè olómìnira ti Soviet Union wò. Bákan náà, mo tún ń ṣiṣẹ́ kí n fi lè gbọ́ bùkátà ìdílé mi, Lidiya àtàwọn ọmọ mi sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú mi tinútinú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láwọn ìgbà míì, n kì í sí nílé fún bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan, mo máa ń gbìyànjú láti fi ìfẹ́ bàbá sọ́mọ hàn sí àwọn ọmọ mi mo sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí. Èmi àti Lidiya fi taratara gbàdúrà àgbàpọ̀ sí Jèhófà pé kó ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́, a sì máa ń bá wọn jíròrò bí wọ́n ṣe lè borí ìbẹ̀rù èèyàn kí wọ́n sì sún mọ́ Ọlọ́run. Ọpẹ́lọpẹ́ ìyàwó mi ọ̀wọ́n tó dúró tì mí gbágbáágbá, n kì bá tí lè ṣiṣẹ́ mi bí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Lidiya àtàwọn arábìnrin wa yòókù kì í ṣe “ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀” tí ọ̀gá sójà yẹn sọ pé wọ́n jẹ́. Obìnrin bí ọkùnrin ni wọ́n, ká sòótọ́, òmìrán ni wọ́n nípa tẹ̀mí!—Fílípì 4:13.

Lọ́dún 1988, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ wa ti dàgbà, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká alákòókò kíkún. Àwọn orílẹ̀-èdè tó pọ̀ jù lọ ní Àárín gbùngbùn Éṣíà ló wà lábẹ́ àyíká tí mò ń bójú tó. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi orúkọ wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1991 ní Soviet Union àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó láǹfààní láti máa wàásù, àwọn ọkùnrin mìíràn tí wọ́n dáńgájíá tí wọ́n sì dàgbà dénú nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ sí sìn láwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ti Éṣíà yìí tí wọ́n wà lábẹ́ Soviet Union àtijọ́. Lónìí, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mẹ́rìnlá ló wà ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn, èèyàn ọ̀kẹ́ méjì àbọ̀ [50,000] ló sì wá sí ibi Ayẹyẹ Ìrántí ikú Kristi níbẹ̀ lọ́dún tó kọjá!

Ìkésíni Tí Mi Ò Rò Tì

Lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1998, wọ́n tẹ̀ mí láago láìròtẹ́lẹ̀ láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà. Wọ́n bi mí pé “Anatoly, ǹjẹ́ ìwọ àti Lidiya ti ronú nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún?” Lóòótọ́, a ti ń ronú nípa báwọn ọmọ wa ṣe máa láǹfààní náà. Kódà, Oleg ọmọkùnrin wa ti ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Rọ́ṣíà láti bí ọdún márùn-ún.

Nígbà tí mo sọ fún Lidiya nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ ká wá ṣiṣẹ́ alákòókò kíkún yìí, ó bi mí pé: “Báwo wá la ṣe fẹ́ ṣe ilé wa, ọgbà wa àtàwọn dúkìá wa?” Lẹ́yìn tá a ti gbàdúrà tá a sì finúkonú, a pinnu pé a ó lọ. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n ní ká wá sìn ní ibùdó tá a ti ń bójú tó ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Issyk lórílẹ̀-èdè Kazakhstan, níbi tí kò jìnnà sí ìlú ńlá náà Alma-Ata. Níbí yìí ni wọ́n ti ń túmọ̀ àwọn ìwé wa tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí àwọn èdè ìbílẹ̀ táwọn èèyàn jákèjádò ibẹ̀yẹn ń sọ.

Bí Ìdílé Wa Ṣe Rí Lónìí

A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó ràn wá lọ́wọ́ láti lè kọ́ àwọn ọmọ wa ní òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì o! Àkọ́bí wa obìnrin, Valentina ṣègbéyàwó ó sì tẹ̀ lé ọkọ rẹ̀ lọ sí ìlú Ingelheim lórílẹ̀-èdè Jámánì lọ́dún 1993. Wọ́n bí ọmọ mẹ́ta, gbogbo wọ́n sì ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Lilya, ọmọbìnrin wa kejì ní ìdílé tiẹ̀ pẹ̀lú. Òun àti ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ Belyye Vody ń tọ́ àwọn ọmọ wọn méjèèjì láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Oleg gbé Natasha, arábìnrin kan láti ilú Moscow, níyàwó, àwọn méjèèjì sì ń sìn ní Rọ́ṣíà, ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tó wà létí ìlú St. Petersburg. Ní ọdún 1995, àbígbẹ̀yìn wa obìnrin, Natasha lọ́kọ, òun àti ọkọ rẹ̀ sì ń sìn ní ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Rọ́ṣíà lórílẹ̀-èdè Jámánì.

A máa ń kóra jọ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Àwọn ọmọ wa máa ń pìtàn fún àwọn ọmọ wọn nípa bí “Màmá” àti “Bàbá” ṣe fetí sí Jèhófà tí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà kí wọ́n sì máa sìn ín. Mo rí i pé irú ìjíròrò báyìí ran àwọn ọmọ ọmọ wa lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí. Ọmọ ọmọ wa tó kéré jù tó jẹ́ ọkùnrin rí bí mo ṣe rí nígbà tí mo kéré bíi tiẹ̀. Nígbà míì á wá jókòó lé mi lẹ́sẹ̀ á sì ní kí n sọ ìtàn Bíbélì kan fún òun. Ńṣe lomijé máa ń sun lójú mi nígbà tí mo bá rántí bí mo ṣe máa ń jókòó lórí ẹsẹ̀ bàbá mi àgbà àti bó ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa àti láti máa sìn ín.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Moldova tí orílẹ̀-èdè yìí ń jẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí la ó máa fi pè é nínú àpilẹ̀kọ yìí dípò tá ó fi máa lo àwọn orúkọ tó ti jẹ́ rí bíi Moldavia tàbí Soviet Republic of Moldavia.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èmi àtàwọn òbí mi rèé níwájú ilé wa ní lórílẹ̀-èdè Moldova nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n ju bàbá mi sẹ́wọ̀n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Èmi àti Lidiya rèé lọ́dún 1959, nígbà tá a ṣì wà nígbèkùn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Lidiya àti Valentina ọmọbìnrin wa rèé nígbà tí mo ṣì wà lẹ́wọ̀n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Lidiya rèé báyìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwa nìyìí pẹ̀lú àwọn ọmọ wa, àtàwọn ọmọ ọmọ wa, gbogbo wa là ń sin Jèhófà!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́