Ìfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́—Ǹjẹ́ Ó Ṣí Àǹfààní Sílẹ̀ fún Ìgbòkègbodò Púpọ̀ Sí I?
1 Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekára ló ń yán hànhàn fún ìgbà táwọn á fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ káwọn lè bọ́ lọ́wọ́ wàhálà àti kòókòó-jàn-ánjàn-án iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ni ìfẹ̀yìntì máa ń mú kí gbogbo nǹkan súni ó sì ń fa dídarúgbó ọ̀sán gangan. Bí ẹnì kan ò bá ní nǹkan tó ṣe gúnmọ́ tó ń ṣe, èyí lè mú onítọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn ṣáá nípa ara rẹ̀. Ìwé ìròyìn Brazil kan ròyìn pé àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ní àwọn ìṣòro bí ‘àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, kíkanra, àìní ìfọ̀kànbalẹ̀, àìdára ẹni lójú, ìdààmú ọkàn, tó sì máa wá dà bí ẹni pé ayé àwọn ti dojú rú.’
2 Ní ọwọ́ kejì, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni wo ìfẹ̀yìntì gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan tó ṣí sílẹ̀ fún ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i nípa tẹ̀mí. Arákùnrin kan tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ọ̀sẹ̀ kejì tó pé ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta sọ pé: “Mi ò tíì nírú ìbùkún tó pọ̀ tó èyí tí mo ní láàárín ọdún mẹ́wàá tí mo ti lò nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà rí nínú ìgbésí ayé mi.” Tọkọtaya kan kọ̀wé pé: “Àwọn ọdún tí ìgbésí ayé wa lárinrin jù lọ gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà ni ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ ti rí i pé àǹfààní ńláǹlà ni ìfẹ̀yìntì jẹ́ fáwọn láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i, kí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà.
3 Mímú Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Kí O sì Máa Méso Jáde: Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ni wọn ò tọ́ dàgbà pẹ̀lú àwọn nǹkan amáyédẹrùn tó wọ́pọ̀ lóde ìwòyí, láti kékeré ni wọ́n sì ti kọ́ bí a ṣe ń tẹpá mọ́ṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lókun bíi tìgbà ọ̀dọ́, òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ kára ṣì ni wọ́n. Ní ìpínlẹ̀ ẹ̀ka iléeṣẹ́ kan, nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọn jẹ́ aṣáájú ọ̀nà—ìyẹn ìpín méjìlélógún nínú ọgọ́rùn ún—ló jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún ó kéré tán. Ipa táwọn àgbàlagbà wọ̀nyí ń kó nínú iṣẹ́ ìwàásù náà kì í ṣe kékeré. Ìrírí wọn àtàwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí wọ́n ní ń ṣe àwọn ìjọ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ sìn láǹfààní gan-an.—Ják. 3:17, 18.
4 Mímú kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ń jẹ́ kí ara wa lé, ó sì ń mú kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i. Arábìnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin kan tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nígbà tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ sọ pé: “Kíkọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fìfẹ́ hàn sí Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́ ń mú kí ọpọlọ mi máa jí pépé. Mi ò ní mọ́tò, nítorí náà mo máa ń fẹsẹ̀ rìn gan-an. Ìyẹn sì ń jẹ́ kára mi máa le koko.” Tọkọtaya àgbàlagbà kan sọ pé: “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń mú ká ní ọpọlọ tó jí pépé kí ara wa sì le. A máa ń wà pa pọ̀ nígbà gbogbo. A máa ń rẹ́rìn ín gan-an, a sì ń gbádùn ayé wa.”
5 Sísìn Níbi Tí Àìní Wà: Àwọn Kristẹni kan tó rí já jẹ tí wọ́n sì ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ti ṣí lọ síbi tí àìní fún àwọn oníwàásù Ìjọba náà ti gbé pọ̀. Àwọn mìíràn ti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i nípa sísìn láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì. Gẹ́gẹ́ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwọn akéde onítara wọ̀nyí “ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí [wọ́n] lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”—1 Kọ́r. 9:23.
6 Tọkọtaya kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n ti tọ́ àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì dàgbà. Lẹ́yìn ọdún bíi mélòó kan tí wọ́n ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè àwọn ará Ṣáínà. Nísinsìnyí tí wọ́n ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún dáadáa, inú wọn dùn nígbà tí àwùjọ tí wọ́n ń bá ṣiṣẹ́ di ìjọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ìbùkún ńlá gbáà ni irúfẹ́ àwọn tọkọtaya wọ̀nyí mà jẹ́ o!
7 Kò Sí Ìfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ló ń fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, kò sí ìfẹ̀yìntì fún Kristẹni kankan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Gbogbo wọn ní láti máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó títí “dé òpin.” (Mát. 24:13, 14) Lóòótọ́, àwọn kan ò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, nítorí ara wọn ti ń dara àgbà. Àmọ́, ó mà múni lórí yá o, láti rí bí wọ́n ṣe ń fi tọkàntọkàn sa gbogbo ipá wọn! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà kì yóò gbàgbé iṣẹ́ wọn àti ìfẹ́ tí wọ́n ní fún orúkọ rẹ̀.—Lúùkù 21:1-4; Héb. 6:10.
8 Bó o bá ti ń sún mọ́ ọjọ́ orí tó o ti máa fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, o ò ṣe fi sínú àdúrà, kó o ronú nípa bó o ṣe lè lo ipò rẹ tó fẹ́ yí padà ní kíkún? Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, o lè wá rí i pé àkókò ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún ọ láti kópa nínú ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i èyí tí yóò mú ìyìn wá fún Jèhófà tí yóò sì mú kó o rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún.—Sm. 148:12, 13.
Ìfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́—