Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣáwọn òbí méjèèjì lè ròyìn wákàtí tí wọ́n fi ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe bàbá ni láti tọ́ àwọn ọmọ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” síbẹ̀ àwọn òbí méjèèjì ló ń tọ́ wọn ní ti gidi. (Éfé. 6:4) Bíbélì gba àwọn ọmọ níyànjú pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Pàtàkì lára àwọn nǹkan táwọn òbí ń ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé.
Nígbà kan, òbí tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé pẹ̀lú àwọn ọmọ tí ò tíì ṣèrìbọmi nìkan ló máa ń ròyìn àkókò tí wọ́n fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí méjèèjì ló kọ́ àwọn ọmọ náà. A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé ètò yìí ti yí pa dà báyìí. Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí méjèèjì ló kọ́ àwọn ọmọ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àwọn méjèèjì lè ròyìn wákàtí kan lọ́sẹ̀. Ká sòótọ́, àwọn òbí máa ń lò ju wákàtí kan lọ lọ́sẹ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn. Gbogbo ìgbà làwọn òbí gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn ọmọ wọn. (Diu. 6:6-9) Síbẹ̀, ohun tá a bá ṣe lóde ẹ̀rí ló yẹ kó pọ̀ jù nínú ohun tá a bá ròyìn níparí oṣù. Nítorí náà, àwọn òbí ò gbọ́dọ̀ ròyìn ju wákàtí kan lọ lọ́sẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kódà bí àkókò tí wọ́n fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ju wákàtí kan lọ tàbí tí wọ́n bá ṣe é ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀ tàbí tí wọ́n bá darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́ a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé tóṣù bá parí, ọ̀kan lára àwọn òbí yìí ló máa ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lóṣù àti ìpadàbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan láwọn ọ̀sẹ̀ tí wọ́n fi bá àwọn ọmọ wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́.