Awọn Ìdílé Kristian Máa Ń Ṣe Nǹkan Papọ̀
“Mo sì bẹ̀ yín, ará, . . . kí á lè ṣe yín pé ní inú kan-náà, àti ní ìmọ̀ kan-náà.”—1 KORINTI 1:10.
1. Kí ni ipò tí ìṣọ̀kan wà nínú ọ̀pọ̀ ìdílé?
ÌDÍLÉ tìrẹ ha ṣọ̀kan bí? Tàbí ó ha jọ pé olúkúlùkù ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ ni bí? Ẹ̀yin ha ń ṣe àwọn nǹkan papọ̀ bí? Tàbí ó ha jẹ́ pé gbogbo yín kìí sábà wà ní ibìkan náà ní àkókò kan-náà bí? Ọ̀rọ̀ náà “ìdílé” fúnni ní èrò agbo-ile tí ó ṣọ̀kan.a Síbẹ̀, kìí ṣe gbogbo ìdílé ni ó ṣọ̀kan. Olùkọ́ ọmọ ilẹ̀ Britain kan tilẹ̀ lọ jìnnà débi sísọ pe: “Dípò jíjẹ́ ìpìlẹ̀ fún ẹgbẹ́-àwùjọ rere, ìdílé . . . ni orísun gbogbo àwọn àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn wa.” Ìyẹn ha jẹ́ òtítọ́ nipa ìdílé rẹ bí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, bí o ha ti yẹ kí ọ̀ràn rí nìyẹn bí?
2. Àwọn ènìyàn inú Bibeli wo ni wọn fúnni ní ẹ̀rí wíwá láti inu ìdílé rere?
2 Ìṣọ̀kan tàbí àìsíṣọ̀kan ìdílé sábà máa ń sinmi lórí ipò-aṣíwájú rẹ̀, yálà nípasẹ̀ àwọn òbí méjì tàbí ọ̀kanṣoṣo. Ní àkókò tí a kọ Bibeli, àwọn ìdílé tí wọ́n ṣọ̀kan tí wọ́n jọ́sìn papọ̀ gbádùn ìbùkún Jehofa. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní Israeli ìgbàanì, níbi tí ọmọbìnrin Jẹfta, Samsoni, àti Samueli, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀síra, ti fi ẹ̀rí wíwá láti inú ìdílé oníwà-bí-Ọlọ́run hàn. (Onidajọ 11:30-40; 13:2-25; 1 Samueli 1:21-23; 2:18-21) Ní àkókò Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, Timoteu, olùṣòtítọ́ alábàáṣiṣẹ́ Paulu nínú díẹ̀ lára àwọn ìrìn-àjò ìjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run Paulu, ni a tọ́ dàgbà pẹ̀lú ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ àgbà Loide àti ìyá rẹ̀, Eunike. Ẹ wo irú ọmọ-ẹ̀yìn títayọ àti òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run tí òun dà!—Iṣe 16:1, 2; 2 Timoteu 1:5; 3:14, 15; tún wo Iṣe 21:8, 9 pẹ̀lú.
Èéṣe Tí Ẹ Fi Nilati Ṣe Àwọn Nǹkan Papọ̀?
3, 4. (a) Àwọn ànímọ́ wo ni ó níláti farahàn nínú ìdílé kan tí ó sopọ̀ṣọ̀kan? (b) Báwo ni inú ilé ṣe lè ju ilé kan lásán lọ?
3 Èéṣe tí ó fi ṣàǹfààní fún àwọn ìdílé láti ṣe àwọn nǹkan papọ̀? Ìdí ni pé ó ń gbé ìlóye àti ọ̀wọ̀ tọ̀tún-tòsì ró. Dípò mímú araawa jìnnà réré sí ẹnìkínní kejì, a ń wà papọ̀ a sì ń fún araawa ní ìtìlẹ́yìn. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí nínú ìwé-agbéròyìnjáde náà Family Relations sọ pé: “Àwòrán ṣíṣekedere dé ìwọ̀n ààyè kan tí ń ṣàpèjúwe àwọn ìwà-ẹ̀yẹ pàtó ti a lè rí lára ‘àwọn ìdílé tí ó lágbára’ ti wá sójútáyé. Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ní nínú dídúró gbọnyingbọnyin ti ẹnìkínní kejì àti mímọrírì ẹnìkínní kejì, wíwà ní yọ̀tọ̀mì papọ̀, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó dára, agbára láti yanjú ìṣòro, àti kí ipò-tẹ̀mí jẹ́ kókó alágbára kan nínú ìgbésí-ayé.”
4 Nígbà tí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí bá wà nínú ìdílé kan, inú ilé kò tún ní dàbí ilé-epo kan mọ́, ibìkan láti yà bàrá gbepo. Ó ju kìkì ilé kan lásán lọ. Ó jẹ́ ibìkan tí ń ṣẹ́wọ́ síni tí ń fa àwọn mẹ́ḿbà ìdílé mọ́ra. Ó jẹ́ ibi ààbò ọlọ́yàyà àti ìfẹ́ni, ìyọ́nú, àti òye. (Owe 4:3, 4) Ó jẹ́ abẹ́-ọ̀dẹ̀dẹ̀ kan níbi tí a ti ń rí ìṣọ̀kan ìdílé, kìí ṣe ihò àkéekèe tí ó jẹ́ ti gbún-gbùn-gbún àti ìyapa. Ṣùgbọ́n báwo ni ọwọ́ ṣe lè tẹ èyí?
Wíwàpapọ̀ Nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé
5. Kí ni a ń lò kí á baà lè kẹ́kọ̀ọ́ ìjọsìn tòótọ́?
5 Ìjọsìn tòótọ́ Jehofa ni a ń kẹkọ̀ọ́ rẹ̀ nípa lílo ọgbọ́n ìrònú, tàbí “agbára ìrònú” wa. (Romu 12:1, NW) Ìwà wa ni a kò níláti darí nípasẹ̀ àwọn èrò-ìmọ̀lára onígbà-díẹ̀ bí irú ìwọ̀nyí tí àwọn ètò-àjọ isin abẹnu-dùn-juyọ̀ àti afìwàásù kóninígbèkùn tí ń tan ìgbàgbọ́ wọn kálẹ̀ nipasẹ tẹlifíṣọ̀n ń gbé jade. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń sún wa ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti àṣàrò lórí Bibeli àti ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí “ẹrú oluṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n-inú” pèsè. (Matteu 24:45, NW) Àwọn ìgbésẹ̀ wa tí ó jẹ́ ti Kristian jẹ́ àbájáde níní èrò-inú Kristi lórí ipò èyíkéyìí tàbí àdánwò tí ó lè dìde. Ní ọ̀nà yẹn, Jehofa ni Olùkọ́ni Ńlá wa.—Orin Dafidi 25:9; Isaiah 54:13; 1 Korinti 2:16.
6. Àpẹẹrẹ kárí-ayé wo níti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ni a ní?
6 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé ń kó ipa ṣíṣe pàtàkì kan nínú ipò-tẹ̀mí gbogbo ìdílé Kristian. Nígbà wo ni o ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ? Bí a bá fi í sílẹ̀ fún èèṣì tàbí ìpinnu àìròtẹ́lẹ̀, nígbà náà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ni ó ṣeeṣe ki a má máa ṣe déédéé, bi a bá tilẹ̀ ń ṣe é rárá. Wíwàpapọ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ń béèrè ìtòlẹ́sẹẹsẹ déédéé, tí a gbékalẹ̀. Nígbà náà ẹni gbogbo á mọ ọjọ́ àti wákàtí tí a retí wọn láti wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti gbádùn ìwàpapọ̀ ìdílé fún nǹkan tẹ̀mí. Iye tí ó jú ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Beteli kárí-ayé mọ̀ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn jẹ́ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Monday. Ó ti wúni lórí tó fún àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni ní Beteli wọ̀nyí láti rántí pé gbogbo wọn ń ṣàjọpín ìkẹ́kọ̀ọ́ kan-náà bi ọjọ́ ti ń parí lọ, ni àwọn erékùṣù Pacific àti New Zealand, àti lẹ́yìn náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ní Australia, Japan, Taiwan, Hong Kong, kí ó tó wá kan Asia, Africa, àti Europe, àti ní paríparí rẹ̀ ní àwọn ilú America. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a yà wọ́n sọ́tọ̀ nípasẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibùsọ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn èdè, ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yìí ń ru ìmọ̀lára ṣiṣe nǹkan papọ̀ sókè nínú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Beteli. Ní ìwọ̀n kékeré, ìwọ náà lè mú irú ìmọ̀lára kan-náà dàgbà nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ.—1 Peteru 2:17; 5:9.
7. Gẹ́gẹ́ bí Peteru ti wí, ojú wo ni a níláti fi wo ọ̀rọ̀ òtítọ́?
7 Aposteli Peteru gbà wá nímọ̀ràn pé: “Bí ọmọ-ọwọ́ titun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti ẹ̀mí náà èyí tí kò ní ẹ̀tàn, kí ẹ̀yin kí ó lè máa ti ipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà, bí ẹ̀yin bá ti tọ́ ọ wò pe olóore ni Oluwa.” (1 Peteru 2:2, 3) Ẹ wo àwòrán mèremère tí Peteru gbé jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì! Ó lo ọ̀rọ̀-ìṣe èdè Griki náà e·pi·po·theʹsa·te, èyí tí ó wá, gẹ́gẹ́ bí Linguistic Key to the Greek New Testament ti wí, láti inú ọ̀rọ̀ kan tí ó túmọ̀ sí “láti yánhànhàn fún, láti fọkànfẹ́, láti ní ìfàsí-ọkàn.” Ó dọ́gbọ́n túmọ̀sí ìfẹ́-ọkàn mímúná. Ìwọ ha ti ṣàkíyèsí ọ̀nà tí ọmọ ẹran kan ń gbà fi ìháragàgà wá orí ọmú ìyá rẹ̀ kiri àti bí ọmọ ènìyàn kan ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn tó nígbà tí ó bá ń mu ọmú ìyá rẹ̀? A níláti ní irú ìfẹ́-ọkàn kan-náà fún ọ̀rọ̀ òtítọ́. Ọ̀mọ̀wé Griki náà William Barclay sọ pé: “Fún Kristian olótìítọ́-inú, láti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun kìí ṣe iṣẹ́ aláápọn ṣùgbọ́n onídùnnú, nítorí ó mọ̀ pe nínú rẹ̀ ni ọkàn-àyà òun yóò ti rí èròjà tí òun ń yánhànhàn fún.”
8. Ìpèníjà wo ni ó dojúkọ olórí ìdílé nínú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé?
8 Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gbé ẹrù-iṣẹ́ títóbi ka orí olórí ìdílé náà. Òun níláti rí i dájú pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn mọ́ gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀ àti pé gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀ ni ó kópa. Àwọn ọmọ kò níláti nímọ̀lára pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà wà fún àwọn tí ó ti dàgbà níti gidi. Ìjójúlówó ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe pàtàkì ju àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ tí a kárí lọ. Jẹ́ kí Bibeli fúnraarẹ̀ sọ̀rọ̀. Nibi tí ó bá ti yẹ, ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti fojú-inú wo àwọn àgbègbè àti ìrísí ilẹ̀ Palestine níbi tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ń jíròrò ti wáyé. Gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀ ni a níláti fún níṣìírí láti ṣe ìwádìí tiwọn fúnraawọn àti láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú ìdílé náà. Ní ọ̀nà yìí àwọn ọmọ pẹ̀lú lè ‘dàgbàsókè níwájú Oluwa.’—1 Samueli 2:20, 21.
Wíwàpapọ̀ Nínú Iṣẹ́-Ajíhìnrere
9. Báwo ni a ṣe lè sọ iṣẹ́ ìwàásù di ìrírí aláyọ̀ ti ìdílé?
9 Jesu sọ pé: “A kò lè ṣàìmá kọ́ wàásù ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Marku 13:10) Àwọn ọ̀rọ̀ wọnni fún gbogbo àwọn Kristian olùfẹ̀rí-ọkàn bìkítà ní iṣẹ́-àyànfúnni kan—láti jíhìnrere, ṣàjọpín ìhìnrere àkóso Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ṣíṣe èyí papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé lè jẹ́ ìrírí aláyọ àti ọ̀kan tí ń fúnni níṣìírí. Inú àwọn ìyá àti baba a máa dùn sí ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ ìhìnrere àwọn ọmọ wọn. Tọkọtaya kan tí ó ní àwọn ọmọkunrin mẹ́rin tí ọjọ́-orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kànlélógún sọ pé àwọn ti máa ń fìgbà gbogbo ní àṣà títẹ̀lé àwọn ọmọ wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìtagbangba ní gbogbo ọjọ́ Wednesday lẹ́yìn ilé-ẹ̀kọ́ àti ní gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ Saturday. Baba náà sọ pé: “A ń kọ́ wọn ní nǹkankan ní gbogbo ìgbà. A sì ń rí i dájú pé ó jẹ́ ìrírí tí ó gbádùnmọ́ni, tí ó sì ń fúnni níṣìírí.”
10. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ṣàǹfààní fún àwọn ọmọ wọn nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́?
10 Ṣíṣiṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan nínú wíwàásù àti kíkọ́ni lè jẹ́ amésojáde gan-an. Nígbà mìíràn àwọn ènìyàn túbọ̀ ń fi àìsí iyèméjì dáhùnpadà sí ojúlówó ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ rírọrùn tí ọmọdé kan bá ṣe. Lẹ́yìn náà, Mọ́mì tàbí Dádì wà níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́ nígbà tí ó bá yẹ. Àwọn òbí lè rí i dájú pe àwọn ọmọ wọn gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ń tẹ̀síwájú kí wọ́n sì tipa báyìí di òjíṣẹ́ “tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ.” Wíwàásù papọ̀ ní ọ̀nà yìí mú kí ó ṣeéṣe fún àwọ̀n òbí láti ṣàkíyèsí ìṣarasíhùwà, ìjáfáfá, àti ìṣesí ọmọ wọn nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà. Nípa níní ọ̀nà-ìgbàṣe déédéé kan, wọ́n ń rí ìtẹ̀síwájú ọmọ náà wọ́n sì ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìṣírí tí ó wàdéédéé láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin lókun. Lákòókò kan-náà, àwọn ọmọ ń rí i pé àwọn òbí wọn jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Ní àwọn àkókò eléwu àti oníwà-ipá wọ̀nyí, ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan tí ó ṣọ̀kan tí ó sì ń bìkítà tún lè pèsè ìwọ̀n ààbò kan ní àdúgbò tí ìwà-ọ̀daràn ti ga pàápàá.—2 Timoteu 2:15; Filippi 3:16.
11. Kí ni ó lè fi tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn dín ìtara ọmọ kan fún òtítọ́ kù?
11 Ó máa ń rọrùn fún àwọn ọmọ láti jádìí àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n méjì nínú àwọn àgbàlagbà. Bí àwọn òbí kò bá fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn fún òtítọ́ àti fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé, agbára káká ni a fi níláti retí pé kí àwọn ọmọ jẹ́ onítara. Nípa báyìí, òbí kan tí ó ní ìlera tí ó jẹ́ pé kìkì iṣẹ́-ìsìn pápá kanṣoṣo tí ó ní jẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ lè ní ìrírí àbájáde tí kò gbádùnmọ́ni nígbà tí àwọn wọnyi bá dàgbà.—Owe 22:6; Efesu 6:4.
12. Báwo ni àwọn ìdílé kan ṣe lè gba ìbùkún àkànṣe láti ọ̀dọ̀ Jehofa?
12 Àǹfààní kan ti jíjẹ́ ẹni tí “a ṣe . . . pé ní inú kan-náà” ni pé bóyá ìdílé náà lè fọwọ́sowọ́pọ̀ kí ó baà lè jẹ́ pé ó kérétán mẹ́ḿbà kan lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò-kíkún nínú ìjọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé yíká ayé ń ṣe èyí, gbogbo wọn sì ń rí ìbùkún gbà láti inú àwọn ìrírí àti ìjáfáfá púpọ̀ síi ti mẹ́ḿbà ìdílé wọn tí ó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.—2 Korinti 13:11; Filippi 2:1-4.
Wíwàpapọ̀ Nínú Bíbójútó Àwọn Ìṣòro
13, 14. (a) Àwọn ipò wo ni ó lè nípa lórí ìṣọ̀kan ìdílé kan? (b) Báwo ni a ṣe lè ṣèdíwọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn ìṣòro ìdílé?
13 Ní àwọn àkókò lílekoko ti “másùnmáwo” àti “ewu” wọ̀nyí, gbogbo wa ń nírìírí ìkìmọ́lẹ̀. (2 Timoteu 3:1, Revised Standard Version; Phillips) Àwọn ìṣòro wà ní ibi iṣẹ́, ní ilé-ẹ̀kọ́, lójú pópó, àti nínú ilé fúnraarẹ̀ pàápàá. Àwọn kan ń jìyà lọ́wọ́ ìlera tí kò sunwọ̀n tàbí àwọn ìṣòro ti èrò-ìmọ̀lára ọlọ́jọ́ pípẹ́, èyí tí ó máa ń yọrísí pákáǹleke àti èdèkòyédè nínú ìdílé. Báwo ni a ṣe lè bójútó irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀? Nípa kí olúkúlùkù di aláìlè jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ni bí? Nipa mímú ara-ẹni dádó àní nígbà ti a ń jìjọ gbé inú ilé kan-náà ha ni bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a níláti jùmọ̀sọ̀ àwọn àníyàn wa papọ̀ kí á sì béèrè fún ìrànlọ́wọ́. Ibòmíràn wo ni ó sì dára fún èyí ju inú agbo ìdílé onífẹ̀ẹ́ kan lọ?—1 Korinti 16:14; 1 Peteru 4:8.
14 Gẹ́gẹ́ bí dókítà èyíkéyìí ti mọ̀, ìdènà-àrùn sàn ju ìwòsàn-àrùn lọ. Ohun kan-náà ni ó jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ìṣòro ìdílé. Ìjíròrò fàlàlà aláìfọ̀rọ̀sábẹ́-ahọ́n lè ṣèdíwọ́ fún àwọn ìṣòro láti máṣe di èyí tí ó léwu. Àní bí àwọn ìṣòro wíwúwo pàápàá bá dìde, a lè bójútó wọn àní kí á tilẹ̀ yanjú wọn pàápàá bí ìdílé náà bá jùmọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà Bibeli tí ó wémọ́ ọn. Níye ìgbà aáwọ̀ ni a lè yí padà sí ipò-ìbátan dídán mọ́rán-mọ́rán kan nípa fífi àwọn ọ̀rọ̀ Paulu ní Kolosse 3:12-14 sílò: “Ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣeun, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù, ìpamọ́ra; ẹ máa faradà á fún ara yin, ẹ sì máa dáríji ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: . . . ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tíí ṣe àmùrè ìwà pípé.”
Wíwàpapọ̀ Nínú Eré-Ìdárayá
15, 16. (a) Ànímọ́ wo ni ó níláti fi àwọn ìdílé Kristian hàn yàtọ̀ (b) Irú àwọn ènìyàn wo ni àwọn ìsìn kan ń mú jáde, èésìtiṣe?
15 Jehofa ni Ọlọrun aláyọ̀, òtítọ́ sì jẹ́ ìhìn-iṣẹ́ aláyọ̀ kan—ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ìrètí fún aráyé. Síwájú síi, ọ̀kan lára àwọn èso ti ẹ̀mí ni ayọ̀. Ayọ̀ yìí yàtọ̀ gédégédé sí ayọ̀-àṣeyọrí onígbà kúkúrú ti sárésáré kan tí ó ṣe àṣeyọrí nínú eré oníbàára-ẹni díje kan. Ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀ tí a ní ni ó ń kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọkàn-àyà gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí mímú ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jehofa. Ayọ̀ tí a gbékarí ìníyelórí tẹ̀mí àti ipò-ìbátan tí ń gbéniró ni.—Galatia 5:22; 1 Timoteu 1:11.
16 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bíi Kristian Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, a kò ní ìdí láti wúgbọ tàbí jẹ́ adájú-gbáú. Awọn ìsìn kan ń mú àwọn ènìyàn bí ìyẹn jáde nítorí pé lódìlódì ni wọ́n máa ń gba nǹkan tiwọn gbọ́ sí. Awọn ẹ̀kọ́ wọn ń yọrísí ìjọsìn oníkàárísọ, aláìláyọ̀, tí kò bá Bibeli mu tàbí wàdéédéé. Wọn kìí mú àwọn ìdílé aláyọ̀ tí wọ́n wà nínú iṣẹ-ìsìn Ọlọrun jáde. Jesu rí àìní náà fún ìnàjú àti ìtura. Lákòókò kan, fún àpẹẹrẹ, ó késí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti lọ sí ‘ibi ijù ní apákan, kí wọ́n sì sinmi díẹ̀.’—Marku 6:30-32; Orin Dafidi 126:1-3; Jeremiah 30:18, 19.
17, 18. Ní àwọn ọ̀nà yíyẹ wo ni àwọn ìdílé Kristian kan lè gbà ṣeré ìtura?
17 Àwọn ìdílé bákan náà gẹ́gẹ́ nílò àkókò láti gbádùn ìtura. Òbí kan sọ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “A ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun gbígbádùnmọ́ni papọ̀—lọ sí etíkun, gbá bọ́ọ̀lù nínú ọgbà ìtura, ṣètò ìjáde ìgbafẹ́ lọ sí àwọn òkè ńlá. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ń ní ‘ọjọ́ aṣáájú-ọ̀nà’ papọ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́; lẹ́yìn naa a ó ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú oúnjẹ àkànṣe kan, a sì lè fún ẹnìkínní kejì ní ẹ̀bùn pàápàá.”
18 Àwọn ìdámọ̀ràn mìíràn tí àwọn òbí lè gbéyẹ̀wò ni ìṣèbẹ̀wò ìdílé sí ọgbà ẹranko, lọ sí àwọn ọgbà ìṣeré àwọn ọmọdé, sí ilé àkójọ-ohun-ìṣẹ̀m̀báyé, àti sí àwọn ibi fífanimọ́ra mìíràn. Rírìn nínú ìgbẹ́, wíwo àwọn ẹyẹ, àti ṣíṣọgbà jẹ́ àwọn ìgbòkègbodò tí a lè fi tìgbádùn-tìgbádùn ṣàjọpín nínú wọn. Awọn òbí tún lè fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ láti lo ohun-èèlò orin tàbí lọ́wọ́ nínú eré ọwọ́dilẹ̀ gbígbéṣẹ́ kan. Dájúdájú, àwọn òbí tí wọ́n wàdéédéé yóò wá àkókò láti bá àwọn ọmọ wọn ṣeré. Bí àwọn ìdílé bá ń ṣeré papọ̀, ó ṣeéṣe jùlọ fún wọn láti túbọ̀ wà papọ̀!
19. Ìtẹ̀sí òde-òní wo ni ó lè wu ìdílé léwu?
19 Ìtẹ̀sí gbogbogbòò òde-òní ni pé kí àwọn ọ̀dọ́langba fẹ́ láti yàsọ́tọ̀ kúrò nínú ìdílé kí wọ́n sì ṣe ohun tí ó wà lọ́kàn wọn nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ìgbafàájì. Nígbà tí kò sí ohun tí ó burú nínú kí ọ̀dọ́ ènìyàn kan ṣe eré-bọ́wọ́dilẹ̀ tàbí eré ìgbà àìrí-nǹkan-ṣèkan tí a dá yàn láàyò, kò ní bá ọgbọ́n mu láti jẹ́ kí irú ọkàn-ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ dá ìyàsọ́tọ̀ wíwà títílọ kúrò lára ìdílé yòókù. Kàkà bẹ́ẹ̀, a fẹ́ láti fi ìlànà tí Paulu sọ sílò pé: “Kí olúkúlùkù yin kí ó máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣùgbọ́n olúkúlùkù ohun ti ẹlòmíràn.”—Filippi 2:4.
20. Báwo ni àwọn àpéjọ àti àwọn àpéjọpọ̀ ṣe lè jẹ́ àkókò aláyọ̀?
20 Ó ti ń fún gbogbo wa láyọ̀ tó láti rí àwọn ìdílé tí wọn ń jókòó papọ̀ ní àwọn àpéjọpọ̀ àti àpéjọ! Ní ọ̀nà yẹn àwọn ọmọ tí wọ́n dàgbà jù lè máa ran àwọn àbúrò wọn lọ́wọ́. Irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ tún ń gba àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ lọ́wọ́ ìtẹ̀sí láti kórajọpọ̀ lọ jókòó sọ́wọ́ ẹ̀yìn kí wọ́n sì fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ ní àfiyèsí tí kò tó nǹkan. Àní lílọ àti bíbọ̀ láti àwọn àpéjọ pàápàá lè jẹ́ aláyọ̀ nígbà tí a bá bi ìdílé nípa ojú-ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà, àwọn ibi tí a ó bẹ̀wò lójú ọ̀nà, àti ibi tí a ó dé sí. Ronú àkókò aláyọ̀ kan tí ó gbọdọ̀ ti jẹ́ ní ọjọ́ Jesu fún àwọn ìdílé láti rìnrìn-àjò papọ̀ lọ sí Jerusalemu!—Luku 2:41, 42.
Àwọn Ìbùkún Wíwàpapọ̀
21. (a) Báwo ni a ṣe lè làkàkà fún ìkẹ́sẹjárí nínú ìgbéyàwó? (b) Kí ni àwọn ìdámọ̀ràn rere mẹ́rin fún ìgbéyàwó tí ó wà pẹ́títí?
21 Àwọn ìgbéyàwó tí ó kẹ́sẹjárí àti àwọn ìdílé tí ó wà ní ìṣọ̀kan kò tíì fìgbà kan rọrùn láti ní, wọn kìí sìi dédé ṣẹlẹ̀. Ó dàbí pé àwọn kan rí i bí ohun tí ó rọrùn láti ‘dáwọ́ ìsapá èyíkéyìí dúró,’ tú ìdè ìgbéyàwó náà nínú ìkọ̀sílẹ̀, kí wọ́n sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi. Síbẹ̀, àwọn ìṣòro kan-náà ni ó sábà máa ń gbé araawọn kalẹ̀ nínú ìgbéyàwó kejì tàbí ẹ̀kẹta. Ìdáhùn tí ó fi púpọ̀ púpọ̀ dára jù ni ti Kristian: Làkàkà fún ìkẹ́sẹjárí nípa fífi àwọn ìlànà Bibeli ti ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ sílò. Àwọn ìdílé tí wọn sopọ̀ṣọ̀kan sinmi lórí ẹ̀mí fífọwọ́-wẹwọ́, àìmọtara-ẹni-nìkan. Olùgbaninímọ̀ràn ìgbéyàwó kan fúnni ní ìlànà àwòṣiṣẹ́ rírọrùn kan tí yóò mú kí ìgbéyàwó wà pẹ́títí. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn kókó ṣíṣepàtàkì mẹ́rin tí a ń rí nínú èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìgbéyàwó rere ni ìmúratán láti fetísílẹ̀, agbára-ìṣe náà láti tọrọ àforíjì, agbára láti pèsè ìtìlẹ́yìn ti èrò-ìmọ̀lára tí ó ṣọ̀kan délẹ̀, àti ìfẹ́-ọkàn náà láti fọwọ́kanni lọ́nà ìfẹ́ni.” Irú àwọn kókó wọ̀nyẹn lè ṣèrànwọ́ nítòótọ́ láti mú kí ìgbéyàwó kan wà pẹ́títí nítorí pé a tún gbé wọn karí àwọn ìlànà Bibeli tí ó yèkooro.—1 Korinti 13:1-8; Efesu 5:33; Jakọbu 1:19.
22. Kí ni àwọn àǹfààní díẹ̀ tí ń wá láti inú níní ìdílé tí ó sopọ̀ṣọ̀kan?
22 Bí a bá tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bibeli, àwa yóò ní ìpìlẹ̀ lílágbára fún ìdílé tí ó sopọ̀ṣọ̀kan, àwọn ìdílé tí ó sopọ̀ṣọ̀kan sì ni ìpìlẹ̀ fún ìjọ tí ó sopọ̀ṣọ̀kan tí ó sì lágbára nípa tẹ̀mí. Nípa báyìí, àwa yóò gba àwọn ìbùkún púpọ̀ yanturu láti ọ̀dọ̀ Jehofa bí a ti ń fi ìṣọ̀kan fi ìyìn tí a mú pọ̀ síi fún un.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Ìdílé wá láti inú ọ̀rọ̀ L[atin] náà familia, tí ó jẹ́ àwọn ìráńṣẹ́ àti àwọn ẹrú ilé ńlá kan ní ì[pìlẹ̀], lẹ́yìn náà ó jẹ́ ilé náà fúnraarẹ̀ tí ó ní ọ̀gá-kùnrin, ọ̀gá-bìnrin kan, àwọn ọmọ—àti àwọn òṣìṣẹ́.”—Origins—A Short Etymological Dictionary of Modern English, láti ọwọ́ Eric Partridge.
Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
◻ Èéṣe tí ó fi ṣàǹfààní fún àwọn ìdílé láti ṣe àwọn nǹkan papọ̀?
◻ Èéṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé déédéé fi pọndandan?
◻ Èéṣe tí ó fi dára fún àwọn òbí láti kópa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn?
◻ Èéṣe tí ó fi ṣèrànwọ́ láti jíròrò àwọn ìṣòro láàárín agbo ìdílé?
◻ Èéṣe tí ìdílé Kristian kò fi níláti jẹ́ èyí tí ó wúgbọ tí ó sì jẹ́ aláìláyọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìdílé rẹ ha ń gbádùn ó kérétán oúnjẹ kan papọ̀ lóòjọ́ bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn ìjádelọ ìdílé níláti jẹ́ èyí tí ń tunilára tí ó sì gbádùnmọ́ni