ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/05 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 4/05 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 11

Orin 4

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù April sílẹ̀. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ April 15 àti Jí! May 8 lọni. (Àbá kẹta ni kẹ́ ẹ lò láti fi Jí! May 8 lọni.) Ẹ lè lo àwọn ọ̀nà míì tó bá dára láti fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Ìwàásù òpópónà ni kí ẹ fi ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà ṣe.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

15 min: “Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù.”a Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a kọ síbẹ̀.

Orin 47 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 18

Orin 76

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kẹjọ.”b Ṣe àṣefihàn kúkúrú kan tó máa fi bí akéde kan ṣe fún ẹnì kan tí kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? Akéde náà fi àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20 han akẹ́kọ̀ọ́ náà ó sì ṣàlàyé ṣókí fún un nípa ìpàdé Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn. Ó sọ ẹṣin ọ̀rọ̀ Àsọyé tó máa tẹ̀ lé e ó sì sọ fún un pé kó wá sípàdé náà.

15 min: Ẹ Máa Lo Èrò Inú Tó Yè Kooro Nínú Ayé Táwọn Ẹ̀rọ Abánáṣiṣẹ́ Ti Gbòde Kan Yìí. (Títù 2:11, 12) Àsọyé tá a gbé ka Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2002, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 1 sí 7, àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1999, ojú ìwé 5, ìpínrọ̀ 24 sí 26, àti ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 35 àti 36. Bí àkókò bá ṣe wà sí, o tún lè mẹ́nu kan àwọn kókó mìíràn tó bá bá àdúgbò yín mu nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1999.

Orin 169 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 25

Orin 111

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lẹ́yìn ìròyìn ìnáwó, ka ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ọrẹ tá à ń ṣe. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù April sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Jí! May 8 lọni. (Àbá kẹrin ni kẹ́ ẹ lò láti fi Jí! May 8 lọni.) Ẹ lè lo àwọn ọ̀nà míì tó dára láti fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, jẹ́ kí àwọn ará mọ ohun tí wọ́n lè sọ bí ẹnì kan bá fẹ́ láti bẹ́gi dínà ìjíròrò nípa sísọ pé, “Emi kò nífẹ̀ẹ́ sí i.” (Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 8.) Mẹ́nu kan àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe káwọn èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.

30 min: “Àpéjọ Àgbègbè ‘Ìgbọràn sí Ọlọ́run’ ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2005.”c Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó o. Tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 2 tán, ka lẹ́tà April 1, 2005 tá a fi yan ìjọ yín sí àpéjọ àgbègbè tẹ́ ẹ máa lọ. Tẹ́ ẹ bá ń gbé ìpínrọ̀ 4 yẹ̀ wò, jíròrò gbogbo kókó tó wà nínú àwọn àpótí ojú ewé 4. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n tètè bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò bí wọ́n ṣe máa lọ sí àpéjọ náà.

Orin 79 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 2

Orin 148

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Ẹ Máa Ṣe Rere Kẹ́ Ẹ sì Máa Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́.”d Láti lè sọ bá a ṣe lè fi ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà sílò nínú ìjọ àti ní ìpínlẹ̀ ìjọ, mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.

20 min: Jíròrò Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun Náà Pẹ̀lú Àwọn Tó Fìfẹ́ Hàn. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Ó yẹ ká padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó gba ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọnà! ká sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Fi àwọn kókó ẹ̀kọ́ tá a fi lẹ́tà tó dúdú kirikiri kọ lójú ìwé 2 ṣàlàyé ṣókí nípa ohun tó wà nínú ìwé náà. Mẹ́nu kan àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a tò sábẹ́ àwọn kókó ẹ̀kọ́ náà. (Wàá rí i pé tó o bá ṣí ojú ìwé tí kókó ẹ̀kọ́ èyíkéyìí wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, àwọn ibi kan wà tá a kùn láwọ̀ tó yàtọ̀, ibẹ̀ la ti ṣàlàyé àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a tó sábẹ́ àwọn kókó ẹ̀kọ́ lójú ìwé 2.) A lè lo àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí láti bá onílé jíròrò ní ṣókí lọ́nà tó múná dóko nígbà tá a bá padà lọ bẹ̀ ẹ́ wò. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ojú ìwé 3 àti 4 la bá onílé jíròrò nígbà tá a kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tá a bá padà lọ, a lè bá a jíròrò ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run Tiẹ̀ Bìkítà Nípa Wa?” èyí tó wà lójú ìwé 5. Ṣàlàyé bá a ṣe lè ṣe ìjíròrò náà. Tún ṣàyẹ̀wò irú àwọn àpótí mìíràn bẹ́ẹ̀, irú bí àwọn tó wà lójú ìwé 6 sí 8 àtàwọn tó wà lójú ìwé 17 àti 18, tàbí àwọn mìíràn tó bá bá àdúgbò yín mu. Ṣe àṣefihàn ìpadàbẹ̀wò kan, kó o lo ọ̀kan lára àwọn àpótí náà. Kí akéde náà ka ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ síbẹ̀ kó sì jíròrò wọn. Ohun tí akéde náà fi parí àṣefihàn rẹ̀ ni pé ó sọ ẹṣin ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa jíròrò nígbà ìbẹ̀wò tó máa ṣe tẹ̀ lé e.

Orin 66 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́