“Jẹ́ Aláìṣahun . . . Múra Tán Láti Ṣe Àjọpín”
1 Lọ́pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nítọ̀ọ́ni pé kí ó fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí pé kí wọ́n “máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín.” (1 Tím. 6:18) Pọ́ọ̀lù tún rán àwọn Kristẹni Hébérù létí pé kí wọ́n má ṣe gbàgbé “rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.” (Héb. 13:16) Kí ló dé tó fi kọ ìtọ́ni wọ̀nyí? Nítorí pé ó mọ̀ pé “ògo àti ọlá àti àlàáfíà” yóò wà “fún gbogbo ẹni tí ń ṣe ohun rere.”—Róòmù 2:10.
2 Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá, òun ni ó ni ohun gbogbo. (Ìṣí. 4:11) Dájúdájú, a mọrírì ohun tó ń fi àwọn nǹkan ìní rẹ̀ ṣe nítorí wa. Láìka ti pé ọ̀pọ̀ nínú aráyé ló ń hùwà àìmoore sí, Ẹni Títóbi Jù Lọ náà ń bá a nìṣó láti jẹ́ kí gbogbo ènìyàn máa jàǹfààní nínú àwọn ìpèsè ọlọ́làwọ́ rẹ̀ tí ń gbẹ́mìí ró. (Mát. 5:45) Ó tilẹ̀ fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n jù lọ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà, kí a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìfẹ́ tó ní sí wa sún wa láti fi hàn pé a moore nípa jíjẹ́ aláìṣahun sí àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa?—2 Kọ́r. 5:14, 15.
3 Kí Ni A Lè Ṣàjọpín? Kò sóhun tó dáa ju pé ká lo ohun ìní èyíkéyìí táa bá ní lọ́nà tó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Ó dájú pé a fẹ́ ṣètìlẹ́yìn nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí fún iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Dájúdájú, ìhìn rere náà ni ìṣúra níníyelórí jù lọ tí ẹnikẹ́ni lè ní, nítorí òun ni “agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà.” (Róòmù 1:16) Nípa lílo àkókò àti ohun ìní wa láìṣahun lóṣooṣù láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́ni, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣàjọpín ìṣúra tẹ̀mí yìí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.
4 Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an nígbà tí a bá ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan ìní. Ó ṣèlérí ìbùkún rẹpẹtẹ, ó sì tún rán wa létí pé: “Àwọn ohun tí ó níye lórí kì yóò ṣàǹfààní rárá ní ọjọ́ ìbínú kíkan, ṣùgbọ́n òdodo ni yóò dáni nídè lọ́wọ́ ikú.” (Òwe 11:4; 19:17) Fífi ohun ìní wa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àti kíkópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà jẹ́ ọ̀nà àgbàyanu tí a lè gbà fi hàn pé a kì í ṣahun, pé a múra tán láti ṣàjọpín.