ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 5/1 ojú ìwé 3-4
  • A Ha Nilo Bibeli Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ha Nilo Bibeli Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Aṣelámèyítọ́ ati Oníyèméjì
  • Aini kan fun Itọsọna
  • Yíyàn-Keji Kanṣoṣo Naa
  • Níbo Ni Ìwọ Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Ṣeé Gbáralé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ohun tó wà nínú ìwé yìí: Ṣé Bíbélì Lè Mú Káyé Ẹ Dáa Sí I?
    Jí!—2019
  • Bibeli—Atọ́nà Gbigbeṣẹ kan fun Eniyan Ode-oni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ṣé Wàá Bá Ọlọ́run Rìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 5/1 ojú ìwé 3-4

A Ha Nilo Bibeli Bi?

OXANA, ọdọmọbinrin ará Russia kan, layọ gidigidi nigba ti ó gán-án-ní Bibeli ti ontawe lẹgbẹẹ títì ni Moscow nawọ rẹ̀ si i. Ẹnikeji rẹ̀, John, ti o wá lati orilẹ-ede kan nibi ti Bibeli ti wà larọọwọto fàlàlà, ni ìtara-ọkàn Oxana mu orí rẹ̀ wú. “Emi—aláìgba-Ọlọrun-gbọ́ kan—fẹ́ lati rà á fun un,” ni ó jẹ́wọ́. Bi o tilẹ jẹ pe Oxana kò kọ́kọ́ gbà, lẹhin-ọ-rẹhin o tẹwọgba ẹ̀bùn John.

Gẹgẹ bi Oxana, ọpọlọpọ ní ìfẹ́-ọkàn ti ń bonimọlẹ lati ni Bibeli kan lọwọ. Eyi ni o tilẹ jẹ́ otitọ ni pataki ni awọn orilẹ-ede nibi ti a ti tẹ̀ ẹ́ rì fun ọpọlọpọ ọdun. Awọn ontẹwe iwe-irohin yii, fun apẹẹrẹ, ń ṣiṣẹ kárakára lati lé ibeere fun Bibeli pupọ sii bá ni ibi ti o jẹ́ Soviet orilẹ-ede alailọba tẹlẹri naa, ati pẹlu ni awọn apa ibomiran ninu ayé. Fun ìgbà akọkọ, ọpọ eniyan ni awọn agbegbe wọnyi ní anfaani lati ṣe ayẹwo ti o yẹ nipa Bibeli—ti a sì fa ọpọlọpọ eniyan mọra ihin-iṣẹ rẹ̀ lilagbara.

Awọn Aṣelámèyítọ́ ati Oníyèméjì

Ni odikeji ẹ̀wẹ̀, o ṣe kedere pe ni iha ariwa Europe, Bibeli ni a kìí kà, ṣugbọn ti a ń fi silẹ lori pẹpẹ ikoweesi nibi ti eruku yoo ti bò ó. “Òkú ìtàn!” ni awọn kan sọ, ni fifikun un pe, “Sanmani miiran ni a kọ ọ́ fun. Kò ni ohunkohun iṣe pẹlu eniyan ode-oni.” Ani awọn gbajumọ alufaa ṣọọṣi paapaa ti sọ awọn ọ̀rọ̀ ti o tàbùkù si Bibeli ní gbangba. Biṣọọbu àgbà ti Anglican Desmond Tutu ni a rohin ninu The Star, iwe-irohin South Africa kan, gẹgẹ bi ẹni ti ó sọ pe: “Awọn apakan Bibeli wà ti kò ni iniyelori ti o wà pẹtiti.” Awọn ọ̀rọ̀ bi iru iwọnyi ti mu ki ọpọlọpọ ṣe kayeefi nipa bawo ni awọn ṣe lè fi ọwọ́ pataki mu Bibeli tó.

Aini kan fun Itọsọna

Awọn aṣelámèyítọ́ ati awọn onigbagbọ bakan naa gbọdọ gbà pe, ju ti igbakigba ri lọ, ayé nilo ojutuu ti o gbeṣẹ. “Ayafi ti eniyan bá tete kẹkọọ lati dari iwọn iyipada ninu awọn ọ̀ràn ti ara-ẹni rẹ̀ ati pẹlu ninu ẹgbẹ́ awujọ lapapọ,” ni Alvin Toffler kọ ninu iwe rẹ̀ Future Shock, “a o ṣagbako ibi iwolulẹ . . . kíkọyọyọ.” Ikilọ yẹn ni a fifunni ni eyi ti o ju nǹkan bii 20 ọdun lọ. Iwolulẹ tí Toffler sọrọ nipa rẹ̀ jọbi ẹni pe o ń ṣẹlẹ nisinsinyi gan an.

Bi ọrundun yii ti ń sunmọ ipari rẹ̀, awọn idagbasoke ọgbọn-iṣẹ-ẹrọ ati aba-ero-ori eniyan ti kuna lati mú ki idurodeede ayé wà. Awọn ifojusọna lọ́ọ́lọ́ọ́ yii fun eto ayé titun kan ni ijanikulẹ ti rọ́pò, ti igbesi-aye ọpọlọpọ kò si kọja ijakadi ojoojumọ fun lilaaja.

Isọfunni oniṣiro fihàn pe ààlà iṣunna-owo laaarin awọn ọlọ́rọ̀ ati awọn otoṣi ti di ọ̀gbun nla kan. Ikẹkọọ lọwọlọwọ kan fihàn pe ipin 82.7 ninu ọgọrun-un ọrọ̀ ayé ni o wà pelemọ lọwọ kiki ipin 20 ninu ọgọrun-un awọn eniyan ti ń gbé inu rẹ̀. O ha yanilẹnu nigba naa pe ogun, ìyàn, àrùn, jagidijagan, ati rudurudu gbilẹ ni ọpọlọpọ orilẹ-ede bi? Ikimọlẹ lati koju ijojulowo igbesi-aye tí ń yìnrìn ń fa masunmawo ti o ga lori ero-imọlara awọn eniyan. Gẹgẹ bi abajade, àní paapaa ẹ̀ka ipilẹ ti ẹgbẹ́ awujọ eniyan paapaa, idile, ń jiya ibajẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ, bii Toffler, dabaa pe o jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ eniyan lati “ṣawari awọn ọ̀nà titun latokedelẹ lati lè fi ẹsẹ araarẹ̀ mulẹ,” ẹ̀rí naa fihàn pe kò ṣeeṣe fun awọn eniyan lati fi ọwọ́ araawọn wá ojutuu.

Yíyàn-Keji Kanṣoṣo Naa

Bibeli Mimọ, eyi ti kíkọ rẹ̀ bẹrẹ ni nǹkan bii 3,500 ọdun sẹhin, kò tii yipada la awọn ọrundun kọja. Awọn ilana rẹ̀ ṣì wà bakan naa. Fun apẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ inu Jeremiah 10:23 ni a ti fihàn pe o jẹ́ otitọ lonii ju ti igbakigba tẹlẹri lọ: “Ọ̀nà eniyan kò si ni ipa araarẹ̀: kò si ni ipa eniyan ti ń rìn, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.” Bi kò ba ṣeeṣe fun awọn eniyan lati dari ipa-ọna wọn, ta ni o lè ṣe é? Bibeli ṣalaye Orisun itọsọna tootọ kanṣoṣo pe: “Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹni ti o tọ́ ọ ni ọ̀nà ti iwọ ìbá maa lọ.”—Isaiah 48:17.

Nipasẹ awọn oju-iwe Bibeli, Jehofa Ọlọrun ń kọ́ wa lati ran araawa lọwọ. Wọn kún fun imọran ti ń fi ọ̀nà ti a gbọdọ maa tọ̀ hàn wá. Itọni rẹ̀ jẹ eyi ti o ṣe pataki lonii gẹgẹ bii ti ìgbà ti a kọ ọ́. Ọrọ-ẹkọ ti o tẹlee yii yoo ṣagbeyẹwo ìgbéṣẹ́ Bibeli fun sanmani igbalode wa. Ninu oniruuru awọn ọ̀ràn, lati ori ilera si ọrọ̀, igbesi-aye idile, ati iwa ẹnikọọkan, yoo ṣeeṣe fun ọ lati rii pe Bibeli niti gidi jẹ́ àpáta idurodeede lori iyanrin alaidurosojukan ti ayé ode-oni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bibeli jẹ́ ìdákọ̀ró idurodeede ninu ayé onírúgúdù ode-oni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́