Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 14
Orin 168
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù June sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (bó bá bá ìpínlẹ̀ yín mu) láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ June 15 lọni. Nínú àṣefihàn náà, kí akéde tó máa bójú tó o máa wàásù níbi táwọn èèyàn ti ń ṣòwò. Ẹ lè ṣe àṣefihàn mìíràn tó bá ipò àdúgbò yín mu láti fi ìwé ìròyìn lọni.
20 min: “Jèhófà Ń Ran Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé E Lọ́wọ́.”a Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fi àlàyé kún un látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2000, ojú ìwé 5, ìpínrọ̀ 14 àti 15, àti ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 67, ìpínrọ̀ 2.
15 min: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Yẹra fún Oògùn Olóró? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ojú ìwé 272 sí 281. Lílo oògùn olóró fún “fàájì” wọ́pọ̀ gan-an. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń rin kinkin pé lílo oògùn olóró lọ́nà yìí kò lè pani lára; àwọn kan tiẹ̀ ń ṣalágbàwí pé kí ìjọba fàṣẹ sí i. Ṣàlàyé bá a ṣe lè bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fèrò wérò.
Orin 179 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 21
Orin 29
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: “Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ràn Wá Lọ́wọ́.”b Bí àkókò bá ṣe wà sí, sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
20 min: Ọgbọ́n Tó Ti Òkè Wá Ń Fòye Báni Lò. (Ják. 3:17) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 251 àti 252. Kí ni jíjẹ́ afòyebánilò túmọ̀ sí? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù? Báwo làwọn akéde ṣe lè fi irú ẹni táwọn èèyàn jẹ́ látilẹ̀wá sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìjọ? Báwo la ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti jẹ́ afòyebánilò? Ṣètò pé kí ẹnì kan tàbí méjì sọ ìrírí wọn nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ afòyebánilò lóde ẹ̀rí.
Orin 53 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 28
Orin 139
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù June sílẹ̀. Lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (bí wọ́n bá bá ìpínlẹ̀ yín mu) láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! July 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ kí akéde tó máa bójú tó o sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ ní ṣókí kó tó bẹ̀rẹ̀. Sọ fún àwọn ará pé ṣíṣe èyí á jẹ́ kí ara tu àwọn tá a fẹ́ wàásù fún.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
18 min: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ—Ìdí Tí A Fi Nílò Rẹ̀.”c Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Fi àlàyé kún un látinú àpilẹ̀kọ náà, “Ṣètìlẹyìn fún Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Rẹ,” èyí tó wà ní ojú ìwé kìíní nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2002.
Orin 20 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 5
Orin 3
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Kí Lo Máa Sọ? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní oṣù July àti August, ìwé pẹlẹbẹ la ó fi lọ àwọn èèyàn. Àwọn ìwé pẹlẹbẹ wo làwọn akéde máa ń lò dáadáa ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín? Sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìgbékalẹ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1997, ní ojú ìwé 4; Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2003, ojú ìwé 8, tàbí látinú àwọn ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa mìíràn tó ti kọjá. Tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ohun mẹ́ta wọ̀nyí wà nínú ìgbékalẹ̀ kọ̀ọ̀kan: (1) ìbéèrè kan, (2) ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, àti (3) kókó pàtàkì kan téèyàn lè ṣàlàyé lé lórí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà. Ṣe àṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn ìgbékalẹ̀ náà. Rọ gbogbo àwọn ará láti máa lo Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń wàásù ìhìn rere.
20 min: Ohun Tó Yẹ Káwọn Òbí Ṣe fún Àwọn Ọmọ Wọn. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, ojú ìwé 6 àti 7. Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọdé mọ àwọn ìlànà Bíbélì tá a gbé ìjọsìn tòótọ́ kà, kí wọ́n sì lóye ipa pàtàkì tí àwọn òbí ń kó nínú kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àbá tí a dá nípa bá a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà. Béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí bí wọ́n ti ṣe ń lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí. Sọ pé kí ọmọdé kan tàbí méjì sọ ìdí tí wọ́n fi fẹ́ràn ìwé yìí.
Orin 65 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.