Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ẹ Ṣọ́ra fún Ewu Tó Wà Níbẹ̀!
1 Àwa èèyàn Jèhófà jọ máa ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ gbígbámúṣé. A máa ń gbádùn sísọ àwọn ìrírí tí a ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá fúnra ẹni, a sì máa ń mọrírì gbígbọ́ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. A máa ń fẹ́ pé kí a fi ohunkóhun tó bá ṣàrà ọ̀tọ̀, tó bá ṣẹlẹ̀ sí àwọn arákùnrin wa tó wa létí, irú bíi rògbòdìyàn tàbí ìjábá tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, a sì máa ń fẹ́ láti mọ̀ bóyá ohun kan wà tí a lè ṣe láti ṣèrànwọ́. Irú ìdàníyàn bẹ́ẹ̀ ń fi ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará hàn, ó sì ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa ní tòótọ́.—Jòh. 13:34, 35.
2 Lóde òní, a tètè máa ń gbọ́ nípa àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Ìròyìn orí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n máa ń gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ jáde lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ fún gbogbo ayé bí wọ́n ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Tẹlifóònù tún mú kó ṣeé ṣe láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́gán kárí ayé. Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ nínú ayé báyìí ni a mọ̀ sí Íńtánẹ́ẹ̀tì (ọ̀nà táa ń gbà fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà).—Wo Jí!, July 22, 1997.
3 Ẹ̀rọ tẹlifóònù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ kárí ayé lọ́nà tó yára kánkán. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹlifóònù wúlò gidigidi, ó yẹ ká fìṣọ́ra lò ó nítorí ó lè jẹ́ irinṣẹ́ fún ìbákẹ́gbẹ́ tàbí ìgbòkègbodò tí kò tọ́, bí a bá sì lo tẹlifóònù jù, ó lè náni lówó gọbọi. Tẹlifíṣọ̀n àti rédíò lè ranni lọ́wọ́ bó bá dọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìwé. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn ní ń bá ìwà rere jẹ́, fífi àkókò ṣòfò ni yóò sì jẹ́ bí a bá ń jókòó tì wọ́n. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká ṣọ́ra gidigidi nígbà tí a bá ń lo tẹlifíṣọ̀n àti rédíò.
4 Íńtánẹ́ẹ̀tì ń mú kó ṣeé ṣe láti bá ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn èèyàn mìíràn sọ̀rọ̀ jákèjádò ayé lọ́nà tí kò fi bẹ́ẹ̀ náni lówó, ó sì ń jẹ́ kí a lè mọ ọ̀pọ̀ jaburata ìsọfúnni. (Jí!, January 8, 1998) Ṣùgbọ́n, lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì láìkíyèsára lè wuni léwu gidigidi nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere. Báwo lèyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?
5 Ọ̀pọ̀ máa ń fẹ́ mọ̀ nípa ìsọfúnni tí wọ́n lè tètè rí tó sọ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe àwọn ohun ìjà títí kan bọ́ǹbù. Inú àwọn iléeṣẹ́ ò dùn rárá sí àkókò táwọn òṣìṣẹ́ fi ń ṣòfò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì. A ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa nípa àwọn ewu tẹ̀mí tó hàn gbangba pé ó lè wu èèyàn nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ìwà ipa àti ìṣekúṣe tí kò yẹ rárá fún Kristẹni. (Sm. 119:37) Láfikún sí ewu wọ̀nyí, ewu fífarasin mìíràn tún wà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní pàtàkì gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún. Kí ni ewu yìí?
6 Ṣé wàá jẹ́ kí àjèjì kan wọ ilé rẹ láìkọ́kọ́ wádìí ẹni tó jẹ́? Bí kò bá sí ọ̀nà láti wádìí ńkọ́? Ṣé wàá jẹ́ kí àjèjì yẹn dá wà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ? Èyí lè ṣẹlẹ̀ dáadáa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
7 O lè fi lẹ́tà ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí àwọn èèyàn tí oò mọ̀, o sì lè rí lẹ́tà gbà láti ọ̀dọ̀ wọn. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí bí o bá ń bá àwọn èèyàn jíròrò lórí kọ̀ǹpútà tàbí kí o wọ ẹgbẹ́ àpérò orí kọ̀ǹpútà. Nígbà míì, àwọn tí ẹ jọ ń jíròrò lè sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Ẹnì kan lè sọ pé ọ̀dọ́ lòun tí á sì jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀dọ́. Ẹlòmíì sì rèé, ó lè parọ́ pọ́kùnrin lòun nígbà tí á sì jẹ́ pé obìnrin ni.
8 Ó ṣeé ṣe kẹ́ni yẹn sọ àwọn ìrírí tàbí kó ṣe àlàyé kan fún ẹ nípa àwọn ohun tí a gbà gbọ́. Ìwọ á wá sọ ohun tó sọ fún ẹ fún àwọn ẹlòmíì, àwọn náà á sì tún sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì. Bó ti sábà máa ń rí, kì í ṣeé ṣe láti wádìí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀, ó sì lè ṣàìjóòótọ́. Àlàyé yẹn lè jẹ́ ọ̀nà awúrúju láti gbà tan èrò apẹ̀yìndà kálẹ̀.—2 Tẹs. 2:1-3.
9 Pẹ̀lú ewu wọ̀nyí lọ́kàn, bí o bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Kí ni mo ń lò ó fún? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà tí mo ń gbà lò ó ṣèpalára fún mi nípa tẹ̀mí? Ṣé kì í ṣe pé ṣe ni mo ń lọ́wọ́ sí ṣíṣe àwọn ẹlòmíì léṣe nípa tẹ̀mí?’
10 Ibi Tí Àwọn “Ẹlẹ́rìí Jèhófà” Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì: Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ibi ìkósọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé kalẹ̀. Wọ́n á sọ pé kí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn láti ka àwọn ìrírí tí àwọn míì tó sọ pé Ẹlẹ́rìí làwọn fi ránṣẹ́. Wọ́n á fún ẹ níṣìírí pé kí o sọ èrò rẹ àti ojú ìwòye rẹ nípa àwọn ìwé Society. Àwọn kan máa ń dábàá àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a lè lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Àwọn ibi ìsọfúnni yẹn máa ń pèsè ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan lè lò, tí yóò jẹ́ kí ó lè bá àwọn ẹlòmíì jíròrò, bí ìgbà tí èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù. Wọ́n sábà máa ń sọ àwọn ibi ìsọfúnni mìíràn fún ọ tí o ti lè bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ kárí ayé. Ṣùgbọ́n ṣé ó dá ọ lójú pé kì í ṣe àwọn apẹ̀yìndà ló ń díbọ́n, tí wọ́n ń ṣètò ìjíròrò yìí?
11 Bíbá àwọn èèyàn kẹ́gbẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè máà sí ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí ó wà ní Éfésù 5:15-17. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú. Ní tìtorí èyí, ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”
12 Ìjọ Kristẹni ni ọ̀nà ìṣàkóso Ọlọ́run tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń gbà bọ́ wa nípa tẹ̀mí. (Mát. 24:45-47) Nínú ètò Ọlọ́run, a ń rí ìtọ́sọ́nà àti ààbò láti pa wá mọ́ kúrò nínú ayé, a sì ń gba ìṣírí láti máa ṣiṣẹ́ kára nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa. (1 Kọ́r. 15:58) Onísáàmù fi hàn pé òun máa ń láyọ̀, ọkàn òun sì máa ń balẹ̀ láàárín ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Sm. 27:4, 5; 55:14; 122:1) Ìjọ tún ń pèsè ìtìlẹ́yìn àti ìrànwọ́ tẹ̀mí fún àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ọn. Níbẹ̀, o lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa rẹ, tí wọ́n sì bìkítà nípa rẹ—àwọn èèyàn tí ìwọ fúnra rẹ mọ̀ tí wọ́n sì múra tán láti ṣèrànwọ́ kí wọ́n sì tu àwọn ẹlòmíì nínú lákòókò wàhálà. (2 Kọ́r. 7:5-7) Àṣẹ Ìwé Mímọ́ náà pé kí a yọ àwọn tó bá ń dá ẹ̀ṣẹ̀ láìronúpìwàdà tàbí tí wọ́n ń gbé èrò apẹ̀yìndà lárugẹ lẹ́gbẹ́ ń dáàbò bo àwọn mẹ́ńbà ìjọ. (1 Kọ́r. 5:9-13; Títù 3:10, 11) Ǹjẹ́ a lè retí pé a óò rí irú ìṣètò onífẹ̀ẹ́ yìí nígbà tí a bá ń bá àwọn ẹlòmíì kẹ́gbẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
13 Ó ti hàn gbangba pé kò lè rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ó hàn gbangba pé àwọn Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ ọ̀nà tí àwọn apẹ̀yìndà ń gbà ṣe ìgbékèéyíde wọn. Ó lè fara hàn lórí àwọn Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀, àwọn tó sì ń ṣonígbọ̀wọ́ ibi ìsọfúnni kan lè ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ làwọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tilẹ̀ lè béèrè àwọn ìsọfúnni kan lọ́wọ́ rẹ láti lè rí i dájú pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
14 Jèhófà fẹ́ kí o lo ìfòyemọ̀. Èé ṣe? Nítorí ó mọ̀ pé ìyẹn yóò dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ onírúurú ewu. Òwe 2:10-19 bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” Ṣọ́ ọ lọ́wọ́ kí ni? Yóò máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ àwọn nǹkan bí “ọ̀nà búburú,” àwọn tí ń fi ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán sílẹ̀, àti àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe àti oníbékebèke ní gbogbo ipa ọ̀nà wọn.
15 Nígbà tí a bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, kò sí iyèméjì pé àwọn ará wa la bá pé jọ. A mọ̀ wọ́n. Kò sẹ́ni tí ń béèrè pé kí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nítorí ìfẹ́ ará tí wọ́n ń fi hàn mú kí ìyẹn ṣe kedere. Kò sẹ́ni tí ń sọ pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa kó àwọn ìwé ẹ̀rí wá láti jẹ́rìí sí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá lóòótọ́. Ibẹ̀ gan-an la ti ń rí pàṣípààrọ̀ ìṣírí tòótọ́ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ nínú Hébérù 10:24, 25. A ò lè gbára lé Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, èyí tó fàyè gba ìbákẹ́gbẹ́ orí kọ̀ǹpútà, láti pèsè èyí fún wa. Fífi àwọn ọ̀rọ̀ Sáàmù 26:4, 5 sọ́kàn lè mú ká wà lójúfò sí àwọn ewu tó lè tètè wu wá nígbà tí a bá ń lo Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
16 Irú àwọn ìsọfúnni tí àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lè fi síbẹ̀ àti èyí tí wọ́n lè bá níbẹ̀ kò láàlà, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣeé ká lọ́wọ́ kò. Ó rọrùn gan-an láti tipasẹ̀ ibi ìsọfúnni yìí hùwà ọ̀daràn sáwọn ọmọdé, kí wọ́n sì kó wọn nífà. Àwọn ọmọdé máa ń gba nǹkan gbọ́, wọ́n máa ń ṣòfíntótó, wọ́n sì máa ń yánhànhàn láti ṣèwádìí nípa ayé onígbòkègbodò kọ̀ǹpútà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde. Nítorí náà, àwọn òbí gbọ́dọ̀ bójú tó àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tó jíire látinú Ìwé Mímọ́ lórí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì, àní bí wọn yóò ṣe bójú tó bí wọn yóò ṣe yan orin àti sinimá.—1 Kọ́r. 15:33.
17 Ó bani nínú jẹ́ pé, a ní láti yọ àwọn kan tí wọ́n fìgbà kan rí jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin wa lẹ́gbẹ́ nítorí ìbákẹ́gbẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ nípa pípàdé àwọn ẹni ayé ní ibi àpérò orí kọ̀ǹpútà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó sì wá yọrí sí ìṣekúṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Èyí tó tún wá bani lẹ́rù jù lọ ni pé, àwọn alàgbà ti kọ̀wé pé àwọn kan tilẹ̀ fi ọkọ tàbí aya wọn sílẹ̀ láti lọ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. (2 Tim. 3:6) Àwọn ẹlòmíì ti kọ òtítọ́ sílẹ̀ nítorí gbígba ohun tí àwọn apẹ̀yìndà sọ gbọ́. (1 Tím. 4:1, 2) Nítorí àwọn ewu ńláǹlà yìí, ǹjẹ́ kò dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu láti ṣọ́ra fún kíkópa nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Dájúdájú, lílo ọgbọ́n, ìmọ̀, agbára láti ronú, àti ìfòyemọ̀ tí Òwe 2:10-19 sọ yẹ kó ṣọ́ wa lọ́wọ́ èyí.
18 A ti ṣàkíyèsí pé àwọn kan wà tí wọ́n ṣètò Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nítorí àtimáa wàásù ìhìn rere. Àwọn ará tí ò lóye ló ń ṣagbátẹrù ọ̀pọ̀ nínú àwọn ibi ìsọfúnni yìí. Àwọn ibi ìsọfúnni mìíràn wà tó jẹ́ pé àwọn apẹ̀yìndà tó fẹ́ dẹkùn mú àwọn tí ò fura ló ń ṣonígbọ̀wọ́ wọn. (2 Jòh. 9-11) Nígbà tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1997, ojú ìwé 3, ń sọ̀rọ̀ lórí bóyá ó yẹ kí àwọn ará wa dá irú àwọn Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, ó sọ pé: “Kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni láti kọ ìsọfúnni nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ìgbòkègbodò wa, tàbí àwọn ohun tí a gbà gbọ́, fún lílò lórí Ìsọkọ́ra Alátagbà Internet. Ibi Ìsọkọ́ra tí a fàṣẹ sí [www.watchtower.org] pèsè ìsọfúnni tí ó péye fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ẹ.”
19 Àwọn Ọ̀nà Táa Lè Gbà Kẹ́kọ̀ọ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì Ńkọ́? Àwọn kan ti ronú pé àwọn ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ará nípa fífi àwọn ìsọfúnni tí wọ́n kó jọ, tó jẹ mọ́ onírúurú ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run ránṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè gbé ìwádìí rẹ̀ ka ìtòlẹ́sẹẹsẹ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, kí ó sì wá fi èyí ránṣẹ́, ní ríronú pé irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ yóò ṣàǹfààní fún àwọn tó bá fẹ́ sọ àsọyé kan náà. Àwọn mìíràn yóò fi gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ń bọ̀ lọ́nà ránṣẹ́ tàbí kí wọ́n pèsè àkójọ ọ̀rọ̀ tí a ti mú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ jáde. Àwọn kan lè dábàá àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a lè lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ gbọ́, ṣóòótọ́ ni irú nǹkan báwọ̀nyẹn ń ṣèrànwọ́?
20 Àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Jèhófà pèsè ń sún èrò inú wa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú èrò tí ń gbéni ró, wọ́n sì ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ “láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Ǹjẹ́ a lè sọ pé èyí rí bẹ́ẹ̀ bó bá jẹ́ pé àwọn ẹlòmíì ló ń ṣèwádìí fún wa?
21 A sọ pé àwọn Kristẹni tó wà ní Bèróà “ní ọkàn-rere ju àwọn ti Tẹsalóníkà lọ.” Èé ṣe? Nítorí pé “wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” (Ìṣe 17:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù àti Sílà wàásù fún wọn, wọn ò lè sọ òtítọ́ di tiwọn bí àwọn fúnra wọn ò bá gbé e yẹ̀ wò.
22 Lílo ìwádìí tí ẹlòmíì ṣe fún àsọyé tàbí láti fi múra ìpàdé mìíràn sílẹ̀ ní ti gidi fagi lé ìjẹ́pàtàkì ìdákẹ́kọ̀ọ́. Kì í ha í ṣe ohun tí o fẹ́ ni pé kí o gbé ìgbàgbọ́ ró nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Bí ìwọ fúnra rẹ̀ bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìgbà náà lo tó lè sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ ní gbangba—nípasẹ̀ àsọyé tí o bá sọ, nípa dídáhùn ní àwọn ìpàdé, àti nípa kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. (Róòmù 10:10) Lílo ìwádìí tí ẹlòmíì ṣe kò bá ohun tí a ṣàpèjúwe nínú Òwe 2:4, 5 mu pé kí a fúnra wa ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin.’
23 Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí o bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú Bíbélì tìẹ, o lè ṣàyẹ̀wò ráńpẹ́ nípa àyíká ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan. O lè ‘tọpasẹ̀ ohun gbogbo pẹ̀lú ìpéye,’ bí Lúùkù ti ṣe nígbà tó kọ ìwé Ìhìn Rere rẹ̀. (Lúùkù 1:3) Àfikún ìsapá tí o bá ṣe yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáńgájíá nínú ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti nígbà tí o bá ń sọ àsọyé. Ọ̀pọ̀ ti sọ pé àwọn gba ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí wọ́n mọ bí a ṣe ń lo Bíbélì. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí èyí lè gbà jóòótọ́ nínú ọ̀ràn tiwa ni nígbà tí olúkúlùkù wa bá sọ ọ́ dàṣà láti máa yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wò nínú Bíbélì tiwa.
24 Fífi Ọgbọ́n Lo Àkókò Wa: Ohun mìíràn tí a tún lè gbé yẹ̀ wò nípa ọ̀ràn yìí ní í ṣe pẹ̀lú iye àkókò tí a óò lò láti wá ìsọfúnni orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, láti kà á, àti láti fèsì sí i. Sáàmù 90:12 fún wa níṣìírí láti gbàdúrà pé: “Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.” Pọ́ọ̀lù wí pé: “Àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́r. 7:29) Ó tún sọ síwájú sí i pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—Gál. 6:10.
25 Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ń tẹnu mọ́ ọn pé kò yẹ ká máa fàkókò ṣòfò. Ó mà ń ṣàǹfààní o láti lo àkókò láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! (Sm. 1:1, 2) Ìyẹn ni ìbákẹ́gbẹ́ tó dára jù lọ tí a lè ní. (2 Tím. 3:16, 17) Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ ń kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ pé fífi ọgbọ́n lo àkókò wọn nínú ìgbòkègbodò Ìjọba náà wúlò gidigidi? (Oníw. 12:1) Àkókò tí a bá fi dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí tí a bá fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìdílé, tí a fi lọ sí ìpàdé, tí a sì lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá níye lórí gidigidi ju títú ìsọfúnni tí ń bẹ nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì yẹ̀ wò.
26 Lójú ìwòye èyí, ó jẹ́ ọ̀nà ọgbọ́n láti gbájú mọ́ àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí àti àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tí wọ́n sì ṣe kókó. Èyí ń béèrè pé kí a ronú gidigidi kí a tó yan àwọn ìsọfúnni tó yẹ kó gba àkókò wa àti èrò wa. Kristi ṣàkópọ̀ ohun tó jẹ mọ́ ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó wí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mát. 6:33) Àbí inú rẹ kì í dùn jọjọ nígbà tí o bá ń fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò Ìjọba náà dípò lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò mìíràn?
27 Fífi Lẹ́tà Ránṣẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣàjọpín ìrírí àti èrò ara ẹni pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ tí ibi tí wọ́n ń gbé jìnnà síni bójú mu, ǹjẹ́ ó fi ìfẹ́ hàn ní tòótọ́ láti sọ èyí fún àwọn ẹlòmíì tí wọ́n lè má mọ ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ? Tàbí ṣé ó yẹ ká fi eléyìí ránṣẹ́ sínú Ibi Tí A Ń Kó Ìsọfúnni Sí Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fún ẹnikẹ́ni láti kà á? Ǹjẹ́ ó yẹ kí a ṣe ẹ̀dà àwọn ìsọfúnni ara ẹni yìí kí a sì máa fi ránṣẹ́ sí gbogbo èèyàn tó ṣeé ṣe kí o mọ̀ tàbí kí o má mọ̀? Bákan náà, bí o bá rí ìhìn gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì tó sì ṣe kedere pé ìwọ kọ́ ló wà fún, ǹjẹ́ fífi wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíì fi ìfẹ́ hàn?
28 Ká ní ìrírí tí o sọ fún ẹlòmíì kò tọ̀nà ńkọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn ò ní jẹ́ pé o ń bá wọn tan irọ́ kálẹ̀? (Òwe 12:19; 21:28; 30:8; Kól. 3:9) Dájúdájú, ṣíṣọ́ra “lójú méjèèjì pé bí [a] ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n” yóò mú ká ronú lórí èyí. (Éfé. 5:15) Inú wá mà dùn o pé ìwé Yearbook, Ilé Ìṣọ́, àti Jí! kún fún àwọn ìrírí tòótọ́, tí ń fún wa níṣìírí, tó sì ń sún wa láti máa rìn ní ‘ọ̀nà náà’!—Aísá. 30:20, 21.
29 Ewu mìíràn tún wà níbẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn kan pé: “Wọ́n tún kọ́ láti jẹ́ olóòrayè, wọ́n ń rin ìrìn ìranù kiri lọ sí àwọn ilé; bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe aláìníṣẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n olófòófó pẹ̀lú àti alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” (1 Tím. 5:13) Ọ̀rọ̀ yìí kò ṣètìlẹyìn fún lílo àkókò àti sísapá láti fi ìsọfúnni tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ránṣẹ́ sí àwọn ará.
30 Tún ronú ná, nípa iye àkókò tí ṣíṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ jaburata ìsọfúnni tí a ti fi ránṣẹ́ nípasẹ̀ kọ̀ǹpútà yóò máa gbà. Ó dùn mọ́ni pé, ìwé náà, Data Smog, sọ pé: “Bí èèyàn bá ti ń lo àkókò lórí àkókò láti yẹ àwọn ìsọfúnni yìí wò, ìsọfúnni náà á wá yí padà kúrò ní ohun amóríyá tuntun kan, á wá di ẹrù iṣẹ́ tí ń gba àkókò, ọ̀pọ̀ ìsọfúnni téèyàn gbọ́dọ̀ kà, kí ó sì fèsì sí, la ó máa rí gbà lójoojúmọ́ ayé látọ̀dọ̀ àwọn alájọṣe, àwọn ọ̀rẹ́, ìdílé, . . . àti àwọn ìpolówó ọjà tí a ò béèrè fún.” Síwájú sí i, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti di agbọ́teku-rò-fẹ́yẹ nídìí ìsọfúnni orí kọ̀ǹpútà ti sọ àṣà búburú kan di bárakú, tí wọ́n á máa fi gbogbo ìsọfúnni amóríwú tí wọ́n bá rí gbà ránṣẹ́ sí gbogbo ẹni tó bá wà nínú àdírẹ́sì orí kọ̀ǹpútà wọn, ì báà jẹ́ àwàdà, ìtàn àròsọ dídùn mọ̀ràn-ìnmọran-in, àwọn lẹ́tà tí a ń bẹ èèyàn láti tún fi ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ èèyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
31 Èyí hàn gbangba nínú àwọn Lẹ́tà Orí Kọ̀ǹpútà tí a fi ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ àwọn ará—irú àwọn nǹkan bí àwàdà tàbí ìtàn apanilẹ́rìn-ín nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́; ewì tí àwọn kan sọ pé àwọn gbé ka àwọn ohun tí a gbà gbọ́; àpèjúwe láti inú onírúurú àsọyé tí wọ́n gbọ́ ní àwọn àpéjọ, àpéjọpọ̀, tàbí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba; àwọn ìrírí láti inú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—àwọn nǹkan tó dà bí ẹni pé kò léwu. Ọ̀pọ̀ ti sọ ọ́ dàṣà láti máa fi irú Lẹ́tà Orí Kọ̀ǹpútà bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíì láìṣàyẹ̀wò ibi tó ti wá, èyí máa ń mú kó ṣòro láti mọ ẹni tó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ gan-an, èyí sì lè mú kí èèyàn ṣe kàyéfì pé bóyá ni ìsọfúnni náà jóòótọ́.—Òwe 22:20, 21.
32 Irú àwọn ìsọfúnni tí kì í sábà ṣe pàtàkì yìí kì í ṣe irú àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé sí Tímótì pé: “Máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tí ìwọ gbọ́ lọ́dọ̀ mi mú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (2 Tím. 1:13) “Èdè mímọ́ gaara” ti òtítọ́ Ìwé Mímọ́ ní “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tí a gbé karí ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì ní pàtàkì, ìyẹn ni ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà nípasẹ̀ Ìjọba náà. (Sef. 3:9) Ó yẹ ká sapá gidigidi láti lo gbogbo àkókò àti agbára tí a bá ní láti ṣètìlẹyìn fún ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà yìí.
33 Níwọ̀n bí a ti rìn jìnnà ní àkókò òpin ètò àwọn nǹkan yìí, kì í ṣe àkókò tó yẹ ká dẹra sílẹ̀ nìyí. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8) Ó sọ síwájú sí i pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”—Éfé. 6:11.
34 Àṣìlò Íńtánẹ́ẹ̀tì lè jẹ́ ọ̀nà kan tí ọwọ́ Sátánì ń gbà tẹ àwọn tí agbára Íńtánẹ́ẹ̀tì bá ti mú níyè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wúlò títí dé àyè kan, ewu ń bẹ níbẹ̀ bí a kò bá ṣọ́ra. Àwọn òbí ní pàtàkì gbọ́dọ̀ ṣàníyàn nípa bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.
35 Níní ojú ìwòye tó tọ́ nípa Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ ààbò. A mọrírì ìránnilétí tó bọ́ sákòókò látọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù pé: “Kí . . . àwọn tí ń lo ayé [dà] bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́r. 7:29-31) Bí a bá fi nǹkan wọ̀nyí sọ́kàn, yóò gba àwa àti ìdílé wa lọ́wọ́ ìpínyà ọkàn tí ń wá nípasẹ̀ gbogbo ohun tí ayé yìí ń gbé jáde, títí kan ohun tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
36 Ó ṣe pàtàkì pé kí a sún mọ́ àwọn ará nínú ìjọ pẹ́kípẹ́kí kí a sì máa fi ọgbọ́n lo àkókò tó ṣẹ́ kù ní títipa báyìí yọ̀ǹda ara wa fún gbígbé àwọn ire Ìjọba náà lárugẹ. Bí ètò nǹkan yìí ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀, kí a “má ṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn,” ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a “máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”—Éfé. 4:17; 5:17.