Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
1 “[Ẹ] wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ afúnniníṣìírí gan-an lèyí jẹ́ fún gbogbo àwọn tó ń pa àṣẹ Jésù mọ́, ìyẹn àṣẹ tó pa pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa [sọni] di ọmọ ẹ̀yìn”! (Mát. 28:18–20) Ọ̀nà pàtàkì kan tí Jésù fi wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni tòótọ́ ni nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. (Mát. 13:36–43) Ká sòótọ́, ohun ìdùnnú gan-an ni pé à ń polongo “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí olóòótọ́ wọ̀nyí!—Ìṣí. 14:6, 7.
2 Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa: Bíbélì fi hàn pé a rán àwọn áńgẹ́lì jáde “láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà.” (Héb. 1:14) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn áńgẹ́lì ran àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá àwọn ẹni yíyẹ rí. (Ìṣe 8:26) Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣì ń rí ẹ̀rí pé àwọn áńgẹ́lì ń tọ́ wọn sọ́nà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn onílé ti sọ pé báwọn ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́ fún ìrànlọ́wọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí kan ilẹ̀kùn ilé àwọn. Dájúdájú, àwa àtàwọn áńgẹ́lì láyọ̀ gan-an pé àwọn èèyàn wọ̀nyí ń fetí sí ìhìn Ìjọba Ọlọ́run!—Lúùkù 15:10.
3 Nígbà Tá A Bá Dojú Kọ Àtakò: Dáníẹ́lì, àwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n ti fojú winá ìṣòro tó le koko ti rí i bí Jèhófà ṣe lo àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n “tóbi jọjọ nínú agbára” láti dáàbò bò wọ́n. (Sm. 103:20; Dán. 3:28; 6:21, 22; Ìṣe 12:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, a lè máa rò pé kò sí ìrànlọ́wọ́ nígbà tá a bá ń dojú kọ àtakò, ìrírí tí ìránṣẹ́ Èlíṣà ní nígbà tó mọ̀ pé “àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú [àwọn alátakò] lọ” lè fún wa níṣìírí. (2 Àwọn Ọba 6:15–17) Kódà bí wọ́n bá fipá mú wa kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará wa pàápàá, kò yẹ ká bọkàn jẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká.”—Sm. 34:7.
4 Láìpẹ́, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti fòpin sí gbogbo ohun tó bá ń ṣe àtakò sí ìjọba Kristi. (Ìṣí. 19:11, 14, 15) Bí a ṣe ń dúró de ọjọ́ náà, ẹ jẹ́ ká máa fi àìṣojo yin Jèhófà, ká sì ní ìgbọ́kànlé kíkún pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n wà lábẹ́ àṣẹ Kristi yóò tì wá lẹ́yìn gbágbáágbá.—1 Pét. 3:22.