Orin 113
A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Ọlọ́run Nítorí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Baba wa, a dúpẹ́ púpọ̀
Lọ́wọ́ rẹ nítorí Ọ̀rọ̀ rẹ táa ní!
O mí sí àwọn tó kọọ́ láti sọ èrò rẹ.
O ńfi Ìwé Mímọ́ rẹ tọ́ wa sọ́nà.
2. Ọ̀rọ̀ rẹ tó wà níbẹ̀ ń dùn mọ́ èèyàn.
Èèyàn bíi tiwa ni àwọn wòlíì rẹ.
Ìgbé ayé wọn ńkọ́ wa
nígbàgbọ́, ìgboyà.
Ọ̀rọ̀ rẹ ńta wá jí; ó ńtù wá lára.
3. Ọ̀rọ̀ rẹ lágbára, ó ń dọ́kàn wa,
Ó ń pín ọkàn àti ẹ̀mí níyà.
Ó sì mọ gbogbo ìpètepèrò ọkàn wa.
Ó ń tọ́ni sọ́nà, ó ńkọ́ni lọ́gbọ́n.
(Tún wo Sm. 119:16, 162; 2 Tím. 3:16; Ják. 5:17; 2 Pét. 1:21.)