Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2005
1 Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá ti ṣètò pé ká péjọ kóun lè kọ́ wa láwọn ọ̀nà Rẹ̀. (Aísá. 30:20, 21; 54:13) Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ló máa ń lò, ẹgbẹ́ yẹn ló sì máa ń ṣètò àwọn ìpàdé wa, irú bí àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. (Mát. 24:45-47) Bó ṣe rí lára wa gẹ́lẹ́ ni Dáfídì ṣe fi kọrin pé: “Inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.” (Sm. 26:12) Ó yé Dáfídì kedere bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn gbẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì pinnu láti máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbàkigbà tí wọ́n bá pé jọ.
2 Ṣé ìwọ náà á wà lára “ọ̀pọ̀ ènìyàn” tó máa lọ sí àpéjọ àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” tọdún yìí? Tó o bá máa lọ, àwọn ìtọ́ni yìí á wúlò fún ọ nígbà tó o bá ń múra sílẹ̀ láti lọ.
3 Bẹ̀rẹ̀ sí Múra Sílẹ̀ Kó O Lè Wà Níbẹ̀ Lọ́jọ́ Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Òwe 21:5) Ẹ ò rí i pé ńṣe lọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká tètè bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ ká lè lọ sí àpéjọ yẹn! Kí èyíkéyìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó ń tuni lára yìí má bàa fò ọ́ dá, ohun tó máa dáa ni pé kó o yáa bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbogbo ètò tó bá yẹ láti òní lọ kó o lè wà níbẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Bó bá jẹ́ pé o máa tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ ni, má fi falẹ̀ o. Tó bá sì jẹ́ pé o ṣì kọ́kọ́ máa bá ọkọ tàbí aya rẹ tí kì í ṣe Kristẹni sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ná ni, má ṣe dúró dìgbà tọ́jọ́ bá ti sún mọ́ tán kó o tó sọ fún un. Ohun yòówù kó fẹ́ dí ọ lọ́wọ́, gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀, sì jẹ́ kó dá ọ lójú pé ó máa fìdí “àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 16:3) Láfikún sí i, báwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ ṣe ń múra sílẹ̀ kí wọ́n lè wà níbẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ì bá dáa tó o bá lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
4 Ilé Gbígbé: Kó bàa lè rọrùn fún ọ, a ó ṣètò ibi tó o máa wọ̀ sí ní ìlú tá ó ti ṣe àpéjọ náà. Lọ́pọ̀ àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí, a ò ṣètò ilé gbígbé sínú ọgbà àpéjọ náà. Èyí lè jẹ́ ilé tá a kàn fẹ́ lò fún ìgbà díẹ̀ tàbí èyí tá a dìídì kọ́ káwọn ará lè máa ríbi dé sí. Jọ̀wọ́ fi sọ́kàn pé ètò Ọlọ́run ò lè kọ́lé tó máa gba gbogbo èèyàn tó bá wá sí àpéjọ kan. Kìkì àwọn tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí ló máa lè sùn sínú ilé tó bá wà ní ọgbà àpéjọ náà. Tí wọn ò bá fi ọ́ wọ̀ sínú ọgbà àpéjọ, jọ̀wọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, kó o sì wà níbi tí wọ́n fi ọ́ wọ̀ sí. Tó bá jẹ́ pé ṣe lo fẹ́ máa wọkọ̀ lọ wọkọ̀ bọ̀ sí ibi àpéjọ náà lójoojúmọ́, tún rántí pé ìnáwó kan nìyẹn náà. Nítorí náà, nígbà tó o bá ń tọ́jú owó tó o máa lò ní àpéjọ, ó ṣe pàtàkì kó o fìyẹn náà kún un. Kó o tó kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, gbé àwọn kókó tó wà nínú àpótí yìí yẹ̀ wò, ìyẹn “Bó O Ṣe Lè Ti Ìṣètò Ilé Gbígbé Lẹ́yìn.” Lẹ́yìn náà, kó o tẹ̀ lé àwọn ìgbésẹ̀ tó wà nínú àpótí tá a pè ní “Ọ̀nà Wo Ló Dára Jù Lọ Láti Rí Ilé Gbígbé?”
5 Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ará kan pé wọ́n jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún òun. (Kól. 4:7-11) Lára ọ̀nà tí wọ́n gbà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ ni bí wọ́n ṣe fún un láwọn nǹkan tó nílò. Báwo ni ìwọ alára ṣe lè jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” nígbà àpéjọ? Àwọn akéde tó ti dàgbà, àwọn aláìlera, àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àtàwọn mìíràn lè nílò ìrànlọ́wọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa wọkọ̀ lọ síbẹ̀ tàbí nípa ibi tí wọ́n máa dé sí. Ojúṣe mọ̀lẹ́bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni láti bójú tó wọn. (1 Tím. 5:4) Àmọ́, bí wọn ò bá wá lè ṣe é, ó ṣeé ṣe káwọn ará ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ják. 1:27) Kí alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ wo àwọn tó wà nínú àwùjọ rẹ̀ láti lè mọ àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, kó sì rí i pé ìṣètò wọn ti wà ní sẹpẹ́ ṣáájú àkókò àpéjọ àgbègbè náà.
6 Kìkì àwọn tó nílò àkànṣe ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n lè wà ní àpéjọ àgbègbè ni ètò yìí wà fún, pàápàá nípa ọ̀ràn ilé gbígbé. Wọ́n tún lè nílò ìrànwọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn, ó sinmi lórí ipò kálukú wọn. Àwọn akéde, àwọn aṣáájú ọ̀nà àwòfiṣàpẹẹrẹ àtàwọn ọmọ wọn tó mọ̀wàá hù, tí wọ́n nílò àkànṣe àbójútó nìkan ni ètò Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó wà fún, Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sì ní láti fọwọ́ sí i kí wọ́n tó lè rí ìrànwọ́ náà gbà. Ìjọ táwọn ẹni wọ̀nyí ń dara pọ̀ mọ́ ni kó ṣe àwọn ètò yòókù láti bójú tó wọn dípò tí wọ́n á fi ti ojúṣe yìí sí àwọn tí ń ṣètò àpéjọ àgbègbè lọ́rùn.
7 Lílọ sí Àpéjọ Mìíràn: Kí ìṣètò tá a ṣe nípa ìjókòó, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ibùgbé, àtàwọn nǹkan míì lè gún régé, à ń rọ àwọn ará láti lọ sí àpéjọ àgbègbè tá a yán ìjọ wọn sí. Ṣùgbọ́n bí o bá ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti lọ sí àpéjọ kan tó yàtọ̀ sí èyí tá a yan ìjọ rẹ sí, tó o sì ń fẹ́ ilé tó o máa dé sí, jọ̀wọ́ rí akọ̀wé ìjọ rẹ̀ kó lè fún ọ ní fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé. Fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ. Tó bá jẹ́ pé àpéjọ tí wọ́n á ṣe níbẹ̀ ju ẹyọ kan lọ, rí i pé o kọ déètì ọjọ́ àpéjọ àgbègbè tó o fẹ́ lọ sínú fọ́ọ̀mù náà.
8 A Nílò Àwọn Tó Lè Yọ̀ọ̀da Ara Wọn: Àpẹẹrẹ tó dára jù lọ ni Jésù fi lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè jẹ́ ẹni tó ń fara balẹ̀ láti lè mọ ohun táwọn ẹlòmíràn nílò. (Lúùkù 9:12-17; Jòh. 13:5, 14-16) Irú ẹ̀mí yẹn làwọn tó máa ń yọ̀ọ̀da ara wọn láwọn àpéjọ máa ń fi hàn. Ká lè rí àwọn tó máa ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka-iṣẹ́ àpéjọ, Ìgbìmọ̀ Àpéjọ máa tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sáwọn tó máa bá wọn ṣiṣẹ́. Pàápàá jù lọ, ó yẹ káwọn alàgbà yọ̀ọ̀da ara wọn kí wọ́n sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wọn. Àpẹẹrẹ tó dáa ló máa jẹ́ fún ìjọ, tí wọ́n bá yọ̀ọ̀da ara wọn tinútinú.—1 Pét. 5:2, 3.
9 Ohun Táwọn Ẹlòmíràn Kíyè Sí: Obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀gá àwọn òǹtajà ní òtẹ́ẹ̀lì kan sọ pé: “Kò tíì sáwọn èèyàn tó dà bíi tiyín. Ẹ ṣe ọmọlúwàbí púpọ̀púpọ̀ ju àwọn ẹlòmíì lọ. Àwọn obìnrin tó ń tún ilé ṣe ní òtẹ́ẹ̀lì sọ pé wọn ò fi ohunkóhun ni àwọn lára. Kódà, gbogbo wa la máa ń fẹ́ wá ṣiṣẹ́ lópin ọ̀sẹ̀ tẹ́ ẹ bá wà níbí!” Aṣojú òtẹ́ẹ̀lì mìíràn sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló rọrùn jù láti bá ṣiṣẹ́.” Ó ṣeé ṣe kí ìwà ọmọlúwàbí tìẹ náà ti pa kún oríyìn tá a gbọ́ yìí. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà á dùn gan–an pé à ń ṣe ohun tó ń buyìn kún un!—1 Pét. 2:12.
10 Jèhófà Ọlọ́run ti ṣètò báwọn èèyàn rẹ̀ ṣe máa pé jọ láti gba ìtọ́ni tẹ̀mí nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́” ní ìparí ọdún tá a wà yìí sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tó ń bọ̀. (Lúùkù 12:42) A mọ̀ pé ìsapá ló gbà láti lè lọ sí àpéjọ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, síbẹ̀, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó dájú pé Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” tọdún yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ dúró lórí ẹ̀jẹ́ wa láti sin Jèhófà nísinsìnyí àti títí ayérayé. Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó fi ìmọ̀ràn onísáàmù yìí sílò pé: “Ẹ fi ìbùkún fún Ọlọ́run nínú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.”—Sm. 68:26
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday àti Saturday
9:20 àárọ̀ sí 4:50 ìrọ̀lẹ́
Sunday
9:00 àárọ̀ sí 3:20 ọ̀sán
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Bó O Ṣe Lè Ti Ìṣètò Ilé Gbígbé Lẹ́yìn
◼ Jẹ́ kí ilé tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fi ọ́ sí tẹ́ ọ lọ́rùn. Má ṣe dé sínú ilé tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò fi ọ́ sí. Iye àwọn tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé fọwọ́ sí ni kẹ́ ẹ jọ wà nínú ilé náà.
◼ Má ṣe dé ibi tí ẹni tó ni ilé tí wọ́n bá fi ẹ́ wọ̀ sí ò bá fẹ́ kó o dé. Bí onílé bá sọ pé òun ò fẹ́ kó o dáná, má ṣe dáná o, tó bá gbà pé o lè dáná, ibi tó bá lóun fẹ́ ni kó o ti dáná.
◼ Rí i pé o tètè fi fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ìyẹn ló máa jẹ́ kí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé lè ní àsìkò tó pọ̀ tó láti wá ilé tó bójú mu fún ọ.
◼ Jẹ́ kí ìsọfúnni tó o máa kọ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé ṣe kedere.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ọ̀nà Wo Ló Dára Jù Lọ Láti Rí Ilé Gbígbé?
1. Gba fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ rẹ.
2. Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà lásìkò. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o kọ ìsọfúnni náà lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́, ìyẹn ìsọfúnni bí orúkọ, ọjọ́ orí rẹ, bóyá o jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin àti bóyá aṣáájú ọ̀nà ni ọ́ tàbí akéde ìjọ.
3. Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé ìsọfúnni inú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé péye kó sì fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní ìlú tí àpéjọ náà yóò ti wáyé. MÁ ṢE FI RÁNṢẸ́ SÍ Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ O. Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kó pẹ́ kó tó dọ́wọ́ Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé tó bá jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ kọ́kọ́ fi ránṣẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arákùnrin kan fi fọ́ọ̀mù ránṣẹ́ láti Èkó lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé kí wọ́n fi ránṣẹ́ padà sí Èkó. Ó máa mú kó yá, á sì tún rọrùn tó bá jẹ́ pé Gbọ̀ngàn àpéjọ kan tó bá wà ní àgbègbè Èkó lẹ fi ránṣẹ́ sí dípò ẹ̀ka ọ́fíìsì.
4. Má ṣe sọ fún onílé pé wàá san owó tó pọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé san lọ nítorí kó o lè rí ilé gbà.
5. Nígbà tó o bá ń ṣètò ilé tó o má wọ̀ sí fúnra rẹ, dákun kọ́kọ́ wádìí lọ́dọ̀ Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kó má lọ jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti gbà ni ìwọ náà tún fẹ́ gbà.