Apá Kẹjọ: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bá A Ṣe Lè Máa Darí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Sínú Ètò Ọlọ́run
1. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé kó o máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ohun kan nípa ètò Jèhófà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Kì í ṣe nítorí káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè mọ ẹ̀kọ́ ìsìn nìkan la ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí kò ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ káwọn pẹ̀lú lè di ara ìjọ Kristẹni. (Sek. 8:23) Ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? ló dáa jù láti lò. Fún àwọn tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ẹ̀dà kan ìwé yìí, kó o sì gbà wọ́n níyànjú láti kà á. Láfikún sí i, máa fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti fi kọ́ wọn ní ohun kan nípa ètò Jèhófà.
2. Báwo lo ṣe lè rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé?
2 Ìpàdé Ìjọ: Ọ̀nà kan tó dáa jù táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi lè mọrírì ètò Ọlọ́run ni pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé ìjọ. (1 Kọ́r. 14:24, 25) Nítorí náà, o lè máa ṣàlàyé ìpàdé márààrún tá à ń ṣe lọ́sẹ̀ fún wọn níkọ̀ọ̀kan kí wọ́n bàa lè mọ̀ nípa àwọn ìpàdé wa. Jẹ́ kí wọ́n mọ àkòrí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ nípàdé lọ́sẹ̀ yẹn. Fi àpilẹ̀kọ tá a máa kà lọ́sẹ̀ náà nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti ibi tá a máa kà nínú ìwé tá à ń lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ hàn wọ́n. Ṣàlàyé fún wọn nípa Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Tó o bá ní iṣẹ́ nínú ìpàdé ilé ẹ̀kọ́, kò burú tó o bá fi dánra wò lójú wọn. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó o gbọ́ rí láwọn ìpàdé fún wọn. Fi àwòrán tó wà nínú àwọn ìwé wa hàn wọ́n kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fọkàn yàwòrán bí ìpàdé wa ṣe máa ń rí. Ọjọ́ tó o bá kọ́kọ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ni kó o ti fi ìpàdé lọ̀ wọ́n.
3. Kí làwọn nǹkan tó ń lọ nínú ètò yìí tó yẹ ká jíròrò?
3 Ìgbà tí ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣe pàtàkì bá ṣì wà lọ́nà ni kó o ti fi ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣàlàyé fún wọn nípa rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì bẹ́ẹ̀ sì lè jẹ́ Ìrántí Ikú Kristi, àpéjọ àyíká, àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àgbègbè, tàbí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Ṣàlàyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀ lé sáwọn ìbéèrè bíi, Kí nìdí tá a fi ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí ló fà á tó fi jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń pe ibi tá a ti ń ṣèpàdé? Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? Ọ̀nà wo la gbà ṣètò iṣẹ́ ìwàásù àti ìpínlẹ̀ ìwàásù? Báwo la ṣe ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́? Ibo lowó tí ètò yìí ń lò ti ń wá? Kí ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń ṣe láti bójú tó iṣẹ́ náà?
4, 5. Báwo làwọn fídíò wa ṣe lè jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọyì ètò Ọlọ́run?
4 Àwọn Fídíò Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́: A tún lè lo àwọn fídíò wa láti jẹ́ kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ nípa ètò Jèhófà tó jẹ́ àgbàyanu yìí. Fídíò tá a pè ní To the Ends of the Earth, fi bá a ṣe ń ṣíṣẹ ìwàásù káàkiri ayé hàn, bí ẹgbẹ́ ará kárí ayé ṣe rí ló wà nínú fídíò Our Whole Association of Brothers, nígbà tí èyí tá a pè ní United by Divine Teaching gbé ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yọ rekete. Nígbà tí obìnrin kan tó ti máa ń gba àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa mìíràn wo fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name, kò mọ̀gbà tó bú sẹ́kún. Tẹ́lẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ló fọkàn tán, àmọ́ lẹ́yìn tó wo fídíò yìí tán, ó wá yé e pé ó tún yẹ kóun fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó sì di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, òun náà lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
5 Tá a bá ń lo ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ́sẹ̀ pẹ̀lú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì tún ń lo àwọn irin iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́, ní kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀, a ó lè máa darí wọn wá sínú ètò kan ṣoṣo tí Jèhófà ń lò lónìí.