Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Jèrè Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè
1 Aposteli Paulu ṣàlàyé pé ó jẹ́ ‘ìfẹ́-inú Ọlọrun pé kí gbogbo onírúurú ènìyàn wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.’ (1 Tim. 2:4) Báwo ní a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ yẹn sínú? Ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ti ru ọkàn-ìfẹ́ wọn sókè jẹ́ ọ̀nà kan. Ìtẹ̀jáde yìí gbé òtítọ́ Bibeli kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kedere, tí ó rọrùn, tí a sì ṣà yàn dáradára. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, a lè sin onírúurú ènìyàn lọ sí ìyè. Kí ni a lè sọ láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú wa?
2 Fún àwọn tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́, o lè padà lọ láti fí ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ wọ́n, bóyá ní sísọ pé:
◼ “Nígbà tí mo kọ́kọ́ wá síbí, a jíròrò ìdí tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli gẹ́gẹ́ bí orísun ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́. Nítorí pé Ọlọrun ni ó mí sí i, Bibeli tún jẹ́ orísun dídájú fún ìtùnú àti ìrètí, àní gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn aposteli Kristi ti sọ. [Ka Romu 15:4.] Ní òpin ìjíròrò wa àkọ́kọ́, mo béèrè ìbéèrè náà pé, Báwo ni àwa fúnra wa ṣe lè jàǹfààní láti inú ìmọ̀ tí ó wà nínú Bibeli?” Ka ìpínrọ̀ 18, ní ojú ìwé 11, nínú ìwé Ìmọ̀. Ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó tó mílíọ̀nù márùn-ún kárí ayé, ní ríran àwọn ènìyàn níbi gbogbo lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun sínú. Ṣe àṣefihàn kúkúrú lórí bí a ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́, ní lílo ìpínrọ̀ márùn-ún àkọ́kọ́ ní orí 1.
3 Bí ó bá jẹ́ pé àdúrà ni àkòrí ọ̀rọ̀ tí o bá ẹnì kan jíròrò lákọ̀ọ́kọ́, o lè gbìyànjú ìyọsíni yìí nínú ìsapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́:
◼ “Mo lérò pé o gbádùn ìsọfúnni nípa àdúrà tí a jíròrò láti inú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Mo ṣèlérí láti padà wá láti bá ọ jíròrò, bí àwọn tí ń gbàdúrà sí Ọlọrun ṣe lè fetí sílẹ̀ sí i pẹ̀lú. Kíyè sí ohun tí a sọ ní ojú ìwé 158. [Ka ìpínrọ̀ 18.] Nípa báyìí, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fúnra ẹni, a ń fetí sí ohun tí Ọlọrun ní í sọ fún wa. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń fà wá sún mọ́ ọn, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti dojú kọ àwọn ìṣòro ojoojúmọ́ tí a tìtorí rẹ̀ gbàdúrà. Inú mi yóò dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ.” Bí ẹni náà bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, bẹ̀rẹ̀ orí kìíní ìwé Ìmọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
4 Bí o bá lo ìyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹni tí ó gba ìwé, o lè sọ èyí láti máa bá ìjíròrò àkọ́kọ́ nìṣó:
◼ “Mo ṣe àkànṣe ìsapá láti tún bẹ̀ ọ́ wò, nítorí pé mo fẹ́ sọ fún ọ sí i nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ọ̀fẹ́ tí a ń ṣe. Mo fi ẹ̀dá kan ìwé yìí, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí a ń lò láti fi bá àwọn ènìyàn kẹ́kọ̀ọ́, sílẹ̀ fún ọ. Kíyè sí bí ó ti fún wa níṣìírí láti gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yẹ̀ wò. [Ka ìpínrọ̀ 23 ní ojú ìwé 22.] Bí ìwọ yóò bá jọ̀wọ́ mú ẹ̀dà ìwé tìrẹ, bóyá yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nìṣó níbi tí a dúró sí ní ìjọ́sí.” Bí ẹ kò bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà ìkésíni àkọ́kọ́, o lè sọ pé: “Bóyá èyí yóò jẹ́ àkókò dáradára kan fún mi láti fi bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli hàn.” Lẹ́yìn tí o bá ti gbé ìpínrọ̀ díẹ̀ yẹ̀ wò, ṣètò àkókò pàtó kan láti padà wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí yóò tẹ̀ lé e.
5 Lílo ìwé Ìmọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ yóò mú kí a lè tan ìmọ̀ pípéye kálẹ̀ fún ìbùkún àwọn ẹlòmíràn. (Owe 15:7) Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò mú ìdùnnú wa fún àwọn tí ó ní ọkàn títọ́, yóò sí jẹ́ ìsúnniṣe alágbára fún wọn láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òdodo Jehofa, tí yóò sìn wọ́n lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.