Ìfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́ Ilẹ̀kùn Ṣíṣísílẹ̀ Kan sí Ìgbòkègbodò Ìṣàkóso Ọlọ́run Ha Ni bí?
ÌFẸ̀YÌNTÌ lẹ́nu iṣẹ́—fún ọ̀pọ̀, ó ń fòpin sí másùnmáwo àti ìmúnibínú. Lẹ́yìn tí ìgbòkègbodò tí ń tánni lókun tàbí tí ń mẹ́mìí gbóná ti dè wọ́n mọ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ máa ń wọ̀nà fún ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀kùn sí àwọn ọdún ìdẹ̀ra àti òmìnira ara ẹni. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, bí ó ti sábà máa ń rí, ilẹ̀kùn yẹn máa ń ṣamọ̀nà sí kí ìgbésí ayé máa súni àti kí nǹkan má fani lọ́kàn mọ́ra mọ́. Eré ìtura àti àwọn ìgbòkègbodò àfipawọ́ kì í wulẹ̀ pèsè ìmọ̀lára iyì ara ẹni tí iṣẹ́ ń pèsè.
Ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ lè ṣí “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò.” (Kọ́ríńtì Kìíní 16:9) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ogbó ní àwọn ìṣòro àti ààlà tirẹ̀, àwọn àgbàlagbà kan ti rí i pé pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, wọ́n lè mú iṣẹ́ ìsìn wọn sí i pọ̀ si. Gbé ìrírí àwọn Kristẹni àgbàlagbà mélòó kan ní Netherlands yẹ̀ wò. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1995, 269 lára èyí tí ó ju 1,223 àwọn aṣáájú ọ̀nà (àwọn alákòókò kíkún olùpòkìkí Ìjọba) jẹ́ ẹni ọdún 50 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lára àwọn wọ̀nyí, àwọn 81 jẹ́ ẹni ọdún 65 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ṣe aṣáájú ọ̀nà nípa wíwulẹ̀ máa bá ipa ọ̀nà dídí fọ́fọ́ tí wọ́n ti gbé kalẹ̀ nígbà tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ nìṣó. (Fi wé Fílípì 3:16.) Kristẹni kan tí ó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Karel rántí pé: “Nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi, mo máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní agogo 7:30 òwúrọ̀. Nígbà ti mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ mi, mo pinnu láti máa bá ipa ọ̀nà ìṣiṣẹ́ déédéé kan náà nìṣó. Mo ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nípa ṣíṣe ìjẹ́rìí òpópónà pẹ̀lú ìwé ìròyìn ní iwájú ibùdó ọkọ̀ ojú irin láràárọ̀ ní agogo méje.”
Ìwéwèé àfẹ̀sọ̀ṣe tún jẹ́ kọ́kọ́rọ́ kan sí àṣeyọrí. (Òwe 21:5) Fún àpẹẹrẹ, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan láti tọ́jú owó tí ó tó pamọ́ láti ṣètìlẹ́yìn fún wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Àwọn mìíràn ti pinnu láti dín ìnáwó ara ẹni kù kí wọ́n sì wá iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ ṣe. Gbé ọ̀ràn Theodore àti Ann yẹ̀ wò. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lọ́kọláya gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà títí tí ẹrù ìdílé fi béèrè pé kí wọ́n dá ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà dúró. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà wọn ṣì wà láàyè síbẹ̀! Bí àwọn ọmọbìnrin wọn ti ń dàgbà, a fún wọn níṣìírí láti ìgbà dé ìgbà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ní pàtàkì jù lọ, Theodore àti Ann fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, ní sísábà ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bí àwọn ọmọdébìnrin náà ti ń dàgbà, Theodore àti Ann bẹ̀rẹ̀ sí í dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù kí wọ́n baà lè ní àkókò sí i fún iṣẹ́ ìsìn pápá.
Lẹ́yìn tí àwọn ọmọbìnrin wọ́n wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí wọ́n sì fi ilé sílẹ̀, Ann bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ní ọjọ́ kan, ó fún Theodore níṣìírí láti fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ó dámọ̀ràn pé: “Àwa méjèèjì lè ṣe aṣáájú ọ̀nà.” Theodore sọ ìpinnu rẹ̀ fún agbanisíṣẹ́ rẹ̀. Sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, ọ̀gá rẹ̀ nawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí i nípa fífún un ní àbọ̀ọ̀ṣẹ́, ní sísọ pé: “Mo ronú pé o fẹ́ ṣiṣẹ́ alákòókò kíkún fún ọ̀gá rẹ tí ń bẹ lókè lọ́hùn-ún [lókè ọ̀run].” Nísinsìnyí, Theodore àti Ann ń gbádùn ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà pọ̀.
Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìhùwàpadà sí àwọn àyíká ipò tí ó jẹ yọ nínú ìgbésí ayé wọn. Ikú oníbànújẹ́ ti ọmọbìnrin àti ọmọ ọmọbìnrin wọ́n mú kí àwọn tọkọtaya àgbàlagbà kan ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀nà tí wọn yóò gbà lo àwọn ọdún wọn tí ó ṣẹ́ kù. (Oníwàásù 7:2) Dípò jíjẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, tí wọ́n ti gbádùn nísinsìnyí fún ohun tí ó ju ọdún mẹ́jọ lọ!
Láìṣeé sẹ́, ó gba ìpinnu gan-an láti wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Fún àpẹẹrẹ, Ernst àti aya rẹ̀, Riek, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà gbàrà tí àwọn ọmọ wọ́n fi ilé sílẹ̀. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà, oníṣòwò ẹlẹgbẹ́ Ernst tẹ́lẹ̀rí nawọ́ iṣẹ́ olówó gọbọi sí i. Ernst fèsì pé: “A ti ní agbanisíṣẹ́ tí ó dára jù lọ, a kò sì fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀!” Nítorí pé Ernst àti aya rẹ̀ ń bá a nìṣó nínú “iṣẹ́” Jèhófà, àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míràn ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n ṣiṣẹ́ sìn nínú iṣẹ́ àyíká fún ohun tí ó ju 20 ọdún, wọ́n sì ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà dòní olónìí. Wọ́n ha kábàámọ̀ ipa ọ̀nà onífara-ẹni-rúbọ wọn bí? Ní àkókò kan láìpẹ́ sẹ́yìn, tọkọtaya náà kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, ní oṣù mẹ́ta sí i, a fojú sọ́nà láti ṣayẹyẹ 50 ọdún ìgbéyàwó wa, tí a sábà ń pè ní àjọ̀dún oníwúrà. Ṣùgbọ́n, a sọ pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé ọdún oníwúrà wa gan-án bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà.”
Ọ̀pọ̀ rí i pé ọ̀nà náà tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò tí ó pọ̀ sí i tún ń ṣamọ̀nà sí ìdùnnú tí ó pọ̀ sí i! Arákùnrin kan tí ó bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí ó di ẹni ọdún 65 sọ pé: “Mo gbọ́dọ̀ sọ pé n kò tí ì nírìíri sáà kan nínú ìgbésí ayé mi tí ó kún fún ìbùkún jìngbìnnì bíi ti ọdún mẹ́wàá tí ó kọjá ti ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà.” Tọkọtaya kan tí wọ́n ti ṣe aṣáájú ọ̀nà fún èyí tí ó ju ọdún méje lọ sọ pé: “Kí ni ohun mìíràn tí ó tún yẹ kí tọkọtaya tí ó wà ní ọjọ́ orí tiwa àti àyíká ipò tiwa máa ṣe? A sábà máa ń rí irú wa ní agbègbè ìpínlẹ̀ wa—tí wọ́n á jókòó sínú ilé pẹ̀sẹ̀, tí wọ́n á ṣáà máa tóbi, tí wọ́n ti darúgbó, tí wọn á sì máa ṣe kẹ̀jẹ́kẹ̀jẹ́. Iṣẹ́ ìsìn ń mú kí a lera ní ti èrò orí àti ní ti ara. A máa ń wà pọ̀ ṣáá ni. A máa ń rẹ́rìn-ín gan-an, a sì ń gbádùn ìgbésí ayé.”
Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe gbogbo àgbàlagbà ni ipò àyíká wọ́n gbà wọ́n láyè láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Àwọn Kristẹni wọ̀nyí lè ní ìdánilójú pé Jèhófà mọrírì ohunkóhun tí wọ́n bá lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Fi wé Máàkù 12:41-44.) Fún àpẹẹrẹ, arábìnrin aláàbọ̀ ara kan ń gbé ní ilé ìtọ́jú aláìsàn. Ṣùgbọ́n, ilẹ̀kùn ìgbòkègbodò ṣì ṣí sílẹ̀ fún un síbẹ̀! Dókítà kan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó ṣe ń lo àkókò rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo sọ fún un pé àkókò kò tilẹ̀ tó fún mi. Kò lóye èyí. Mo sọ fún un pé, èyí jẹ́ nítorí pé àwọn àkókò mí kún fún àwọn ìgbòkègbodò tí ń tẹ́ni lọ́rùn. N kò dánìkan wà, ṣùgbọ́n mo ń wá àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n dá nìkan wà kiri, mo sì ń gbìyànjú láti sọ ohun tí Ọlọ́run ní ní ìpamọ́ fún aráyé fún wọn.” Ó ṣàkópọ̀ ọ̀ràn náà nípa sísọ pé: “Ẹnì kan kò lè béèrè púpọ̀ jù lọ́dọ̀ ẹni tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 80 ọdún. Gbàdúrà fún mi kí ń baà lè ṣamọ̀nà púpọ̀ sí i wá sọ́dọ̀ Jèhófà.”
Ìwọ́ ha wà ní ọjọ́ orí ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ bí? Ilẹ̀kùn sí ìdẹ̀ra lè fani mọ́ra, ṣùgbọ́n kì í ṣe ilẹ̀kùn sí ìbùkún tẹ̀mí. Fi tàdúrà tàdúrà ronú lórí ipò àyíká rẹ. Ó lè ṣeé ṣe pé kí o lè tọ ojú ọ̀nà náà tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ lè ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́