ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 2/22 ojú ìwé 17-19
  • Ohun Tí Ó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Irọ́ Pípa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Ó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Irọ́ Pípa
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Irọ́ Àkọ́kọ́
  • Àwọn Àbáyọrí Aṣekúpani
  • Àṣà Tí Ó Ti Fìdí Múlẹ̀
  • Irọ́ Tí Ó Wà Nínú Ìsìn Lónìí
  • Àìní Láti Wà Lójúfò
  • Mímú Ìdúró Ní Ìhà Òtítọ́
  • Eeṣe Ti Ó Fi Rọrùn Tobẹẹ Lati Purọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Máa Sọ Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • A Sọ Párádísè Nù
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Ibo Làwọn Òkú Wà?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 2/22 ojú ìwé 17-19

Ohun Tí Ó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Irọ́ Pípa

“ÒPÙRỌ́ burúkú!” Ẹnì kan ha ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ń tani lára wọ̀nyẹn sí ọ rí bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò síyèméjì pé o mọ ipa búburú tí wọ́n ń ní lórí ìmọ̀lára.

Lọ́nà kan náà tí àgé òdòdó kan lè gbà fọ́ yángá bí o bá là á mọ́lẹ̀ ni ìbátan oníyebíye kan lè gbà rún jégé nítorí irọ́ pípa. Òtítọ́ ni pé bí ọjọ́ bá gorí ọjọ́, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣàtúnṣe ìbàjẹ́ náà, àmọ́ ipò ìbátan náà lè máà rí bákan náà mọ́ láé.

Ìwé náà, Lying—Moral Choice in Public and Private Life, sọ pé: “Àwọn tí wọ́n já irọ́ tí a pa fún wọn máa ń ṣọ́ra fún wíwọnú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ẹni náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Wọ́n sì tún máa ń sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn ìgbàgbọ́ àti ìgbésẹ̀ wọn àtẹ̀yìnwá látàrí irọ́ tí wọ́n já náà.” Lẹ́yìn tí àṣírí ẹ̀tàn náà bá ti tú, ìfura àti iyèméjì lè fún ipò ìbátan kan tí ó ti fìgbà kan ṣe jọ́mújọ́mú pẹ̀lú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀léni fàlàlà pa.

Pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀lára òdì tí ó rọ̀ mọ́ irọ́ pípa, a gbọ́dọ̀ béèrè pé, ‘Báwo ni irú àṣà békebèke bẹ́ẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀?’

Irọ́ Àkọ́kọ́

Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run ṣẹ̀dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sí ibùgbé ọgbà ẹlẹ́wà kan. Ibùgbé wọn kò ní ẹ̀tàn tàbí jìbìtì èyíkéyìí nínú. Párádísè gbáà ni!

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lákòókò kan lẹ́yìn tí a dá Éfà, Sátánì Èṣù tọ̀ ọ́ lọ, ó sì fi ìdẹwò kan lọ̀ ọ́. Ó wí fún Éfà pé bí ó bá jẹ “èso igi” tí Ọlọ́run kà léèwọ̀, kì yóò kú gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ pé yóò kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò ‘dà bí Ọlọ́run, yóò mọ rere àti búburú.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:1-5) Éfà gba Sátánì gbọ́. Ó já èso náà, ó jẹ ẹ́, ó sì fún ọkọ rẹ̀ nínú rẹ̀. Àmọ́ dípò kí wọ́n dà bí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Sátánì ti ṣèlérí, Ádámù àti Éfà di aláìgbọ́ràn ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹrú ìdíbàjẹ́. (Pétérù Kejì 2:19) Nípa pípa irọ́ àkọ́kọ́, Sátánì di “bàbá gbogbo irọ́.” (Jòhánù 8:44, Today’s English Version) Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí wá mọ̀ pé irọ́ pípa kì í ṣe òpùrọ́ àti ẹni tí ń gba irọ́ gbọ́ láǹfààní.

Àwọn Àbáyọrí Aṣekúpani

Jèhófà fẹ́ kí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀—ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé—mọ̀ pé, mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọ́ràn yóò mú ìjìyà lọ́wọ́. Ó gbégbèésẹ̀ láìjáfara nípa dídájọ́ fún ọlọ́tẹ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí náà láti gbé ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ lóde ètò àjọ mímọ́ ti Ọlọ́run. Ní àfikún sí i, bó pẹ́ bó yá, Jèhófà Ọlọ́run yóò rí i pé òun pa Sátánì run pátápátá. Èyí yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí “irú ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí láti mú wá bá fọ́ ọ lórí.—Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15; Gálátíà 3:16.

Ní ti Ádámù àti Éfà, a lé wọn kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Ọlọ́run dájọ́ fún Ádámù, ní wíwí pé: “Ní òógùn ojú rẹ ni ìwọ óò máa jẹun, títí ìwọ óò fi pa dà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ sá ni ìwọ, ìwọ óò sì pa dà di erùpẹ̀.” Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, òun àti Éfà kú, bí Ọlọ́run ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.

Gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù, a ti ‘ta’ gbogbo ìdílé ẹ̀dá ènìyàn “sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.” Gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ti jogún àìpé tí ń yọrí sí ikú. (Róòmù 5:12; 6:23; 7:14) Ẹ wo bí ìyọrísí irọ́ àkọ́kọ́ yẹn ti jẹ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó!—Róòmù 8:22.

Àṣà Tí Ó Ti Fìdí Múlẹ̀

Níwọ̀n bí a kò tí ì pa Sátánì àti àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé wọ́n ń sún àwọn ènìyàn láti “purọ́.” (Tímótì Kíní 4:1-3) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, irọ́ pípa ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Ìwé agbéròyìnjáde Los Angeles Times sọ pé: “A ti fìdí irọ́ pípa múlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ àwùjọ gan-an débi pé ọkàn ẹgbẹ́ àwùjọ ti yigbì sí i.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ń so irọ́ pípa mọ́ ìṣèlú àti àwọn òṣèlú, àmọ́ ìwọ ha mọ̀ pé àwọn aṣáájú ìsìn wà lára àwọn tí a mọ̀ sí ògbógi jù lọ nídìí irọ́ pípa bí?

Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, àwọn onísìn tí ń ṣòdì sí i tan irọ́ kálẹ̀ nípa rẹ̀. (Jòhánù 8:48, 54, 55) Ó fi wọ́n bú ní gbangba, ní wíwí pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́ ọkàn bàbá yín. . . . Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òun jẹ́ òpùrọ́ àti bàbá irọ́.”—Jòhánù 8:44.

Ǹjẹ́ o rántí irọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tàn kálẹ̀ nígbà tí wọ́n rí i tí sàréè Jésù ṣófo lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀? Bíbélì sọ pé, àwọn olórí àlùfáà “fún àwọn ọmọ ogun náà ní iye àwọn ẹyọ fàdákà tí ó pọ̀ tó, wọ́n sì wí pé: ‘Ẹ wí pé, “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá ní òru, wọ́n sì jí i gbé nígbà tí a ń sùn.”’” Wọ́n tan irọ́ yìí dé ibi púpọ̀ jọjọ, wọ́n sì fi tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ. Ẹ wo bí àwọn aṣáájú ìsìn náà ṣe ya olubi tó!—Mátíù 28:11-15.

Irọ́ Tí Ó Wà Nínú Ìsìn Lónìí

Kí ni lájorí irọ́ tí àwọn aṣáájú ìsìn máa ń pa lónìí? Ó jọ èyí tí Sátánì pa fún Éfà pé: “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4) Àmọ́ Éfà kú, ó sì pa dà sínú ilẹ̀, ó pa dà di erùpẹ̀ tí a fi dá a.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ha wulẹ̀ fara hàn pé ó ti kú, kí ó sì máa wà láàyè lọ ní ara mìíràn ni bí? Ikú ha wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà àbáwọlé sí ìwàláàyè míràn ni bí? Bíbélì kò sọ pé apá kan tí kò kú lára Éfà ń wà láàyè nìṣó. Ọkàn rẹ̀ kò là á já. Nítorí pé ó ṣàìgbọ́ràn sí Ọlọ́run, ó ti dẹ́sẹ̀, Bíbélì sì wí pé: “Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, òun óò kú.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4) A ṣẹ̀dá Éfà ní alààyè ọkàn, bíi ti ọkọ rẹ̀, ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alààyè ọkàn sì ṣíwọ́ iṣẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Bíbélì sọ nípa ipò tí àwọn òkú wà pé: “Àwọn òkú kò mọ ohun kan.” (Oníwàásù 9:5) Síbẹ̀síbẹ̀, kí ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sábà máa ń fi kọ́ni?

Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sábà máa ń kọ́ni pé ẹ̀dá ènìyàn ní ọkàn tí kò lè kú àti pé ikú ń tú u sílẹ̀ láti lọ lo ìgbésí ayé mìíràn—yálà ti ayọ̀ kíkún tàbí ti ìdálóró. Fún àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì ń fìtẹnumọ́ kọ́ni pé ìrora hẹ́ẹ̀lì jẹ́ ti ayérayé, gẹ́gẹ́ bíi kókó ìgbàgbọ́ tí ẹnikẹ́ni kò lè sẹ́ tàbí pè níjà láìsí àdámọ̀ tí ó hàn gbangba.”—Ìdìpọ̀ 7, ojú ìwé 209, ẹ̀dà ti 1913.

Ẹ wo bí ẹ̀kọ́ yẹn ṣe yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ ní kedere tó! Bíbélì kọ́ni pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, “ó pa dà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.” (Orin Dáfídì 146:4) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, òkú kò lè jẹ̀rora, nítorí wọn kò mọ ohunkóhun. Nítorí náà, Bíbélì rọni pé: “Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ rí ní ṣíṣe, fi agbára rẹ ṣe é; nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà òkú, níbi tí ìwọ ń rè.”—Oníwàásù 9:10.

Àìní Láti Wà Lójúfò

Bí irọ́ tí àwọn àlùfáà ọjọ́ Jésù pa ṣe ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà tó ni ewu dídi ẹni tí àwọn ẹ̀kọ́ èké ti àwọn aṣáájú ìsìn lónìí tàn jẹ ṣe wà. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti “fi irọ́ ṣe pàṣípààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run,” wọ́n sì gbé irú àwọn ẹ̀kọ́ èké bí àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, àti èrò náà pé a óò dá ọkàn àwọn ẹ̀dá ènìyàn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì kan lárugẹ.—Róòmù 1:25.

Ní àfikún sí i, àwọn ìsìn òde òní sábà máa ń gbé ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àti ọgbọ́n èrò orí ẹ̀dá ènìyàn sí ìpele kan náà pẹ̀lú òtítọ́ Bíbélì. (Kólósè 2:8) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òfin Ọlọ́run nípa ìwà rere—títí kan àwọn òfin nípa àìlábòsí àti ìwà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀—ni wọ́n wò bí èyí tí ó láàlà, tí kì í ṣe pátápátá. Àbáyọrí rẹ̀ bá àpèjúwe inú ìwé ìròyìn Time mu pé: “Irọ́ pípa máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú àìdájú àjọṣepọ̀ ẹ̀dá, nígbà tí àwọn ènìyàn kò bá lóye, tàbí fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ìlànà tí ń ṣàkóso ìhùwà wọn sí ẹnì kejì wọn mọ́.”—Fi wé Aísáyà 59:14, 15; Jeremáyà 9:5.

Gbígbé ní àyíká ibi tí a kò ti ka òtítọ́ sí tó bẹ́ẹ̀ ń mú kí ó ṣòro láti kọbi ara sí ìṣílétí tí Ọlọ́run fún wa láti má ṣe purọ́. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo?

Mímú Ìdúró Ní Ìhà Òtítọ́

Ìfẹ́ ọkàn wa láti yin Ẹlẹ́dàá wa lógo ń fún wa ní ìsúnniṣe dídára jù lọ láti sọ sísọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ dàṣà. Ní pàtàkì, Bíbélì pè é ní “Ọlọ́run òtítọ́.” (Orin Dáfídì 31:5) Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa láti tẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, tí ó kórìíra “ètè èké,” lọ́rùn, yóò ru wá sókè láti fara wé e. (Òwe 6:17) Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí?

Fífi taratara kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè fún wa ní okun láti ‘máa sọ òtítọ́ olúkúlùkù pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀.’ (Éfésù 4:25) Bí ó ti wù kí ó rí, wíwulẹ̀ mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa kò tó. Bíi ti ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú ayé lónìí, bí a kì í bá fìgbà gbogbo ní ìtẹ̀sí láti sọ òtítọ́, a óò ní láti sapá gidigidi láti ṣe bẹ́ẹ̀. A lè ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kí a má sì gba gbẹ̀rẹ́ fún ara wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.”—Kọ́ríńtì Kíní 9:27.

Àfikún ìrànwọ́ kan nínú ìlàkàkà láti máa sọ òtítọ́ ní gbogbo ìgbà ni àdúrà. Nípa bíbẹ Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, a lè ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:7) Ní tòótọ́, níní “ètè òtítọ́,” kí a sì yẹra fún “ahọ́n èké” lè jẹ́ ìjàkadì gidi. (Òwe 12:19) Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè ṣàṣeparí rẹ̀.—Fílípì 4:13.

Máa rántí nígbà gbogbo pé Sátánì Èṣù ní ń jẹ́ kí ó máa jọ pé irọ́ pípa bójú mu. Ó tan obìnrin àkọ́kọ́, Éfà, jẹ, nípa fífi àránkàn parọ́ fún un. Bí ó ti wù kí ó rí, a mọ ìyọrísí àwọn ọ̀nà irọ́ Sátánì lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. A ti tú ìjìyà púpọ̀ rẹpẹtẹ dà sórí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn nítorí irọ́ onímọtara-ẹni-nìkan kan àti àwọn ẹ̀dá onímọtara-ẹni-nìkan mẹ́ta—Ádámù, Éfà, àti Sátánì.

Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa irọ́ pípa ni pé ó jọ májèlé aṣekúpani kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ṣọpẹ́ pé a lè ṣe nǹkan sí i. A lè jáwọ́ nínú àṣà irọ́ pípa, kí a sì gbádùn ojú rere Jèhófà, Ọlọ́run “tí ó pọ̀ ní oore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́” títí ayérayé.—Ẹ́kísódù 34:6.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Irọ́ pípa jọ májèlé aṣekúpani

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìyọrísí irọ́ pípa dà bí ìgbà tí a fọ́ àgé òdòdó kan yángá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́