Ẹ Máa Ṣe Rere Kẹ́ Ẹ sì Máa Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́
1 Dọ́káàsì “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú [tó] ń fi fúnni.” (Ìṣe 9:36, 39) Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó ní ló mú kó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú àwọn tó mọ̀ ọ́n àti lójú Jèhófà Ọlọ́run. Hébérù 13:16 sọ pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” Báwo la ṣe lè ṣe rere ká sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lónìí?
2 Ọ̀nà kan táwọn ẹlòmíràn lè gbà jàǹfààní lára wa ni pé ká fi ‘àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí’ ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 3:9) Àwọn owó tá a fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé ló ń jẹ́ ká lè máa kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì káàkiri ayé. Ìwà ọ̀làwọ́ wa yìí sì ti jẹ́ kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jàǹfààní látinú ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa àti ìbákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró nípa tẹ̀mí.
3 Ẹ Máa Tù Wọ́n Nínú: Nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwa èèyàn Jèhófà kì í lọ́ra láti “ṣe ohun rere” fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa àtàwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwa. (Gál. 6:10) Nígbà tí ilé iṣẹ́ kan tó ń po kẹ́míkà gbiná lórílẹ̀-èdè Faransé, tọkọtaya kan tí wọ́n ń gbé nítòsí ilé iṣẹ́ yẹn sọ pé: “Lójú ẹsẹ̀ làwọn ará ti dé láti ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n palẹ̀ pàǹtírí tó wà nínú iyàrá wa àti iyàrá àwọn yòókù nínú ilé náà mọ́. Ńṣe làwọn tá a jọ ń gbé àdúgbò lanu sílẹ̀ tí wọn ò lè pa á dé nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá ràn wá lọ́wọ́.” Arábìnrin mìíràn fi kún un pé: “Àwọn alàgbà ò fi wá sílẹ̀. Wọ́n fún wa ní ìṣírí. Ìṣírí ọ̀hún gan-an lohun tá a nílò ju ohun ìní tara lọ.”
4 Òótọ́ ni pé ọ̀nà pọ̀ tá a lè gbà ṣe ohun rere fáwọn tá a jọ ń gbé àdúgbò, àmọ́, ọ̀nà tó ṣàǹfààní jù lọ tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká fi ìmọ̀ òtítọ́ ṣíṣeyebíye kọ́ wọn. Lára ìmọ̀ òtítọ́ ọ̀hún ni “ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun” tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣèlérí. (Títù 1:1, 2) Àwọn tó ń kẹ́dùn nítorí ipò tí ayé yìí wà àti ipò ẹ̀ṣẹ̀ táwọn fúnra wọn wà máa ń rí ìtùnú tòótọ́ látinú ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì. (Mát. 5:4) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe rere ká sì máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nígbà tó bá wà ní agbára wa láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Òwe 3:27.